Àpótí Ìbéèrè
◼ Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a fún ìwọṣọ àti ìmúra wa ní àfiyèsí àkànṣe nígbà tí a bá ń ṣèbẹ̀wò sí àwọn ilé Society ní Brooklyn, Patterson, àti Wallkill, New York, àti àwọn ọ́fíìsì ẹ̀ka jákèjádò ayé?
A retí pé kí àwọn Kristẹni máa bá a nìṣó ní híhu ìwà ìmẹ̀tọ́mẹ̀yẹ. Ní gbogbo ìgbà, ìwọṣọ àti ìmúra wa gbọ́dọ̀ máa fi ìwàlétòlétò àti iyì tí ó yẹ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run hàn. Èyí jẹ́ òótọ́ ní pàtàkì nígbà tí a bá ń ṣèbẹ̀wò sí àwọn ilé Society ní New York àti ní àwọn ẹ̀ka káàkiri ayé.
Ní ọdún 1998, a óò ṣe àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè àti ti àgbáyé. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará wa láti ọ̀pọ̀ ilẹ̀ yóò ṣèbẹ̀wò sí orílé-iṣẹ́ Society ní New York àti sí àwọn ẹ̀ka ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Kì í ṣe ìgbà tí a bá ń ṣèbẹ̀wò sí àwọn ilé wọ̀nyí nìkan, ṣùgbọ́n ní àwọn ìgbà mìíràn pẹ̀lú, a gbọ́dọ̀ ‘dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo,’ títí kan nínú ìwọṣọ àti ìmúra wa tí ó bójú mu.—2 Kọ́r. 6:3, 4.
Ní jíjíròrò ìjẹ́pàtàkì ìwọṣọ àti ìmúra tí ó bójú mu, ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-Ojiṣẹ Wa sọ̀rọ̀ lórí bí ó ti yẹ kí a mọ́ tónítóní nípa ti ara, kí a wọṣọ níwọ̀ntúnwọ̀nsì, kí a sì múra lọ́nà tí ó dára nígbà tí a bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá àti nígbà tí a bá ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni. Lẹ́yìn náà, ní ojú ìwé 131, ìpínrọ̀ 1, ó sọ pé: “Ohun kan naa ni yoo wémọ́ ọn nigba tí a bá nṣe ibẹwo si ile Bethel ní Brooklyn tabi eyikeyi ninu awọn ẹka ile-iṣẹ Society. Ranti, orukọ naa Bethel tumọsi ‘Ile Ọlọrun,’ nitori naa aṣọ wa, imura wa ati iwa wa gbọdọ rí bakan naa pẹlu ohun tí a reti lati ọ̀dọ̀ wa nigba tí a bá nlọ si awọn ipade fun ijọsin ní Gbọngan Ijọba.” Ìlànà gíga kan náà yìí ni àwọn akéde Ìjọba láti àgbègbè àdúgbò àti àwọn tí ó ti ibi tí ó jìnnà wá tí wọ́n wá láti rí àwọn mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì, kí wọ́n sì bá wọn kẹ́gbẹ́ àti láti ṣe ìbẹ̀wò sí àwọn ilé ẹ̀ka, gbọ́dọ̀ pa mọ́.
Aṣọ wa gbọ́dọ̀ ní ipa rere lórí àwọn ẹlòmíràn ní ti bí wọ́n ṣe ń wo ìjọsìn tòótọ́ Jèhófà. Ṣùgbọ́n, a ti kíyè sí i pé nígbà tí àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin kan bá ń ṣe ìbẹ̀wò sí àwọn ilé Society, wọ́n máa ń wọṣọ lọ́nà yẹpẹrẹ jù. Irú ìwọṣọ bẹ́ẹ̀ kò bójú mu nígbà tí a bá ń ṣèbẹ̀wò sí èyíkéyìí nínú àwọn ilé Bẹ́tẹ́lì. Nínú ọ̀ràn yìí, bí ó ti rí nínú gbogbo apá mìíràn nínú ìgbésí ayé Kristẹni wa, a fẹ́ láti pa ìlànà gíga kan náà mọ́ tí ń fi àwọn ènìyàn Ọlọ́run hàn yàtọ̀ sí ayé nípa ṣíṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run. (Róòmù 12:2; 1 Kọ́r. 10:31) Ó tún dára láti bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa àti àwọn mìíràn tí wọ́n lè máa ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì fún ìgbà àkọ́kọ́ sọ̀rọ̀ kí a sì rán wọn létí nípa bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti fún ìwọṣọ àti ìmúra bíbójúmu ní àfiyèsí.
Nítorí náà, nígbà tí o bá ń ṣèbẹ̀wò sí àwọn ilé Society, bi ara rẹ léèrè pé: ‘Ṣé ìwọṣọ àti ìmúra mi wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì?’ (Fi wé Míkà 6:8.) ‘Ó ha ń fi Ọlọ́run tí mo ń jọ́sìn hàn lọ́nà tí ó dára bí? Ìrísí mi yóò ha pín ọkàn àwọn ẹlòmíràn níyà tàbí yóò ha bí wọn nínú bí? Mo ha ń fi àpẹẹrẹ yíyẹ lélẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n lè máa ṣèbẹ̀wò fún ìgbà àkọ́kọ́ bí?’ Nígbà gbogbo, ǹjẹ́ kí àwa, nípa ìwọṣọ àti ìmúra wa, máa “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́ nínú ohun gbogbo.”—Títù 2:10.