Ẹ̀kọ́ 14
Bí A Ṣe Ṣètò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa
Nígbà wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bẹ̀rẹ̀ lóde òní? (1)
Báwo ni a ṣe ń darí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa? (2)
Báwo ni wọ́n ṣe ń bójú tó ìnáwó? (3)
Ta ní ń mú ipò iwájú nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan? (4)
Àwọn ìpàdé ńlá wo ni wọ́n ń ṣe lọ́dọọdún? (5)
Iṣẹ́ wo ni wọ́n ń ṣe ní orílé-iṣẹ́ wọn àti ní àwọn ọ́fíìsì ẹ̀ka wọn? (6)
1. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bẹ̀rẹ̀ lóde òní ní àwọn ọdún 1870. Lákọ̀ọ́kọ́, a pè wọ́n ní Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Ṣùgbọ́n, ní ọdún 1931, wọ́n gba orúkọ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. (Isaiah 43:10) Láti ìbẹ̀rẹ̀ kékeré kan, ètò àjọ náà ti gbèrú di àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí, tí ọwọ́ wọn dí nínú wíwàásù ní àwọn ilẹ̀ tí ó ju 230 lọ.
2. Ọ̀pọ̀ jù lọ ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa máa ń ṣe ìpàdé lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́sẹ̀. A ké sí ọ láti lọ sí èyíkéyìí nínú ìwọ̀nyí. (Heberu 10:24, 25) Bibeli ni ìpìlẹ̀ fún ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni. Wọ́n ń bẹ̀rẹ̀ ìpàdé pẹ̀lú àdúrà, wọ́n sì ń parí rẹ̀ pẹ̀lú àdúrà. Wọ́n tún máa ń kọ “awọn orin ẹ̀mí” látọkàn wá nínú ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìpàdé wọn. (Efesu 5:18, 19) Wọn kì í gba owó ìwọlé, wọn kì í sì í gba ìdáwó èyíkéyìí.—Matteu 10:8.
3. Ọ̀pọ̀ jù lọ ìjọ máa ń ṣe ìpàdé nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ìwọ̀nyí sábà máa ń jẹ́ ilé mímọníwọ̀n, tí àwọn Ẹlẹ́rìí olùyọ̀ǹda ara ẹní kọ́. Ìwọ kì yóò rí ère, àgbélébùú, tàbí àwọn nǹkan bí ìwọ̀nyí nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Wọ́n ń bójú tó ìnáwó nípasẹ̀ ọrẹ àtinúwá. Àpótí ọrẹ wà fún àwọn tí ó bá fẹ́ láti ṣe ìtọrẹ.—2 Korinti 9:7.
4. Àwọn alàgbà tàbí alábòójútó wà nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan. Wọ́n ń mú ipò iwájú nínú kíkọ́ni nínú ìjọ. (1 Timoteu 3:1-7; 5:17) Àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń ràn wọ́n lọ́wọ́. (1 Timoteu 3:8-10, 12, 13) A kò gbé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ga ju àwọn yòókù nínú ìjọ lọ. (2 Korinti 1:24) A kò fún wọn ní àkànṣe orúkọ oyè. (Matteu 23:8-10) Wọn kì í múra yàtọ̀ sí àwọn yòókù. Bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í gbowó fún iṣẹ́ wọn. Àwọn alàgbà ń fi tinútinú bójú tó àìní tẹ̀mí ìjọ. Wọ́n lè pèsè ìtùnú àti ìdarísọ́nà ní àwọn àkókò wàhálà.—Jakọbu 5:14-16; 1 Peteru 5:2, 3.
5. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tún máa ń ṣe àpéjọ àti àpéjọpọ̀ ńlá lọ́dọọdún. Ní àwọn àkókò wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ ìjọ máa ń péjọ fún àkànṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìtọ́ni láti inú Bibeli. Ìrìbọmi àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun jẹ́ apá ṣíṣe déédéé nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ tàbí àpéjọpọ̀ kọ̀ọ̀kan.—Matteu 3:13-17; 28:19, 20.
6. Orílé-iṣẹ́ àgbáyé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wà ní New York. Níbẹ̀ ni Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, àwùjọ àwọn alàgbà onírìírí tí ń bójú tó ìjọ kárí ayé, wà. Àwọn ọ́fíìsì ẹ̀ka tí ó ju 100 tún wà kárí ayé. Ní àwọn ibi wọ̀nyí, àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni ń ṣèrànwọ́ láti tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, wọ́n sì ń ṣèrànwọ́ láti kó wọn ránṣẹ́ pẹ̀lú. Níbẹ̀ ni a tún ti ń pèsè ìdarísọ́nà fún ìṣètò iṣẹ́ ìwàásù. Èé ṣe tí o kò fi wéwèé láti ṣèbẹ̀wò sí ọ́fíìsì ẹ̀ka tí ó sún mọ́ ọ jù lọ?