Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ sí Wọn Sábà Máa Ń Béèrè
Bí Ọlọ́run bá jẹ́ ìfẹ́, èé ṣe tó fi fàyè gba ìwà ibi?
ÒÓTỌ́ ni pé Ọlọ́run fàyè gba ìwà ibi, èyí sì mú kí ẹgbàágbèje èèyàn mọ̀ọ́mọ̀ di aṣebi paraku. Bí àpẹẹrẹ, wọn a dá ogun sílẹ̀, wọn a rọ̀jò bọ́ǹbù lu àwọn ògo wẹẹrẹ, wọn a rí i pé àwọn ba ojú ilẹ̀ jẹ́ pátápátá, wọn a fi ìyẹn dá ìyàn sílẹ̀. Ẹgbàágbèje èèyàn ń mu sìgá, wọn a sì tibẹ̀ kó àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró, wọ́n ń ṣàgbèrè, wọn a sì kó àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń fà, wọ́n ń mu ọtí ní ìmukúmu, wọn a sì kó ìsúnkì ẹ̀dọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Irú àwọn bẹ́ẹ̀ kò fẹ́ kí gbogbo ìwà ibi dópin rárá ni. Kí wọ́n ṣáà ti mú ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tó lè tipa bẹ́ẹ̀ jẹ wọ́n kúrò lọ́nà ni wọ́n ń fẹ́. Bí wọ́n bá wá ń jẹ iṣẹ́ ọwọ́ wọn, wọ́n á máa kébòòsí pé, “Áà, tèmi ṣe jẹ́?” Wọ́n á wá ní àmúwá Ọlọ́run ni, bí ohun tí Òwe 19:3 wí, tó ní: “Èèyàn fúnra rẹ̀ fi ìwà òmùgọ̀ fọ́ ayé ara rẹ̀ bà jẹ́, ó sì wá ń kanra mọ́ OLÚWA.” (The New English Bible) Bí Ọlọ́run bá sì wá fòpin sí ibi tí wọn ń ṣe, wọn a fẹ̀hónú hàn, wọn a ní wọ́n du àwọn lómìnira láti ṣe é!
Ìdí pàtàkì tí Jèhófà fi fàyè gba ìwà ibi ni láti yanjú ìpèníjà Sátánì. Sátánì Èṣù sọ pé Ọlọ́run ò lè dá ẹnikẹ́ni sí ayé kí onítọ̀hún sì jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run bí ìdánwò bá bá a. (Jóòbù 1:6-12; 2:1-10) Jèhófà wá dá Sátánì sí kí ó lè rí àyè fi ẹ̀rí ìpèníjà rẹ̀ múlẹ̀. (Ẹ́kísódù 9:16) Sátánì ń bá a lọ láti máa mú àwọn ègbé bá aráyé di ìsinsìnyí, láti lè mú kí aráyé kẹ̀yìn sí Ọlọ́run, bí ó ṣe ń sapá láti wá ẹ̀rí láti fi ṣètìlẹyìn ìpèníjà rẹ̀. (Ìṣípayá 12:12) Ṣùgbọ́n Jóòbù pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Jésù ṣe. Bẹ́ẹ̀ náà làwọn Kristẹni tòótọ́ ń ṣe nísinsìnyí.— Jóòbù 27:5; 31:6; Mátíù 4:1-11; 1 Pétérù 1:6, 7.
Mo ń fẹ́ láti gbà gbọ́ pé Párádísè ilẹ̀ ayé, níbi tí àwọn èèyàn yóò ti máa gbé títí láé yóò wà, ṣùgbọ́n ṣe kì í ṣe àlá tí kò lè ṣẹ ni o?
Kì í ṣe àlá tí ò lè ṣẹ rárá, lójú ohun tí Bíbélì wí. Ohun tó fi dà bí àlá tí ò lé ṣẹ kò ju pé látọdúnmọ́dún wá, aburú ni ọmọ aráyé ti ń rí. Ńṣe ni Jèhófà dá ayé tó sì sọ pé kí ọmọ aráyé bí àwọn ẹni olódodo lọ́kùnrin lóbìnrin kún inú rẹ̀, kí wọ́n máa bójú tó àwọn ewéko àti ẹ̀dá ẹranko inú rẹ̀, kí wọ́n sì mú kí ẹwà rẹ̀ máa dán gbinrin dípò bíbà á jẹ́. (Wo ojú ìwé kejìlá àti ìkẹtàdínlógún.) Kàkà kí Párádísè tí Ọlọ́run ṣèlérí yẹn jẹ́ àlá tí kò lè ṣẹ, ipò ìbànújẹ́ inú ayé tó ti burú kọjá àlà yìí ni yóò lọ kúrò. Párádísè ló máa rọ́pò rẹ̀.
Báwo ni mo ṣe lè dá àwọn ẹlẹ́gàn tó ń sọ pé Bíbélì jẹ́ ìtàn àròsọ, pé kò sì bá sáyẹ́ǹsì mu lóhùn?
Gbígbà téèyàn gba àwọn ìlérí yìí gbọ́ kì í ṣe ọ̀ràn pé èèyàn jẹ́ ẹni tó kàn ń gba ohun gbogbo gbọ́. “Ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́.” Béèyàn bá ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ọgbọ́n inú rẹ̀ yóò túbọ̀ hàn síni kedere, ìgbàgbọ́ ẹni a sì máa jinlẹ̀ sí i.— Róòmù 10:17; Hébérù 11:1.
Àwọn tó ń wú ohun ìṣẹ̀ǹbáyé jáde nínú ilẹ̀ láti fi wá ẹ̀rí nípa ìtàn Bíbélì ti jẹ́rìí sí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú ìtàn Bíbélì pé ó péye. Sáyẹ́ǹsì tòótọ́ àti Bíbélì kò takora rárá. Àwọn òkodoro òtítọ́ tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí ti wà nínú Bíbélì tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ inú ayé tó ṣàwárí wọn, àwọn nìyí: ó sọ nípa ipele-ipele tí ayé gbà yí padà nígbà ìṣẹ̀dá rẹ̀, ó sọ pé ńṣe ni ayé rí bìrìkìtì, pé ilẹ̀ ayé rọ̀ sórí òfo, àti pé àwọn ẹyẹ a máa ṣí kiri.—Jẹ́nẹ́sísì orí kìíní; Aísáyà 40:22; Jóòbù 26:7; Jeremáyà 8:7.
Jíjẹ́ tí Bíbélì jẹ́ ìwé onímìísí hàn látinú bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú rẹ̀ ṣe ń ṣẹ. Dáníẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí àwọn orílẹ̀ èdè alágbára jù lọ yóò ṣe máa dìde àti bí wọn yóò ṣe ṣubú, ó sì tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìgbà tí Mèsáyà yóò dé tí wọn yóò sì pa á. (Dáníẹ́lì, orí kejì, orí kẹjọ; àti orí kẹsàn-án, ẹsẹ ìkẹrìnlélógún dé ìkẹtàdínlọ́gbọ̀n) Lóde òní, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn ṣì ń ṣẹ lọ lọ́wọ́, tó ń jẹ́ ká mọ̀ pé àsìkò “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí. (2 Tímótì 3:1-5; Mátíù orí kẹrìnlélógún) Níní ìmọ̀ nípa ọjọ́ iwájú lọ́nà báyìí ré kọjá agbára òye ènìyàn. (Aísáyà 41:23) Fún ẹ̀rí síwájú sí i, wo ìwé The Bible—God’s Word or Man’s? àti Is There a Creator Who Cares About You?, tí Watchtower Bible and Tract Society tẹ̀ jáde.
Báwo ni mo ṣe lè mọ bí a ti ń dáhùn àwọn ìbéèrè nípa Bíbélì?
O ní láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí o sì ṣàṣàrò lé e lórí, kí o sì tún máa gbàdúrà pé kí ẹ̀mí Ọlọ́run tọ́ ọ sọ́nà nípa rẹ̀. (Òwe 15:28; Lúùkù 11:9-13) Bíbélì sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni; a ó sì fi í fún un.” (Jákọ́bù 1:5) Àwọn ohun èlò aṣèrànwọ́ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tún wà pẹ̀lú, èyí tó yẹ kí o ṣàyẹ̀wò. Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé wàá nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn, bí ìgbà tí Fílípì kọ́ ará Etiópíà lẹ́kọ̀ọ́. (Ìṣe 8:26-35) Ọ̀fẹ́ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́ àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì nínú ilé wọn. Ìwọ sáà máà jáfara láti sọ fún wọn pé o nífẹ̀ẹ́ sí i.
Èé ṣe tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi máa ń tako àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n sì ń sọ pé kí n má gbà kí wọ́n kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́?
Àwọn èèyàn tako iṣẹ́ ìwàásù ti Jésù ṣe, ó sì sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun náà yóò rí àtakò. Nígbà tí ọ̀nà tí Jésù gbà ń kọ́ni wú àwọn kan lórí, ńṣe ni àwọn onísìn tó ǹ ṣàtakò ń kanra mọ́ wọn pé: “A kò tíì ṣi ẹ̀yin náà lọ́nà, àbí a ti ṣe bẹ́ẹ̀? Kò sí ọ̀kan nínú àwọn olùṣàkóso tàbí àwọn Farisí tí ó ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, àbí ó wà?” (Jòhánù 7:46-48; 15:20) Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbà ọ́ nímọ̀ràn pé kí ó má gbà kí àwọn Ẹlẹ́rìí kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ló jẹ́ pé yálà àìmọ bọ́ràn ṣe jẹ́ tàbí ẹ̀tanú ló mú kí wọ́n máa sọ bẹ́ẹ̀. Jẹ́ kí àwọn Ẹlẹ́rìí kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ kí o wá fúnra rẹ wò ó bóyá ìmọ̀ tí o ní nípa Bíbélì yóò pọ̀ sí i tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.—Mátíù 7:17-20.
Èé ṣe tí àwọn Ẹlẹ́rìí fi máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ti ní ẹ̀sìn tiwọn?
Àpẹẹrẹ Jésù ni wọ́n ń tẹ̀ lé tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀. Jésù tọ àwọn Júù lọ. Àwọn Júù ní ẹ̀sìn tiwọn, ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ni wọ́n ti yà kúrò nínú ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wí. (Mátíù 15:1-9) Kò sí orílẹ̀-èdè tí kò ní oríṣi ẹ̀sìn tirẹ̀, ì báà jẹ́ àwọn tó sọ pé Kristẹni làwọn tàbí àwọn tí kì í ṣe Kristẹni. Ó ṣe pàtàkì gidigidi pé kí ó jẹ́ ohun tó bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ mu ni àwọn èèyàn gbà gbọ́, ìsapá tí àwọn Ẹlẹ́rìí sì ń ṣe láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ṣe èyí fi hàn pé wọ́n fẹ́ràn ọmọnìkejì wọn.
Ǹjẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí gbà gbọ́ pé ẹ̀sìn tiwọn nìkan ṣoṣo ló tọ̀nà?
Ẹnikẹ́ni tó bá ti ń ṣe ẹ̀sìn rẹ̀ lójú méjèèjì ti ní láti gbà pé ìyẹn ni ẹ̀sìn tí ó tọ̀nà. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí wá ni ìdí tó fi ń ṣe ẹ̀sìn yẹn? Ọ̀rọ̀ ìṣítí tí a sọ fún àwọn Kristẹni ní pé: “Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú; ẹ di ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ mú ṣinṣin.” (1 Tẹsalóníkà 5:21) Ó yẹ kéèyàn wádìí láti rí i dájú pé àwọn ohun tí òun gbà gbọ́ ṣe é fi múlẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́, nítorí pé ìgbàgbọ́ tòótọ́ kan ṣoṣo péré ló wà. Éfésù 4:5 ti èyí lẹ́yìn, tó fi mẹ́nu kan “Olúwa kan, ìgbàgbọ́ kan, ìbatisí kan.” Jésù kò fara mọ́ èrò tí àwọn èèyàn fi ń dára wọn nínú dùn lóde òní pé ọ̀nà kan ò wọjà lọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, pé gbogbo ẹ̀sìn lọ̀nà ìgbàlà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní: “Tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé àwọn ti rí ọ̀nà yẹn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọ́n á ti kọjá sínú ẹ̀sìn mìíràn.—Mátíù 7:14.
Ǹjẹ́ wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn nìkan ni yóò rí ìgbàlà?
Rárá o. Ẹgbàágbèje èèyàn tó ti gbé ayé ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni yóò padà wá nígbà àjíǹde, àǹfààní ìyè yóò sì wà fún wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà láàyè báyìí ló ṣì lè tẹ́wọ́ gba òtítọ́ àti òdodo ṣáájú “ìpọ́njú ńlá” náà, tí wọn yóò sì rí ìgbàlà. Ní àfikún sí i, Jésù sọ pé kí á má máa dá ọmọnìkejì wa lẹ́jọ́. Ìrísí òde ẹni lèèyàn ń wò; Ọlọ́run ló ń wo ọkàn. Arínúróde ni, àánú ló sì fi ń ṣèdájọ́. Jésù ló gbé ìdájọ́ ṣíṣe lé lọ́wọ́ kì í ṣe àwa.—Mátíù 7:1-5; 24:21; 25:31.
Àwọn ìtọrẹ tó la owó lọ wo ni wọ́n ń retí pé kí àwọn tó bá ń wá sí àwọn ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe?
Ní ti ọ̀ràn ìdáwó, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” (2 Kọ́ríńtì 9:7) Wọn kì í gba owó igbá rárá ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti gbọ̀ngàn àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn àpótí máa ń wà níbẹ̀ kí ó lè túbọ̀ rọrùn fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ ṣe ìtọrẹ láti ṣe é. Kò sẹ́ni tó ń mọ iye tí ẹlòmíràn fi síbẹ̀, kò sì sẹ́ni tó ń mọ ẹni tó fi sí i tàbí ẹni tí kò fi sí i. Àwọn kan lágbára àtifi ohun tó pọ̀ síbẹ̀ ju àwọn ẹlòmíràn lọ; àwọn kan lè máà ní nǹkan kan tí wọ́n lè fi síbẹ̀ rárá. Jésù fi irú ojú tó tọ́ láti fi wò ó hàn nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa àpótí ìṣúra tó wà ní tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù àti àwọn tó ń ṣe ìtọrẹ níbẹ̀, ìyẹn ni pé: Bí èèyàn ṣe lágbára sí láti fi nǹkan sílẹ̀, àti ọkàn tó fi ṣe é ló ṣe pàtàkì, kì í ṣe iye tí onítọ̀hún fi sílẹ̀.—Lúùkù 21:1-4.
Bí mo bá di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣe wọ́n á retí pé kí n máa wàásù bíi tiwọn?
Bí ìmọ̀ nípa Párádísè tí Ọlọ́run ṣèlérí fún ilẹ̀ ayé, èyí tí Ìjọba Kristi yóò ṣàkóso, bá ti wọni lọ́kàn dáadáa, onítọ̀hún yóò fẹ́ láti sọ nípa rẹ̀ fún ẹlòmíràn. Yóò wù ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Ìhìn rere mà ni o!—Ìṣe 5:41, 42.
Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọ̀nà pàtàkì láti gbà fi hàn pé o jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi. Nínú Bíbélì, wọ́n pe Jésù ní “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé àti olóòótọ́.” Nígbà tó wà láyé, ó wàásù pé: “Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé,” ó sì rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ láti wàásù bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. (Ìṣípayá 3:14; Mátíù 4:17; 10:7) Lẹ́yìn náà, Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn.” Ó tún sọ tẹ́lẹ̀ pé kí òpin tó dé “a ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.”—Mátíù 24:14; 28:19, 20.
Onírúurú ọ̀nà lèèyàn lè gbà kéde ìhìn rere yìí. Àyè rẹ̀ sábà máa ń yọ nígbà tí èèyàn bá ń bá àwọn ará àti ojúlùmọ̀ rẹ̀ jíròrò. Lẹ́tà kíkọ tàbí ká lo tẹlifóònù ni àwọn mìíràn fi ń ṣe é. Àwọn mìíràn máa ń fi ìwé tí wọ́n rò pé ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ yóò wu ojúlùmọ̀ wọn kan ní pàtàkì ránṣẹ́ sí wọ́n nípasẹ̀ ilé ìfìwéránṣẹ́. Ìfẹ́ pé kó máà sí ẹnikẹ́ni tí wọ́n fò dá ló mú kí àwọn Ẹlẹ́rìí máa mú ìhìn náà lọ láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà.
Ìkésíni ọlọ́yàyà yìí wà nínú Bíbélì pé: “Àti ẹ̀mí àti ìyàwó ń bá a nìṣó ní sísọ pé: ‘Máa bọ̀!’ Kí ẹnikẹ́ni tí ń gbọ́ sì wí pé: ‘Máa bọ̀!’ Kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣípayá 22:17) Ńṣe lèèyàn máa ń fínnú fíndọ̀ sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa Párádísè ilẹ̀ ayé àti àwọn ìbùkún tí yóò mú wá, ẹni tí ìfẹ́ láti sọ nípa ìhìn rere yìí bá sì ń jẹ lọ́kàn gidigidi ní ń sọ ọ́.
A mọ̀ dájú pé o ní àwọn ìbéèrè mìíràn tóo fẹ́ béèrè nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Bóyá àwọn ọ̀ràn mìíràn tilẹ̀ jẹ́ èyí tó la àríyànjiyàn lọ. A óò fẹ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ. Kò sí àyè púpọ̀ tó nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí, nítorí náà, a rọ̀ ọ́ pé kí o béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ. O lè lọ béèrè ní àwọn ìpàdé wọn ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí nígbà tí wọ́n bá ṣèbẹ̀wò sí ilé rẹ. Tàbí kí o fi àwọn ìbéèrè rẹ ránṣẹ́ sí Watch Tower, kí o lo èyí tó yẹ nínú àdírẹ́sì ìsàlẹ̀ yìí.