ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ba ojú ìwé 6
  • Ìwé Tí A Tíì Pín Kiri Jù Lọ Lágbàáyé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwé Tí A Tíì Pín Kiri Jù Lọ Lágbàáyé
  • Ìwé kan tí ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwé Tó Dáa Jù Lọ Láyé
    Jí!—2019
  • Ìwé Kan Tí Ó Wà Fún Gbogbo Ènìyàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ Tínú Ọlọ́run Dùn Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ọlọrun Sọ Fun Wa Nipa Awọn Ete Rẹ̀
    Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
Àwọn Míì
Ìwé kan tí ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn
ba ojú ìwé 6

Ìwé Tí A Tí ì Pín Kiri Jù Lọ Lágbàáyé

“Bíbélì ni ìwé tí a tí ì kà níbi púpọ̀ jù lọ nínú ìtàn. . . . Iye ẹ̀dà Bíbélì tí a pín kiri ju ti ìwé èyíkéyìí mìíràn lọ. A sì ti túmọ̀ Bíbélì níye ìgbà tí ó pọ̀, àti sí iye èdè tí ó pọ̀, ju ti ìwé èyíkéyìí mìíràn lọ.”—“The World Book Encyclopedia.”1

NÍ ÀWỌN ọ̀nà kan, ọ̀pọ̀ jù lọ ìwé dà bí àwọn ènìyàn. Wọ́n máa ń wá sójútáyé, wọ́n sì lè di gbajúmọ̀, kí—yàtọ̀ sí àwọn ìwé mélòó kan tí a kọ lọ́nà títayọ—wọ́n di ogbó kí wọ́n sì kú. Àwọn ibi ìkówèésí ni ó sábà máa ń di itẹ́ òkú fún àìmọye ìwé tí ó ti dí ògbólógbòó, tí a kò kà mọ́, tí ó fi jẹ́ pé, nítorí bẹ́ẹ̀, wọ́n ti di òkú.

Ṣùgbọ́n, Bíbélì yàtọ̀ pátápátá àní láàárín àwọn ìwé tí a kọ lọ́nà títayọ pàápàá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a bẹ̀rẹ̀ kíkọ rẹ̀ ní 3,500 ọdún sẹ́yìn, ó ṣì gbéṣẹ́ dáadáa. Òun ni ìwé tí a tí ì pín kiri jù lọ lórí ilẹ̀ ayé.a Lọ́dọọdún, a ń pín nǹkan bí 60 mílíọ̀nù odindi tàbí apá kan ẹ̀dà Bíbélì kiri. Ẹ̀dà àkọ́kọ́ tí a tẹ̀ lórí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tí àwọn lẹ́tà rẹ̀ ṣeé tún tò ni a tẹ̀ jáde lẹ́nu ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ará Germany náà tí ó jẹ́ olùhùmọ̀, Johannes Gutenberg, ní nǹkan bí ọdún 1455. Láti ìgbà náà, a ti tẹ iye Bíbélì (lódindi tàbí lápá kan) tí a díwọ̀n sí bílíọ̀nù mẹ́rin. Kò sí ìwé mìíràn, ì báà jẹ́ ti ìsìn tàbí òmíràn, tí ó tilẹ̀ sún mọ́ iye ìyẹn.

Bíbélì sì tún ni ìwé tí a tí ì túmọ̀ jù lọ nínú ìtàn. Odindi Bíbélì tàbí apá kan rẹ̀ ni a ti túmọ̀ sí ohun tí ó ju 2,100 èdè àti àwọn ẹ̀ka èdè.b Ó ju ìpín 90 nínú ọgọ́rùn ún ìdílé ẹ̀dá ènìyàn tí ó ní, ó kéré tán, apá kan Bíbélì lárọ̀ọ́wọ́tó ní èdè tiwọn.2 Ìwé yìí ti tipa báyìí ré kọjá àwọn ààlà ìpínlẹ̀ orílẹ̀-èdè, ó sì ti borí àwọn ìdènà ti ẹ̀yà àti ti ìran.

Ó ṣeé ṣe kí àwọn àkọsílẹ̀ oníṣirò nìkan má lè pèsè ìdí tí ó tó láti sún ọ ṣe àyẹ̀wò Bíbélì. Síbẹ̀síbẹ̀, iye ìpínkiri àti iye ìtumọ̀ tí a ti ṣe jẹ́ èyí tí ó wúni lórí, ní jíjẹ́rìí sí bí Bíbélì ṣe fa àwọn ènìyàn mọ́ra kárí ayé. Dájúdájú, ìwé tí ó tà jù lọ tí a sì túmọ̀ jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dà ènìyàn yẹ fún àgbéyẹ̀wò rẹ.

[Àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìwé pẹlẹbẹ ẹlẹ́yìn pupa náà, Quotations From the Works of Mao Tse-tung, ni a rò pé ó jẹ́ ìtẹ̀jáde tí ìpínkiri rẹ̀ tún pọ̀ tẹ̀ lé e, èyí tí a fojú díwọ̀n pé a ti tà tàbí a ti pín 800 mílíọ̀nù ẹ̀dà rẹ̀ kiri.

b A gbé àwọn àkọsílẹ̀ oníṣirò nípa iye àwọn èdè karí iye nọ́ńbà tí United Bible Societies tẹ̀ jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Bíbélì Gutenberg, ní èdè Látìn, odindi ìwé àkọ́kọ́ tí a tẹ̀ lórí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tí àwọn lẹ́tà rẹ̀ ṣeé tún tò

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́