Padà Lọ Láti Gba Àwọn Díẹ̀ Là
1 Ó jẹ́ ìfẹ́ inú Ọlọrun “pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là kí wọn sì wá sí ìmọ̀ pípéye nipa òtítọ́.” (1 Tim. 2:4) Kí ni a lè ṣe láti ṣèrànwọ́? Ṣe ìpadàbẹ̀wò pẹ̀lú ète fífi òtítọ́ kọ́ni. Kí ni ìwọ yóò sọ? Àwọn àbá tí ó tẹ̀ lé e yìí lè ṣèrànwọ́ fún ọ.
2 Nígbà tí o bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹnì kan tí ó gba ìwé “Jẹ́ Kí Ijọba Rẹ Dé,” o lè tọ́ka sí àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé 4 àti 5 lẹ́ẹ̀kan sí i, kí o sì bi onílé pé:
◼ “Lẹ́yìn ṣíṣàyẹ̀wò ìwé tí mo fi sílẹ̀ fún ọ kínníkínní síwájú sí i, àti ríronú lórí ìlérí paradise kan lórí ilẹ̀ ayé tí Ọlọrun ṣe, kí ni èrò rẹ nípa àwọn ìlérí àgbàyanu wọ̀nyí tí Ọlọrun ti ṣe fún aráyé?” Lẹ́yìn gbígbọ́ ìdáhùn onílé, tí o sì ti fèsì sí i ní kúkúrú, o lè pe àfiyèsí sí orí 6, kí ẹ sì gbé bí ó ṣe yẹ kí a dáhùn padà sí àǹfààní ìyè àìnípẹ̀kun lábẹ́ ìjọba pípé yẹ̀ wò. Ẹ gbé ìpínrọ̀ 1 sí 3 àti gbogbo àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tí a tọ́ka sí nínú àwọn ìpínrọ̀ náà yẹ̀ wò.
3 Bí o bá lo ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó wà ní ojú ìwé 12, ìpínrọ̀ 5, nínú ìwé “Reasoning” láti fi ìwé “Jẹ́ Kí Ijọba Rẹ Dé” lọni, o lè máa bá ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ náà nìṣó nípa sísọ pé:
◼ “Nígbà tí mo wábí kẹ́yìn, a jíròrò nípa bí Ìjọba Ọlọrun ṣe jẹ́ gidi. A gbé àwọn ohun tí Ìjọba Ọlọrun yóò ṣàṣeparí rẹ̀ yẹ̀ wò, irú bíi mímú ikú àti ìkárísọ kúrò, àti sísọ ilẹ̀ ayé di paradise kan. Ìbéèrè náà nísinsìnyí ní pé: Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe láti tóótun fún àwọn ìbùkún wọ̀nyí? Báwo ni ìwọ yóò ṣe dáhùn ìbéèrè yẹn? [Jẹ́ kí ó fèsì.]” Ṣí i sí ojú ìwé 174 àti 175, kí o sì jíròrò àwọn èrò tí ń bẹ nínú ìpínrọ̀ 1 sí 4, ní títẹnu mọ́ ìdí tí ó fi yẹ kí a pinnu, bíi ti àwọn Kristian àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, láti sin Jehofa. Ṣàlàyé bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé yóò ṣe ràn án lọ́wọ́ láti sin Jehofa.
4 O lè ṣiṣẹ́ lórí ìwé “Yiyan Ọna Igbesi Ayé Ti O Dara Julọ” tí o fi síta, pẹ̀lú ọ̀nà ìgbàyọsíni yìí:
◼ “Ní ìṣáájú, mo pe àfiyèsí rẹ sórí ìlérí Ọlọrun tí yóò mú kí ìgbésí ayé wa ní ète. Mo tún mẹ́nu kàn án pé, a lè ní ìgbésí ayé tí ó dára jù lọ nísinsìnyí nípa fífi àwọn ìlànà Jehofa sílò nínú ìgbésí ayé wa. Báwo ni èyí ti jẹ́ òtítọ́ tó? Èmi yóò fẹ́ láti lo ìṣẹ́jú díẹ̀ pẹ̀lú rẹ láti yẹ àwọn kókó díẹ̀ wò ní ojú ìwé 9, ìpínrọ̀ 11, lórí ìdí tí gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọrun fi jẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó dára jù lọ.” Ka àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́, kí o sì lò wọn.
5 O lè ṣiṣẹ́ lórí ìwé “Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ” tí o fi síta, nípa sísọ pé:
◼ “Mo padà wá láti fi ìdí tí a fi lè wo ọjọ́ ọ̀la pẹ̀lú ìgbọ́kànlé hàn ọ́.” Gbé orí 2, ìpínrọ̀ 24 sí 28 yẹ̀ wò pẹ̀lú rẹ̀. Fẹ̀rí hàn pé Ẹlẹ́dàá wa lọ́kàn-ìfẹ́ nínú ọjọ́ ọ̀la rẹ̀. Yíyẹ ìwé náà wò síwájú sí i yóò pèsè ìjíròrò nípa ìmọ̀ràn òdodo Jehofa fún ire rẹ̀. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ lọ̀ ọ́.
6 Rántí pé, ète ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò jẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. A ṣe ìwé tuntun náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, ní pàtàkì, fún dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tí a bá ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìwé ògbólógbòó tí a fi síta, tí a sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ti gidi, yóò dára láti darí àfiyèsí sórí ìwé tuntun yìí. A óò rí ìdùnnú púpọ̀ bí àwọn tí ń kẹ́kọ̀ọ́ ti ń kọ́ láti ké pe Jehofa fún ìgbàlà.—Ìṣe 2:21.