ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • gf ẹ̀kọ́ 9 ojú ìwé 15
  • Àwọn Wo Ni Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Wo Ni Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?
  • Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹgbẹẹgbẹrun Awọn Ẹda Ẹmi
    Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha wa Niti Gidi Bi?
  • Àwọn Áńgẹ́lì Jẹ́ “Ẹ̀mí Fún Iṣẹ́ Ìsìn Gbogbo Ènìyàn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ṣáwọn Èèyàn Máa Ń Di Áńgẹ́lì Lẹ́yìn Tí Wọ́n Bá Kú?
    Jí!—2006
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
gf ẹ̀kọ́ 9 ojú ìwé 15

Ẹ̀kọ́ 9

Àwọn Wo Ni Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?

Jésù Kristi ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, àwọn áńgẹ́lì sì ń darí iṣẹ́ ìwàásù

Jésù Kristi jẹ́ Ọmọ Jèhófà, òun sì ni ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́, tó nífẹ̀ẹ́ jù lọ. Kí Jésù tó wá gbé lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí èèyàn, ó ti gbé lọ́run gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára. (Jòhánù 17:5) Lẹ́yìn náà, ó wá sórí ilẹ̀ ayé láti kọ́ àwọn èèyàn ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run. (Jòhánù 18:37) Ó tún fi ìwàláàyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn lélẹ̀ láti gba àwọn èèyàn onígbọràn là kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Róòmù 6:23) Ní báyìí, Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ìṣàkóso ti ọ̀run tí yóò mú Párádísè wá sórí ilẹ̀ ayé yìí.—Ìṣípayá 19:16.

Àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Orí ilẹ̀ ayé yìí kọ́ ni àwọn áńgẹ́lì ti gòkè re ọ̀run. Ọlọ́run ti dá wọn sókè ọ̀run kí ó tó dá ilẹ̀ ayé. (Jóòbù 38:4-7) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ áńgẹ́lì ló wà. (Dáníẹ́lì 7:10) Àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run wọ̀nyí, tí wọ́n ń bẹ lọ́run, fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa Jèhófà.—Ìṣípayá 14:6, 7.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù fún obìnrin kan

Ọlọ́run tún láwọn ọ̀rẹ́ lórí ilẹ̀ ayé; ẹlẹ́rìí rẹ̀ ló pè wọ́n. Bí ẹnì kan bá ń jẹ́rìí ní ilé ẹjọ́, á sọ ohun tó mọ̀ nípa ẹnì kan tàbí nípa ohun kan. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sọ ohun tí wọ́n mọ̀ nípa Jèhófà àti ète rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn. (Aísáyà 43:10) Gẹ́gẹ́ bíi àwọn áńgẹ́lì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fẹ́ láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí o lè mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa Jèhófà. Wọ́n ń fẹ́ kí ìwọ pẹ̀lú jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́