Àkókò Ìṣe Ìrántí—Àkókò Tí Ìgbòkègbodò Tẹ̀mí Wa Máa Ń Pọ̀ Sí I
1. Báwo ni “àwọn àjọyọ̀ abágbàyí” ṣe ṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run láǹfààní?
1 Láyé ọjọ́un, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe “àwọn àjọyọ̀ abágbàyí ti Jèhófà” láwọn àkókò tí Jèhófà ti yà sọ́tọ̀ láàárín ọdún. (Léf. 23:2) Bí wọ́n ṣe ń wá àyè láti ronú jinlẹ̀ nípa oore Ọlọ́run ń jẹ́ kí wọ́n láyọ̀ gan-an, ó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa fi ìtara ṣe ìjọsìn mímọ́.—2 Kíró. 30:21–31:2.
2, 3. Kí nìdí tó fi yẹ ká mú kí ìgbòkègbodò tẹ̀mí wa pọ̀ sí i lákòókò Ìṣe Ìrántí, ọjọ́ wo la sì máa ṣe Ìṣe Ìrántí?
2 Lóde òní, àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí wa tí ń fún wa láyọ̀ máa ń pọ̀ lọ́dọọdún lákòókò Ìṣe Ìrántí. Àkókò yẹn la túbọ̀ máa ń ronú jinlẹ̀ lórí ẹ̀bùn iyebíye tí Jèhófà fún wa, ìyẹn ni Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo. (Jòh. 3:16; 1 Pét. 1:18, 19) Bí a bá ń ṣàṣàrò lórí ìfẹ́ tí Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ fi hàn sí wa, á máa wù wá láti yin Jèhófà látọkànwá, a ó sì fẹ́ sa gbogbo ipá wa láti ṣe ohun tó fẹ́.—2 Kọ́r. 5:14, 15.
3 Lọ́dún yìí, a ó ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ní Thursday, March 24, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Báwo la ṣe lè mú kí ìgbòkègbodò tẹ̀mí wa pọ̀ sí i lóṣù March, April àti May?
4, 5. (a) Kí làwọn ará kan máa ń ṣe kí wọ́n lè wàásù ìhìn rere fún àwọn èèyàn púpọ̀ sí i? (b) Kí lo máa ń ṣe kó o lè wàásù fún àwọn èèyàn púpọ̀ sí i ní ìpínlẹ̀ ìjọ rẹ?
4 Ohun Tí A Lè Ṣe Ká Lè Wàásù fún Àwọn Èèyàn Púpọ̀ Sí I: Ronú nípa oríṣiríṣi ọ̀nà tí wàá fi lè wàásù fún àwọn èèyàn púpọ̀ sí i nígbà tó o bá lọ sóde ẹ̀rí. Ǹjẹ́ o lè lọ ṣe iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń wà nílé, irú bíi lọ́wọ́ ọ̀sán tàbí ìrọ̀lẹ́? Bí àwọn ará kan ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ yín bá fẹ́ wàásù fúngbà díẹ̀ kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀, alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ lè ṣètò pé kí a ṣe ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá ní ṣókí kí wọ́n lè lọ ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ tó bá wà nítòsí.
5 Ohun mìíràn tá a lè ṣe ká bàa lè wàásù fún ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé ká lọ wàásù láwọn ibi tí èrò máa ń pọ̀ sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ arábìnrin kan ní Japan máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò, ó wù ú láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Alàgbà kan wá gbà á nímọ̀ràn pé, láràárọ̀ kó tó lọ sẹ́nu iṣẹ́, kó gbìyànjú láti máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nítòsí ibùdókọ̀ ojú irin. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀, ojú máa ń tì í, àwọn èrò ọkọ̀ kan sì máa ń fi ṣe yẹ̀yẹ́, àmọ́ nígbà tó yá ó borí nǹkan wọ̀nyí. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn èèyàn tó tó ogójì ló bẹ̀rẹ̀ sí fún ní ìwé ìròyìn déédéé, lára wọn sì ni àwọn èrò inú ọkọ̀, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ibùdókọ̀ ojú irin náà àtàwọn tó ń tajà nítòsí ibẹ̀. Ó máa ń fi nǹkan bí ìwé ìròyìn ọgọ́rùn-ún méjì ó lé márùndínlógójì síta lóṣooṣù. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ó tún máa ń lo ìṣẹ́jú díẹ̀ láti fi bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
6. Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè mú kí ìgbòkègbodò tẹ̀mí wọn pọ̀ sí i?
6 Àwọn Àǹfààní Tá A Ní Láti Wàásù: Ọ̀pọ̀ akéde tí wọ́n ṣì ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ máa ń gbọlidé láàárín ọdún. Wọ́n lè fi àkókò yìí ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Síwájú sí i, àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí lè mú kí ìgbòkègbodò wọn pọ̀ sí i bí wọ́n bá ń wàásù ní ilé ẹ̀kọ́. Ìyàlẹ́nu ló máa jẹ́ fún ọ pé àwọn ọmọ kíláàsì rẹ á fẹ́ mọ̀ nípa àwọn ohun tó o gbà gbọ́. O ò ṣe lo àǹfààní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tẹ́ ẹ máa ń ṣe nínú kíláàsì tàbí àròkọ tó o bá kọ láti fi jẹ́rìí? Àwọn fídíò tí ètò àjọ Ọlọ́run ṣe làwọn kan máa ń lò láti fi wàásù. Àwọn akéde kan bá àwọn ọmọ kíláàsì wọn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́ débi pé wọ́n ṣe ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi. Gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ ọ̀nà dáradára tá a lè gbà “yin orúkọ Jèhófà.”—Sm. 148:12, 13.
7. (a) Báwo ni arákùnrin kan ṣe lo àǹfààní kan tó ní láti fi wàásù fún àwọn èèyàn? (b) Ǹjẹ́ o ti ní irú ìrírí yìí?
7 Nínú ìgbòkègbodò rẹ ojoojúmọ́, máa wá onírúurú ọ̀nà tó o lè gbà bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run ìyanu wa àtàwọn ìlérí àgbàyanu tó ṣe. Arákùnrin kan tó máa ń wọ ọkọ̀ ojú irin kan náà lójoojúmọ́ máa ń jẹ́rìí fún àwọn èrò ọkọ̀ nígbà tí àyè bá ti lè ṣí sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó bá ń dúró de ọkọ̀, ó máa ń lo àǹfààní yẹn láti fi nǹkan bí ìṣẹ́jú márùn-ún wàásù fún ọ̀dọ́kùnrin kan lójoojúmọ́. Àbájáde èyí ni pé ọ̀dọ́kùnrin náà àti ẹnì kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ gbà pé kó máa bá àwọn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú ọkọ̀ ojú irin yìí ni wọ́n ti máa ń kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì náà bí wọ́n ṣe ń lọ. Láìpẹ́, obìnrin àgbàlagbà kan tó ti máa ń fetí kọ́ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wọn lọ bá arákùnrin yìí pé kó máa bá òun náà ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí arákùnrin yìí ṣe tún ń bá obìnrin náà ṣèkẹ́kọ̀ọ́ láwọn ọjọ́ tó bá wọ ọkọ̀ ojú irin náà nìyẹn. Lọ́nà yìí, arákùnrin náà ti bá àwọn èèyàn mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ nínú ọkọ̀ ojú irin náà.
8. Báwo làwọn tó jẹ́ pé ìwọ̀nba lohun tí wọ́n lè ṣe nítorí ọjọ́ ogbó tàbí àìsàn ṣe lè mú kí ìgbòkègbodò wọn pọ̀ sí i?
8 Àmọ́ o, tó bá jẹ́ pé ìwọ̀nba lo lè ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ nítorí ọjọ́ ogbó tàbí àìsàn ńkọ́? Àwọn ohun mìíràn ṣì wà tó o lè ṣe láti túbọ̀ fi ìyìn fún Jèhófà. Ǹjẹ́ o ti gbìyànjú lílo tẹlifóònù láti fi wàásù? Bí o kò bá mọ bó o ṣe lè ṣe é, sọ fún alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ yín. Ó lè ṣètò pé kí àwọn akéde tó máa ń fi tẹlifóònù jẹ́rìí dáadáa bá ọ ṣiṣẹ́. Bí ẹ bá jọ ṣiṣẹ́ pọ̀, ẹ ó lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára ara yín, ẹ ó sì lè ran ara yín lọ́wọ́ láti wàásù lọ́nà tó máa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn. Àwọn àbá tó lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè mọ bá a ṣe lè fi tẹlifóònù jẹ́rìí wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 2001, ojú ìwé 5 àti 6.
9. Báwo la ṣe lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè kúnjú òṣùwọ̀n láti máa lọ sóde ẹ̀rí pẹ̀lú àwọn ará?
9 Bí àwọn ẹni tuntun bá wá síbi Ìṣe Ìrántí, èyí lè mú kí wọ́n fẹ́ láti túbọ̀ yin Jèhófà. Bí wọ́n bá ń bẹ̀rù láti lọ wàásù lóde ẹ̀rí, máa sọ àwọn ìrírí tí ń gbéni ró tí ìwọ tàbí àwọn akéde mìíràn ní lóde ẹ̀rí fún wọn láti fi ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí ìbẹ̀rù yìí. Síwájú sí i, máa dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀díẹ̀ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n ṣe lè ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì fún àwọn ẹlòmíràn àti bí wọ́n ṣe lè fi ẹ̀rí ti ohun tí wọ́n gbà gbọ́ lẹ́yìn. (1 Pét. 3:15) Bí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bá sọ pé òun fẹ́ máa kéde ìhìn rere, sọ fún alábòójútó olùṣalága. Yóò ṣètò pé kí àwọn alàgbà méjì rí akẹ́kọ̀ọ́ náà kí wọ́n lè mọ̀ bóyá ó kúnjú òṣùwọ̀n láti máa lọ sóde ẹ̀rí pẹ̀lú àwọn ará. Dájúdájú, inú Jèhófà yóò máa dùn gan-an bó ṣe ń rí i pé àwọn ẹni tuntun ń gbà pé òun ni ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run!—Òwe 27:11.
10. (a) Báwo ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó dára ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́? (b) Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún ọ láti ṣètò àwọn ìgbòkègbodò rẹ lọ́dún tó kọjá kó o lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lákòókò Ìṣe Ìrántí? Báwo lo ṣe ṣe é?
10 Ǹjẹ́ O Lè Ṣe Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́? Ó yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú àádọ́ta wákàtí tí à ń retí pé kí àwọn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ròyìn lóṣù. (Mát. 5:37) Ìyẹn túmọ̀ sí pé o ní láti ṣètò àwọn ìgbòkègbodò rẹ kó o lè máa lo nǹkan bí wákàtí méjìlá lóde ẹ̀rí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ǹjẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ṣe lè ṣètò àkókò òde ẹ̀rí tó wà lójú ìwé 5 lè wúlò fún ọ? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ǹjẹ́ o lè ṣe ètò kan fúnra rẹ tó máa jẹ́ kó o lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù March, April tàbí May? Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó bù kún gbogbo ìsapá rẹ láti mú kí ìgbòkègbodò rẹ pọ̀ sí i.—Òwe 16:3.
11. Báwo làwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ṣe lè ṣètìlẹyìn fún àwọn tó bá ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?
11 Àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ á ṣètìlẹyìn fún ọ gan-an kó o lè lo àkókò Ìṣe Ìrántí yìí láti fi yin Jèhófà lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Kódà, ó lè jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára wọn ló máa ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Àwọn alàgbà yóò ṣètò àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá mìíràn sí i, irú bíi lọ́wọ́ ọ̀sán tàbí ìrọ̀lẹ́ láàárín ọ̀sẹ̀, àti ní òpin ọ̀sẹ̀, bí wọ́n bá ṣe rí i pé ó yẹ. Kí àwọn alàgbà lè ṣètò ibi tá a ti máa ṣe ìpàdé wọ̀nyí àti àkókò tá a máa ṣe é, àti ẹni tó máa wà níbẹ̀ láti bójú tó ètò iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n lè bá àwọn tó ti ṣe ètò gúnmọ́ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà tàbí àwọn tó ń gbèrò láti ṣe bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀. Àwọn alàgbà yóò gbìyànjú láti ṣe àwọn ètò tó yẹ kó o lè rí àwọn akéde tó o máa bá ṣiṣẹ́ láwọn ọjọ́ àti àkókò tó o ti yà sọ́tọ̀ fún òde ẹ̀rí. Lọ́nà yìí, àwọn ètò tó o ti ṣe á lè fìdí múlẹ̀, wàá sì lè ṣe àṣeyọrí tó pọ̀ gan-an.—Òwe 20:18.
12. Kí ló ń sún wa láti máa yin Jèhófà ní gbogbo ìgbà?
12 Sa Gbogbo Ipá Rẹ: Bí kò bá ṣeé ṣe fún ọ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nítorí bí nǹkan ṣe rí fún ọ, máa rántí pé Jèhófà yóò tẹ́wọ́ gba àwọn ohun tí à ń sapá láti ṣe àti ẹbọ wa ‘ní ìbámu pẹ̀lú ohun tá a ní, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kò ní.’ (2 Kọ́r. 8:12) Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ti ṣe fún wa tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Abájọ tí Dáfídì fi kọ̀wé pé: “Ṣe ni èmi yóò máa fi ìbùkún fún Jèhófà ní gbogbo ìgbà; ìgbà gbogbo ni ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi.” (Sm. 34:1) Ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ó ṣe ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ lákòókò Ìṣe Ìrántí yìí.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
Báwo Ni Wàá Ṣe Mú Kí Ìgbòkègbodò Rẹ Pọ̀ Sí I?
◼ Máa wàásù nígbà táwọn èèyàn bá wà nílé
◼ Máa wàásù láwọn ibi táwọn èrò máa ń pọ̀ sí
◼ Máa jẹ́rìí níbi iṣẹ́ àti ní ilé ẹ̀kọ́
◼ Máa fi tẹlifóònù jẹ́rìí
◼ Gba iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 5]
Bí Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Ṣe Lè Ṣètò Àkókò Òde Ẹ̀rí—Bí A Ṣe Lè Máa Lo Wákàtí Méjìlá Lóde Ẹ̀rí Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀
Òwúrọ̀—Monday Títí Di Saturday
O lè fi Sunday dípò ọjọ́ èyíkéyìí.
Ọjọ́ Àkókò Wákàtí
Monday Òwúrọ̀ 2
Tuesday Òwúrọ̀ 2
Wednesday Òwúrọ̀ 2
Thursday Òwúrọ̀ 2
Friday Òwúrọ̀ 2
Saturday Òwúrọ̀ 2
Àròpọ̀ Wákàtí: 12
Ọjọ́ Méjì Lọ́sẹ̀
O lè yan ọjọ́ méjì èyíkéyìí lọ́sẹ̀. (Ó láwọn ọjọ́ tó o lè yàn tí gbogbo wákàtí tó o máa ní lóṣù kò ní ju wákàtí méjìdínláàádọ́ta lọ.)
Ọjọ́ Àkókò Wákàtí
Wednesday Ojúmọ́ 6
Saturday Ojúmọ́ 6
Àròpọ̀ Wákàtí: 12
Ìrọ̀lẹ́ Méjì àti Òpin Ọ̀sẹ̀
O lè yan ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ méjì èyíkéyìí láàárín ọ̀sẹ̀.
Ọjọ́ Àkókò Wákàtí
Monday Ìrọ̀lẹ́ 1 1⁄2
Wednesday Ìrọ̀lẹ́ 1 1⁄2
Saturday Ojúmọ́ 6
Sunday Ìdajì ọjọ́ 3
Àròpọ̀ Wákàtí: 12
Ọ̀sán Mẹ́ta àti Saturday
O lè fi Sunday dípò ọjọ́ èyíkéyìí.
Ọjọ́ Àkókò Wákàtí
Monday Ọ̀sán 2
Wednesday Ọ̀sán 2
Friday Ọ̀sán 2
Saturday Ojúmọ́ 6
Àròpọ̀ Wákàtí: 12
Àkókò Tí Mo Fẹ́ Máa Lọ Sóde Ẹ̀rí
Pinnu iye wákàtí tó o fẹ́ máa lò ní àkókò kọ̀ọ̀kan
Ọjọ́ Àkókò Wákàtí
Monday
Tuesday
Wednesday
Thursday
Friday
Saturday
Sunday
Àròpọ̀ Wákàtí: 12