Ta ni Jésù Kristi?
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í tiẹ̀ ṣe Kristẹni ló gbà pé ọ̀gá ni láàárín àwọn olùkọ́, pé ó sì tún jẹ́ ọlọgbọ́n èèyàn. Ó dájú pé ọ̀kan lára àwọn aṣáájú tó lókìkí jù lọ ni láyé.” (The World Book Encyclopedia) Ta nìwé yẹn ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ná? Kì í ṣe ẹlòmíràn bí kò ṣe Jésù Kristi, olùdásílẹ̀ ìsìn Kristẹni. Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí Jésù jẹ́? Ǹjẹ́ ohun tó gbé ṣe tiẹ̀ kàn ẹ́?
Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì, ìyẹn nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere. Ṣóòótọ́ pọ́nbélé làwọn ìtàn tó wà nínú àwọn ìwé yìí? Lẹ́yìn tí òpìtàn kan tó ń jẹ́ Will Durant gbé àwọn ìwé náà yẹ̀ wò dáadáa, ó kọ̀wé pé: “Tó bá jẹ́ pé ńṣe làwọn gbáàtúù ẹ̀dá kan ṣàdédé kóra jọ nínú ìran kan, tí wọ́n sì wá hùmọ̀ ìtàn ẹnì kan bẹ́ẹ̀ tó kóni mọ́ra, tó sì lágbára, tí wọ́n tún wá gbé àwọn ìlànà kan tí ò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn kalẹ̀ lórí ìwà híhù, tí wọ́n sì wá dá ẹgbẹ́ ará kan sílẹ̀ láàárín aráyé, ìyẹn á jẹ́ iṣẹ ìyanu tó ju àwọn tó wà nínú ìtàn inú Ìwé Ìhìn Rere lọ.”
Síbẹ̀, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ní Ìlà Oòrùn Ayé àti ní ibòmíì ni ò mẹni tó ń jẹ́ Jésù Kristi. Wọ́n lè gbà pé ẹnì kan ti wà tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀ nígbà kan rí o, àmọ́ wọn ò gbà pé ọ̀ràn Jésù kan ìgbésí ayé àwọn. Àwọn míì ò ka Jésù sẹ́ni tí wọ́n á máa ronú nípa rẹ̀ látàrí ohun táwọn tó pe ara wọn ní ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ti dán wò. Ohun táwọn kan lórílẹ̀-èdè Japan máa sọ nípa wọn ni pé: ‘Ṣebí àwọn ló ju bọ́ǹbù sí ìlù Nagasákì, tó jẹ́ ìlú táwọn Kristẹni ti pọ̀ jù lọ lórílẹ̀-èdè Japan.’
Àmọ́ wo àpejúwe yìí ná. Tí aláìsàn kan bá kọ̀ tí kò lo oògùn bí dòkítà ṣe ní kó lò ó, tí àìsàn rẹ̀ kò sì yéé yọ ọ́ lẹ́nu, ṣé dókítà yẹn ló yẹ ká dá lẹ́bi? Rárá o, kò lè jẹ́ ẹ̀bi dókítà yẹn. Ọjọ́ pẹ́ táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti kọ ìtọ́ni Jésù lórí bí wọ́n ṣe máa borí ìṣòro tó ń dé bá wọn lójoojúmọ́. Torí náà, dípò tí wàá fi kọ Jésù nítorí pé àwọn tó ń pe ara wọn ní Kristẹni ò tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni rẹ̀, ohun tí ì bá dáa ni pé kí ìwọ fúnra rẹ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù fúnra rẹ̀. Ka Bíbélì kó o lè rí irú ẹni tí Jésù jẹ́ gan-an àti bó ṣe lè tún ìgbésí ayé rẹ ṣe.
Ó Sọ Pé Ká Máa Lo Ìfẹ́
Jésù Kristi, tó jẹ́ ọ̀gá láàárín àwọn olùkọ́, gbé láyé nílẹ̀ Palẹ́sìnì ní nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn. Díẹ̀ la mọ̀ nípa ìgbà kékeré rẹ̀. (Mátíù, orí 1 àti 2; Lúùkù orí 1 àti 2) Nígbà tó pé ẹni ọgbọ̀n ọdún, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, kó bàa “lè jẹ́rìí sí òtítọ́.” (Jòhánù 18:37; Lúùkù 3:21-23) Èyí tó pọ̀ jù lára ìtàn táwọn òpìtàn mẹ́rin kọ nípa Jésù dá lórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ tó fi ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tó lò gbẹ̀yìn láyé ṣe.
Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ohun tó lè yanjú onírúurú ìṣòro inú ìgbésí ayé wọn. Kí ni nǹkan ọ̀hún? Ìfẹ́ ni. Nínú ìwàásù kan táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó, èyí tí wọ́n ń pè ní Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bí wọ́n ṣe lè máa fi ìfẹ́ bá ọmọlàkejì wọn lò. Ó sọ pé: “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12) Ìlànà yìí là ń pè ní Òfin Pàtàkì. Àwọn tí Jésù kà sí “àwọn ènìyàn” níbí yìí kan àwọn ọ̀tá wa pẹ̀lú. Nínú ìwàásù yẹn kan náà, ó sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín.” (Mátíù 5:44) Ṣé irú ìfẹ́ yẹn ò ní yanjú ọ̀pọ̀ nínú ìṣòro tó ń dojú kọ wá lónìí? Lérò ti aṣáájú ẹ̀sìn Híńdù kan tó ń jẹ́ Mohandas Gandhi, ìfẹ́ á yanjú ẹ̀. Wọ́n ló sọ pé: “Tí [a] bá lè ń tẹ̀ lé àwọn ẹ̀kọ́ tí Kristi gbé kalẹ̀ nínú Ìwàásù Lórí Òkè yìí, à bá ti yanjú ìṣòro gbogbo ayé lápapọ̀.” Òótọ́ kúkú ni. Tá a bá tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni nípa ìfẹ́, ọ̀pọ̀ wàhálà tó gbayé kan lónìí ò ní sí.
Bó Ṣe Lo Ìfẹ́
Ohun tí Jésù kọ́ àwọn èèyàn ló fi ń ṣèwà hù. Ó fi ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì ṣáájú tara ẹ̀, ó sì fi hàn nínú ìṣe rẹ̀ pé òun ní ìfẹ́. Lọ́jọ́ kan, Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń wàásù fún àwọn èèyàn láìráyè jẹun. Jésù rí i pé ó yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun “sinmi díẹ̀,” torí náà ó kó wọn lọ síbi àdádó kan. Àmọ́ ogunlọ́gọ̀ èrò tí wọ́n ń wàásù fún ò dẹ̀yìn lẹ́yìn wọn. Wọ́n ti ṣáájú Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dé ibi tí wọ́n ti fẹ́ lọ sinmi yẹn. Ká ní ìwọ ni Jésù, kí lò bá ṣe? Ohun tí Jésù ṣe ni pé ó “bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ohun púpọ̀” nítorí pé “àánú wọ́n ṣe é.” (Máàkù 6:30-34) Àánú tó ṣe é yìí mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í ràn wọ́n lọ́wọ́.
Ohun tí Jésù ṣe fáwọn èèyàn kọjá pé ó kàn kọ́ wọn nípa Ọlọ́run. Ó tún ṣe ohun tí wọ́n nílò lójú ẹsẹ̀ fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, ó bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] géńdé (láìka àwọn obìnrin àti ọmọdé) tí wọ́n ti ń fetí sí i látàárọ̀ títí dìrọ̀lẹ́. Ìgbà kan tún wà tó bọ́ àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] míì. Nígbà tàkọ́kọ́ yẹn, ìṣù búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì ló fi bọ́ wọn. Ní ti ẹlẹ́ẹ̀kejì, ìṣù búrẹ́dì méje àti ẹja wẹ́wẹ́ mélòó kan péré ló lò. (Mátíù 14:14-21; 15:32-38; Máàkù 6:35-44; 8:1-9) Ṣé iṣẹ́ ìyanu kọ́ lèyí? Iṣẹ́ ìyanu kúkú ni, oníṣẹ́ ìyanu ni Jésù.
Jésù tún wo ọ̀pọ̀ àwọn tára wọn ò le sàn. Ì báà ṣe afọ́jú, arọ, adẹ́tẹ̀ tàbí adití, gbogbo wọn ló wò sàn. Àní ó tiẹ̀ jí òkú dìde! (Lúùkù 7:22; Jòhánù 11:30-45) Ìgbà kan wà tí adẹ́tẹ̀ kan parọwà fún un pé: “Bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.” Kí ni Jésù fi dá a lóhùn? Ó “na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fọwọ́ kàn án, ó sì wí fún un pé: ‘Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.’” (Máàkù 1:40, 41) Ohun tó mú kí Jésù máa ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ni pé, ṣe ló ń wù ú ṣáá láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ ìyanu yẹn, ó fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn tójú ń pọ́n.
Bó bá ṣòro fún ọ láti gba èyí gbọ́, rántí pé ojú ọ̀pọ̀ èèyàn ni Jésù ti ṣe púpọ̀ lára iṣẹ́ ìyanu tó ṣe o. Kódà àwọn alátakò rẹ̀ gan-an, tí wọ́n ń wá ẹ̀sùn sí i lẹ́sẹ̀ lójú méjèèjì ò lè jiyàn pé kò ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu yẹn. (Jòhánù 9:1-34) Yàtọ̀ síyẹn, ó nídìí tó fi ń ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. Àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe yẹn jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jésù lẹni tí Ọlọ́run rán.—Jòhánù 6:14.
Ìwọ̀nba kéréje tá a rọra gbé yẹ̀ wò nínú ẹ̀kọ́ àti ìgbésí ayé Jésù yìí mú ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ká sì fẹ́ láti ní irú ìfẹ́ tó ní. Síbẹ̀, ọ̀nà yẹn nìkan kọ́ ni ọ̀rọ̀ Jésù gbà kan ìgbésí ayé rẹ. Kì í ṣe àgbà olùkọ́ tó kàn kọ́ wa láti nífẹ̀ẹ́ nìkan. Ó sọ pé kóun tó wá sáyé bí èèyàn, òun ti wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ọmọ bíbí kan ṣoṣo. (Jóhánù 1:14; 3:16; 8:58; 17:5; 1 Jòhánù 4:9) Lẹ́yìn tó wá sáyé tó sì ti lọ, ó ṣì tún wà láàyè lọ́run. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé kó o mọ̀ ọ́n dáadáa. Bíbélì fi hàn pé Jèhófà jí Jésù dìde, ó sì fi í jẹ Ọba Ìjọba Ọlọ́run. (Ìṣípayá 11:15) Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3; 20:31) Òdodo ọ̀rọ̀, gbígbà téèyàn bá gba ìmọ̀ Jésù Kristi sínú lè mú kéèyàn ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè! Báwo ló ṣe lè rí bẹ́ẹ̀? Gbìyànjú láti mọ̀ sí i nípa Jésù kó o lè rí bí “ìfẹ́ tí Kristi ní” ṣe “sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa” pé ká fara wé e? (2 Kọ́ríńtì 5:14) Tayọ̀tayọ̀ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà á fi ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́ yẹn.—Jòhánù 13:34, 35.
Bá ò bá fi hàn pé ó yàtọ̀, gbogbo ẹsẹ Bíbélì wá láti inú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.