Ohun Tí a Rọ̀ ọ́ Láti Ṣe
Ó dùn mọ́ wa bí a ṣe lo ìwé pẹlẹbẹ yìí láti fi bá ọ sọ̀rọ̀. A ronú pé ó dùn mọ́ ìwọ náà bí o ti ṣe kọ́ nǹkan púpọ̀ sí i nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Jọ̀wọ́ wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa tó wà ládùúgbò rẹ. Kí o rí bí a ti ń ṣe àwọn ìpàdé wa. Kí o rí bí a ṣe ń sapá láti sọ ìhìn rere fún àwọn ẹlòmíràn, nípa ilẹ̀ ayé tí yóò di Párádísè, tí Ìjọba Kristi yóò ṣàkóso.
Ọlọ́run ti ṣèlérí rẹ̀. “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ti kọjá lọ láti ìgbà yẹn. Àkókò tí a óò fi máa retí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ayé ló fi hàn bẹ́ẹ̀.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé,” ńṣe ni “kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀.” (Hébérù 10:24, 25) A rọ̀ ọ́ pé kí o ṣe bí Pọ́ọ̀lù ṣe gbà ọ́ nímọ̀ràn, kí o wá péjọ pẹ̀lú wa.