ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/96 ojú ìwé 8
  • Ẹ Máa Bá A Lọ Ní Sísọ Òtítọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Máa Bá A Lọ Ní Sísọ Òtítọ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Padà Lọ Láti Gba Àwọn Díẹ̀ Là
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • “Ìgbàgbọ́ Ń Tẹ̀lé Ohun Tí A Gbọ́”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Ìmọ̀ Ọlọrun Tòótọ́ Ń Sinni Lọ sí Ìyè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Ìmọ̀ Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ń Dáhùn Ọ̀pọ̀ Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 5/96 ojú ìwé 8

Ẹ Máa Bá A Lọ Ní Sísọ Òtítọ́

1 Àwọn aposteli sọ pé: “Awa kò lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa awọn ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.” (Ìṣe 4:20) Lónìí, a ní láti máa bá a lọ ní sísọ òtítọ́. Bí ìpínkiri Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! tilẹ̀ jẹ́ ọ̀nà kan láti fi wá àwọn tí yóò tẹ́tí sílẹ̀ rí, kí a tó lè kọ́ àwọn olùfìfẹ́hàn ní òtítọ́ sí i, a ní láti padà lọ.

2 Nígbà tí o bá ń ṣiṣẹ́ lórí àkànṣe “Jí!” ti April tí ó ní àkọlé náà, “Nígbà Tí Ogun Kì Yóò Sí Mọ́,” tí o fi sóde, o lè fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lọ onílé nípa bíbéèrè pé:

◼ “Lọ́jọ́sí, a sọ̀rọ̀ nípa ogun tí àwọn orílẹ̀-èdè ń jà àti ipa tí ìsìn ń kó nínú wọn. O ha mọ̀ pé irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ fi hàn kedere pé à ń gbé ní àkókò tí Bibeli pè ní ọjọ́ ìkẹ́yìn bí? [Fi ìwé Ìmọ̀ hàn án. Ka ìpinrọ̀ àkọ́kọ́ nínú orí 11, kí ó sì ṣàlàyé ṣókí lórí àpótí tí ó wà ní ojú ìwé 102.] Ìwé yìí ṣàlàyé kókó ẹ̀kọ́ yìí pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn 18 mìíràn tí a to lẹ́sẹẹsẹ síhìn-ín níbi tí àwọn kókó ẹ̀kọ́ inú ìwé wà. [Fi ojú ìwé 3 hàn án.] Tí o bá lè gbà mí láyè, èmi yóò fẹ́ láti fi bí ìwé yìí ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní òye àwọn ọ̀ràn Bibeli ṣíṣe kókó wọ̀nyí hàn ọ́.” Bí ó bá gbà ọ́ láyè, bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ojú ìwé 6.

3 Bí o bá ṣèlérí tẹ́lẹ̀ pé ìwọ yóò padà wá láti ṣàlàyé bí ó ṣe lè ṣeé ṣe láti gbádùn ìgbésí ayé aláàbò nísinsìnyí, o lè sọ ohun kan bí èyí:

◼ “Nígbà tí a kọ́kọ́ pàdé, mo ṣàjọpín àyọkà ọ̀rọ̀ kan tí ó fún wa ní ìdí láti jẹ́ olùfojúsọ́nà-fún-rere nípa ọjọ́ ọ̀la ènìyàn pẹ̀lú rẹ láti inú Bibeli. Lónìí, èmi yóò fẹ́ láti pe àfiyèsí rẹ sí ohun kan tí ó fi ẹni náà gan-an tí ó lè mú kí a ní ìmọ̀lára ààbò nísinsìnyí hàn.” Ka Orin Dafidi 4:8. Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí ojú ìwé 168, kí o sì ka ìpinrọ̀ 19. Lẹ́yìn náà, béèrè pé: “Inú rẹ yóò ha dùn láti máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ tí ó lè fi bí ìwọ pẹ̀lú ṣe lè rí irú ààbò yìí nínú ìgbésí ayé rẹ hàn ọ́ ní kedere bí?” Bí ìdáhùn náà bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ṣí i sí orí 1.

4 Bí ó bá jẹ́ pé ìdágunlá sí ìsìn ni ẹ jíròrò nígbà ìbẹ̀wò rẹ àkọ́kọ́, o lè gbìyànjú ìyọsíni yìí nígbà ìpadàbẹ̀wò:

◼ “Ìwọ yóò rántí pé a jíròrò nípa ìdágunlá sí ìsìn nígbà ìbẹ̀wò mi àkọ́kọ́, mò sì ṣèlérí pé a óò jíròrò nípa bí a ṣe lè rí ìsìn tí Ọlọrun tẹ́wọ́ gbà, nígbà ìbẹ̀wò mi yìí. Gbólóhùn Jesu, tí a ṣàkọsílẹ̀ nínú Matteu 7:21-23 lè nípa lórí ìṣarasíhùwà ẹni sí ìsìn.” [Ka àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ náà, kì o sì ṣàlàyé wọn.] “Nígbà ìbẹ̀wò mi àkọ́kọ́, a ka Isaiah 11:9, nípa ìmọ̀ Ọlọrun tí yóò pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ ayé. [Ṣàlàyé ní ṣókí.] Láti jèrè irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé kí a kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé. Àwọn ìtọ́sọ́nà tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí ìsìn tí Ọlọrun tẹ́wọ́ gbà ń bẹ́ nínú Bibeli.” Tọ́ka sí orí 5 ìwe Ìmọ̀, “Ìjọsìn Ta Ni Ọlọrun Tẹ́wọ́gbà?,” kí o sì ka ìpínrọ̀ méjì àkọ́kọ́. Lẹ́yìn náà, fi ìwé náà lọ̀ ọ́ ní iye tí a ń fi síta, kí o sì ṣètò láti padà wá, láti máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ.

5 O lè fi ìkẹ́kọ̀ọ́ lọni ní tààràtà pẹ̀lú rẹ̀ nígbà ìpadàbẹ̀wò nípa sísọ pé:

◼ “À ń pín àwọn ìwé ìròyìn wa káàkiri àgbáyé láti sọ fún àwọn ènìyàn níbi gbogbo nípa ohun tí Bibeli fi kọ́ni. A máa ń fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ lọ àwọn ènìyàn tí ó bá ka ohun tí wọ́n kọ́ sí iyebíye. [Tọ́ka sí àpótí ‘Ìwọ Yóò Ha Fẹ́ Kí A Bẹ̀ Ọ́ Wò Bí?’ tí ó wà lára èèpo ẹ̀yin Ilé-Ìṣọ́nà.] À ń lo ìwé yìí, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, gẹ́gẹ́ bí amọ̀nà. Jẹ́ kí ń fi bí a ṣe ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ hàn ọ́ ní ṣókí.”

6 Bí a bá ń bá a lọ ní sísọ òtítọ́, a lè ní ìdánilójú pé àwọn kan yóò wà tí yóò tẹ́tí sílẹ̀, tí yóò sì dáhùn padà lọ́nà rere.—Marku 4:20.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́