ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 10/06 ojú ìwé 26-27
  • Ṣáwọn Èèyàn Máa Ń Di Áńgẹ́lì Lẹ́yìn Tí Wọ́n Bá Kú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣáwọn Èèyàn Máa Ń Di Áńgẹ́lì Lẹ́yìn Tí Wọ́n Bá Kú?
  • Jí!—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Áńgẹ́lì Yàtọ̀ Lẹ́dàá
  • Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ Sẹ́ni Tó Ti Kú?
  • Àwọn Wo Là Ń Pè Ní Áńgẹ́lì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ohun Tí Àwọn Áńgẹ́lì Ń Ṣe fún Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àwọn Áńgẹ́lì Jẹ́ “Ẹ̀mí Fún Iṣẹ́ Ìsìn Gbogbo Ènìyàn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Àwọn Wo Làwọn Áńgẹ́lì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Jí!—2006
g 10/06 ojú ìwé 26-27

Ṣáwọn Èèyàn Máa Ń Di Áńgẹ́lì Lẹ́yìn Tí Wọ́n Bá Kú?

ỌMỌ ọdún méje péré ni ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Argyro nígbà tó kú. Ìbànújẹ́ dorí àwọn òbí ẹ̀ kodò bí wọ́n ṣe ń wò ó nínú pósí tí wọ́n tẹ́ ẹ sí pẹ̀lú aṣọ funfun lọ́rùn. Torí pé àlùfáà wọn ń wá ohun tó máa sọ láti tù wọ́n nínú, ó sọ pé: “Ọlọ́run ń fẹ́ áńgẹ́lì mìíràn torí ìyẹn ló ṣe mú Argyro ọmọ yín sọ́dọ̀. Ní báyìí, ọkàn ẹ̀ á ti máa fò yíká ìtẹ́ Olódùmarè.”

Àwọn kan gbà gbọ́ pé ọkàn àwọn èèyàn tó ti kú ló ń di áńgẹ́lì bó tilẹ̀ jẹ́ pé èrò yẹn ò sí lára ẹ̀kọ́ tí ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn fọwọ́ sí. Àwọn fíìmù àtàwọn eré tí wọ́n máa ń ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n nípa bí àwọn tó kú ṣe padà wá di áńgẹ́lì nítorí pé wọ́n ń ran àwọn alààyè lọ́wọ́ tí wọ́n sì ń dáàbò bò wọ́n ti jẹ́ kí èrò náà tàn kálẹ̀.

Ṣé o rò pé ó tọ̀nà láti máa retí pé àwọn èèyàn ẹ á di áńgẹ́lì lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kú? Kí ni Bíbélì fi kọni lórí ọ̀ràn yìí? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ lórí irú ẹni táwọn áńgẹ́lì jẹ́ àti ipò táwọn òkú wà.

Àwọn Áńgẹ́lì Yàtọ̀ Lẹ́dàá

Ìránṣẹ́ Ọlọ́run làwọn áńgẹ́lì, wọn ò ṣeé fojú rí, wọ́n lágbára gan-an, ibùgbé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí sì ni wọ́n ń gbé. Wíwà tí wọ́n wà ò lọ́wọ́ èèyàn nínú. Ẹ̀dá ẹ̀mí làwọn áńgẹ́lì, Ọlọ́run ló dá wọn bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Kí [àwọn áńgẹ́lì] máa yin orúkọ Jèhófà; nítorí pé òun fúnra rẹ̀ ni ó pàṣẹ, a sì dá wọn.”—Sáàmù 148:2, 5.

Bíbélì fi hàn pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn áńgẹ́lì ló wà lọ́run, lára wọn sì làwọn séráfù àti kérúbù tí wọ́n ní iṣẹ́ pàtó tí wọ́n ń ṣe tìgbọràntìgbọràn gẹ́gẹ́ bí ipò olúkúlùkù wọn àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí Jèhófà yàn fún wọn. (Sáàmù 103:20, 21; Aísáyà 6:1-7; Dáníẹ́lì 7:9, 10) Ṣé Ọlọ́run ò lè dá àwọn áńgẹ́lì béèyàn ò bá kú ni? Irú ìyẹn ò tiẹ̀ lè wáyé rárá àti rárá ni. Torí kí ni?

Bíbélì fi hàn pé tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí Jèhófà tóó dá àwọn èèyàn ló ti dá àwọn áńgẹ́lì. Nígbà tí Jèhófà ń dá ilẹ̀ ayé níbi táwọn èèyàn ṣì ń bọ́ wá gbé tó bá yá, àwọn áńgẹ́lì tí Bíbélì fi èdè ewì pè ní ìràwọ̀ òwúrọ̀, ‘jùmọ̀ ń fi ìdùnnú ké jáde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí hó yèè nínú ìyìn.’ (Jóòbù 38:4-7) Torí náà látọdúnmọdún làwọn áńgẹ́lì ti wà kéèyàn tó dáyé.

Yàtọ̀ síyẹn, àwọn áńgẹ́lì yàtọ̀ sí àwa èèyàn, ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún wọn yàtọ̀, ààyè ọ̀tọ̀ ló sì tò wọ́n sí.a Ọlọ́run dá èèyàn “ní ẹni rírẹlẹ̀ díẹ̀ ju àwọn áńgẹ́lì,” torí náà bá a bá pe àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí yìí ní ẹ̀dá tó ju èèyàn lọ ní ti ọgbọ́n orí àti agbára, a ò jayò pa. (Hébérù 2:7) Ní tàwọn áńgẹ́lì, ọ̀run ni “ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Júúdà 6) Ṣùgbọ́n ní tàwọn èèyàn, ayé ni ibi tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún wọn láti máa gbé títí láé láti ìpilẹ̀ṣẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:17; Sáàmù 37:29) Ká ní tọkọtaya àkọ́kọ́ ti gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu ni, wọn ì bá tí kú rárá. Nítorí náà, látọjọ́ táláyé ti dáyé, ààyè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Ọlọ́run ní lọ́kàn pé káwọn èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì wà.

Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ Sẹ́ni Tó Ti Kú?

Àwọn ìbéèrè pàtàkì míì tó yẹ ká béèrè ni pé: Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn tó bá ti kú? Ṣé wọ́n ń para dà tí wọ́n á sì máa wà láàyè nìṣó ni, bóyá kí wọ́n di áńgẹ́lì tó ń gbé ibi táwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ń gbé? Ìdáhùn Bíbélì sí ìbéèrè náà, èyí tó rọrùn tó sì ṣe kedere ni pé: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Torí náà, ẹní bá ti kú ti di aláìsí. Àwọn òkú ò mọ nǹkan kan, nǹkan kì í ṣe wọ́n bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í ní ìrírí kankan.

Ṣé ìrètí ṣì wà fáwọn òkú? Bẹ́ẹ̀ ni! Bíbélì fi hàn pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ti kú ló máa jíǹde. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn ló máa jíǹde sí ìyè gẹ́gẹ́ bí èèyàn nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.—Lúùkù 23:43; Jòhánù 5:28.

Àwọn díẹ̀ nínú àwọn èèyàn ní ìrètí àjíǹde sí ìyè ti ọ̀run. Wọ́n kéré níye, ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ni wọ́n. Àmọ́, àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì yìí yàtọ̀ pátápátá sáwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tá a mọ̀ sáwọn áńgẹ́lì o. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì yìí máa bá Kristi ṣàkóso bí ọba àti àlùfáà, wọn ò sì lè kú mọ́. Wọ́n ti gba àṣẹ láti di onídàájọ́. (1 Kọ́ríńtì 6:3; Ìṣípayá 20:6) Ṣáwọn ọmọdé tó ti kú ni wọ́n? Rárá o. Àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tó ti dojú kọ ìṣòro tí àdánwò sì ti sè jinná ni wọ́n!—Lúùkù 22:28, 29.

Tún rántí ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn èèyàn tó ti kú àtàwọn áńgẹ́lì tó wà láàyè. Nígbà tó jẹ́ pé àwọn òkú èèyàn “ò mọ nǹkan kan rárá,” àwọn áńgẹ́lì mọ ohun tó ń lọ, wọ́n ní ìmọ̀lára wọ́n sì lè ṣèpinnu tó bá wù wọ́n. Ẹ̀dá tó mọnúúrò ni wọ́n. (Jẹ́nẹ́sísì 6:2, 4; Sáàmù 146:4; 2 Pétérù 2:4) Bíbélì sọ̀rọ̀ àwọn òkú bí “aláìlè-ta-pútú” tàbí aláìlágbára, nígbà tó sì sọ̀rọ̀ àwọn áńgẹ́lì bí àwọn ẹni tó “tóbi jọjọ nínú agbára.” (Aísáyà 26:14; Sáàmù 103:20) Yàtọ̀ síyẹn, nígbà táwọn èèyàn tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù ń kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé, ẹni pípé làwọn áńgẹ́lì tó ń bẹ̀rù Ọlọ́run, wọ́n wà ní ipò ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Jèhófà.—Mátíù 18:10.

Wọ́n lè máa fi ṣeré lórí tẹlifíṣọ̀n àti nínú fíìmù pé ọkàn àwọn èèyàn tó ti kú ló ń di áńgẹ́lì o, àmọ́ Ìwé Mímọ́ ò ti irú èrò bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn rárá. Òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe gba èrò òdì èyíkéyìí láàyè lórí ipò táwọn èèyàn wa tó kú wà. Bíbélì sì fi dá wa lójú pé Ọlọ́run dá àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ yàtọ̀ pátápátá sáwọn èèyàn, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Rẹ̀ alágbára, wọn ju àwa èèyàn lọ, wọ́n sì ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà ní gbogbo ìgbà. A mà dúpẹ́ o, pé ó wà lára ìfẹ́ Ọlọ́run láti jẹ́ káwọn áńgẹ́lì máa ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí àwọn tó ń fi tinútinú bọ̀wọ̀ fún Jèhófà tí wọ́n sì ń fẹ́ láti fi tọkàntọkàn sìn ín. Ó sì tún fẹ́ kí wọ́n máa ràn wọ́n lọ́wọ́.—Sáàmù 34:7.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀rọ̀ náà “áńgẹ́lì,” tó túmọ̀ ní pọ́ńbélé sí “òjíṣẹ́,” lè tún ní ìtumọ̀ tó gbòòrò jù bẹ́ẹ̀ lọ nígbà míì, ó lè túmọ̀ sí onírúurú ẹ̀dá ẹ̀mí, ó sì lè túmọ̀ sí àwọn èèyàn tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Àmọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí, àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tí Bíbélì sábàá máa ń pè ní áńgẹ́lì là ń bá wí.

ǸJẸ́ Ó TI ṢE Ọ́ RÍ BÍI KÓ O BÉÈRÈ PÉ?

◼ Ṣé àwọn èèyàn rẹ tó ti kú ti di áńgẹ́lì tó ń sin Ọlọ́run lọ́run báyìí?—Oníwàásù 9:5, 10.

◼ Ṣé torí pé Ọlọ́run nílò àwọn áńgẹ́lì sí i lọ́run làwọn ọmọdé ṣe ń kú?—Jóòbù 34:10.

◼ Ṣé àwọn òkú tún lè padà wá máa ran àwọn alààyè lọ́wọ́?—Aísáyà 26:14.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]

“Kí [àwọn áńgẹ́lì] máa yin orúkọ Jèhófà; nítorí pé òun fúnra rẹ̀ ni ó pàṣẹ, a sì dá wọn.”—Sáàmù 148:2, 5

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́