Pésẹ̀ sí Àwọn Ìpàdé “Pàápàá Jù Lọ”
1 Pípàdépọ̀ ti máa ń fi ìgbà gbogbo ṣe kókó fún àwọn ènìyàn Jèhófà. Tẹ́ńpìlì àti àwọn sínágọ́gù jẹ́ ojúkò ìjọsìn tòótọ́, ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá, àti ìbákẹ́gbẹ́ aláyọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Bákan náà, àwọn Kristẹni ìjímìjí kò kọ pípéjọpọ̀ sílẹ̀. Bí àwọn pákáǹleke àti àdánwò ti ń pọ̀ sí i ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn lílekoko wọ̀nyí, àwa pẹ̀lú nílò ìfúnlókun nípa tẹ̀mí tí àwọn ìpàdé ìjọ wa ń pèsè—a sì nílò rẹ̀ “pàápàá jù lọ.” (Héb. 10:25) Ṣàkíyèsí ìdí mẹ́ta tí a fi ń lọ sí àwọn ìpàdé.
2 Fún Ìbákẹ́gbẹ́: Ìwé Mímọ́ ṣí wa létí láti ‘máa tu ara wa nínú lẹ́nì kìíní-kejì, kí a sì máa gbé ara wa ró lẹ́nì kìíní-kejì.’ (1 Tẹs. 5:11) Ìbákẹ́gbẹ́ oníwà-bí-Ọlọ́run máa ń fi èrò rere kún inú wa, ó sì ń sún wa láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Ṣùgbọ́n bí a bá ya ara wa sọ́tọ̀, ó ṣeé ṣe kí a fàyè gba èrò òmùgọ̀, èrò ìmọtara-ẹni-nìkan, tàbí èrò oníwà pálapàla pàápàá.—Òwe 18:1.
3 Fún Ìtọ́ni: Àwọn ìpàdé Kristẹni ń pèsè ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìtọ́ni Bíbélì tí ń bá a nìṣó, tí a pète láti fi mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run máa wà nínú ọkàn-àyà wa. Wọ́n ń pèsè ìtọ́sọ́nà gbígbéṣẹ́ nínú fífi “gbogbo ìpinnu Ọlọ́run” sílò. (Ìṣe 20:27) Àwọn ìpàdé ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ nínú ọ̀nà wíwàásù àti kíkọ́ni ní ìhìn rere náà, òye tí a nílò pàápàá jù lọ nísinsìnyí láti lè nírìírí ìdùnnú tí kò ṣeé fẹnu sọ ti wíwá àwọn tí yóò tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì kí a sì ràn wọ́n lọ́wọ́.
4 Fún Ààbò: Nínú ayé búburú yìí, ìjọ jẹ́ ibi ààbò tẹ̀mí ní ti gidi—ibi àlàáfíà àti ìfẹ́ ní ti gidi. Nígbà tí a bá pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé ìjọ, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa ń ní agbára ìdarí lílágbára lórí wa, ó máa ń ṣàmújáde àwọn èso ti “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.” (Gál. 5:22, 23) Àwọn ìpàdé máa ń fún wa lókun láti dúró gbọn-in kí a sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́. Wọ́n ń mú wa gbára dì láti múra sílẹ̀ fún àwọn àdánwò tí ó wà níwájú.
5 Nípa lílọ sí ìpàdé déédéé, a ń nírìírí ohun tí onísáàmù ṣàpèjúwe, bí a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Sáàmù 133:1, 3 pé: “Wò ó! Ó mà dára o, ó mà dùn o, pé kí àwọn ará máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan!” Níbikíbi tí àwọn ènìyàn Ọlọ́run bá ti ń sìn tí wọ́n sì ń pàdé pọ̀ lónìí, “ibẹ̀ ni Jèhófà pàṣẹ pé kí ìbùkún wà, àní ìyè fún àkókò tí ó lọ kánrin.”