ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • gf ẹ̀kọ́ 16 ojú ìwé 26-27
  • Fi Ìfẹ́ Tó O Ní sí Ọlọ́run Hàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fi Ìfẹ́ Tó O Ní sí Ọlọ́run Hàn
  • Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Olùfúnni Ọlọ́yàyà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Bó O Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ọlọ́run Ń Pè Ọ́ Pé Kí O Wá Di Ọ̀rẹ́ Òun
    Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
  • Jehofa Nífẹ̀ẹ́ Awọn Olufunni Ọlọ́yàyà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
gf ẹ̀kọ́ 16 ojú ìwé 26-27

Ẹ̀kọ́ 16

Fi Ìfẹ́ Tóo Ní Sí Ọlọ́run Hàn

Ọkùnrin kan ń gbàdúrà, ó sì ń ka Bíbélì

Kí ọ̀rẹ́ ìwọ àti ẹnì kan tó lè wọ̀, o gbọ́dọ̀ máa bá a sọ̀rọ̀. Wàá máa fetí sí i, òun náà á sì máa fetí sí ọ. Wàá tún máa sọ ọ̀rọ̀ tó dáa nípa ọ̀rẹ́ rẹ fún àwọn ẹlòmíràn. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí bí o bá jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Gbé ohun ti Bíbélì sọ nípa èyí yẹ̀ wò:

Máa bá Jèhófà sọ̀rọ̀ déédéé nínú àdúrà. “Ẹ máa ní ìforítì nínú àdúrà.”—Róòmù 12:12.

Máa Ka Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́.”—2 Tímótì 3:16.

Máa kọ́ àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.”—Mátíù 28:19, 20.

Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì ń wàásù fún ọkùnrin kan

Sún mọ́ àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.”—Òwe 13:20.

Máa lọ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, . . . kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì.”—Hébérù 10:24, 25.

Kóo ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ìjọba náà. “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.”—2 Kọ́ríńtì 9:7.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba
    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́