ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • gf ẹ̀kọ́ 12 ojú ìwé 20
  • Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nígbà Ikú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nígbà Ikú?
  • Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ Sáwọn Tó Ti Kú?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ibo Làwọn Baba Ńlá Wa Wà?
    Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Ṣó Yẹ Kó O Máa Bẹ̀rù Àwọn Òkú?
    Jí!—2009
Àwọn Míì
Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
gf ẹ̀kọ́ 12 ojú ìwé 20

Ẹ̀kọ́ 12

Kí Ló Máa Ń ṣẹlẹ̀ Nígbà Ikú?

Ikú ni òdì kejì ìyè. Ńṣe ni ikú dà bí oorun àsùnwọra. (Jòhánù 11:11-14) Àwọn òkú kò lè gbọ́ nǹkan kan, wọn ò lè rí nǹkan kan, wọn ò lè sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò lè ronú ohunkóhun. (Oníwàásù 9:5, 10) Ìsìn èké ń kọ́ni pé ìlú àwọn ẹ̀mí ni àwọn òkú máa ń lọ láti lọ máa bá àwọn baba ńlá wọn gbé. Kì í ṣe ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nìyẹn.

Jésù jí ọmọbìnrin Jáírù dìde

Àwọn tó ti kú kò lè ràn wá lọ́wọ́, wọn ò sì lè pa wá lára. Ó wọ́pọ̀ kí àwọn èèyàn máa ṣe onírúurú ààtò, kí wọ́n sì máa rú àwọn ẹbọ tí wọ́n gbà gbọ́ pé yóò dùn mọ́ àwọn tó ti kú nínú. Èyí kò dùn mọ́ Ọlọ́run nínú nítorí ọ̀kan lára irọ́ tí Sátánì pa ló pilẹ̀ rẹ̀. Kò tiẹ̀ lè mú ìtẹ́lọ́rùn kankan wá bá òkú pàápàá, níwọ̀n bí wọn kò ti sí láàyè mọ́. A kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù àwọn òkú, bẹ́ẹ̀ la ò gbọ́dọ̀ jọ́sìn wọn. Ọlọ́run nìkan la gbọ́dọ̀ jọ́sìn.—Mátíù 4:10.

Àwọn òkú yóò tún padà wà láàyè. Jèhófà yóò jí àwọn òkú dìde sí ìyè lórí párádìsè ilẹ̀ ayé. Àkókò yẹn ṣì wà lọ́jọ́ iwájú. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Ọlọ́run lè jí àwọn tó ti kú bí ìwọ alára ṣe lè jí ẹni tó sùn.—Máàkù 5:22, 23, 41, 42.

Èrò náà pé èèyàn kì í kú jẹ́ irọ́ tí Sátánì Èṣù tàn káàkiri. Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ máa ń mú kí àwọn èèyàn rò pé ẹ̀mí àwọn òkú ń bẹ láàyè, àti pé àwọn ló ń fa àìsàn àti àwọn ìṣòro mìíràn. Nígbà míì, Sátánì máa ń lo àlá àti ìran láti fi tan àwọn èèyàn jẹ. Jèhófà bẹnu àtẹ́ lu àwọn tó máa ń gbìyànjú láti bá àwọn òkú sọ̀rọ̀.—Diutarónómì 18:10-12.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́