Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kí A Gba Jésù Kristi Gbọ́?
“Ọ̀ PỌ̀ èèyàn tí kì í ṣe Kristẹni pàápàá ló gbà gbọ́ pé Ó jẹ́ olùkọ́ ńlá tí ọgbọ́n rẹ̀ pọ̀ jọjọ. Dájúdájú, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn akọni èèyàn tó tí ì gbé ayé rí.” (Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia) Ta ni ‘Onítọ̀hún’? Jésù Kristi, olùdásílẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni ni.
Ṣùgbọ́n láìka gbogbo ohun tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà sọ sí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tó wà ní Ìlà Oòrùn àti ní àwọn ibòmíràn ló ka Jésù Kristi sí àjèjì lásán, orúkọ tó jẹ́ pé àwọn ìwé tí wọ́n ń kà nílé ẹ̀kọ́ gíga ni kò jẹ́ kí wọ́n gbàgbé rẹ̀. Kódà nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù pàápàá, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn àti àwọn àlùfáà kan wà tí wọ́n sọ pé àwọn kò mọ Jésù ní ti gidi tí wọ́n sì ń ṣiyè méjì nípa ìjóòótọ́ àwọn àkọsílẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó nípa ìgbésí ayé rẹ̀ ìyẹn ni (àwọn ìwé Ìhìn Rere) táa rí nínú Bíbélì.
Àbí àwọn òǹkọ̀wé Ìhìn Rere wulẹ̀ kọ ohun tó wù wọ́n nípa ìtàn ìgbésí ayé Jésù, kí wọ́n bàa lè tú wa jẹ ni? Rárá o, ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀! Lẹ́yìn tí gbajúmọ̀ òpìtàn nì, Will Durant, ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ àwọn àkọsílẹ̀ ìwé Ìhìn Rere wọ̀nyẹn, ó kọ̀wé pé: “Tó bá jẹ́ pé àwọn gbáàtúù kéréje láti inú ìran kan ṣoṣo ló fúnra wọn hùmọ̀ irú ẹni ńlá bẹ́ẹ̀, ẹni tí ìwà rẹ̀ fani mọ́ra gan-an, tó ní ìlànà ìwà híhù tó ga lọ́lá, tí ẹ̀mí ìṣọ̀kan ẹgbẹ́ ará tó ní sì wuni lórí jọjọ, ìyẹn ni ì bá jẹ́ iṣẹ́ ìyanu tó tayọ gbogbo èyí tó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere. Lẹ́yìn ṣíṣe Lámèyítọ́ Ìtàn àti Ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ fún ọ̀rúndún méjì, ìtàn ìgbésí ayé Kristi, ìwà rẹ̀, àti ẹ̀kọ́ rẹ̀, ṣì ṣe kedere lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, òun ló sì wá para pọ̀ jẹ́ apá tó fani mọ́ra jù lọ nínú ìtàn àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn.”
Pẹ̀lú gbogbo atótónu yìí, àwọn kan tún wà tí wọn kò ka Jésù Kristi sí ẹni táwọn lè fún láfiyèsí nítorí ohun táwọn tí wọ́n pe ara wọn ní ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ti ṣe. Àwọn kan ní Japan lè sọ pé, ‘ṣe báwọn ló ju bọ́ǹbù kan si Nagasaki. Bẹ́ẹ̀ àwọn Kristẹni tó wà ní Nagasaki pọ̀ ju ti àwọn ìlú ńlá mìíràn ní Japan.’ Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ a lè dẹ́bi fún oníṣègùn bí aláìsàn bá kọ̀ láti tẹ̀lé ohun tí dókítà sọ? Tipẹ́tipẹ́ ni ọ̀pọ̀ tó pe ara wọn ní Kristẹni ti kọ egbòogi tí Jésù ṣètò láti wo àìsàn ìran ènìyàn san. Síbẹ̀, Jésù pèsè ojútùú sí àwọn ìṣòro wa ojoojúmọ́ títí kan àtúnṣe sí ìyà tí ń pọ́n gbogbo aráyé lójú. Ìdí nìyẹn táa fi rọ̀ ọ́ láti ka àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e kí o lè fúnra rẹ rí irú ẹni tí ó jẹ́.