ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/98 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 3/98 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní March: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun fún ₦55. Pọkàn pọ̀ sórí bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. April àti May: Gbogbo èdè—Àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́ àti Jí!. June: Èyíkéyìí nínú àwọn ìwé olójú ewé 192 tí ó tẹ̀ lé e yìí tí ìjọ lè ní lọ́wọ́: Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia,” Ayọ̀—Bi A Ṣe Lè Rí I, Fifetisilẹ si Olukọ Nla na, Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Isopọṣọkan ninu Ijọsin Ọlọrun Tootọ Kanṣoṣo Naa, “Jẹ́ Kí Ijọba Rẹ Dé,” àti Lilaaja Sinu Ilẹ-ayé Titun. ÀKÍYÈSÍ: Kí àwọn ìjọ tí yóò bá nílò àwọn ìwé ìgbétáásì tí a mẹ́nu kàn lókè yìí béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn ti oṣù tí ń bọ̀.

◼ Kí àwọn akéde tí wọ́n fẹ́ láti sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù April àti May ṣe àwọn ìwéwèé wọn nísinsìnyí, kí wọ́n sì tètè fi ìwé ìwọṣẹ́ wọn sílẹ̀. Èyí yóò ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ètò tí ó yẹ fún iṣẹ́ ìsìn pápá, kí wọ́n sì ní ìwé ìròyìn àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tí ó pọ̀ tó lọ́wọ́. Kí a kéde orúkọ gbogbo àwọn tí a fọwọ́ sí láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún ìjọ.

◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí òun yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní March 1 tàbí bí ó bá ti lè ṣeé ṣe kí ó yá tó lẹ́yìn náà. Ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ṣe èyí.

◼ Kí àwọn ìjọ ṣe ètò rírọgbọ láti ṣe ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ọdún yìí ní Saturday, April 11, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ àsọyé náà lè tètè bẹ̀rẹ̀, gbígbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìṣe Ìrántí kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀, àfi lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀. Ẹ wádìí ládùúgbò láti mọ ìgbà tí oòrùn máa ń wọ̀ ní àgbègbè yín. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dára kí ìjọ kọ̀ọ̀kan ṣe ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí tirẹ̀, èyí lè má fìgbà gbogbo ṣeé ṣe. Níbi tí ó ti jẹ́ pé àwọn ìjọ púpọ̀ ní ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, bóyá ìjọ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lè lọ wá gbọ̀ngàn mìíràn lò ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn. Kò yẹ kí bíbẹ̀rẹ̀ Ìṣe Ìrántí náà pẹ́ jù débi tí kì yóò fi rọrùn fún àwọn olùfìfẹ́hàn tuntun láti pésẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà kò gbọ́dọ̀ kún fọ́fọ́ jù débi pé kò ní sí àkókò ṣáájú tàbí lẹ́yìn ayẹyẹ náà láti kí àwọn àlejò, láti ṣètò ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí tí ń bá a lọ fún àwọn ẹni tuntun, tàbí láti gbádùn ìṣepàṣípààrọ̀ ìṣírí ní gbogbogbòò. Lẹ́yìn gbígbé gbogbo ọ̀ràn yẹ̀ wò dáadáa, àwọn alàgbà ní láti pinnu ètò tí yóò ran àwọn tí wọ́n pésẹ̀ síbi Ìṣe Ìrántí náà lọ́wọ́ jù lọ láti jàǹfààní kíkúnrẹ́rẹ́ láti inú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

◼ Láti January 1, 1998, a kò tún pe àwọn Ilẹ̀ Àpéjọ wa ní Ilẹ̀ Àpéjọ mọ́. Orúkọ tí a ń pé àwọn ilé wọ̀nyí nísinsìnyí ni Gbọ̀ngàn Àpéjọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́