Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa—Àfihàn Ìfẹ́ Tòótọ́
1 Nípasẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a ń fi ìgbọràn wa sí àwọn àṣẹ méjì tí ó tóbi jù lọ hàn. (Mát. 22:37-39) Ìfẹ́ wa fún Jèhófà ń sún wa láti sọ̀rọ̀ lọ́nà rere nípa rẹ̀. Ìfẹ́ wa fún àwọn aládùúgbò wa ń sún wa láti fún wọn níṣìírí láti wá ìmọ̀ nípa ohun tí ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run àti àwọn ète rẹ̀ kí wọ́n lè wá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kí wọ́n sì fi ara wọn sí ìlà fún èrè ìyè àìnípẹ̀kun gẹ́gẹ́ bí àwa. Nítorí náà, nípasẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a ń bọlá fún orúkọ Jèhófà a sì ń ṣàjọpín ìrètí Ìjọba aláìlẹ́gbẹ́ náà pẹ̀lú àwọn aládùúgbò wa. Bẹ́ẹ̀ ni, iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa jẹ́ àfihàn ìfẹ́ tòótọ́ fún Ọlọ́run àti fún ènìyàn.
2 Ìfẹ́ wa ń sún wa láti bá onírúurú ènìyàn sọ̀rọ̀ ní onírúurú ipò. (1 Kọ́r. 9:21-23) Kí a ṣàkàwé: Nínú ọkọ̀ òfuurufú, Kristẹni alàgbà kan jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ àlùfáà Roman Kátólíìkì kan. Alàgbà náà mú kí àlùfáà náà sọ èrò rẹ̀ nípa fífọgbọ́n béèrè àwọn ìbéèrè mélòó kan, lẹ́yìn náà, ó sì darí ìjíròrò yìí sí Ìjọba náà. Nígbà tí àlùfáà yìí yóò fi sọ̀ kalẹ̀ nínú ọkọ̀ òfuurufú náà, ó ti gba méjì nínú àwọn ìwé wa. Ẹ wo bí fífi tí alàgbà yìí fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn fún aládùúgbò rẹ̀ ti yọrí sí rere tó!
3 Ìfẹ́ Tòótọ́ Ń Sún Wa Láti Wàásù: Dájúdájú, àwọn tí ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ olùrànlọ́wọ́ aṣáájú ọ̀nà àti aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún ń fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn fún Ọlọ́run àti aládùúgbò. Ìgbà gbogbo ni àwọn aṣáájú ọ̀nà ń fi àkókò àti okun wọn rúbọ láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Kí ni ó ń sún wọn láti ṣe èyí? Aṣáájú ọ̀nà kan sọ pé: “Mo mọ̀ pé ìfẹ́ jẹ́ èso ẹ̀mí Ọlọ́run. Nítorí náà, láìsí i, n kò ní wà nínú òtítọ́ rárá, ká má tilẹ̀ sọ nípa ṣíṣe àṣeyọrí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà. Ìfẹ́ ń mú kí n ṣàníyàn nípa àwọn ènìyàn, kí n mọ ohun tí ó jẹ́ àìní wọn, mo sì mọrírì rẹ̀ pé àwọn ènìyàn máa ń dáhùn padà sí ìfẹ́.” Jésù fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn fún àwọn ènìyàn. Nígbà kan tí òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí àárẹ̀ ti mú ń lọ síbì kan láti lọ “sinmi díẹ̀,” ogunlọ́gọ̀ ènìyàn dé ibẹ̀ ṣáájú wọn. Kí ni Jésù ṣe? “Àánú wọ́n ṣe é,” ó pa àwọn ohun tí ó jẹ́ àìní tirẹ̀ tì kí ó lè “kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.”—Máàkù 6:30-34.
4 Àní nígbà tí àwọn ènìyàn bá kọ ìhìn rere tí a ń mú tọ̀ wọ́n lọ pàápàá, a máa ń ní ìdùnnú inú lọ́hùn-ún, a mọ̀ pé bí ìfẹ́ ti sún wa ṣiṣẹ́, a ti ṣe ohun gbogbo tí a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jèrè ìgbàlà. Nígbà tí Kristi bá ṣe ìdájọ́ gbogbo wa nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, inú wa yóò dùn jọjọ pé a ti fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn nípa ‘ṣíṣe àṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.’—2 Tím. 4:5.