ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ba ojú ìwé 4-5
  • Ìwé Kan Tí A Ṣojú Fún Lọ́nà Òdì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwé Kan Tí A Ṣojú Fún Lọ́nà Òdì
  • Ìwé kan tí ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣíṣàwárí Ìtumọ̀ Tòótọ́ fún Àwọn Apá Àyọkà Inú Bíbélì
  • Ìsìn Ṣojú fún Un Lọ́nà Òdì
  • “Sibẹ Ó Ńyí!”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Bí Àríyànjiyàn Ṣe Bẹ̀rẹ̀ Lórí Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Àti Ẹ̀kọ́ Ìsìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ṣé Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Àti Ẹ̀kọ́ Bíbélì Ta Ko Ara Wọn Lóòótọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Àwọn Ohun Tó Ń fa Ìṣòro—Láàárín Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì àti Ìsìn
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Ìwé kan tí ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn
ba ojú ìwé 4-5

Ìwé Kan Tí A Ṣojú Fún Lọ́nà Òdì

“Ẹ̀kọ́ nípa pé ayé ń yí po lọ́nà méjì lójú ipa ìyípo rẹ̀ àti yí ká oòrùn jẹ́ èké, ó sì lòdì pátápátá sí Ìwé Mímọ́.” Bí ìjọ Congregation of the Index of the Roman Catholic Church ṣe sọ nìyẹn nínú àṣẹ kan ní 1616.1 Bíbélì ha ta ko àwọn òkodoro òtítọ́ tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu ní tòótọ́ bí? Tàbí a ha ti ṣojú fún un lọ́nà òdì bí?

NÍ ÌGBÀ òtútù 1609 sí 1610, Galileo Galilei kọjú awò awọ̀nàjíjìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe sí ọ̀run, ó sì ṣàwárí òṣùpá mẹ́rin tí ń yí po pílánẹ́ẹ̀tì Júbítà. Ohun tí ó rí fọ́ èrò tí ó gbòde nígbà náà pé ṣe ni gbogbo àwọn ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run ń yí po ayé yángá. Ṣáájú ìgbà náà, ní 1543, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà náà, Nicolaus Copernicus tí ó jẹ́ ará Poland, ti dá àbá èrò orí náà pé ṣe ni àwọn pílánẹ́ẹ̀tì ń yí po oòrùn. Galileo f ìdí èyí múlẹ̀ pé ó jẹ́ òtítọ́ tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu.

Àmọ́, sí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Kátólí ìkì, èyí jẹ́ ẹ̀kọ́ àdámọ̀. Tipẹ́tipẹ́ ni ṣọ́ọ̀ṣì ti gbà gbọ́ pé ayé wà ní àárín gbùngbùn àgbáyé.2 Ojú ìwòye yìí ni wọ́n gbé karí ìtumọ̀ olówuuru tí wọ́n ṣe lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó fi ayé hàn gẹ́gẹ́ bí èyí tí a f ìdí rẹ̀ múlẹ̀ “lórí àwọn ìpìlẹ̀ rẹ̀, tí kò lè mì títí ayérayé.” (Sáàmù 104:5, The Jerusalem Bible) Ní pípè é lọ sí Róòmù, Galileo fara hàn níwájú àwọn Aṣèwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀. Bí a ti mú kí ó kojú àyẹ̀wò lílé koko, a sún un láti yíhùn pa dà ní gbangba lórí àwọn àwárí rẹ̀, ó sì lo ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀ lábẹ́ ìsémọ́lé.

Ní 1992, nǹkan bí 350 ọdún lẹ́yìn ikú Galileo, Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólí ìkì ṣẹ̀ṣẹ̀ wá gbà pé ó tọ̀nà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.3 Ṣùgbọ́n bí Galileo bá tọ̀nà, ṣé Bíbélì wá kùnà ni?

Ṣíṣàwárí Ìtumọ̀ Tòótọ́ fún Àwọn Apá Àyọkà Inú Bíbélì

Galileo gba Bíbélì gbọ́ pé ó jẹ́ òtítọ́. Nígbà tí àwọn àwárí rẹ̀ tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mú ta ko ìtumọ̀ tí ó gbòde nípa àwọn ẹsẹ kan nínú Bíbélì, ó ṣàlàyé pé àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ni kò ní òye tòótọ́ nípa àwọn apá àyọkà náà. Ó ṣe tán, “òtítọ́ méjì kò lè ta ko ara wọn láé,” ni ohun tí ó kọ.4 Ó dábàá pé ohun tí àwọn ipò àfilélẹ̀ nínú sáyẹ́ǹsì sọ kò ta ko àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì tí a ń lò lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kò jẹ́ gbà pẹ̀lú rẹ̀. Wọ́n rinkinkin mọ́ ọn pé gbogbo àlàyé Bíbélì nípa ilẹ̀ ayé ni a ní láti gbà bẹ́ẹ̀ ṣangiliti. Nítorí náà, kì í ṣe kìkì pé wọ́n kọ àwọn àwárí Galileo nìkan ni ṣùgbọ́n wọ́n tún kùnà níní òye tòótọ́ nípa irú àwọn gbólóhùn bẹ́ẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́.

Ní tòótọ́, ó yẹ kí làákàyè sọ fún wa pé nígbà tí Bíbélì tọ́ka sí “igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé,” kò túmọ̀ sí pé òye àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì ni pé ilẹ̀ ayé jẹ́ igun mẹ́rin níbùú lóòòró ní ti gidi. (Ìṣípayá 7:1) A kọ Bíbélì ní èdè àwọn gbáàtúù, tí ó sì sábà máa ń lo àwọn àkànlò èdè àpèjúwe tí ó ṣe kedere. Nítorí náà, nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀ nípa ilẹ̀ ayé pé ó ní “igun mẹ́rin,” “ìpìlẹ̀” tí ó wà pẹ́ títí, “ìtẹ́lẹ̀,” àti “òkúta igun,” kì í ṣe pé Bíbélì ń fúnni ní àlàyé ti sáyẹ́ǹsì nípa ilẹ̀ ayé; ó dájú pé ó ń sọ̀rọ̀ lọ́nà ìfohun-ṣàpèjúwe, gẹ́gẹ́ bí a ti sábà máa ń ṣe nínú ọ̀rọ̀ wa ojoojúmọ́.a—Aísáyà 51:13; Jóòbù 38:6.

Nínú ìwé rẹ̀, Galileo Galilei, òǹkọ̀wé nípa ìtàn ìgbésí ayé, L. Geymonat sọ pé: “Àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn olójú ìwòye kúkúrú tí ń fẹ́ láti pààlà sí sáyẹ́ǹsì lójú ìwòye àlàyé lórí Bíbélì yóò wulẹ̀ sọ Bíbélì fúnra rẹ̀ di aláìṣeégbàgbọ́ ni.”5 Ìyẹn gan-an ni wọ́n sì ṣe. Ní tòótọ́, ìtumọ̀ tí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn fún Bíbélì—kì í ṣe Bíbélì fúnra rẹ̀—ni ó ń gbé ìkálọ́wọ́kò tí kò bọ́gbọ́n mu karí sáyẹ́ǹsì.

Bákan náà, àwọn tí ń rinkinkin mọ́ ìlànà ìsìn lóde òní lọ́ Bíbélì po nígbà tí wọ́n fi dandan lé e pé ọjọ́ mẹ́fà oníwákàtí 24 ni a fi dá ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:3-31) Irú ojú ìwòye bẹ́ẹ̀ kò fohùn ṣọ̀kan yálà pẹ̀lú sáyẹ́ǹsì tàbí Bíbélì. Nínú Bíbélì, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń rí nínú ọ̀nà ìgbàsọ̀rọ̀ ojoojúmọ́, ọ̀rọ̀ náà “ọjọ́” jẹ́ èdè tí ó ṣeé lò sọ́tùn-únsósì, tí ń sọ nípa ìdíwọ̀n iye àkókò ní onírúurú ìwọ̀n gígùn yíyàtọ̀ síra. Nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:4, gbogbo ọjọ́ ìṣẹ̀dá mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ni a tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí “ọjọ́” kan ṣoṣo lápapọ̀. Ọ̀rọ̀ èdè Hébérù náà tí a túmọ̀ sí “ọjọ́” nínú Bíbélì lè wulẹ̀ túmọ̀ sí “ìgbà gígùn kan.”6 Nítorí náà, kò sí ìdí tí ó bá Bíbélì mu láti fi dandan lé e pé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀dá jẹ́ wákàtí 24. Nípa kíkọ́ni ní ohun tí ó yàtọ̀ sí èyí, àwọn arinkinkin-mọ́lànà ṣojú fún Bíbélì lọ́nà òdì.—Tún wo 2 Pétérù 3:8.

Jálẹ̀ ìtàn, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ti sábà máa ń lọ́ Bíbélì po. Gbé àwọn ọ̀nà míràn tí àwọn ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ti ṣojú lọ́nà òdì fún ohun tí Bíbélì sọ yẹ̀ wò.

Ìsìn Ṣojú fún Un Lọ́nà Òdì

Ìṣesí àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn ń tẹ̀ lé Bíbélì sábà máa ń kó èérí bá iyì ìwé tí wọ́n sọ pé àwọn bọ̀wọ̀ fún. Àwọn tí a ń pè ní Kristẹni ti ta ẹ̀jẹ̀ ara wọn lẹ́nì kíní kejì sílẹ̀ lórúkọ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, ìṣílétí tí Bíbélì fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi ni pé kí wọ́n ‘nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì.’—Jòhánù 13:34, 35; Mátíù 26:52.

Àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan ń sọ àwọn agbo wọn di ìjẹ, ní fífi ọ̀rọ̀ dídùn gba owó tí wọ́n ṣiṣẹ́ kárakára kí wọ́n tó rí lọ́wọ́ wọn—ohun kan tí ó jìnnà pátápátá sí ìsọfúnni inú Ìwé Mímọ́ pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.”—Mátíù 10:8; 1 Pétérù 5:2, 3.

Dájúdájú, a kò lè ṣèdájọ́ Bíbélì nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe àwọn tí wọ́n wulẹ̀ ń tọ́ka sí i tàbí tí wọ́n sọ pé àwọn ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀. Nítorí náà, ẹnì kan tí ó jẹ́ ọlọ́kàn ṣíṣísílẹ̀ yóò fẹ́ láti fúnra rẹ̀ ṣàwárí ohun tí Bíbélì jẹ́ àti ìdí tí ó fi jẹ́ irú ìwé tí ó gbàfiyèsí bẹ́ẹ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àpẹẹrẹ, kódà àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí sísọ̀rọ̀ ní ṣangiliti jù lọ lóde òní máa ń sọ̀rọ̀ nípa “yíyọ” àti “wíwọ̀” oòrùn, àwọn ìràwọ̀, àti àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní tòótọ́, ìwọ̀nyí wulẹ̀ dà bí ẹni pé wọ́n ń sún nítorí ìyípo-yípo ayé.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Méjì lára awò awọ̀nàjíjìn Galileo

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Galileo dojú kọ àwọn tí ń ṣèwádìí rẹ̀ láti gbógun ti àdámọ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́