Ìrètí Wo Ló Wà Fáwọn Táa Fẹ́ràn Tí Wọ́n Ti Kú?
Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn ni ọkùnrin náà, Jóòbù, ti béèrè pé: “Bi enia ba kú yio si tun yè bi?” (Jóòbù 14:14, Bibeli Mimọ) Bóyá ìwọ náà tilẹ̀ ti ṣe kàyéfì nípa èyí rí. Báwo ni yóò ṣe rí lára rẹ bí o bá mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí o tún wà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn tóo fẹ́ràn, lórí ilẹ̀ ayé níhìn-ín gan-an, lábẹ́ àwọn ipò tó mìnrìngìndìn?
Ó dára, Bíbélì ṣèlérí pé: “Àwọn òkú rẹ yóò wà láàyè. . . . Wọn yóò dìde.” Bíbélì sì tún sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Aísáyà 26:19; Sáàmù 37:29.
Láti ní ìgbọ́kànlé gidi nínú irú àwọn ìlérí bẹ́ẹ̀, a ní láti dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì kan: Èé ṣe tí ènìyàn fi ń kú? Ibo ni àwọn òkú wà? Báwo ni a sì ṣe lè ní ìdánilójú pé wọ́n tún lè padà wà láàyè?
Ikú, àti Ohun Tí Ń Ṣẹlẹ̀ Nígbà Tí A Bá Kú
Bíbélì mú un ṣe kedere pé Ọlọ́run kò pète ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ pé kí àwọn ènìyàn máa kú. Ó dá tọkọtaya kìíní, Ádámù àti Éfà, ó sì fi wọ́n sínú párádísè ilẹ̀ ayé kan tí a ń pè ní Édẹ́nì, ó sì fún wọn ní ìtọ́ni pé kí wọ́n bí àwọn ọmọ kí wọ́n sì mú Párádísè ibùgbé wọn gbòòrò yíká ilẹ̀ ayé. Wọn yóò kú kìkì bí wọ́n bá ṣàìgbọràn sí àwọn ìtọ́ni rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:15-17.
Bí wọn kò ti mọrírì inú rere Ọlọ́run, Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn, wọ́n sì ní láti fojú winá àbájáde rẹ̀ tí Ọlọ́run ti sọ ṣáájú. Ọlọ́run sọ fún Ádámù pé: “Ìwọ yóò . . . padà sí ilẹ̀, nítorí láti inú rẹ̀ ni a ti mú ọ jáde. Nítorí ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Kí a tó dá Ádámù, Ádámù kò sí; ó jẹ́ erùpẹ̀. Nítorí pé Ádámù ṣàìgbọràn, tàbí pé ó dẹ́ṣẹ̀, Ọlọ́run dá a lẹ́jọ́ pé kí ó padà sí ekuru, sínú ipò àìsí.
Nípa báyìí, ikú jẹ́ àìsí ìwàláàyè. Bíbélì fi ìyàtọ̀ tó wà láàárín wọn hàn, ó sọ pé: “Nítorí owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun.” (Róòmù 6:23) Bíbélì fi hàn pé ikú jẹ́ ipò àìmọ̀kan rárá nígbà tó wí pé: “Nítorí àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Nígbà tí ènìyàn kan bá kú, Bíbélì ṣàlàyé pé: “Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.”—Sáàmù 146:3, 4.
Ṣùgbọ́n, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ádámù àti Éfà nìkan ni ó ṣàìgbọràn sí àṣẹ náà ní Édẹ́nì, èé ṣe tí gbogbo wa fi ń kú? Ó jẹ́ nítorí pé gbogbo wa ni a bí lẹ́yìn ìgbà tí Ádámù ṣàìgbọràn, nítorí èyí gbogbo wa jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú látọ̀dọ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti ṣàlàyé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan [Ádámù] wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.”—Róòmù 5:12; Jóòbù 14:4.
Síbẹ̀ ẹnì kan lè béèrè pé: ‘Ṣáwọn èèyàn ò ní ọkàn tí kò lè kú, tí ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn ikú ni?’ Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti fi èyí kọ́ni, tí wọ́n tiẹ̀ ń sọ pé ikú jẹ́ ojú ọ̀nà kan sí ìgbésí ayé mìíràn. Ṣùgbọ́n irú èrò bẹ́ẹ̀ kò tinú Bíbélì wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi kọ́ni pé ìwọ jẹ́ ọkàn, pé ọkàn rẹ ni ìwọ alára, pẹ̀lú gbogbo àwọn ànímọ́ rẹ ní ti ara àti ti èrò orí. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7; Jeremáyà 2:34; Òwe 2:10) Bákan náà, Bíbélì sọ pé: “Ọkàn tí ń dẹ́ṣẹ̀—òun gan-an ni yóò kú.” (Ìsíkíẹ́lì 18:4) Kò sí ibì kankan tí Bíbélì ti fi kọ́ni pé ènìyàn ní ọkàn tí kò lè kú, tí ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn ikú ara.
Bí Àwọn Ènìyàn Ṣe Lè Wà Láàyè Lẹ́ẹ̀kan Sí I
Lẹ́yìn tí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ti wọnú ayé, Ọlọ́run fi hàn kedere pé ète òun ni pé kí á mú àwọn òkú padà wá sí ìyè nípasẹ̀ àjíǹde. Nípa báyìí, Bíbélì ṣàlàyé pé: “Ábúráhámù . . . ṣírò pé Ọlọ́run lè gbé [Ísákì ọmọkùnrin òun] dìde, àní kúrò nínú òkú.” (Hébérù 11:17-19) Ẹ̀tàn kọ́ ni Ábúráhámù gbọ́kàn lé, nítorí Bíbélì sọ nípa Olódùmarè pé: “Kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè, nítorí gbogbo wọn wà láàyè lójú rẹ̀.”—Lúùkù 20:37, 38.
Bẹ́ẹ̀ ni, kì í ṣe pé Ọlọ́run Olódùmarè ní agbára láti jí àwọn ènìyàn tí òun bá fẹ́ dìde nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Jésù Kristi fúnra rẹ̀ sọ pé: “Kí ẹnu má yà yín sí èyí, nítorí pé wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.”—Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15.
Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Jésù sọ èyí, ló bá pàdé ọ̀wọ́ àwọn aṣọ̀fọ̀ tí ń jáde bọ̀ láti inú ìlú Ísírẹ́lì kan tí ń jẹ́ Náínì. Ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó kú jẹ́ ọmọ kan ṣoṣo tí obìnrin opo kan bí. Nígbà tí Jésù rí ẹ̀dùn ọkàn obìnrin náà pé ó dé góńgó, àánú ṣe é lọ́pọ̀lọpọ̀. Nítorí náà, ó pàṣẹ fún òkú náà pé: “Ọ̀dọ́kùnrin, mo wí fún ọ, Dìde!” Ọkùnrin náà sì dìde jókòó, Jésù sì fi í fún ìyá rẹ̀.—Lúùkù 7:11-17.
Bó ti rí nínú ọ̀ràn ti opó yẹn, bẹ́ẹ̀ náà ni ayọ̀ ńláǹlà wà pẹ̀lú nígbà tí Jésù ṣèbẹ̀wò sí ilé Jáírù, alága sínágọ́gù àwọn Júù. Ọmọbìnrin rẹ̀ ọlọ́dún méjìlá ti kú. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù dé ilé Jáírù, ó lọ sí ọ̀dọ̀ ọmọ tó ti kú náà, ó sì sọ pé: “Ọmọdébìnrin, dìde!” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀!—Lúùkù 8:40-56.
Lẹ́yìn náà, Lásárù ọ̀rẹ́ Jésù kú. Nígbà tí Jésù dé ilé Lásárù, ó ti tó ọjọ́ mẹ́rin tó ti kú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kó ẹ̀dùn ọkàn bá Màtá arábìnrin rẹ̀ gidigidi, Màtá sọ̀rọ̀ ìrètí jáde, wí pé: “Mo mọ̀ pé yóò dìde nínú àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn.” Ṣùgbọ́n Jésù lọ síbi ibojì náà, ó pàṣẹ pé kí wọ́n gbé òkúta kúrò, ó sì kígbe pé: “Lásárù, jáde wá!” Òun sì jáde!—Jòhánù 11:11-44.
Wá ronú nípa èyí ná: Kí ni ipò tí Lásárù wà láàárín ọjọ́ mẹ́rin tó fi jẹ́ òkú yẹn? Lásárù kò sọ ohunkóhun nípa wíwà ní ọ̀run onígbàádùn kẹlẹlẹ kan tàbí nípa ọ̀run àpáàdì kan tí a ti ń dáni lóró, èyí tí ì bá sọ bó bá jẹ́ pé ó lọ síbẹ̀. Rárá, Lásárù wà láìmọ nǹkan kan rárá nínú ikú, bí ì bá sì ṣe wà nìyẹn títí di “àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn” ká ní Jésù kò dá ìwàláàyè rẹ̀ padà nígbà yẹn.
Òtítọ́ ni pé àwọn iṣẹ́ ìyanu Jésù wọ̀nyí kàn ṣàǹfààní fún ìgbà díẹ̀ ni, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé gbogbo àwọn tó jí dìde ló padà kú lẹ́yìn náà. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó fi ẹ̀rí hàn ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbàá [1,900] ọdún sẹ́yìn pé nípasẹ̀ agbára Ọlọ́run, àwọn okú lè wà láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i ní tòótọ́! Nítorí náà nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, Jésù fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run hàn lọ́nà kékeré.
Nígbà tí Ẹni Tí O Fẹ́ràn Bá Kú
Nígbà tí ọ̀tá náà, ikú, bá ṣọṣẹ́, ẹ̀dùn ọkàn tó ga lè bá ẹ, àní bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ní ìrètí àjíǹde. Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ pé ìyàwó rẹ̀ yóò tún padà wà láàyè, síbẹ̀ a kà á pé “Ábúráhámù sì wọlé láti pohùn réré ẹkún Sárà àti láti sunkún lórí rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 23:2) Nípa ti Jésù ńkọ́? Nígbà tí Lásárù kú, Jésù “kérora nínú ẹ̀mí, ó sì dààmú,” ní kété lẹ́yìn náà, ó sì “bẹ̀rẹ̀ sí da omijé.” (Jòhánù 11:33, 35) Nítorí náà, nígbà tí ẹnì kan tí o fẹ́ràn bá kú, kò fi hàn pé o jẹ́ aláìlera bí o bá sunkún.
Nígbà tí ọmọ kan bá kú, kì í ṣe ohun tó rọrùn fún ìyá ọmọ náà. Fún ìdí yìí, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀dùn ọkàn kíkorò tí ìyá kan lè ní. (2 Àwọn Ọba 4:27) Ní tòótọ́, ó jẹ́ ohun tó ṣòro fún baba tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ bákan náà. Dáfídì Ọba kédàárò nígbà tí ọmọkùnrin rẹ̀, Ábúsálómù, kú pé: “Áà ì bá ṣe pé mo ti kú, èmi fúnra mi, dípò ìwọ.”—2 Sámúẹ́lì 18:33.
Àmọ́ ṣá o, nítorí pé o ní ìgbọ́kànlé nínú àjíǹde, ìkárísọ rẹ kì yóò jẹ́ aláìdabọ̀. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí, ìwọ kì yóò “kárísọ gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù tí kò ní ìrètí.” (1 Tẹsalóníkà 4:13) Kàkà bẹ́ẹ̀, ìwọ lè sún mọ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ nínú àdúrà, Bíbélì sì ṣèlérí pé “òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.”—Sáàmù 55:22.
Bí a kò bá fi hàn pé ó yàtọ̀, gbogbo ẹsẹ Bíbélì tí a fà yọ wá láti inú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.