ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • rq ẹ̀kọ́ 3 ojú ìwé 6-7
  • Ta Ni Jesu Kristi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ta Ni Jesu Kristi?
  • Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ta Ni Jésù Kristi?
    Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
  • Ta Ni Jésù Kristi?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Jésù Ń gbani Là—Lọ́nà Wo?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ta Ni Jésù Kristi?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
rq ẹ̀kọ́ 3 ojú ìwé 6-7

Ẹ̀kọ́ 3

Ta Ni Jesu Kristi?

Èé ṣe tí a fi pe Jesu ní “àkọ́bí” Ọmọkùnrin Ọlọrun? (1)

Èé ṣe tí a fi pè é ní “Ọ̀rọ̀ naa”? (1)

Èé ṣe tí Jesu fi wá sí ayé gẹ́gẹ́ bí ènìyàn? (2-4)

Èé ṣe tí ó fi ṣe iṣẹ́ ìyanu? (5)

Kí ni Jesu yóò ṣe ní ọjọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́? (6)

1. Jesu gbé ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ẹni ẹ̀mí, kí ó tó wá sí orí ilẹ̀ ayé. Òun ni ẹ̀dá àkọ́kọ́ ti Ọlọrun dá, nítorí náà ni a sì ṣe pè é ní “àkọ́bí” Ọmọkùnrin Ọlọrun. (Kolosse 1:15; Ìṣípayá 3:14) Jesu ni Ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí Ọlọrun fúnra rẹ̀ dá. Jehofa lo Jesu, ṣáájú kí ó tó di ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí “ọ̀gá oníṣẹ́” rẹ̀, láti dá àwọn ohun mìíràn ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé. (Owe 8:​22-⁠31, NW; Kolosse 1:​16, 17) Ọlọrun tún lò ó gẹ́gẹ́ bí olórí agbọ̀rọ̀sọ Rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí a fi pe Jesu ní “Ọ̀rọ̀ naa.”​—⁠Johannu 1:​1-⁠3; Ìṣípayá 19:⁠13.

2. Ọlọrun rán Ọmọkùnrin Rẹ̀ wá sí ayé nípa títa àtaré ìwàláàyè rẹ̀ sínú ilé ọlẹ̀ Maria. Nítorí náà, Jesu kò ní bàbá tí ó jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn. Ìdí nìyẹn tí kò fi jogún ẹ̀ṣẹ̀ tàbí àìpé èyíkéyìí. Ọlọrun rán Jesu wá sí ayé fún ìdí mẹ́ta: (1) Láti fi òtítọ́ nípa Ọlọrun kọ́ wa (Johannu 18:37), (2) láti pa ìwà títọ́ mọ́ pérépéré, ní pípèsè àpẹẹrẹ fún wa láti tẹ̀ lé (1 Peteru 2:21), àti (3) láti fi ìwàláàyè rẹ̀ rúbọ láti tú wa sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Èé ṣe tí a fi nílò èyí?​—⁠Matteu 20:⁠28.

3. Nípa ṣíṣàìgbọràn sí òfin Ọlọrun, ọkùnrin àkọ́kọ́, Adamu, dá ohun tí Bibeli pè ní “ẹ̀ṣẹ̀.” Nítorí náà, Ọlọrun dájọ́ ikú fún un. (Genesisi 3:​17-⁠19) Kò kún ojú ìlà ìlànà Ọlọrun mọ́, nítorí náà, kì í ṣe ẹni pípé mọ́. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó di arúgbó, ó sì kú. Adamu ta àtaré ẹ̀ṣẹ̀ sórí gbogbo ọmọ rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí àwa pẹ̀lú ṣe ń di arúgbó, tí a ń ṣàìsàn, tí a sì ń kú. Báwo ní a ṣe lè gba aráyé là?​—⁠Romu 3:23; 5:⁠12.

4. Jesu jẹ́ ẹni pípé, gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí Adamu. Bí ó ti wù kí ó rí, láìdàbí Adamu, Jesu ṣègbọràn sí Ọlọrun délẹ̀délẹ̀, kódà, lábẹ́ àdánwò gíga jù lọ pàápàá. Nítorí náà, ó lè fi ìwàláàyè rẹ̀ pípé rúbọ láti ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ Adamu. Èyí ni Bibeli tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí “ìràpadà.” Àwọn ọmọ Adamu lè wá tipa báyìí rí ìtúsílẹ̀ gbà kúrò lọ́wọ́ ìdálẹ́bi ikú. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá lo ìgbàgbọ́ nínú Jesu lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà, kí wọ́n sì jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.​—⁠1 Timoteu 2:​5, 6; Johannu 3:⁠16; Romu 5:​18, 19.

5. Nígbà tí Jesu wà lórí ilẹ̀ ayé, ó wo àwọn aláìsàn sàn, ó bọ́ àwọn tí ebi ń pa, ó sì dá ìjì dúró. Ó jí òkú dìde pàápàá. Èé ṣe tí ó fi ṣe iṣẹ́ ìyanu? (1) Ó káàánú àwọn ènìyàn tí ń jìyà, ó sì fẹ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. (2) Àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fẹ̀rí hàn pé ó jẹ́ Ọmọkùnrin Ọlọrun. (3) Wọ́n fi ohun tí yóò ṣe fún aráyé onígbọràn, nígbà tí ó bá ń ṣàkóso bí Ọba lórí ilẹ̀ ayé, hàn.​—⁠Matteu 14:14; Marku 2:​10-⁠12; Johannu 5:​28, 29.

6. Jesu kú, Ọlọrun sì jí i dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí, ó sì padà sí ọ̀run. (1 Peteru 3:18) Láti ìgbà náà, Ọlọrun ti sọ ọ́ di Ọba. Láìpẹ́, Jesu yóò mú gbogbo ìwà búburú àti ìjìyà kúrò lórí ilẹ̀ ayé yìí.​—⁠Orin Dafidi 37:​9-⁠11; Owe 2:​21, 22.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jesu wé mọ́ kíkọ́ni, ṣíṣe iṣẹ́ ìyanu, àti fífi ìwàláàyè rẹ̀ pàápàá rúbọ fún wa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́