Ṣé A Óò Ṣe É Lẹ́ẹ̀kan Sí I?—Ìpè Mìíràn fún Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́
1 Kí ni ohun tí a óò tún ṣe lẹ́ẹ̀kan sí i? A óò ha ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní àkókò Ìṣe Ìrántí bí? Àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 1997 gba àfiyèsí wa pẹ̀lú àkọlé gàdàgbà náà: “A Ń Fẹ́—30,000 Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́.” Ní ìgbà náà, a ní ìgbọ́kànlé pé ẹ óò fi ọwọ́ pàtàkì mú ìkésíni yẹn. Nígbà tí a ṣàkójọ ìròyìn iṣẹ́ ìsìn oṣù March 1997, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè dé góńgó 30,000 náà, inú wa dùn láti mọ̀ pé 19,218 forúkọ sílẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́! Bí a bá fi 19,295 aṣáájú ọ̀nà déédéé àti 398 aṣáájú ọ̀nà àkànṣe tí ó ròyìn ní oṣù yẹn kún iye yìí, a rí i pé èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo akéde ni ó wà nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà.
2 A gbóríyìn tọ̀yàyàtọ̀yàyà fún gbogbo àwọn tí ó ṣe àfikún ìsapá láti mú kí ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá wọn pọ̀ sí i lọ́dún tó kọjá. Ní kedere, ìfẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan fún Jèhófà Ọlọ́run àti fún aládùúgbò yín ni ó sún gbogbo yín ṣiṣẹ́. (Lúùkù 10:27; 2 Pét. 1:5-8) Àwọn akéde ní onírúurú àyíká ipò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ìgbésí ayé wá àyè fún ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ní ìjọ kan, akéde 51 ṣe aṣáájú ọ̀nà pa pọ̀ ní oṣù kan náà, èyí ní nínú, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn alàgbà, abiyamọ kan tí ó ní ọmọdébìnrin olóṣù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, arábìnrin kan tí ó fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì wá iṣẹ́ aláàbọ̀ àkókò láti lè jẹ́ kí ó ṣe aṣáájú ọ̀nà, àti arábìnrin àgbàlagbà kan tí kò tíì ṣe aṣáájú ọ̀nà rí. Alábòójútó àyíká kọ̀wé pé: “Ìsapá gígọntiọ nínú iṣẹ́ ìwàásù ń lọ lọ́wọ́. . . . Kì í ṣe kìkì pé èyí ń nípa lórí ìpínlẹ̀ nìkan ni, ṣùgbọ́n àwọn ìjọ ń fi ìtara gbéṣẹ́ṣe. Àwọn ará ń gbádùn títúbọ̀ mọ ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì àti rírí àbájáde rere nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.”
3 A kò yọ àwọn ọ̀dọ́ sílẹ̀ lọ́dún tó kọjá. Ọmọ ọlọ́dún mẹ́tàlá kan, tí ó jẹ́ akéde tí kò tíì ṣe batisí ti ń fojú sọ́nà fún àkókò náà tí òun yóò lè fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ òun sí Jèhófà hàn. Lẹ́yìn tí ó ṣe batisí ní oṣù February, ó kọ̀wé nípa ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù March pé: “Bí kò ti sí ohun tí ó ń dí mi lọ́wọ́ báyìí, mo fi ìwé ìwọṣẹ́ mi sílẹ̀ lójú ẹsẹ̀. . . . Ọ̀pọ̀ ìrírí àgbàyanu tí a gbádùn kì bá tí ṣeé ṣe láé ká ní kì í ṣe nítorí ìkésíni onífẹ̀ẹ́ yín pé kí a ṣe aṣáájú ọ̀nà. Mo kún fún ìmoore sí Jèhófà pé mo ní àǹfààní yìí láti wà lára àwọn tí ó dáhùn padà.” Ó ti gbé góńgó kalẹ̀ láti ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i.
4 Bóyá o wà lára àwọn 19,218 tí wọ́n lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù March tó kọjá, tàbí lára àwọn 18,662 ní oṣù April, tàbí àwọn 13,434 ní oṣù May. Ṣé ìwọ yóò ṣe é lẹ́ẹ̀kan sí i ní ọdún yìí? Bí kò bá ṣeé ṣe fún ọ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà ní ọdún tó kọjá, ṣé o lè ṣe é ní ọdún yìí? Ṣé a lè kọjá 22,199, iye àwọn tí ó ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù April 1990, bóyá kí a sì dójú àmì 30,000 lọ́dún yìí? Iye ti 1990 ni iye tí ó pọ̀ jù lọ ti àwọn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù kan ṣoṣo èyíkéyìí ní Nàìjíríà.
5 Pọkàn Pọ̀ Sórí Oṣù April àti May: Lọ́dún yìí, Ìṣe Ìrántí bọ́ sí Saturday, April 11, ó mú kí oṣù April jẹ́ oṣù dídára jù lọ fún ìgbòkègbodò tí a mú pọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. (2 Kọ́r. 5:14, 15) Ní ọjọ́ 11 àkọ́kọ́ nínú oṣù náà, a óò fún kíkésí àwọn olùfìfẹ́hàn, bí ó bá ti ṣeé ṣe kí wọ́n pọ̀ tó, láti wá sí Ìṣe Ìrántí ní àfiyèsí. Bí o bá wéwèé láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, jọ̀wọ́ fi ìwé ìwọṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ ní ìgbà pípẹ́ ṣáájú déètì tí o fẹ́ láti bẹ̀rẹ̀.—1 Kọ́r. 14:40.
6 Níwọ̀n bí oṣù May ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún kíkúnrẹ́rẹ́, àwọn akéde tí ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tàbí tí ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ alákòókò kíkún lè rí i pé ó túbọ̀ rọrùn fún wọn láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù yẹn. Nípa ṣíṣètò wákàtí mẹ́wàá nínú iṣẹ́ ìsìn pápá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún náà, ìwọ yóò ní láti ṣètò àfikún wákàtí mẹ́wàá péré nínú oṣù náà láti dórí 60 wákàtí tí a béèrè.
7 Ní oṣù April àti May, a óò máa fi àsansílẹ̀ owó Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọni gẹ́gẹ́ bí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àfilọni. Èyí yẹ kí ó fún púpọ̀ sí i lára wa pàápàá níṣìírí láti sapá kí a sì ṣe aṣáájú ọ̀nà. Èé ṣe tí a fi sọ ìyẹn? Ó rọrùn láti fi àwọn ìwé ìròyìn lọni, ó sì ń gbádùn mọ́ni láti fi wọ́n ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Wọ́n ṣeé lò nínú gbogbo apá iṣẹ́ ìsìn—iṣẹ́ ilé dé ilé àti ilé ìtajà dé ilé ìtajà, títí kan ìgbà tí a bá ń tọ àwọn ènìyàn lọ ní òpópónà, ní àwọn ibi ìgbọ́kọ̀sí, àti ní àwọn ọgbà ìtura àti àwọn ipò mìíràn tí kò jẹ́ bí àṣà. Ní pàtàkì jù lọ, Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ń ṣagbátẹrù òtítọ́ Ìjọba náà. Wọ́n ń pe àfiyèsí sí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, wọ́n ń fẹ̀rí hàn pé Ìjọba Ọlọ́run ń ṣàkóso. Wọ́n tún ń ní ipa lórí àwọn òǹkàwé nípa bíbójútó àìní àwọn ènìyàn gan-an. Bí a bá ronú nípa bí àwọn ìwé àtìgbàdégbà yìí ti ṣe ní ipa lórí ìgbésí ayé wa, a óò sún wa láti nípìn-ín nínú pípín wọn kiri bí ó bá ti lè ṣeé ṣe kí ó gbòòrò tó ní oṣù April àti May, kí a sì fún ọ̀pọ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó níṣìírí láti san àsansílẹ̀ owó.
8 Ní ìmúrasílẹ̀ fún ìgbòkègbodò ìwé ìròyìn tí a mú gbòòrò sí i yìí, ìwọ yóò jàǹfààní láti inú ṣíṣàtúnyẹ̀wò àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí: “Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí!—Àwọn Àkànṣe Ìwé-Ìròyìn Òtítọ́ Bíbọ́sákòókò” (Ilé-Ìṣọ́nà, January 1, 1994), “Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Lọ́nà Tí Ó Dára Jù Lọ” (Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, March 1996), àti “Múra Ìgbékalẹ̀ Tìrẹ fún Ìfilọni Ìwé Ìròyìn” (Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, October 1996).
9 Àwọn Alàgbà Ń Mú Ipò Iwájú: Láti ṣèrànwọ́ fún ọ̀pọ̀ akéde tí wọ́n ṣe aṣáájú ọ̀nà lọ́dún tó kọjá, àwọn alàgbà inú ìjọ kan ṣagbátẹrù ọjọ́ Saturday kan nínú oṣù gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àkànṣe fún ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ìjọ náà. Wọ́n ṣètò láti pàdé ní àwọn ìgbà mélòó kan ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ọjọ́ náà, èyí fún gbogbo àwọn tí ó wà nínú ìjọ ní àǹfààní láti nípìn-ín nínú onírúurú ọ̀nà ìjẹ́rìí. Ìwọ̀nyí ní nínú, ṣíṣiṣẹ́ ní àwọn ibi iṣẹ́ ajé, jíjẹ́rìí ní òpópónà, kíkésíni láti ilé dé ilé, àti ṣíṣe àwọn ìpadàbẹ̀wò. Ìdáhùnpadà náà ga lọ́lá, akéde 117 ni ó lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá ní ọjọ́ yẹn. Àpapọ̀ wákàtí tí wọ́n lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ jẹ́ 521, wọ́n sì fi 617 ìwé ìròyìn, ìwé pẹlẹbẹ, àti ìwé ńlá sóde! Ìdùnnú ọjọ́ Saturday yẹn bá wọn wọ ọjọ́ Sunday, tí iye àwọn tí ó pésẹ̀ sí Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ti èyí tí ó jẹ́ iye tí ó pọ̀ jù lọ tẹ́lẹ̀ rí.
10 Nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn kọ̀ọ̀kan ní oṣù April àti May, kí a rán ìjọ létí nípa àkókò tí a óò ṣe ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e àti ibi tí a óò ti ṣe é, pàápàá bí a bá ṣe àwọn ètò kan ní àfikún yàtọ̀ sí èyí tí a ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. A fún àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé àti àwọn akéde tí kì í ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ níṣìírí láti ṣètìlẹ́yìn fún ìṣètò àwùjọ wọ̀nyí bí àyíká ipò wọn bá ti fàyè gbà wọ́n sí.
11 Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn yóò ní láti pàdé pọ̀ pẹ̀lú arákùnrin tí ń pín àwọn ìpínlẹ̀ fúnni láti ṣètò fún ṣíṣiṣẹ́ ní àwọn ibi tí a kì í ṣe lóòrèkóòrè. A lè fún àwọn tí kì í sí nílé ní àfiyèsí púpọ̀ sí i kí a sì ṣiṣẹ́ ní àwọn òpópónà àti láti ilé ìtajà dé ilé ìtajà. A lè tẹra mọ́ ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́ ní oṣù April. Kí a béèrè fún àwọn ìwé ìròyìn tí ó tó fún oṣù April àti May ní ìfojúsọ́nà fún ìgbòkègbodò tí a mú pọ̀ sí i.
12 Ọ̀pọ̀ Akéde Lè Tóótun: Gbólóhùn àkọ́kọ́ lórí ìwé ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ sọ pé: “Nitori ifẹ mi fun Jehofah ati ifẹ-ọkan mi lati ran awọn ẹlomiran lọwọ lati kẹkọọ nipa rẹ̀ ati awọn ete rẹ̀ onifẹẹ, emi yoo fẹ́ lati fikun ìpín-ipa mi ninu iṣẹ-isin pápá-oko nipasẹ fiforukọsilẹ gẹgẹ bi aṣaaju-ọna oluranlọwọ.” Nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti fífẹ́ láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí jẹ́ ìdí pàtàkì fún ìyàsímímọ́ wa. (1 Tím. 4:8, 10) Láti tóótun fún ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, ẹnì kan gbọ́dọ̀ ṣe batisí, kí ó ní ìdúró rere ní ti ìwà híhù, kí ó sì wà ní ipò láti ya 60 wákàtí sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú oṣù náà. Bí gbogbo wa ti ń gbé àyíká ipò wa yẹ̀ wò, ǹjẹ́ díẹ̀ lára àwa tí a kò tíì ṣe aṣáájú ọ̀nà rí ha lè ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ọdún yìí ní oṣù April tàbí May bí?
13 Ọ̀pọ̀ nínú ìjọ lè rí i pé àwọn pẹ̀lú lè ṣe aṣáájú ọ̀nà nígbà tí wọ́n bá rí àwọn ẹlòmíràn tí àyíká ipò wọn jọ tiwọn tí wọ́n ń forúkọ sílẹ̀. Àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́, àgbàlagbà, òṣìṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ alákòókò kíkún, títí kan àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, àti àwọn mìíràn ti kẹ́sẹ járí nínú ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ìyàwó ilé kan tí ó sì jẹ́ ìyá ọlọ́mọ méjì tí ó ń ṣe iṣẹ́ alákòókò kíkún lé 60 wákàtí bá, ó fi ìwé ìròyìn 180 sóde, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì 3 ní oṣù kan tí ó fi ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Báwo ni òun ṣe ṣe é? Ó lo àkókò oúnjẹ ọ̀sán rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ láti jẹ́rìí ní ìpínlẹ̀ tí ó wà nítòsí, ó jẹ́rìí nípa kíkọ lẹ́tà, ó sì lọ́wọ́ nínú jíjẹ́rìí ní ibi ìgbọ́kọ̀sí àti ní òpópónà. Ó tún lo àyè ìsinmi rẹ̀ kúrò lẹ́nu iṣẹ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ lọ́nà tí ó ṣàǹfààní gidigidi nípa nínípìn-ín pẹ̀lú ìjọ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ronú lákọ̀ọ́kọ́ pé ọwọ́ òun kò lè tó ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, pẹ̀lú ìṣírí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn àti ìṣètò gbígbéṣẹ́, ó borí àwọn ìdènà náà.
14 Jésù mú un dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú pé: “Àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Mát. 11:30) Ìyẹn ni àkọlé àpilẹ̀kọ kan tí ń fúnni níṣìírí nínú Ilé-Ìṣọ́nà August 15, 1995. Ó sọ nípa arábìnrin kan tí ń ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ alákòókò kíkún tí ń kó pákáǹleke báni. Òun ha ronú pé òun kò lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ bí? Ó tì o. Àní, ó ń sapá láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣooṣù. Èé ṣe? Nítorí pé ó rò ó pé ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà ń ran òun lọ́wọ́ ní ti gidi láti pa ìwàdéédéé òun mọ́. Ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ bí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti rírí wọn bí wọ́n ti ń yí ìgbésí ayé wọn padà láti jèrè ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run ni orísun ìdùnnú gíga jù lọ fún un nínú ìgbésí ayé rẹ̀ tí ó dí fọ́fọ́.—Òwe 10:22.
15 Fífi ara ẹni rúbọ àti àtúnṣe èyíkéyìí tí ẹnì kan ní láti ṣe kí ó lè ṣe aṣáájú ọ̀nà kò tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ìbùkún tí ẹni náà yóò gbádùn. Arábìnrin kan kọ̀wé nípa ìrírí rẹ̀ lẹ́nu ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ pé: “Ó ràn mí lọ́wọ́ láti má ṣe mọ ti ara mi nìkan, ó sì jẹ́ kí n túbọ̀ pọkàn pọ̀ sórí ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. . . . Mo dámọ̀ràn rẹ̀ fún àwọn tí ó bá lè ṣe é.”
16 Ó Ń Béèrè Ìṣètò Rere: Ní ojú ìwé tí ó kẹ́yìn àkìbọnú yìí, a ti tún pèsè àpẹẹrẹ ìṣètò tí ó fara hàn nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 1997. Bóyá ọ̀kan lára ìwọ̀nyí bá àyíká ipò rẹ mu. Bí o ti ń ṣàyẹ̀wò wọn, ronú nípa ìgbòkègbodò tí o máa ń ṣe déédéé lóṣooṣù. Àwọn iṣẹ́ wo ni o lè ṣe ní àyíká ilé ṣáájú ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà tàbí tí o lè pa tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan fún ìgbà díẹ̀ di ọjọ́ iwájú? O ha lè fagi lé díẹ̀ nínú àkókò tí o ń lò fún eré ìnàjú, eré ìtura, tàbí onírúurú àwọn ìgbòkègbodò fàájì mìíràn bí? Dípò ríronú nípa àròpọ̀ 60 wákàtí tí a ń béèrè, wéwèé ìṣètò rẹ lórí ìpìlẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tàbí ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Wákàtí 2 péré lóòjọ́ tàbí wákàtí 15 péré lọ́sẹ̀ ni a ń béèrè láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Wo àpẹẹrẹ àwọn ìṣètò náà, bí o sì ti mú pẹ́ńsù dání, wo ohun tí o lè ṣe ní ti ìṣètò fún iṣẹ́ ìsìn tìrẹ, tí ó bá a mu jù lọ fún ìwọ àti ìdílé rẹ.
17 Ìdáhùnpadà rere àti àfikún ìtìlẹ́yìn tí ìjọ fi hàn fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní ọdún tó kọjá fún ìtara aṣáájú ọ̀nà déédéé kan lágbára, ẹni tí ó kọ̀wé pé: “Ẹ ṣeun lọ́pọ̀lọpọ̀ fún ìfẹ́ yín tí ń fúnni níṣìírí láti ṣe àfikún ìsapá láti ṣètìlẹ́yìn fún ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. . . . Àwọn ìṣètò tí ẹ dábàá ran ọ̀pọ̀ tí kò tíì ṣe aṣáájú ọ̀nà rí lọ́wọ́ láti mọ̀ pé wọ́n lè ṣe é. . . . Mo láyọ̀ gidigidi láti jẹ́ ara ètò àjọ Jèhófà kí n sì tẹ̀ lé ìdarí onífẹ̀ẹ́, tí ó jẹ́ aláyọ̀ ti ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà.”
18 Òwe 21:5 mú un dá wa lójú pé: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.” Òwe 16:3 fún wa níṣìírí pé: “Yí àwọn iṣẹ́ rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà tìkára rẹ̀, a ó sì fìdí àwọn ìwéwèé rẹ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.” Bẹ́ẹ̀ ni, nípa fífi tàdúràtàdúrà fi Jèhófà sínú ìpinnu wa, tí a sì gbára lé e gidigidi láti ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí, a lè fojú sọ́nà fún rere nípa àwọn ìwéwèé wa láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ó lè jẹ́ pé lẹ́yìn rírí bí ìṣètò wa ṣe yọrí sí rere tó fún oṣù kan tàbí méjì nínú ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, a óò lè sàmì o-gbà á sínú àpótí tí ó wà lórí ìwé ìwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tí ó kà pé: “Sami o-gbà-á sinu apoti yii bi o bá dàníyànfẹ́ lati maa ṣiṣẹsin lọ bii aṣaaju-ọna oluranlọwọ titi iyipada miiran yoo fi ṣẹlẹ.” Bí ó ti wù kí ó rí, a lè fojú sọ́nà fún ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lẹ́ẹ̀kan sí i ní oṣù August, nígbà tí a óò ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún kíkúnrẹ́rẹ́. Bí a óò ti parí ọdún iṣẹ́ ìsìn ní oṣù August, a óò ṣe ìsapá àjùmọ̀ṣe kí gbogbo wa lè kópa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó.
19 Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, ẹni yẹn pẹ̀lú yóò ṣe àwọn iṣẹ́ tí èmi ń ṣe; yóò sì ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó tóbi ju ìwọ̀nyí.” (Jòh. 14:12) Ó jẹ́ àǹfààní aláyọ̀ wa láti sìn gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń ní ìmúṣẹ rẹ̀ títóbilọ́lá. Ìsinsìnyí ni àkókò láti wàásù ìhìn rere pẹ̀lú okun ńláǹlà ju ti ìgbàkígbà rí lọ, kí a máa ra àkókò tí ó rọgbọ padà láti ṣe iṣẹ́ yìí. (1 Kọ́r. 3:9; Kól. 4:5) Lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóòrèkóòrè bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó jẹ́ ọ̀nà tí ó dára jù lọ láti ṣe ipa tiwa gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba. A ń fi ìháragàgà dúró láti rí i bí orin ìyìn láti ọ̀dọ̀ àwọn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ yóò ṣe pọ̀ tó ní àkókò Ìṣe Ìrántí yìí. (Sm. 27:6) Bí a ṣe ń ronú nípa àbájáde ti ọdún tí ó kọjá, a ń ṣe kàyéfì pé, ‘Ṣé a óò ṣe é lọ́dún yìí?’ A ní ìgbọ́kànlé pé a óò ṣe é!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
Ṣé O Lè Ṣe Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́?
“Ipo ara-ẹni yowu tí tirẹ lè jẹ́, bi iwọ bá ti ṣe iribọmi tí o sì wà ní iduro deedee nipa iwarere, iwọ lè ṣeto lati dé oju-ila 60 wakati tí a beere fun ní oṣu kan ninu iṣẹ-ojiṣẹ pápá-oko ki o sì gbagbọ pe o lè sìn fun oṣu kan tabi jù bẹẹ lọ gẹgẹ bi aṣaaju-ọna oluranlọwọ, awọn alagba ijọ yoo ní inudidun lati ṣiṣẹ lori iwe-ìwọṣẹ́ rẹ fun anfaani iṣẹ-isin yii.”—Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-Ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 114.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Ìṣètò Olùrànlọ́wọ́ Aṣáájú Ọ̀nà
Àpẹẹrẹ Àwọn Ọ̀nà Láti Ṣètò Wákàtí 15 Lọ́sẹ̀ fún Iṣẹ́ Ìsìn Pápá
Òwúrọ̀—Monday títí di Saturday
A lè fi Sunday dípò ọjọ́ èyíkéyìí
Ọjọ́ Àkókò Wákàtí
Monday Òwúrọ̀ 2 1⁄2
Tuesday Òwúrọ̀ 2 1⁄2
Wednesday Òwúrọ̀ 2 1⁄2
Thursday Òwúrọ̀ 2 1⁄2
Friday Òwúrọ̀ 2 1⁄2
Saturday Òwúrọ̀ 2 1⁄2
Àròpọ̀ Wákàtí: 15
Odindi Ọjọ́ Méjì
A lè yan ọjọ́ méjì èyíkéyìí nínú ọ̀sẹ̀
Ọjọ́ Àkókò Wákàtí
Wednesday Odindi Ọjọ́ 7 1⁄2
Saturday Odindi Ọjọ́ 7 1⁄2
Àròpọ̀ Wákàtí: 15
Ìrọ̀lẹ́ Méjì àti Òpin Ọ̀sẹ̀
A lè yan ìrọ̀lẹ́ méjì èyíkéyìí láàárín ọ̀sẹ̀
Ọjọ́ Àkókò Wákàtí
Monday Ìrọ̀lẹ́ 1 1⁄2
Wednesday Ìrọ̀lẹ́ 1 1⁄2
Saturday Odindi Ọjọ́ 8
Sunday Ìlàjì Ọjọ́ 4
Àròpọ̀ Wákàtí: 15
Ọ̀sán Àwọn Ọjọ́ Àárín Ọ̀sẹ̀ àti Saturday
A lè fi Sunday dípò ọjọ́ èyíkéyìí
Ọjọ́ Àkókò Wákàtí
Monday Ọ̀sán 2
Tuesday Ọ̀sán 2
Wednesday Ọ̀sán 2
Thursday Ọ̀sán 2
Friday Ọ̀sán 2
Saturday Odindi Ọjọ́ 5
Àròpọ̀ Wákàtí: 15
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Iṣẹ́ Ìsìn Tèmi
Pinnu iye wákàtí fún àkókò kọ̀ọ̀kan
Ọjọ́ Àkókò Wákàtí
Monday
Tuesday
Wednesday
Thursday
Friday
Saturday
Sunday
Àròpọ̀ Wákàtí: 15