Àwọn Wo Làwọn Áńgẹ́lì?
KÀYÉFÌ gbáà ló jẹ́ fún ọba ilẹ̀ Bábílónì tó jẹ́ ìjọba alágbára. Ó ní kí wọ́n sọ àwọn géńdé mẹ́ta sínú iná ìléru àmọ́ wọ́n rẹ́ni dáàbò bò wọ́n tí iná náà ò fi tu irun kankan lára wọn! Ta ló gbà wọ́n? Ọba náà fúnra rẹ̀ sọ fáwọn géńdé mẹ́ta tó yè bọ́ náà pé: “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run [yín], tí ó rán áńgẹ́lì rẹ̀, tí ó sì gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e sílẹ̀.” (Dáníẹ́lì 3:28) Ọba tó ṣàkóso ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn yìí fojú ara rẹ̀ rí i bí àwọn áńgẹ́lì ṣe gbani là. Láyé àtijọ́, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló gbà pé áńgẹ́lì wà. Bákan náà lónìí, yàtọ̀ sí pé ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé àwọn áńgẹ́lì wà, wọ́n tún gbà pé wọ́n ń nípa lórí àwọn láwọn ọ̀nà kan. Àwọn wo làwọn áńgẹ́lì, ibo ni wọ́n sì ti wá?
Bíbélì fi yé wa pé ẹ̀dá ẹ̀mí làwọn áńgẹ́lì gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ṣe jẹ́ Ẹ̀mí. (Sáàmù 104:4; Jòhánù 4:24) Àwọn áńgẹ́lì ọ̀run pọ̀ gan-an ni, ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù ni wọ́n. (Ìṣípayá 5:11) Gbogbo wọn ló sì “tóbi jọjọ nínú agbára.” (Sáàmù 103:20) Àwọn áńgẹ́lì láwọn ànímọ́, wọ́n sì ní òmìnira láti ṣe ohun tó bá wù wọ́n bíi tàwa èèyàn, àmọ́ kì í ṣe èèyàn ló ń di áńgẹ́lì. Ọlọ́run tiẹ̀ ti dá àwọn áńgẹ́lì tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kó tó dá èèyàn, àní ó dá wọn ṣáájú kó tó dá ilẹ̀ ayé yìí pàápàá. Bíbélì sọ pé nígbà tí Ọlọ́run ‘fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀, àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ [ìyẹn àwọn áńgẹ́lì] jùmọ̀ ń fi ìdùnnú ké jáde, gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí hó yèè nínú ìyìn.’ (Jóòbù 38:4, 7) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ló dá àwọn áńgẹ́lì, Bíbélì pè wọ́n ní ọmọ Ọlọ́run.
Tìtorí kí ni Ọlọ́run ṣe dá àwọn áńgẹ́lì? Ìrànlọ́wọ́ wo làwọn áńgẹ́lì ti ṣe fáwa èèyàn? Ǹjẹ́ wọ́n ń ṣe ohunkóhun fáwa èèyàn lóde òní? Níwọ̀n bí àwọn áńgẹ́lì ti lómìnira láti ṣe ìpinnu fúnra wọn, ǹjẹ́ a rí nínú àwọn áńgẹ́lì wọ̀nyí tí wọ́n tẹ̀ lé Sátánì Èṣù tí wọ́n sì tipa báyìí sọ ara wọn dọ̀tá Ọlọ́run? Bíbélì fún wa ní ìdáhùn tòótọ́ sáwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn.