ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • gt orí 18
  • Johanu Ńpẹ̀dín, Jesu Nbisii

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Johanu Ńpẹ̀dín, Jesu Nbisii
  • Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jòhánù Ń Dín Kù, Àmọ́ Jésù Ń Pọ̀ Sí I
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Johanu Ha Ṣàìní Ìgbàgbọ́ Bí?
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Jòhánù Arinibọmi—Àpẹẹrẹ Ẹnì Kan Tó Láyọ̀ Láìka Ìyípadà Tó Dé Bá A
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Jòhánù Fẹ́ Gbọ́rọ̀ Látẹnu Jésù
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
Àwọn Míì
Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
gt orí 18

Orí 18

Johanu Ńpẹ̀dín, Jesu Nbisii

TẸLE Irekọja nigba ìrúwé 30 C.E., Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ fi Jerusalẹmu silẹ. Bi o ti wu ki o ri, wọn kò pada sí ile wọn ni Galili ṣugbọn wọn lọ si agbegbe Judia, nibi ti wọn ti nṣe baptisi. Johanu Arinibọmi ti nṣe iṣẹ kan naa fun nǹkan bii ọdun kan nisinsinyi, oun sì ní awọn ọmọ ẹhin ti ndarapọ pẹlu rẹ̀ sibẹsibẹ.

Nitootọ, Jesu kò ṣe baptisi eyikeyii funni tìkáraarẹ̀, ṣugbọn awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ nṣe e labẹ itọsọna rẹ̀. Baptisi wọn ni ijẹpataki kan naa bi eyi ti Johanu nṣe, eyi ti nṣe ami ironupiwada ẹ̀ṣẹ̀ Juu kan lodisi majẹmu Òfin Ọlọrun. Bi o ti wu ki o ri, lẹhin ajinde rẹ̀, Jesu fi itọni fun awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ lati ṣe baptisi ti o ní ijẹpataki ọ̀tọ̀ kan. Baptisi Kristẹni lonii jẹ apẹẹrẹ iyasimimọ ẹnikan lati sin Jehofa Ọlọrun.

Ní ibẹrẹ iṣẹ ojiṣẹ Jesu yii, bi o ti wu ki o ri, oun ati Johanu, bi wọn tilẹ nṣiṣẹ lọtọọtọ, nkọ wọn sì nṣe baptisi fun awọn ti o ronupiwada. Ṣugbọn awọn ọmọ ẹhin Johanu bẹrẹ sii jowú wọn sì nṣe awawi fun un nitori Jesu: “Rabi, . . . wòó, oun nbaptisi, gbogbo eniyan sì ńtọ̀ ọ́ wá.”

Kaka ki o jowú, Johanu yọ̀ ninu aṣeyọri Jesu o sì nfẹ ki awọn ọmọ ẹhin oun maa yọ̀. O rán wọn leti pe: “Ẹyin tikaraayin jẹrii mi, pe mo wipe, Emi kii ṣe Kristi naa, ṣugbọn pe a rán mi ṣiwaju rẹ̀.” Lẹhin naa o lo akawe ti o fanimọra kan: “Ẹni ti o ba ni iyawo ni ọkọ iyawo. Ṣugbọn ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo ti o duro ti o sì ńgbóhùn rẹ̀, ó yọ̀ gidigidi nitori ohùn ọkọ iyawo. Nitori naa ayọ̀ mi yii di kíkún.”

Johanu, gẹgẹ bi ọ̀rẹ́ Ọkọ iyawo, yọ̀ ni nǹkan bii oṣu mẹfa sẹhin nigba ti o fi awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ han Jesu. Awọn kan ninu wọn di mẹmba ọjọ iwaju ti ẹgbẹ́ iyawo Kristi ti ọrun ti yoo ni ninu apapọ awọn Kristẹni ti a fi òróró yàn. Johanu fẹ ki awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ isinsinyi bakan naa tẹle Jesu, niwọn bi ète rẹ̀ ni lati tún ọna ṣe fun aṣeyọri iṣẹ-ojiṣẹ Kristi. Gẹgẹ bi Johanu Arinibọmi ti ṣalaye: “Oun kò lè ṣaima pọ̀ sí i, ṣugbọn emi kò lè ṣaima rẹ̀hìn.”

Johanu ọmọ ẹhin ti Jesu ṣẹ̀ṣẹ̀ ní, ẹni ti o ti jẹ ọmọ ẹhin Johanu Arinibọmi tẹlẹri, kọ nipa ipilẹṣẹ Jesu ati ipa pataki ti Oun kó ninu igbala araye, ni wiwi pe: “Ẹni ti o ti ọ̀run wá ju gbogbo eniyan lọ. . . . Baba fẹ́ Ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo lé e lọwọ. Ẹni ti o ba gba ọmọ gbọ́, o ní iye ainipẹkun: ẹni tí kò bá sì gba ọmọ gbọ́, ki yoo rí iye; ṣugbọn ibinu Ọlọrun nbẹ lori rẹ̀.”

Kò pẹ́ pupọ lẹhin ti Johanu Arinibọmi sọrọ nipa ìpẹ̀dìn igbokegbodo ara rẹ̀, tí Ọba Hẹrọdu fi àṣẹ ọba mú un. Hẹrọdu ti mú Hẹrọdiasi, iyawo Filipi arakunrin rẹ̀, gẹgẹ bi tirẹ̀, nigba ti Johanu sì ṣipaya awọn igbesẹ rẹ̀ ní gbangba gẹgẹ bi ohun tí kò yẹ, Hẹrọdu mú kí a fi i sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n. Nigba ti Jesu gbọ́ pe a ti fi àṣẹ ọba mu Johanu, oun fi Judia silẹ pẹlu awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ lọ sí Galili. Johanu 3:22–4:3; Iṣe 19:4; Matiu 28:19; 2 Kọrinti 11:2; Maaku 1:14; 6:17-20.

▪ Ki ni ijẹpataki awọn baptisi ti a ṣe labẹ itọsọna Jesu ṣaaju ajinde rẹ̀? Ati lẹhin ajinde rẹ̀?

▪ Bawo ni Johanu ṣe fihan pe àwáwí awọn ọmọ ẹhin rẹ̀ jẹ́ alaiyẹ?

▪ Eeṣe ti a fi sọ Johanu sí ọgbà ẹ̀wọ̀n?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́