ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w12 11/1 ojú ìwé 6-7
  • Ìbéèrè Kejì: Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ sí Mi Nígbà Tí Mo Bá Kú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Kejì: Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ sí Mi Nígbà Tí Mo Bá Kú?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ibo Làwọn Òkú Wà?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ibo Là Ń Lọ Tá A Bá Kú?
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • “A Ti Gbé Ikú Mì Títí Láé”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ìrètí Wo Ló Wà Fáwọn Táa Fẹ́ràn Tí Wọ́n Ti Kú?
    Ìrètí Wo Ló Wà Fáwọn Táa Fẹ́ràn Tí Wọ́n Ti Kú?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
w12 11/1 ojú ìwé 6-7

Ìbéèrè Kejì: Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ sí Mi Nígbà Tí Mo Bá Kú?

NÍGBÀ tí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Roman ṣì wà lọ́mọdé, ọkọ̀ pa ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ kan. Ó sọ pé: “Ikú ọ̀rẹ́ mi yìí dùn mí gan-an. Lẹ́yìn ìjàǹbá náà, ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi ń ronú nípa ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ séèyàn nígbà téèyàn bá kú.”

Kí ló ń jẹ́ káwọn èèyàn béèrè irú ìbéèrè yìí?

Ikú jẹ́ ohun tí kì í bá àwa èèyàn lára mu. Bó ti wù ká dàgbà tó, a kì í sábà fẹ́ kú. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn lẹ́yìn tí wọ́n bá kú.

Kí ni àwọn kan sọ nípa ìbéèrè yìí?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé tí a bá kú nǹkan kan wà lára wa tí kì í kú. Wọ́n gbà gbọ́ pé táwọn èèyàn rere bá kú wọn yóò lọ sí ọ̀run, àmọ́ àwọn èèyàn burúkú yóò máa joró títí láé nínú ọ̀run àpáàdì nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Àwọn míì sì gbà pé téèyàn bá ti kú onítọ̀hún kò sí mọ́ nìyẹn, pé aráyé a sì gbàgbé rẹ̀ tó bá yá.

Kí làwọn ìdáhùn yìí ń fi hàn?

Ohun tí ìdáhùn àkọ́kọ́ ń fi hàn ni pé téèyàn bá ṣaláìsí ó kàn papò dà lásán ni. Ìdáhùn kejì sì túmọ̀ sí pé kò sídìí kan gúnmọ́ tí a fi wà láàyè. Àwọn tó máa ń ronú pé kò sídìí kan gúnmọ́ tí a fi wà láàyè máa ń gbà pé kádàrá ni gbogbo nǹkan. Irú wọn ló máa ń dáṣà pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí a sì máa mu, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú.”—1 Kọ́ríńtì 15:32.

Kí ni Bíbélì fi kọ́ni?

Bíbélì kò sọ pé tí a bá kú nǹkan kan wà lára wa tí kì í kú. Ọlọ́run mí sí Sólómọ́nì láti kọ̀wé pé: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Àwọn tí “kò mọ nǹkan kan rárá” kò mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní àyíká wọn mọ́. Wọn kò lè ṣe ohunkóhun, wọn kò sì mọ nǹkan kan lára mọ́. Torí náà òkú kò lè ran alààyè lọ́wọ́, wọn kò sì lè pa alààyè lára.

Ète Ọlọ́run fún àwa èèyàn yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ, pé Ọlọ́run dá ikú mọ́ wa. Kì í ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run rárá pé kí àwa èèyàn máa kú. Ṣe ni ó dá Ádámù lọ́nà tí á fi lè máa wà láàyè lọ títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Ìgbà tí Ọlọ́run ń sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Ádámù tó bá ṣàìgbọràn nìkan ni Ọlọ́run mẹ́nu kan ikú. Ó sọ pé Ádámù kò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi kan, ó sì wá kìlọ̀ fún un pé tó bá jẹ̀ ẹ́ “dájúdájú . . . yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Ká ní Ádámù àti Éfà kò ṣàìgbọràn ni, àwọn àti gbogbo àtọmọdọ́mọ wọn tó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ì bá wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.

Ṣe ni Ádámù mọ̀ọ́mọ̀ má tẹ̀ lé ìkìlọ̀ Ọlọ́run. Torí náà ẹ̀ṣẹ̀ ló dá nígbà tó ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ìdí nìyẹn tó fi kú. (Róòmù 6:23) Nígbà tí Ádámù kú, kò sí nǹkan kan lára rẹ̀ tó tún ṣì wà láàyè, tí kò kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí Ádámù ṣe kú, kò sí níbikíbi mọ́. Ohun tí Ọlọ́run sọ fún Ádámù ni pé: “Inú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò ti máa jẹ oúnjẹ títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí láti inú rẹ̀ ni a ti mú ọ jáde. Nítorí ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Nígbà tó sì jẹ́ pé Ádámù ni baba ńlá gbogbo ìran èèyàn, ọ̀dọ̀ rẹ̀ la ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.—Róòmù 5:12.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ádámù mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn, Ọlọ́run ṣì máa ṣe ohun tó ní lọ́kàn, ìyẹn láti mú kí àwọn èèyàn pípé tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù kún ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; Aísáyà 55:11) Láìpẹ́ Jèhófà máa jí èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tó ti kú dìde. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbà yẹn, ó ní: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”—Ìṣe 24:15.

Ọkùnrin tó ń jẹ́ Roman tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó wá mọ ohun tó sọ nípa ikú àti irú ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run jẹ́. Àwọn ohun tí ó wá mọ̀ yìí ní ipa tó jinlẹ̀ lórí rẹ̀. Ka ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ lójú ìwé 11 nínú ìwé ìròyìn yìí.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ séèyàn nígbà téèyàn bá kú, wo orí 6 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? O lè rí ìwé yìí wà jáde lórí ìkànnì wa, ìyẹn www.jw.org

Kí Ni Jésù Sọ Nípa Ikú?

Nígbà tí Jésù wà láyé, kò gbà pé òótọ́ ni àwọn aṣáájú ìsìn tí wọ́n sọ pé kò sí àjíǹde ń sọ. (Lúùkù 20:27) Kò sì kọ́ni pé téèyàn bá kú, nǹkan kan wà lára rẹ̀ tí kì í kú. Ohun tí Jésù kọ́ni rèé:

Ikú dà bí ìgbà tí èèyàn bá sùn. Nígbà tí Lásárù ọ̀rẹ́ Jésù kú, Jésù ní: “Lásárù ọ̀rẹ́ wa ti lọ sinmi, ṣùgbọ́n mo ń rìnrìn àjò lọ sí ibẹ̀ láti jí i kúrò lójú oorun.” Ohun tí Jésù ń sọ kò yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n wá fèsì pé: “Olúwa, bí ó bá jẹ́ pé ó lọ sinmi ni, ara rẹ̀ yóò dá.” Bíbélì ṣàlàyé pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, Jésù sọ̀rọ̀ nípa ikú rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n lérò pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa sísinmi nínú oorun. Nítorí náà, ní àkókò yẹn, Jésù wí fún wọn láìfọ̀rọ̀-bọpo-bọyọ̀ pé: ‘Lásárù ti kú.’” —Jòhánù 11:11-14.

Àwọn òkú máa jíǹde. Nígbà tí Jésù dé ìlú tí Lásárù wà, ó tu Màtá arábìnrin Lásárù nínú pé: “Arákùnrin rẹ yóò dìde.” Lẹ́yìn náà ó wá ṣe ìlérí ìyanu yìí, ó ní: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè. Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè.” Ìlérí tí Jésù ṣe yìí kì í ṣe ọ̀rọ̀ orí ahọ́n lásán o. Torí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti di ọjọ́ kẹrin tí Lásárù ti kú, Jésù jí i dìde níṣojú ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà níbẹ̀. —Jòhánù 11:23, 25, 38-45.

Nínú ìran tí Jésù fi han àpọ́sítélì Jòhánù, Jésù tún ṣèlérí pé àwọn òkú máa jíǹde. Ó sọ ọ́ lọ́nà àpèjúwe pé lọ́jọ́ iwájú, ikú yóò tú àwọn òkú sílẹ̀.—Ìṣípayá 20:13.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́