ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 12/15 ojú ìwé 22-24
  • “Sibẹ Ó Ńyí!”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Sibẹ Ó Ńyí!”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Ẹkọ Ti Ṣọọṣi Tako
  • Kii Ṣe Iwe-atọna Imọ Ijinlẹ Kan
  • A Ka Iṣẹ Leewọ
  • A Dá Galileo Lẹjọ Ẹbi Adamọ
  • Ìwé Kan Tí A Ṣojú Fún Lọ́nà Òdì
    Ìwé kan tí ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn
  • Bí Àríyànjiyàn Ṣe Bẹ̀rẹ̀ Lórí Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Àti Ẹ̀kọ́ Ìsìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ṣé Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Àti Ẹ̀kọ́ Bíbélì Ta Ko Ara Wọn Lóòótọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Àwọn Ohun Tó Ń fa Ìṣòro—Láàárín Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì àti Ìsìn
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 12/15 ojú ìwé 22-24

“Sibẹ Ó Ńyí!”

“BIBELI kọni bi a ṣe lè lọ si ọrun, kii ṣe bi ọrun ṣe nlọ sí,” ni onimọ ijinlẹ ati oluhumọ ti ọ̀rúndún kẹrindinlogun ara Italy naa Galileo Galilei sọ. Awọn igbagbọ bi iru iyẹn fi i sinu iforigbari pẹlu Ṣọọṣi Roman Katoliki, awọn ti wọn halẹ idaloro ati ifisẹwọn mọ ọn. Nǹkan bi 350 ọdun lẹhin naa, ṣọọṣi naa ṣatunyẹwo ọna ti ó gbà bá Galileo lò. Ohun ti ó ṣẹlẹ ni ọjọ Galileo ni a ti pe ni “iforigbari laaarin imọ ijinlẹ ti a gbekari iriri nipa ayé ati igbagbọ oloju iwoye gbà-bẹ́ẹ̀-láìjanpata.”

Lonii, awọn olùwá otitọ kiri lè kẹkọọ lati inu iriri Galileo. Ṣugbọn eeṣe ti iru iforigbari bẹẹ fi lè ṣẹlẹ? Ayẹwo awọn oju iwoye onimọ ijinlẹ ti a tẹwọgba ni akoko rẹ̀ yoo pese idahun naa.

Ni agbedemeji ọ̀rúndún kẹrindinlogun, ilẹ-aye ni a ronu pe ó jẹ́ aarin agbaye. Awọn Planẹti ni a lero pe wọn ńyípo ninu obiri wọn laitase. Bi o tilẹ jẹ pe a kò ladii rẹ̀ nipa awọn ilana onimọ ijinlẹ, awọn ero wọnyi ni a fi igbagbọ tẹwọgba gẹgẹ bi otitọ iṣẹlẹ ti a fidii rẹ̀ mulẹ. Niti tootọ, imọ ijinlẹ pẹlu “awọn ero ìjìnlẹ̀” rẹ̀ jẹ alaiṣee yasọtọ kuro lara isin.

Ninu iru ayé bẹẹ ni a ti bí Galileo sinu idile kan ti a bọ̀wọ̀ fun ni Pisa ni 1564. Baba rẹ̀ fẹ́ ki ó kẹkọọ imọ iṣegun, ṣugbọn ọmọkunrin atọpinpin naa ni ẹkọ iṣiro fà mọra. Bi akoko ti nlọ, gẹgẹ bi ọjọgbọn ninu imọ ijinlẹ, ó ṣawari awọn ilana ti ó niiṣe pẹlu ipá ti nmu nǹkan duro lojukan. Nigba ti awọn apẹẹrẹ awọn awò ti a fi nwo ọna jijin ti Dutch ijimiji dé ọdọ rẹ̀, ó mu ihumọ naa sunwọn sii lọna titobi o sì ṣe ohun eelo ọnà tirẹ ti ó dara ju. Ó yi oju rẹ̀ si ọrun ó sì tẹ ohun ti ó loye jade ninu iwe rẹ̀ akọkọ, Sidereus Nuncius (The Starry Messenger), ti ó nfi awọn oṣupa mẹrin Jupiter han awọn iran rẹ̀. Ni 1611 a pe e lọ si Roomu, nibi ti ó ti gbe awọn àwárí rẹ̀ kalẹ niwaju Jesuit Collegio Romano (Ile-ẹkọ giga ti Roomu). Wọn fi ọla fun un nipa pipolongo ọjọ Galileo kan.

Awọn Ẹkọ Ti Ṣọọṣi Tako

Lọna alámì ibi, ki Galileo tó fi Roomu silẹ, ẹni ti ó jẹ́ alagbara kan lara awọn Jesuit, Alufaa agba, Bellarmine, ru iwadii kan dide sinu awọn ẹkọ Galileo. Galileo gbagbọ pe iṣẹda ni a ṣakoso nipa awọn ofin ti awọn eniyan lè kọ́ nipa ifarabalẹ kẹkọọ. Ṣọọṣi Katoliki tako oju iwoye yii.

Ani awọn onimọ ijinlẹ sánmọ̀ tako ero Galileo paapaa. Wọn gbagbọ pe kò ṣeeṣe fun awò ti a fi ńwo ọna jijin lati ṣalekun otitọ ati pe àwárí naa jẹ́ ìgán kan. Alufaa kan tilẹ dabaa pe awọn irawọ ti a rí ni a ti ṣe sara awò naa! Nigba ti Galileo ṣawari awọn oke nla inu oṣupa, ni titubọ mu un daju pe awọn ohun aṣeefojuri inu ọrun kò ri rogodo delẹ, alufaa Clavius tako oju iwoye naa pe oṣupa ni okuta mimọgaara bòmọ́lẹ̀ bámúbámú, debi pe, bi o tilẹ jẹ pe eniyan lè riran gba inu awọn ori oke naa kọja, sibẹ o ṣì jẹ rogodo kan delẹdelẹ! Galileo wi ni idahunpada pe, “Eyi jẹ ìméfo iyè inu patapata gbáà.”

Ifẹ isunniṣe Galileo lati kà lati inu “Iwe Ẹ̀dá Agbaye,” gẹgẹ bi oun ti pe ẹkọ iṣẹda, sún un debi iṣẹ onimọ ijinlẹ sánmọ̀ ara Poland naa Nicolaus Copernicus. Ni 1543, Copernicus ti ṣe iwe kan ti njiyan pe ayé yí oorun ká. Galileo jẹrii si otitọ yii. Bi o ti wu ki o ri, eyi fi Galileo sinu ìfagagbága lodisi igbekalẹ imọ ijinlẹ, oṣelu, ati isin ti ọjọ rẹ̀.

Nigba ti Ṣọọṣi Katoliki lo ẹkọ ti Copernicus nipa sánmọ̀ fun ṣiṣagbekalẹ awọn ọjọ, iru bii Easter, awọn oju iwoye Copernicus ni a ko tii tẹwọgba labẹ aṣẹ. Ẹgbẹ awọn alufa ṣọọṣi pọ̀n sẹhin àbá èrò ori ti Aristotle pe ilẹ-aye ni agbedemeji agbaye. Sibẹsibẹ, awọn ero Galileo pe iyì ati agbara wọn nija.

Bi o tilẹ jẹ pe awọn onimọ ijinlẹ ọtọọtọ yika ilẹ Europe ṣiṣẹ lati mu ilana ti Copernicus daju, wọn ni itẹlọrun lati jiroro rẹ̀ ninu pápá imọ ẹkọ-iwe nikan. Lori ipilẹ yii Ṣọọṣi Katoliki jọ̀wọ́ wọn silẹ. Galileo kọwe kii ṣe ni èdè Latin ṣugbọn ni èdè Italy tí gbogbogboo gbọ ti o si tipa bayii sọ awọn àwárí rẹ̀ di olokiki. Ẹgbẹ awọn alufaa nimọlara pe oun npe kii ṣe awọn nikan bikoṣe Ọrọ Ọlọrun pẹlu nija.

Kii Ṣe Iwe-atọna Imọ Ijinlẹ Kan

Niti tootọ, ṣiṣawari awọn otitọ nipa agbaye kii ṣe pipe Ọrọ Ọlọrun nija nitootọ. Awọn akẹkọọ Ọrọ yẹn mọ pe Bibeli kii ṣe iwe-atọna imọ ijinlẹ kan, bi o tilẹ jẹ pe o pé perepere nigba ti ó ba nmẹnukan awọn ọran ti imọ ijinlẹ. A kọ ọ́ fun idagbasoke nipa tẹmi awọn onigbagbọ, kii ṣe lati kọ́ wọn ni imọ ijinlẹ physics tabi awọn imọ ijinlẹ miiran ti o niiṣe pẹlu adanida. (2 Timoti 3:16, 17) Galileo gbà. Oun dabaa pe oriṣi èdè meji ni ó wà: awọn èdè isọrọ ti imọ ijinlẹ ti o ṣe deedee ati awọn èdè isọrọ ojoojumọ ti awọn onkọwe ti a misi. Ó kọwe pe: “Ó jẹ ohun ti a ko lè ṣe alaini ninu Iwe mimọ . . . lati mu iwọnyi ṣe kedere si oye awọn gbáàtúù eniyan, lati sọ ọpọlọpọ nǹkan ti ó farahan lọna ti o yatọ (niti itumọ awọn ọrọ naa) si okodoro otitọ.”

Awọn apẹẹrẹ eyi wà ninu oniruuru ẹsẹ Iwe mimọ Bibeli. Ọ̀kan ni Joobu 38:6, nibi ti Bibeli ti sọ nipa ayé gẹgẹ bi eyi ti o ni “ipilẹ” ati “okuta-igun.” Awọn kan ṣi eyi lo gẹgẹ bi ẹ̀rí pe ayé wà ni oju kan. Iru awọn isọrọ bawọnyi ni a kò nilọkan gẹgẹ bi apejuwe onimọ ijinlẹ nipa ayé ṣugbọn, kaka bẹẹ, o fi ewì ṣafiwe iṣẹda ayé si igbekalẹ ile kan, pẹlu Jehofa gẹgẹ bi Ọga Olukọle.

Gẹgẹ bi onimọ nipa itan igbesi-aye eniyan L. Geymonat ti ṣalaye ninu iwe rẹ Galileo Galilei: “Awọn ẹlẹkọọ isin ẹlẹtanu ti wọn nfẹ lati paala imọ ijinlẹ lori ipilẹ iwoye Bibeli ni wọn nbuyi Bibeli funraarẹ kù.” Fun awọn idi onimọtara-ẹni awọn eniyan olori kunkun ṣe iyẹn gan-an. A fi lẹta kan ranṣẹ si Ọfiisi Mímọ́ eyi ti o nbeere fun iwadii Galileo.

A Ka Iṣẹ Leewọ

Ni February 19, 1616, awọn ẹlẹkọọ isin Katoliki ni a gbé awọn àbá meji siwaju wọn: (1) “oorun ni agbedemeji agbaye” ati (2) “ilẹ-aye kii ṣe agbedemeji agbaye.” Ni February 24 wọn ṣe idiwọn awọn èrò wọnyi si aláìlọ́gbọ́n ati aládàámọ̀. A paṣẹ fun Galileo lati maṣe fi iru awọn àbá èrò ori wọnyi kọni tabi di i mu. Iye awọn iwe rẹ̀ bii melookan ati ti awọn ẹlomiran ni a tẹ̀rì fun igba diẹ.

A pa Galileo lẹnumọ. Kii ṣe kiki pe Ṣọọṣi Katoliki lodisi i ni ṣugbọn awọn ọrẹ rẹ ti di alailagbara lati lè ṣeranwọ. Oun wulẹ fi ara rẹ̀ jin iwadii ni. Bi kii ba ṣe ti ipaarọ poopu ni 1623, awa ki ba ti má gbọ nipa rẹ̀ mọ. Bi o ti wu ki o ri, poopu titun naa, Urban Kẹjọ, jẹ olóye eniyan ati alatilẹhin Galileo kan. Ọrọ kan Galileo lara pe poopu naa ki yoo lodi si iwe titun kan. Ni àpèjọ kan poopu naa tilẹ damọran ariyanjiyan ti ó lè ni ninu. Pẹlu iṣiri ti ó han gbangba yii, Galileo lọ bẹrẹ iṣẹ.

Bi o tilẹ jẹ pe Dialogue Concerning the Two Chief World Systems ti Galileo ni a kọkọ tẹjade labẹ iwe aṣẹ Katoliki ni 1632, itara poopu parẹ laipẹ. Ni ọjọ ori 70, a fi aṣẹ pe Galileo lati farahan niwaju ajọ Iwadii ṣáká naa ni ìgbà keji. Ẹsun ifurasi àdámọ̀ beere pe ki a kọkọ ṣalaye aṣẹ ti ṣọọṣi naa fi funni lati tẹwe naa, a sì tẹnumọ ọn pe Galileo fi ikaleewọ ti akọkọ lori kikọni ni ẹkọ Copernicus pamọ lọna onijibiti. Niwọn bi Dialogue ti ṣefiwera awọn ilana ẹkọ nipa sánmọ̀, eyi ti o ni ti Copernicus ninu, a tẹnumọ ọn pe ó tẹ ikaleewọ naa loju.

Galileo dahunpada pe iwe oun ṣariwisi Copernicus. Ó jẹ ijẹjọ ti kò lẹsẹnilẹ, nitori ninu iwe naa ọran ayinilọkanpada kan ni a ṣe fun Copernicus. Siwaju sii, awọn ọrọ poopu ni a fi si ẹnu eniyan ti o jẹ òpè julọ ninu iwe naa, Simplicio, ti o tipa bẹẹ ṣẹ Poopu Urban Kẹjọ.

A Dá Galileo Lẹjọ Ẹbi Adamọ

Wọn ri i pe Galileo jẹbi. Bi o ti jẹ pe o nṣaisan ṣiwaju akoko naa ati pe a ti ndẹru idaloro baa ayafi bi ó bá ko ọrọ jẹ, ó ṣe bẹẹ. Ni ori ikunlẹ ó bura pe: “Mo bura pe mo kọ̀ . . . awọn aṣiṣe ati adamọ ti a sọ silẹ . . . emi ki yoo sọ . . . iru awọn nǹkan ti ó lè mu mi wa sabẹ ifura iru kan naa mọ lae.” Ó runi lọkan soke pe, itan sọ pe nigba ti o dide, o fọwọ gba ilẹ ó sì ranmu sọ pe, “Eppur si muove! [Sibẹ ó ńyí!]”

Aṣẹ ijiya naa ni ifisẹwọn ati ijẹniya titi di ọjọ iku rẹ̀, eyi ti ó ṣẹlẹ ni ọdun mẹsan-an lẹhin naa. Lẹta kan ti ó kọ ni 1634 kà pe: “Kii ṣe eyikeyii ninu awọn ero mi ni ó dá ogun naa silẹ, ṣugbọn wiwa mi ní ojúbi awọn mẹmba ẹgbẹ Jesuit.”

Ni 1822 ikaleewọ ti ó wà lori awọn iṣẹ rẹ̀ ni a mú kuro. Ṣugbọn afi ìgbà ti ó tó di 1979 ni Pope John Paul Keji tun ṣiju ibeere naa ti ó sì gbà pe Galileo ni a ti “mu jiya jọjọ . . . lati ọwọ awọn ọkunrin naa ati awọn eto ajọ Ṣọọṣi.” Ninu iwe irohin Vatican naa L’Osservatore Romano, Mario D’Addio, mẹmba ajọ pataki kan ti Pope John Paul Keji gbekalẹ lati ṣatunyẹwo idanilẹjọ ẹbi Galileo ti 1633, naa wi pe: “Ohun ti a pe ni adamọ Galileo naa ni ó dabi eyi ti ko ni ipilẹ kankan, yala lọna ti ẹkọ isin tabi labẹ ofin awọn iwe inu Bibeli.” Gẹgẹ bi D’Addio ti wi, ile-ẹjọ ajọ Iwadii ṣáká naa rekọja aala aṣẹ rẹ̀—awọn àbá èrò ori Galileo kò rú ofin kankan ninu apa awọn adehun igbagbọ. Iwe irohin Vatican naa gbà pe idajọ ẹbi ti a ṣe fun Galileo nitori adamọ kò lẹsẹnilẹ.

Ki ni ohun ti a kọ́ lati inu iriri Galileo? Kristẹni kan gbọdọ mọ pe Bibeli kii ṣe iwe ẹkọ imọ ijinlẹ kan. Nigba ti o ba dabi ẹni pe aibaramu kan yọju laaarin Bibeli ati imọ ijinlẹ, oun ko nilati gbiyanju lati ṣe imubaradọgba gbogbo “iyatọ.” O ṣetan, igbagbọ Kristẹni ni a gbekari “ọrọ nipa Kristi,” kii ṣe lori aṣẹ imọ ijinlẹ. (Roomu 10:17) Ni afikun sii, imọ ijinlẹ ni o nyipada leralera. Àbá èrò ori kan ti ó dabi eyi ti o tako Bibeli ti o sì jẹ eyi ti ó gbajumọ lonii lè di eyi ti a wa ri lọla gẹgẹ bi eyi ti ó ni aṣiṣe ti a sì kọ̀ silẹ.

Sibẹ, nigba ti a ba ntọka si ọran ti Galileo lati ṣaṣefihan itẹri imọ ijinlẹ lati ọwọ isin, awọn onimọ ijinlẹ yoo ṣe daradara lati ranti pe àwárí Galileo ni ajọ iṣewadii ọjọ rẹ̀ ko tẹwọgba. Lodi si ironu igba kan naa, Bibeli kò ṣaiwa ni iṣọkan pẹlu otitọ yẹn. Ọrọ Ọlọrun kò nilo itunyẹwo. Iṣitumọ Ṣọọṣi Katoliki ti Bibeli ni ó fa iṣoro naa.

Olukuluku eniyan ni a gbọdọ ṣí lori nipa iṣọkan kikọyọyọ ati ofin adanida ti ó wà ni agbaye debi mimọriri Ẹlẹdaa naa, Jehofa Ọlọrun lọna giga julọ. Galileo beere pe: “Njẹ Iṣẹ rẹ̀ ha kere ni iyì si Ọrọ rẹ̀ bi?” Apọsiteli naa dahun pe: “Awọn animọ alaiṣeeri ti [Ọlọrun] ni a rí ni kedere lati ìgbà iṣẹda ayé wa, nitori a nfi òye awọn ohun ti a dá mọ wọn.”—Roomu 1:20, NW.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́