ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/98 ojú ìwé 8
  • Gbin Ìrètí Ìyè Àìnípẹ̀kun Sínú Àwọn Ẹlòmíràn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbin Ìrètí Ìyè Àìnípẹ̀kun Sínú Àwọn Ẹlòmíràn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìmọ̀ Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ń Dáhùn Ọ̀pọ̀ Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • “Èyí Túmọ̀ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Dámọ̀ràn fún Lílò Lóde Ẹ̀rí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Padà Lọ Láti Gba Àwọn Díẹ̀ Là
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 3/98 ojú ìwé 8

Gbin Ìrètí Ìyè Àìnípẹ̀kun Sínú Àwọn Ẹlòmíràn

1 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ènìyàn ti wá àwọn ọ̀nà láti fawọ́ bí òun ṣe ń di arúgbó sẹ́yìn, kí ó sì mú kí àkókò ìwàláàyè òun gùn sí i, síbẹ̀ ọjọ́ ogbó àti ikú kò tíì ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Ẹ wo bí a ti kún fún ọpẹ́ tó pé Bíbélì ṣàlàyé ìdí tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn fi ń di arúgbó tí wọ́n sì ń kú, àti bí a óò ṣe yí èṣe tí ọjọ́ ogbó ń ṣe padà, tí a óò sì mú ikú kúrò. Òtítọ́ wọ̀nyí ni a fi ìdánilójú ṣàlàyé nínú ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Ìwé náà dáhùn àwọn ìbéèrè tí ń dani láàmù nípa ìyè àti ikú, ó ń tọ́ka òǹkàwé sí àkókò kan nígbà tí a óò mú Párádísè padà bọ̀ sípò.

2 Ní oṣù March, a óò fi ìwé Ìmọ̀ lọni pẹ̀lú góńgó bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. (Mát. 28:19, 20) Lẹ́yìn náà, a óò ṣe àwọn ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ gbogbo àwọn tí ó bá fi ọkàn-ìfẹ́ hàn nínú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà. Lọ́nà yìí, a óò lè gbin ìrètí ìyè àìnípẹ̀kún sínú àwọn ẹlòmíràn. (Títù 1:2) Láti ṣàṣeparí èyí, ó ṣeé ṣe kí àwọn àbá tí ó tẹ̀ lé e yìí ṣèrànwọ́ fún ọ.

3 Nígbà tí o bá ń ṣe ìkésíni àkọ́kọ́, o lè béèrè ìbéèrè yìí:

◼ “O ha ti ṣe kàyéfì rí nípa ìdí tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn fi ń yán hànhàn fún ìwàláàyè tí ó gùn sí i? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Àwọn ẹlẹ́sìn Búdà, Kristẹni, Híńdù, Mùsùlùmí, àti àwọn mìíràn ni gbogbo wọn ní ìrètí nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú.” Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí orí 6, “Èéṣe Tí A Fi Ń Darúgbó Tí A sì Ń Kú?,” kí o sì ka ìpínrọ̀ 3. Ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí. Bí o ti ń tọ́ka sí àwọn ìbéèrè méjì tí ó wà ní òpin ìpínrọ̀ náà, béèrè lọ́wọ́ onílé bí òun yóò bá fẹ́ láti rí àwọn ìdáhùn náà fúnra rẹ̀. Bí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, máa bá a nìṣó ní jíjíròrò àwọn ìpínrọ̀ díẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e. O ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nìyẹn! Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, fi lọ̀ ọ́ pé ìwọ yóò fi ìwé náà sílẹ̀ fún un ní iye ọrẹ tí a ń fi í sóde kí òun lè kà á, kí o sì wéwèé láti padà lọ láti jíròrò àwọn ìdáhùn náà, ó dára jù kí ó jẹ́ níwọ̀n ọjọ́ kan tàbí méjì.

4 Nígbà tí o bá ń padà ṣiṣẹ́ lórí ìwé “Ìmọ̀” tí ó fi sóde, o lè sọ pé:

◼ “Mo padà wá láti jíròrò àwọn ìbéèrè méjì náà nípa ikú, èyí tí a fi sílẹ̀ láìdáhùn.” Rán onílé náà létí nípa àwọn ìbéèrè náà. Lẹ́yìn náà, jíròrò ìsọfúnni tí ó wà ní orí 6 lábẹ́ ìsọ̀rí “Ìdìmọ̀lù Ibi Kan.” Ní sísinmi lórí bí àyíká ipò bá ti rí, máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nìṣó tàbí kí o lo ìbéèrè tí ó kẹ́yìn ní òpin ìpínrọ̀ 7 láti fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún àkókò mìíràn. Ṣe ìwéwèé tí ó ṣe gúnmọ́ láti padà wá. Fún onílé náà ní ìwé ìléwọ́, kí o sì ṣàlàyé bí a ṣe ń ṣe àwọn ìpàdé ìjọ ní ṣókí. Ké sí i tọ̀yàyàtọ̀yàyà láti wá.

5 Yálà nínú iṣẹ́ ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà tàbí nínú ìjẹ́rìí aláìjẹ́-bí-àṣà, o lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nípa sísọ pé:

◼ “O ha ti ṣe kàyéfì rí láé nípa ohun tí ọjọ́ ọ̀la ní ní ìpamọ́ fún wa àti fún ilẹ̀ ayé bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì fi ọ̀rọ̀ kan ṣàkópọ̀ ọjọ́ ọ̀la—Párádísè! Ó ṣàlàyé pé ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run ṣe apá kan ilẹ̀ ayé ní párádísè ẹlẹ́wà kan níbi tí ó fi tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn tí òun ti dá sí. Àwọn ni yóò fi àwọn ènìyàn kún ilẹ̀ ayé, ní sísọ ọ́ di párádísè kan ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Kíyè sí àkàwé yìí nípa bí ì bá ti rí.” Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí ojú ìwé 8, kí o sì ka ìpínrọ̀ 9, lábẹ́ ìsọ̀rí “Ìwàláàyè Nínú Paradise.” Lẹ́yìn náà, jíròrò àwọn kókó tí ó wà ní ìpínrọ̀ 10, kí o sì ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí, Aísáyà 55:10, 11. Fi lọ̀ ọ́ pé o fẹ́ máa bá ìjíròrò náà nìṣó nípa bí ìwàláàyè nínú Párádísè tí a mú padà bọ̀ sípò yóò ṣe rí, pé o sì fẹ́ kí ẹ jọ ṣàyẹ̀wò ìpínrọ̀ 11 sí 16 pa pọ̀. Tàbí kẹ̀, fún ẹni náà níṣìírí láti kà á fúnra rẹ̀, kí ẹ sì ṣètò láti tún pàdé pọ̀ kí ẹ sì jíròrò rẹ̀.

6 Bí o kò bá bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nígbà àkọ́kọ́, o lè gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà ìpadàbẹ̀wò nípa sísọ pé:

◼ “Gẹ́gẹ́ bí a ṣe jíròrò nígbà ìjíròrò wa tí ó kẹ́yìn, ète Ọlọ́run ni pé kí a sọ gbogbo ilẹ̀ ayé di párádísè kan. Ìyẹn gbé ìbéèrè náà dìde pé, Báwo ni Párádísè yóò ṣe rí?” Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí orí 1, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ ìpínrọ̀ 11 sí 16 lábẹ́ ìsọ̀rí “Ìgbésí-Ayé Nínú Paradise Tí A Mú Padàbọ̀sípò.” Lẹ́yìn náà, fi àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé 4 àti 5 hàn án, kí o sì béèrè lọ́wọ́ ẹni náà bí òun yóò bá fẹ́ láti gbé nínú irú àyíká ẹlẹ́wà bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, ka gbólóhùn àkọ́kọ́ ní ìpínrọ̀ 17, ní ojú ìwé 10. Ní sísinmi lórí bí àyíká ipò bá ṣe rí, máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nìṣó tàbí kí o sọ pé nígbà ìbẹ̀wò rẹ tí yóò tẹ̀ lé e ìwọ yóò ṣàlàyé ohun tí a ń béèrè kí ẹnì kan tó lè gbé nínú Párádísè tí a mú padà bọ̀ sípò. Fún un ní ìwé ìléwọ́, ṣàlàyé ìṣètò ìpàdé, sì ké sí ẹni náà tọ̀yàyàtọ̀yàyà láti wá sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.

7 Ìwé Ìmọ̀ jẹ́ irin iṣẹ́ àtàtà tí a lè lò láti ṣí “ìyè àìnípẹ̀kún” tí Ọlọ́run ṣèlérí payá fún àwọn ẹlòmíràn. Ṣíṣe tí o bá ń ṣe àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé pẹ̀lú àwọn ènìyàn lè gbin ìrètí kíkọyọyọ yìí, tí Ọlọ́run “tí kò lè purọ́” mú wá sí àfiyèsí wa, sínú wọn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́