ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 8/15 ojú ìwé 8-11
  • Idi Ti o Fi Yẹ Ki O Lọ si Awọn Ipade Kristian

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Idi Ti o Fi Yẹ Ki O Lọ si Awọn Ipade Kristian
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bi Awọn Kristian Ṣe “Ń Pọ́n” Araawọn Ẹnikinni Keji
  • Wíwá Ounjẹ Tẹmi Ní Awọn Akoko Lilekoko
  • Awọn Irannileti Jehofa —Bíi Ohùn kan Lẹhin Rẹ̀
  • Gbígba Ẹmi Mimọ Nipasẹ Ijọ
  • Idanilẹkọọ tí Ijọ Ń Pèsè
  • Rí Ààbò Láàárín Àwọn Ènìyàn Ọlọrun
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Pésẹ̀ sí Àwọn Ìpàdé “Pàápàá Jù Lọ”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Pé Jọ Láti Jọ́sìn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Kí Lo Máa Gbádùn Láwọn Ìpàdé Wa?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 8/15 ojú ìwé 8-11

Idi Ti o Fi Yẹ Ki O Lọ si Awọn Ipade Kristian

FUN ọpọ oṣu, Rosario, ẹni ti ń gbé ni South America, gbadun kikẹkọọ Bibeli pẹlu Elizabeth. Ó dùn mọ́ Rosario ninu lati kọ́ nipa Ijọba Ọlọrun ati bi yoo ṣe mu ipo Paradise wá sori ilẹ̀-ayé. Sibẹ, nigbakigba ti Elizabeth bá késí i lati wá si ipade ni Gbọngan Ijọba, oun yoo kọ̀ jalẹ. Ó lero pe oun lè kẹkọọ Bibeli ni ile ki oun sì fi ohun ti o sọ si ilo, ni ṣiṣe bẹẹ lailọ si awọn ipade ijọ. Iwọ pẹlu ha ti ṣe kayeefi ri nipa boya awọn ipade Kristian ń ṣanfaani fun ọ niti gidi bi? Eeṣe ti Ọlọrun fi ṣeto fun awọn eniyan rẹ̀ lati padepọ?

Niwọn bi o ti jẹ pe awọn Kristian ni ọrundun kìn-ín-ní yatọ gan-an si awọn eniyan ti wọn yí wọn ká, ibakẹgbẹpọ títọ́ ṣe pataki fun lilaaja wọn. Aposteli Paulu kọwe si ijọ awọn Kristian akọkọbẹrẹ kan pe: ‘Ẹyin jẹ́ alailẹgan ati oniwatutu, laaarin oniwa wíwọ́ ati alareekereke orilẹ-ede, laaarin awọn ẹni ti a ń ri yin bi imọlẹ ni ayé.’ (Filippi 2:15) Ó lekoko ni pataki fun awọn Kristian ní Judea, awọn sì ni Paulu kọwe si pe: “Ẹ jẹ́ ki a yẹ ara wa wò lati ru araawa si ifẹ ati si iṣẹ rere: ki a má maa kọ ipejọpọ araawa silẹ, gẹgẹ bi àṣà awọn ẹlomiran; ṣugbọn ki a maa gba ara ẹni niyanju: pẹlupẹlu bi ẹyin ti rii pe ọjọ nì ń sunmọ etile.” (Heberu 10:24, 25) Bawo ni a ṣe ń ru araawa ẹnikinni keji si ifẹ ati si iṣẹ rere nipa pipadepọ?

Bi Awọn Kristian Ṣe “Ń Pọ́n” Araawọn Ẹnikinni Keji

Ọ̀rọ̀ Griki naa ti Paulu lò ti a sì tumọ si ‘ru soke’ lọna olowuuru tumọ si “pípọ́n.” Owe Bibeli kan ṣalaye bi awọn Kristian ṣe “ń pọ́n” ara wọn nigba ti o wí pe: “Irin a maa pọ́n irin: bẹẹ ni ọkunrin í pọ́n ojú ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Owe 27:17; Oniwasu 10:10) A dabi awọn irin-iṣẹ ti o nilo pípọ́n deedee. Niwọn bi o ti jẹ́ pe fifi ifẹ hàn si Jehofa ati ṣiṣe awọn ipinnu ti a gbekari igbagbọ wa tumọsi yiyatọ si ayé, lati ìgbà de ìgbà ni a nilati maa gba ọ̀nà ti o yatọ, ki a sọ bẹẹ, si ti awọn eniyan pupọ julọ.

Isapa lemọlemọ naa lati yatọ lè mú ki itara wa fun iṣẹ rere kújú. Ṣugbọn nigba ti a bá wà pẹlu awọn ẹlomiran ti wọn nifẹẹ Jehofa, a ń pọ́n ara wa—a ń ru ara wa si ifẹ ati si iṣẹ rere. Ni ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, nigba ti a bá dáwà, a ní itẹsi lati gbe araawa yẹwo sii. Awọn èrò iwapalapala, imọtara-ẹni-nikan, tabi alaibọgbọnmu lè kowọ ero-inu wa. “Ẹni ti o ya ara rẹ̀ sọtọ yoo lepa ifẹ ara rẹ̀, yoo si kọju ija nla si ohunkohun ti i ṣe ti òye.” (Owe 18:1) Idi niyẹn ti Paulu fi kọwe si ijọ ti o wà ni ilu-nla Tessalonika pe: “Ẹ maa gba ara yin niyanju, ki ẹ sì maa fi ẹsẹ ara yin mulẹ, àní gẹgẹ bi ẹyin ti ń ṣe.”—1 Tessalonika 5:11.

Nigba ti Rosario pari ikẹkọọ rẹ̀ nipa awọn ẹkọ ipilẹ Bibeli, ó ṣì fasẹhin lati maa pejọpọ pẹlu ijọ. Nitori naa, nitori aile pese iranlọwọ siwaju sii, Elizabeth dawọ ṣiṣebẹwo sọdọ rẹ̀ duro. Ní oṣu diẹ lẹhin naa, alaboojuto arinrin-ajo kan késí Rosario o sì bii leere pe: “Àní bi ẹnikọọkan ninu mẹmba idile kan bá lè ri ounjẹ daradara nipa jijẹun ni ile àrójẹ kan, ki ni gbogbo mẹmba idile yoo padanu nipa ṣiṣaijẹun papọ ni ilé?” Rosario fesi pe: “Wọn yoo padanu ikẹgbẹpọ idile naa.” Ó loye koko naa ó sì bẹrẹ sii wá si awọn ipade deedee. Ó rí i bi ohun ti o ṣanfaani gan-an debi pe ó ti wá sí eyi ti o fẹrẹẹ jẹ gbogbo ipade lati ìgba naa wá.

Bi o ti ń gbọ tí awọn ẹlomiran ń sọ igbagbọ wọn jade ninu awọn ohun kan-naa ti iwọ gbagbọ ń funni ní iṣiri sì ni rírí bi iru igbagbọ bẹẹ ṣe yí igbesi-aye wọn pada. Paulu mọ eyi lati inu iriri ara tirẹ̀, ó sì kọwe si ijọ ti o wà ni Romu pe: “Emi ń fẹ́ gidigidi lati rí yin, ki emi ki o lè fun yin ni ẹbun ẹmi diẹ, ki a lè fi ẹsẹ yin múlẹ̀; eyiini ni, ki a lè jumọ ní itunu ninu yin nipa igbagbọ awa mejeeji, tiyin ati ti emi.” (Romu 1:11, 12) Niti tootọ, o jẹ́ lẹhin ọdun pupọ ni Paulu tó lè bẹ Romu wò, nigba ti o sì ṣe bẹẹ, o jẹ́ gẹgẹ bi ẹlẹwọn kan ni ọwọ́ awọn ará Romu. Ṣugbọn nigba ti ó rí awọn ará lati Romu ti wọn ti rìrìn ti o ju 60 kilomita (40 ibusọ) lati ilu-nla naa lati wá pade rẹ̀, ‘Paulu dupẹ lọwọ Ọlọrun, ó si mú ọkàn le.’—Iṣe 28:15.

Wíwá Ounjẹ Tẹmi Ní Awọn Akoko Lilekoko

Nigba ti ó wà ni àtìmọ́lé ninu ile oun fúnraarẹ̀ ní Romu, Paulu kọwe si awọn ará Heberu nipa ṣiṣaikọ ipejọpọ ara wọn silẹ. O ṣe pataki fun wa pe ó fi awọn ọ̀rọ̀ naa kun un pe: “Pẹlupẹlu bi ẹyin ti rii pe ọjọ nì ń sunmọ etile.” (Heberu 10:25) Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti fihàn leralera lati inu Iwe Mimọ pe ọdun 1914 sami si ibẹrẹ akoko opin ayé yii ati pe “ọjọ idajọ ati iparun awọn alaiwa-bi-Ọlọrun” ti sunmọle. (2 Peteru 3:7) Ní ibamu pẹlu iwe Ìfihàn ti Bibeli, nigba ti a lé Eṣu kuro ní ọ̀run ní ibẹrẹ akoko opin, ó ni ibinu nla o sì “lọ bá awọn iru-ọmọ rẹ̀ iyooku jagun, ti wọn ń pa ofin Ọlọrun mọ́, ti wọn sì di ẹ̀rí Jesu mú.” (Ìfihàn 12:7-17) Nitori naa, pipa awọn ofin Ọlọrun mọ́ ṣoro ni pataki nisinsinyi; a nilati pade pẹlu awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wa lọpọlọpọ sii. Awọn ipade yoo ràn wá lọwọ lati fun igbagbọ ati ifẹ wa fun Ọlọrun lokun ki a baa lè gbejako awọn ikọluni Eṣu.

Ifẹ fun Ọlọrun ati igbagbọ kò dabi awọn ile ti wọn wà titilọ ni gbàrà ti a bá ti kọ́ wọn tan. Kaka bẹẹ, wọn dabi awọn ohun alaaye ti ń dagbasoke diẹdiẹ pẹlu bíbọ́ lati ìgbà de ìgbà ṣugbọn ti wọn ń rọ ti wọn sì ń kú bi a bá febi pa wọn. Idi rẹ̀ niyẹn ti Jehofa fi pese ounjẹ ti ẹmi deedee lati fun awọn eniyan rẹ̀ lokun. Gbogbo wa nilo iru ounjẹ bẹẹ, ṣugbọn nibo ni a ti lè rí i gbà yatọ si lati inu eto-ajọ Ọlọrun ati awọn ipade rẹ̀? Kò si ibi kankan.—Deuteronomi 32:2; Matteu 4:4; 5:3.

Jesu gbé ibeere kan ti o lè ràn wá lọwọ lati ri bi oun ṣe ń bọ́ ijọ Kristian dide. O beere pe: “Ta ni niti gidi ni ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa ẹni ti ọ̀gá rẹ̀ yansipo ṣe olori awọn ara ilé rẹ̀, lati fun wọn ni ounjẹ wọn ni akoko yiyẹ? Alayọ ni ẹrú yẹn bi ọ̀gá rẹ̀ nigba ti o bá dé bá rí i ti o ń ṣe bẹẹ.” (Matteu 24:45, 46, NW) Ta ni Jesu yansipo ṣe olori ní ọrundun kìn-ín-ní lati maa bọ́ awọn ọmọlẹhin rẹ̀, ta ni o sì bá ti o ń bọ́ wọn pẹlu otitọ-inu nigba ipadabọ rẹ̀ ninu agbara Ijọba? Ni kedere, kò si eniyan kan ti o tii walaaye la gbogbo awọn ọrundun wọnyẹn já. Ẹ̀rí tọka si ẹrú naa gẹgẹ bi ijọ awọn Kristian ẹni-ami-ororo, gan-an gẹgẹ bi orilẹ-ede Israeli ṣe jẹ́ iranṣẹ Ọlọrun ṣaaju awọn akoko Kristian. (Isaiah 43:10) Bẹẹni, Jesu ń pese ounjẹ tẹmi wa nipasẹ ẹgbẹ́ awọn ẹni-ami-ororo jakejado ayé yẹn, awọn ẹni ti wọn ń dari ounjẹ tẹmi gba awọn ijọ adugbo ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.

Pipese ti Jesu pese ọ̀nà ipese ounjẹ tẹmi ni aposteli Paulu ṣapejuwe siwaju sii pe: “‘Nigba ti ó goke si ibi giga, ó kó awọn òǹdè lọ; ó funni ni ẹ̀bùn ninu awọn ọkunrin.’ . . . Ó sì fi awọn kan funni bi aposteli, ati awọn kan bii wolii, awọn kan bi ajihinrere, awọn kan bi oluṣọ-agutan ati olukọ, pẹlu èrò itunṣebọsipo awọn ẹni mímọ́, fun iṣẹ-ojiṣẹ, fun ìgbéró ara Kristi, titi gbogbo wa yoo fi dé iṣọkanṣoṣo ninu igbagbọ ati ninu ìmọ̀ ti Ọmọkunrin Ọlọrun, ti a o fi dàgbà-di-géńdé ọkunrin dori iwọn ipò-ìdàgbà ti o jẹ́ ti Kristi.”—Efesu 4:8, 11-13, NW.

Lọna ṣiṣe pataki julọ ninu awọn ijọ adugbo—ní awọn ipade—ni “ẹ̀bùn ninu awọn ọkunrin” wọnyi ń gbé awọn ará ró. Fun apẹẹrẹ, ní Antioku, “Bi Juda oun Sila tikaraawọn ti jẹ́ wolii pẹlu, wọn fi ọ̀rọ̀ pupọ gba awọn arakunrin niyanju, wọn sì mú wọn ni ọkàn le.” (Iṣe 15:32) Awọn ọ̀rọ̀ lati ẹnu awọn ọkunrin ti wọn tootun nipa tẹmi lonii yoo fun igbagbọ wa lokun lọna kan-naa ki o maa baa rọ tabi di alaigbeṣẹ mọ.

O lè jẹ́ otitọ pe a ti ní itẹsiwaju ti o dara nitori iranlọwọ àdáṣe ti mẹmba kan ninu ijọ bi o tilẹ jẹ pe a lè ṣai tii bẹrẹ sii lọ si awọn ipade. Bibeli sọ pe akoko kan wà nigba ti iwọ yoo wà ni ‘ẹni ti ẹnikan yoo maa kọ́ ni ibẹrẹ ipilẹ awọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun; iwọ sì nilo wàrà, kìí ṣe ounjẹ lile.’ (Heberu 5:12) Ṣugbọn ẹnikan kò lè wà ni ipo mímu wàrà titilae. Awọn ipade Kristian pese itolẹsẹẹsẹ itọni Bibeli ti ń baa lọ ti a ṣeto lati pa ifẹ Ọlọrun ati igbagbọ ninu rẹ̀ mọ́ ki a sì tun pese iranlọwọ gbigbeṣẹ ni fifi ‘imọran Ọlọrun’ silo. (Iṣe 20:27) Eyi ju “wàrà” lọ. Bibeli sọ siwaju sii pe: “Ounjẹ líle ni fun awọn ti ó dagba, awọn ẹni nipa ìrírí, ti wọn ń lo ọgbọ́n wọn lati fi iyatọ saaarin rere ati buburu.” (Heberu 5:14) Ní awọn ipade, awọn koko pupọ ni a ń gbeyẹwo ti o lè má jẹ apakan koko ẹkọ ti o tan mọ́ ilana itọni Bibeli inu ile, iru bi ikẹkọọ lẹsẹẹsẹ nipa awọn asọtẹlẹ Bibeli ṣiṣepataki ati ninu awọn ijiroro jijinlẹ niti bi a ṣe lè ṣafarawe Ọlọrun ninu igbesi-aye tiwa.

Awọn Irannileti Jehofa —Bíi Ohùn kan Lẹhin Rẹ̀

Nipasẹ iru awọn ikẹkọọ ijọ bẹẹ, Jehofa ń rán wa leti deedee nipa iru eniyan ti a nilati jẹ́. Iru awọn irannileti bẹẹ ṣe pataki. Laisi wọn, a maa ń tètè yí sipa imọtara-ẹni-nikan, igberaga, ati ìwọra. Awọn irannileti lati inu Iwe Mimọ yoo ràn wá lọ́wọ́ lati gbadun awọn ipo-ibatan ti o yọrisirere pẹlu awọn eniyan miiran ati pẹlu Ọlọrun funraarẹ. “Emi ro ọ̀nà mi, mo sì yí ẹsẹ mi pada si ẹ̀rí rẹ,” ni onkọwe Orin Dafidi 119:59 jẹwọ.

Bi a ti ń lọ si awọn ipade Kristian deedee, a ń ni iriri imuṣẹ asọtẹlẹ Jehofa nipasẹ Isaiah, eyi ti o wi pe: “Awọn olukọni rẹ ki yoo lùmọ́ mọ́, ṣugbọn oju rẹ yoo rí olukọni rẹ: eti rẹ yoo sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹhin rẹ, wi pe, eyiyii ni ọ̀nà, ẹ maa rìn ninu rẹ̀.” Jehofa ń foju si itẹsiwaju wa o sì ń fi ifẹ tọ́ wa sọna bi a bá gbé igbesẹ ti kò tọ́. (Isaiah 30:20, 21; Galatia 6:1) Oun tilẹ ń pese iranlọwọ ti o ju eyi lọ.

Gbígba Ẹmi Mimọ Nipasẹ Ijọ

Nipa pipesẹ si awọn ipade Kristian deedee pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ẹmi mimọ Ọlọrun tí ń bà lé awọn eniyan rẹ̀ lori, ń fun wa lokun. (1 Peteru 4:14) Siwaju sii, awọn Kristian alaboojuto ninu ijọ ni a ti fi ẹmi mimọ yàn. (Iṣe 20:28) Ipá agbékánkánṣiṣẹ́ ti o wá lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun yii ní ipa alagbara kan lori Kristian kan. Bibeli sọ pe: “Eso ti ẹmi ni ifẹ, ayọ̀, alaafia, ipamọra, iwapẹlẹ, iṣoore, igbagbọ, iwatutu, ati ikora-ẹni-nijaanu.” (Galatia 5:22, 23) Ẹmi mimọ, ti ń ṣiṣẹ nipasẹ eto-ajọ Ọlọrun, yoo ràn wá lọ́wọ́ pẹlu lati jere òye ṣiṣe kedere lọna yiyanilẹnu nipa ohun ti Jehofa ní ní ipamọ fun awọn ti wọn nifẹẹ rẹ̀. Lẹhin ṣiṣalaye pe awọn gbajumọ ninu eto awọn nǹkan yii kò lè loye awọn ète Ọlọrun, Paulu kọwe pe: “Ọlọrun ti ṣí wọn payá fun wa nipa ẹmi rẹ̀.”—1 Korinti 2:8-10.

Yatọ si ounjẹ tẹmi ti ń fun igbagbọ lokun, ijọ ń pese idanilẹkọọ fun awọn ti wọn bá fẹ́ lati ṣajọpin ninu igbokegbodo pataki ninu ijọ. Ki ni iyẹn?

Idanilẹkọọ tí Ijọ Ń Pèsè

Ijọ Kristian kìí ṣe ibi apejọ ẹgbẹ-oun-ọgba nibi ti awọn eniyan wulẹ ti maa ń gbadun eré-ìnàjú ati boya ki wọn fun ara wọn ni iṣiri lati gbé igbesi-aye ti o sàn jù. Jesu yan iṣẹ fun ijọ lati mú ihinrere Ijọba naa lọ sọdọ awọn wọnni ti wọn ń gbé ninu okunkun nipa tẹmi. (Iṣe 1:8; 1 Peteru 2:9) Lati ọjọ ti a ti dá a silẹ, ni Pentikosti 33 C.E., eto-ajọ awọn oniwaasu ni o jẹ́. (Iṣe 2:4) Iwọ ha ti ní iriri gbigbiyanju lati sọ fun ẹnikan nipa awọn ète Jehofa ṣugbọn ti o kuna lati yi i lero pada bi? Awọn ipade ijọ pese idanilẹkọọ ara-ẹni lori ọ̀nà idanilẹkọọ. Nipa kikẹkọọ awọn apẹẹrẹ Bibeli, a kọ́ bi a ṣe lè fidi ipilẹ àjọfohùnṣọ̀kan mulẹ lati inu eyi ti a ti lè ṣaṣaro, bi a ṣe lè lo Iwe Mimọ gẹgẹ bi ipilẹ kan fun alaye ọ̀rọ̀ ti o lọgbọn-ninu, ati bi a ṣe lè ran awọn ẹlomiran lọwọ lati ronu nipa lilo awọn ibeere ati apejuwe. Iru awọn òye bẹẹ lè ràn ọ́ lọwọ lati ni iriri ayọ alaiṣeefẹnusọ ti ríran ẹlomiran lọwọ lati loye otitọ Bibeli.

Ninu ayé oniwapalapala, ti o kun fun ija yii, ijọ Kristian jẹ́ ibi-isadi tẹmi tootọ. Bi o tilẹ jẹ pe o kun fun awọn eniyan alaipe, o jẹ́ èbúté alaafia ati ifẹ. Nitori naa, jẹ́ ẹni ti ń wà ní gbogbo ipade rẹ̀ deedee ki o sì ní iriri otitọ awọn ọ̀rọ̀ olorin naa fun araarẹ pe: “Kiyesi i, o ti dara o sì ti dùn tó fun awọn ará lati maa jumọ gbé ni ìrẹ́pọ̀. . . . Nibẹ ni Oluwa gbé paṣẹ ibukun, àní ìyè laelae.”—Orin Dafidi 133:1, 3.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́