ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/98 ojú ìwé 6
  • Àwọn Ìránnilétí Ìṣe Ìrántí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìránnilétí Ìṣe Ìrántí
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ohun Tí Kò Yẹ Ká Gbàgbé Nípa Ìṣe Ìrántí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àwọn Ìránnilétí Ìṣe Ìrántí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Àwọn Ìránnilétí Ìṣe Ìrántí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Rántí Nípa Ìṣe Ìrántí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 3/98 ojú ìwé 6

Àwọn Ìránnilétí Ìṣe Ìrántí

Ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí bọ́ sí ọjọ́ Saturday, April 11. Kí àwọn alàgbà fiyè sí àwọn ọ̀ràn tí ó tẹ̀ lé e yìí:

◼ Ní ṣíṣètò àkókò fún ìpàdé náà, ẹ rí i dájú pé a kì yóò gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ kiri títí di ẹ̀yìn tí oòrùn bá wọ̀.

◼ Kí a fi àkókò tí a óò ṣe ayẹyẹ náà gan-an àti ibi tí a óò ti ṣe é tó gbogbo ènìyàn, títí kan olùbánisọ̀rọ̀ létí.

◼ A gbọ́dọ̀ wá irú búrẹ́dì àti wáìnì tí ó bá a mu wẹ́kú, kí wọ́n sì wà ní sẹpẹ́.—Wo Ile-Iṣọ Naa, February 1, 1985, ojú ìwé 17.

◼ Kí a gbé àwo, ago, àti tábìlì àti aṣọ tí ó yẹ wẹ́kú wá sínú gbọ̀ngàn, kí a sì tò wọ́n ṣáájú àkókò.

◼ Kí a jẹ́ kí Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ibòmíràn tí a óò ti pàdé wà ní mímọ́ nigín-nigín ṣáájú àkókò.

◼ Kí a yan àwọn olùbójútó èrò àti àwọn tí yóò gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ kiri, kí a sì fún wọn nítọ̀ọ́ni ṣáájú nípa ìgbésẹ̀ tí ó yẹ àti ẹrù iṣẹ́ wọn.

◼ A gbọ́dọ̀ ṣètò láti gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ lọ fún ẹni àmì òróró èyíkéyìí tí kò lera, tí kò sì ṣeé ṣe fún láti wà níbẹ̀.

◼ Nígbà tí a bá ṣètò fún ayẹyẹ tí ó ju ẹyọ kan lọ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, ìṣètò dáradára gbọ́dọ̀ wà láàárín àwọn ìjọ, kí ìkórajọ tí kò pọndandan má bàa wà ní ibi àbáwọlé, ẹnu ọ̀nà, àwọn ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀, àti ibi ìgbọ́kọ̀sí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́