Apa 10
Ayé Titun Iyanu naa ti Ọlọrun Ṣe
1, 2. Ki ni yoo ṣẹlẹ lẹhin ogun aṣèwẹ̀nùmọ́ ti Armageddoni?
LẸHIN ogun aṣèwẹ̀nùmọ́ ti Ọlọrun ni Armageddoni, ki ni nigba naa? Nigba naa ni sanmani ologo yoo bẹrẹ. Awọn olula Armageddoni ja, niti pe wọn ti fi iduroṣinṣin wọn han si akoso Ọlọrun ṣaaju, ni a o gbà wọle sinu aye titun naa. Ẹ wo iru sanmani itan titun amunilaraya gágá ti iyẹn yoo jẹ bi awọn anfaani agbayanu ti ń ṣan jade lati ọdọ Ọlọrun wa si ọdọ idile eniyan!
2 Labẹ idari Ijọba Ọlọrun, awọn olulaaja yoo bẹrẹ sii mu paradise kan gberu. Awọn okun wọn ni a o yasọtọ fun awọn ilepa alaimọtara ẹni nikan ti yoo ṣanfaani fun gbogbo awọn ti wọn walaaye nigba naa. Ilẹ̀-ayé yoo bẹrẹ sii di eyi ti a yipada si ibugbe ẹlẹwa, alalaafia, afunni-ni-itẹlọrun kan fun araye.
Iṣododo Dipo Iwa Buburu
3. Itura oju ẹsẹ wo ni a o niriiri rẹ̀ kete lẹhin Armageddoni?
3 Gbogbo eyi ni a o mu ki o ṣeeṣe nipasẹ iparun ayé Satani. Ki yoo tun si awọn isin eke, eto-igbekalẹ ẹgbẹ-oun-ọgba, tabi awọn ijọba apinni-niya mọ. Ki yoo tun si awọn igbekeyide ti Satani lati tan awọn eniyan jẹ mọ́; gbogbo awọn eto-ẹgbẹ ti ń gbe e jade ni yoo wọlẹ̀ pẹlu eto-igbekalẹ ti Satani. Ròó wò ná: gbogbo ayika ayé olóró ti Satani ni a o gbá kuro! Ẹ wo iru itura ti eyi yoo jẹ!
4. Ṣapejuwe iyipada ninu ikọnilẹkọọ ti yoo ṣẹlẹ.
4 Nigba naa awọn àbá-ero aṣeparun ti akoso eniyan ni ikọnilẹkọọ ti ń gbeniro lati ọdọ Ọlọrun yoo rọpo rẹ̀. “A o si kọ gbogbo awọn ọmọ rẹ lati ọdọ Oluwa [“Jehofa,” NW] wá.” (Isaiah 54:13) Pẹlu awọn itọni ti ń gbeniro wọnyii lọdọọdun, “ayé yoo kun fun imọ Oluwa [“Jehofa,” NW] gẹgẹ bi omi ti bo okun.” (Isaiah 11:9) Awọn eniyan ki yoo tun kọ ohun ti o buru mọ, ṣugbọn “awọn ti ń bẹ ni ayé yoo kọ ododo.” (Isaiah 26:9) Awọn ironu ati iṣesi ti ń gbeniro ni yoo gbodekan.—Iṣe 17:31; Filippi 4:8.
5. Ki ni yoo ṣẹlẹ si gbogbo iwa buburu ati awọn eniyan buburu?
5 Nipa bayii, ki yoo tun si iṣikapaniyan, iwa ipa, ifipabanilopọ, ole jija, tabi iwa ọdaran eyikeyii miiran mọ́. Ki yoo si ẹni ti yoo tun jiya nitori iṣẹ buburu awọn ẹlomiran. Owe 10:30 sọ pe: “A ki yoo ṣi olododo nipo lae; ṣugbọn eniyan buburu ki yoo gbe ilẹ̀-ayé.”
Ilera Pipe Ni A Mu Padabọsipo
6, 7. (a) Otitọ igbesi-aye lilekoko wo ni akoso Ijọba yoo mu wá si opin? (b) Bawo ni Jesu ṣe ṣaṣefihan eyi nigba ti o wà lori ilẹ̀-ayé?
6 Ninu ayé titun, atunṣe ti gbogbo abajade buburu ti ìṣọ̀tẹ̀ ipilẹṣẹ yoo wà. Fun apẹẹrẹ, akoso Ijọba yoo mu aisan ati ọjọ ogbo kuro. Lonii, koda bi iwọ bá ń gbadun iwọnba ilera didara, otitọ lilekoko naa ni pe bi iwọ ti ń di agbalagba sii, oju rẹ yoo ṣe baibai, ehin rẹ a jẹrà, agbara ìgbọ́ran rẹ yoo dinku, awọ ara rẹ yoo hunjọ, awọn ẹ̀yà-eto inu ara rẹ yoo daṣẹ silẹ, titi tí iwọ yoo fi ku nikẹhin.
7 Bi o ti wu ki o ri, awọn abajade akó-dààmúbáni ti a jogun lati ọdọ awọn obi wa akọkọ yoo di ohun atijọ laipẹ. Iwọ ha ranti ohun ti Jesu ṣaṣefihan rẹ̀ nipa ilera nigba ti o wa nihin in lori ilẹ̀-ayé bi? Bibeli ṣalaye pe: “Ọpọ eniyan si tọ̀ ọ́ wá ti awọn ti amọkun, afọju, odi, ati arọ, ati ọ̀pọ̀ awọn miiran, wọn si sọ̀ wọn kalẹ lẹba ẹṣẹ Jesu, o si mu wọn larada: Tobẹẹ, ti ẹnu ya ijọ eniyan naa, nigba ti wọn ri ti odi ń fọhun, ti arọ ń di ọ̀tọ́tọ́, ti amọkun ń rìn, ti afọju si ń riran.”—Matteu 15:30, 31.
8, 9. Ṣapejuwe ayọ ti yoo wá ninu aye titun naa nigba ti ilera pipe bá di eyi ti a mu padabọsipo.
8 Iru ayọ ńláǹlà wo ni yoo de ninu ayé titun bi a ti mu awọn okunrun wa kuro! Ijiya ti ń jẹyọ lati inu ainilera ti o dara ki yoo tun dá wa loro mọ lae. “Ki yoo si olugbe ibẹ ti yoo wi pe: ‘Aisan ń ṣe mi.’” “Nigba naa ni oju awọn afọju yoo là, eti awọn aditi yoo si ṣi. Nigba naa ni awọn arọ yoo fò bi agbọnrin, ati ahọn odi yoo kọrin.”—Isaiah 33:24, NW; 35:5, 6.
9 Ki yoo ha jẹ ohun ti ń munilaraya gágá lati ji laraarọ ki o si wá rii pe iwọ ń gbadun ilera jíjípépé nisinsinyi bi? Ki yoo ha mu itẹlọrun ba awọn àgbà ọlọjọ ori lati mọ̀ pe awọn ni a ti dá pada si ilera pọ́n-ún-pọ́n-ún ti ewe ni kikun tí wọn yoo si de ijẹpipe tí Adamu ati Efa gbadun ni ipilẹṣẹ bi? Ileri Bibeli ni pe: “Ara rẹ̀ yoo jà yọ̀yọ̀ ju ti ọmọ kekere, yoo si tun pada si ọjọ igba ewe rẹ̀.” (Jobu 33:25) Iru idunnu wo ni yoo jẹ lati ju awọn awò oju, aranṣe fun igbọran, ọpa-ìkẹ́sẹ̀ awọn arọ, kẹkẹ awọn arọ, ati awọn oogun danu! Awọn ile iwosan, dokita, ati olutọju ehin ni a ki yoo nilo mọ́ lae.
10. Ki ni yoo ṣẹlẹ si iku?
10 Awọn eniyan ti wọn ń gbadun iru ilera ti o jípépé bẹẹ ki yoo fẹ lati ku. Wọn ki yoo si ni lati ṣe bẹẹ, nitori pe araye ki yoo tun wà ninu ìdìmú aipe ati iku ajogunba. Kristi “nilati ṣakoso bi ọba titi Ọlọrun yoo fi fi gbogbo ọta sabẹ ẹsẹ̀ rẹ̀. Bi ọ̀tá ikẹhin, a o sọ iku di asán.” “Ẹbun ọ̀fẹ́ Ọlọrun ni iye ti kò nipẹkun.”—1 Korinti 15:25, 26, NW; Romu 6:23; wo Isaiah 25:8 bakan naa.
11. Bawo ni Ìfihàn ṣe ṣe akopọ awọn anfaani ayé titun naa?
11 Ni ṣiṣe akopọ awọn anfaani ti yoo ṣàn jade wá lati ọdọ Ọlọrun ti o bikita fun idile eniyan ninu Paradise, iwe ti o kẹhin Bibeli sọ pe: “Ọlọrun yoo si nu omije gbogbo nù kuro ni oju wọn; kì yoo si si iku mọ́ tabi ọfọ, tabi ẹkun, bẹẹni ki yoo si irora mọ́: Nitori pe ohun atijọ ti kọja lọ.”—Ìfihàn 21:3, 4.
Awọn Oku Padabọ
12. Bawo ni Jesu ṣe ṣaṣefihan agbara ajinde ti Ọlọrun fi fun un?
12 Jesu ṣe ju wiwo awọn alaisan sàn ati mimu arọ larada. Oun tun mu awọn eniyan pada wa lati inu ibojì. Oun nipa bayii ṣaṣefihan agbara agbayanu ti ajinde ti Ọlọrun ti fi fun un. Iwọ ha ranti ìgbà ti Jesu wa si ile ọkunrin kan ti ọmọbinrin rẹ̀ ti ku? Jesu sọ fun ọmọbinrin ti o ti ku naa pe: “Ọmọbinrin, mo wi fun ọ, Dide.” Pẹlu abajade wo? “Lọgan ọmọbinrin naa si dide, o si ń rìn.” Ni riri iyẹn, “ẹnu si ya” awọn eniyan ti wọn wà nibẹ “gidigidi.” Wọn fẹrẹẹ má lè pa ayọ wọn mọra!—Marku 5:41, 42; wo Luku 7:11-16; Johannu 11:1-45 bakan naa.
13. Iru awọn eniyan wo ni a o ji dide?
13 Ninu ayé titun naa, “ajinde oku ń bọ̀, ati ti oloootọ ati ti alaiṣootọ.” (Iṣe 24:15) Ni akoko naa Jesu yoo lo agbara rẹ̀ ti Ọlọrun fi fun un lati ji awọn oku dide nitori pe, gẹgẹ bi o ti sọ ọ, “Emi ni ajinde ati iye: ẹni ti o bá gbà mi gbọ́, bi o tilẹ kú, yoo yè.” (Johannu 11:25) Oun tun sọ pe: “Gbogbo awọn ti o wà ni isà okú [ninu iranti Ọlọrun] yoo gbọ́ ohùn rẹ̀ [Jesu]. Wọn yoo si jade wá.”—Johannu 5:28, 29.
14. Nitori pe iku kò ni si mọ, awọn nǹkan wo ni a o mu kuro?
14 Ayọ naa yoo pọ̀ jọjọ kárí-ayé nigba ti awujọ awọn oku eniyan kan tẹle omiran yoo maa pada wá si iye lati darapọ p̣ẹlu awọn ololufẹ wọn! Ki yoo tun si ààyè ikede iranti oku ninu awọn iwe irohin lati mu ibanujẹ bá awọn olulaaja. Kàkà bẹẹ, o ṣeeṣe pe odikeji rẹ̀ ni yoo wà: awọn ikede ti awọn ti a ṣẹṣẹ ji dide lati mu ayọ wá bá awọn ololufẹ wọn. Nitori naa kò si awọn ayẹyẹ isinku, itojọ gegere igi ìdáná ti a fi ń jo oku, ibi ifinasun oku, tabi itẹ́-oku mọ́!
Ayé Alalaafia kan Nitootọ
15. Bawo ni a o ṣe wa rí otitọ asọtẹlẹ Mika lẹkun-un-rẹrẹ?
15 Alaafia tootọ ni apa gbogbo igbesi-aye ni a o ni iriri rẹ̀. Awọn ogun, awọn agbátẹrù ogun, ati ṣiṣe awọn ohun ija ogun yoo di ohun atijọ. Eeṣe? Nitori pe ifẹ-ọkan fun orilẹ-ede, ẹ̀yà, ati iran ẹni apinni-niya yoo ti poora. Nigba naa, ni ọna ti o kunrẹrẹ, “orilẹ-ede ki yoo gbe ida soke si orilẹ-ede, bẹẹni wọn ki yoo kọ ogun jija mọ.”—Mika 4:3.
16. Bawo ni Ọlọrun yoo ṣe ri sii pe awọn ogun ni kò ni ṣeeṣe mọ?
16 Eyi lè dabi ohun aṣeni-nikayeefi kan loju iwoye itan ogun onipakupa afẹ̀jẹ̀wẹ̀ leralera ti eniyan. Ṣugbọn iwọnyẹn ti wáyé nitori pe araye ti wà labẹ akoso eniyan ati ti ẹmi eṣu. Ninu ayé titun, labẹ akoso Ijọba, eyi ni ohun ti yoo ṣẹlẹ: “Ẹ wa wo iṣẹ Oluwa [“Jehofa,” NW] . . . O mu ọ̀tẹ̀ tan dé opin ilẹ̀-ayé; o ṣẹ́ ọrun, o si ke ọ̀kọ̀ meji; o si fi kẹkẹ ogun jona.”—Orin Dafidi 46:8, 9.
17, 18. Ninu ayé titun, ipo ibatan wo ni yoo wà laaarin eniyan ati awọn ẹranko?
17 Eniyan ati ẹranko yoo wà ni alaafia pẹlu, bi wọn ti wà ni Edeni. (Genesisi 1:28; 2:19) Ọlọrun wi pe: “Ni ọjọ naa ni emi o si fi awọn ẹranko igbẹ, ati ẹyẹ oju ọrun, ati ohun ti ń rakò lori ilẹ da majẹmu fun wọn . . . emi o si mu wọn dubulẹ ni ailewu.”—Hosea 2:18.
18 Bawo ni alaafia yẹn yoo ti gbooro to? “Ikooko pẹlu yoo maa ba ọdọ-agutan gbe pọ̀, kiniun yoo si dubulẹ pẹlu ọmọ ewurẹ; ati ọmọ maluu ati ọmọ kiniun ati ẹgbọ̀rọ̀ ẹran abọpa yoo maa gbe pọ̀; ọmọ kekere yoo si maa dà wọn.” Awọn ẹranko ki yoo tun halẹ ewu mọ eniyan tabi araawọn mọ́ lae. Koda “kiniun yoo jẹ koriko bi akọ maluu”!—Isaiah 11:6-9; 65:25.
A Yi Ilẹ̀-Ayé Pada Si Paradise Kan
19. A o yi ilẹ̀-ayé pada si ki ni?
19 Gbogbo ilẹ̀-ayé ni a o yipada si ibugbe paradise kan fun araye. Idi niyi ti Jesu fi lè ṣeleri fun ọkunrin kan ti o gba a gbọ pe: “Iwọ o wà pẹlu mi ni Paradise.” Bibeli wi pe: “Aginju ati ilẹ gbigbẹ yoo yọ̀ fun wọn; ijù yoo yọ̀, yoo si tanna bi lili. . . . nitori omi yoo tun jade ni aginju, ati iṣàn omi ni ijù.”—Luku 23:43; Isaiah 35:1, 6.
20. Eeṣe ti ebi ki yoo tun jẹ araye niya lae mọ?
20 Labẹ Ijọba Ọlọrun, ebi ki yoo tun jẹ araadọta ọkẹ niya mọ. ‘Ikunwọ ọkà ni yoo maa wà lori ilẹ̀, ati lori awọn oke ni akunwọsilẹ yoo wà.’ “Igi igbẹ yoo si so eso rẹ̀, ilẹ̀ yoo si ma mu asunkun rẹ̀ wá, wọn o si wà ni alaafia ni ilẹ̀ wọn.”—Orin Dafidi 72:16; Esekieli 34:27.
21. Ki ni yoo ṣẹlẹ si airi-ile-gbe, awọn ile ati adugbo akúṣẹ̀ẹ́ ni ilu-nla, ati awọn adugbo buruku?
21 Ki yoo tun si awọn otoṣi, alairi-ile-gbe, awọn ile ati adugbo awọn akúṣẹ̀ẹ́ ni awọn ilu-nla, tabi awọn adugbo ti iwa ọdaran ti bòmọ́lẹ̀ mọ. “Wọn o si kọ ile, wọn o si gbe inu wọn; wọn o si gbin ọgba ajara, wọn o si jẹ eso wọn. Wọn kì yoo kọ ile fun ẹlomiran igbe, wọn ki yoo gbin fun ẹlomiran ijẹ.” “Wọn o si jokoo olukuluku labẹ ajara rẹ̀ ati labẹ igi ọpọtọ rẹ̀; ẹnikan ki yoo si daya fò wọn.”—Isaiah 65:21, 22; Mika 4:4.
22. Bawo ni Bibeli ṣe ṣapejuwe awọn ibukun akoso Ọlọrun?
22 Awọn eniyan ni a o fi awọn nǹkan wọnyii bukun, ati ju bẹẹ lọ, ninu Paradise. Orin Dafidi 145:16 sọ pe: “Iwọ [Ọlọrun] ṣi ọwọ rẹ, iwọ si tẹ ifẹ gbogbo ohun alaaye lọrun.” Kò yanilẹnu nigba naa ti asọtẹlẹ Bibeli fi polongo pe: “Awọn ọlọkan-tutu ni yoo jogun aye; wọn o si maa ṣe inudidun ninu ọpọlọpọ alaafia. . . . Olododo ni yoo jogun aye, yoo si ma gbe inu rẹ̀ laelae.”—Orin Dafidi 37:11, 29.
Ṣiṣatunṣe Awọn Ohun Atẹhinwa
23. Bawo ni Ijọba Ọlọrun yoo ṣe ṣatunṣe gbogbo ijiya ti a ti niriiri rẹ̀?
23 Iṣakoso Ijọba Ọlọrun yoo ṣatunṣe gbogbo ibajẹ ti a ti ṣe si idile eniyan fun ẹgbẹrun ọdun mẹfa ti o ti kọja. Ayọ akoko naa yoo tayọ ijiya eyikeyii ti awọn eniyan tìí ni iriri rẹ̀ rí lọ lọpọlọpọ. Igbesi-aye ni iranti ijiya eyikeyii ti atẹhinwa ki yoo ṣediwọ fún. Awọn ironu ati igbokegbodo ti ń gbeniro ti yoo jẹ igbesi-aye ojoojumọ awọn eniyan yoo pa awọn iranti aronilara rẹ́ kuro ni kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀.
24, 25. (a) Ki ni Isaiah sọtẹlẹ pe yoo ṣẹlẹ? (b) Eeṣe ti a fi lè ni idaniloju pe awọn iranti atẹhinwa yoo parẹ?
24 Ọlọrun ti o bikita naa polongo pe: “Emi o da ọrun titun [ijọba atọrunwa titun kan lori araye] ati ayé titun [awujọ eniyan olododo kan]; a ki yoo si ranti awọn [“ohun,” NW] ti iṣaaju, bẹẹni wọn ki yoo si wà si àyà. Ṣugbọn ki ẹyin ki o yọ̀, ki inu yin ki o si dùn titi lae ninu eyi ti emi o da.” “Gbogbo ayé simi, wọn si gbe jẹ: wọn bú jade ninu orin kikọ.”—Isaiah 14:7; 65:17, 18.
25 Nitori naa nipasẹ Ijọba rẹ̀, Ọlọrun yoo ṣe ayipada awọn ipo buruku ti o ti wà pẹtiti tobẹẹ patapata. Titi lae fáàbàdà ni oun yoo fi ibikita giga rẹ̀ fun wa han nipa titu awọn ibukun jade sori wa ti yoo ju afidipo ipalara eyikeyii ti o kàn wá ni ìgbà àtẹ̀hìnwà lọ. Awọn idaamu ti a ti ni iriri rẹ̀ ni ìgbà atijọ yoo parẹ di iranti fìrífìrí kan ni ìgbà naa, boya bi a bá tilẹ bikita lati ranti wọn rara.
26. Eeṣe ti Ọlọrun yoo fi san asanfidipo fun ijiya wa atẹhinwa?
26 Bayii ni Ọlọrun yoo ṣe ṣafidipo gbogbo awọn ijiya ti o ṣeeṣe ki a ti farada ninu ayè yii fun wa. O mọ̀ pe kii ṣe ẹbi wa pe a bí wa ni alaipe, nitori ti a jogun aipe lati ọdọ awọn obi wa akọkọ. Kii ṣe ẹbi wa pe a bi wa sinu ayé Satani, nitori kani pe Adamu ati Efa ti jẹ oloootọ ni, àbá ti bi wa sinu paradise dipo eyi. Nitori naa pẹlu ìyọ́nú ńláǹlà Ọlọrun yoo ṣe ju sisan asanfidipo fun awọn ìgbà buburu ti o kọja ti a fi jẹ wa niya.
27. Awọn asọtẹlẹ wo ni yoo ri imuṣẹ agbayanu wọn ninu ayé titun?
27 Ninu ayè titun, araye yoo ni iriri ominira ti a sọ tẹlẹ ninu Romu 8:21, 22 pe: “A o sọ ẹda tikararẹ di ominira kuro ninu ẹru idibajẹ, si ominira ogo awọn ọmọ Ọlọrun. Nitori awa mọ pe gbogbo ẹda ni o jumọ ń kerora ti o si ń rọbi pọ titi di isinsinyi.” Nigba naa awọn eniyan yoo ri ẹkunrẹrẹ imuṣẹ adura naa: “Ki ijọba rẹ de. Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun, bẹẹni ni ayé.” (Matteu 6:10) Awọn ipo agbayanu lori Paradise ilẹ̀-ayé naa yoo ṣagbeyọ awọn ipo ti ọrun.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ninu aye titun, awọn agba ọlọjọ ori yoo pada si okunra igba ewe wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Gbogbo aisan ati abuku ara ni a o mu kuro ninu ayé titun naa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ninu ayé titun, awọn oku ni a o ji dide si iwalaaye
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
“Wọn ki yoo kọ ogun jija mọ”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Awọn eniyan ati ẹranko yoo wà ni alaafia delẹdelẹ ninu Paradise
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
‘Ọlọrun yoo ṣi ọwọ rẹ̀ yoo si tẹ ifẹ gbogbo ohun alaaye lọ́rùn’
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ijọba Ọlọrun yoo ṣe ju ṣiṣafidipo gbogbo awọn ijiya ti a ti farada