Ètò Àjọ Wọn àti Iṣẹ́ Wọn Kárí Ayé
ONÍRÚURÚ ipele ètò tó pọwọ́ léra wọn ni wọ́n ń lò láti fi darí iṣẹ́ ìwàásù náà ní ilẹ̀ tó ju igba ó lé ọgbọ̀n níbi tí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà. Ọ̀dọ̀ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ní orílé iṣẹ́ ní Brooklyn, New York, ni àbójútó gbogbo gbòò ti ń wá. Lọ́dọọdún, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso máa ń rán aṣojú sí àwọn ẹkùn lọ́kan-kò-jọ̀kan kárí ayé, láti lọ foríkorí pẹ̀lú àwọn aṣojú ẹ̀ka tó wà ní àwọn ẹkùn wọ̀nyẹn. Àwọn ilé iṣẹ́ ẹ̀ka máa ń ní àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ẹlẹ́ni bíi mẹ́ta sí méje, tó máa ń bójú tó iṣẹ́ náà ní àwọn orílẹ̀-èdè tó bá wà lábẹ́ ẹ̀ka tiwọn. Àwọn kan lára àwọn ẹ̀ka yìí ní àwọn ohun èlò ìtẹ̀wé, àwọn kan sì ń lo ẹ̀rọ ìtẹ̀wé alátẹ̀yípo tó yára bí àṣà. Wọ́n pín orílẹ̀-èdè tàbí ìpínlẹ̀ tí ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan ń bójú tó sí àwọn àgbègbè, wọ́n sì wá pín àwọn àgbègbè yìí sí àwọn àyíká. Nǹkan bí ogún ìjọ ló máa ń wà nínú àyíká kọ̀ọ̀kan. Alábòójútó àgbègbè kan máa ń ṣèbẹ̀wò yípo àwọn àyíká tó bá wà nínú àgbègbè rẹ̀. Àpéjọ méjì lọ́dún ni àyíká kọ̀ọ̀kan máa ń ṣe. Alábòójútó àyíká tún wà pẹ̀lú, ó sì máa ń bẹ àwọn ìjọ tó wà ní àyíká rẹ̀ wò lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún láti ran àwọn Ẹlẹ́rìí lọ́wọ́ nínú ṣíṣètò àti ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù ní ìpínlẹ̀ tí wọ́n yàn fún ìjọ yẹn.
Inú ìjọ tó wà ládùúgbò yín àti Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn la ti ń ṣètò iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere fún àwọn èèyàn àdúgbò yín. Ìpínlẹ̀ kéékèèké ni wọ́n máa ń pín ibi tó bá wà lábẹ́ ìjọ kọ̀ọ̀kan sí. Wọn a pín wọn fún olúkúlùkù Ẹlẹ́rìí, àwọn náà a sì sapá láti dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tó wà nínú ibùgbé kọ̀ọ̀kan tó wà níbẹ̀. Ìjọ kọ̀ọ̀kan, tí iye rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ látorí Ẹlẹ́rìí mélòó kan dórí nǹkan bí igba, ní àwọn alàgbà tó ń bójú tó onírúurú ẹrù iṣẹ́. Olúkúlùkù tó ń polongo ìhìn rere náà ló ṣe kókó nínú ètò àjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Gbogbo Ẹlẹ́rìí pátá ló ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù yìí láti fẹnu ara wọn sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn, yálà orílé iṣẹ́ ti àgbáyé ni Ẹlẹ́rìí náà ti ń sìn ni o, ẹ̀ka ilé iṣẹ́ ni o, tàbí nínú àwọn ìjọ.
Ìròyìn ìgbòkègbodò yìí máa ń dé orílé iṣẹ́ wọn lágbàáyé níkẹyìn, ìyẹn ni wọ́n sì máa ń kó jọ láti fi tẹ ìwé ọdọọdún náà Yearbook jáde. Bákan náà, wọ́n tún máa ń gbé àtẹ ìgbòkègbodò yẹn jáde lọ́dọọdún nínú ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ January 1. Ìtẹ̀jáde méjèèjì yìí máa ń gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn jáde nípa ohun tí wọ́n gbé ṣe lọ́dún yẹn lẹ́nu iṣẹ́ ìjẹ́rìí nípa Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀ tí Kristi Jésù ń ṣàkóso. Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, nǹkan bí àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà mẹ́rìnlá [14,000,000 ] àwọn Ẹlẹ́rìí àti àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ sí wọn ló ń wá síbi Ìṣe Ìrántí ikú Jésù lọ́dọọdún. Ó ju ẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ lọ́nà àádọ́ta [1,000,000,000] wákàtí lọ́dún tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń polongo ìhìn rere, ó sì ju ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [300,000] ẹni tuntun tí wọ́n ń batisí. Àpapọ̀ iye ìwé tí wọ́n ti pín sọ́wọ́ àwọn èèyàn sì wọ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún.