ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 1/15 ojú ìwé 14-19
  • Jehofa Nífẹ̀ẹ́ Awọn Olufunni Ọlọ́yàyà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jehofa Nífẹ̀ẹ́ Awọn Olufunni Ọlọ́yàyà
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Sún Wọn Nipasẹ Ọkan-Aya Ti O Muratan
  • Ki Ni Ń Súnni Sí Ṣiṣe Ifunni Ọlọ́yàyà?
  • Ṣiṣabojuto Fifunni Tiṣọratiṣọra
  • Kii ṣe Lati Inu Àfipáṣe
  • Fi Imoore Rẹ Han fun Awọn Ẹbun Ọlọrun
  • “Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Olùfúnni Ọlọ́yàyà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • “Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Olùfúnni Ọlọ́yàyà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Ẹni Tó Ń Fúnni Pẹ̀lú Ìdùnnú
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Bí A Ṣe Ń Rí Owó Bójú Tó Iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 1/15 ojú ìwé 14-19

Jehofa Nífẹ̀ẹ́ Awọn Olufunni Ọlọ́yàyà

“Ki olukuluku ṣe gan-an gẹgẹ bi oun ti pinnu ni ọkan-aya rẹ̀, kii ṣe pẹlu kùnrùngbùn tabi labẹ àfipáṣe, nitori Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ olufunni ọlọ́yàyà.”—2 KỌRINTI 9:7, NW.

1. Bawo ni Ọlọrun ati Kristi ti jẹ olufunni ọlọ́yàyà?

JEHOFA ni olufunni ọlọ́yàyà akọkọ. Ó fi tayọtayọ fun Ọmọkunrin bibi-kanṣoṣo rẹ ni ìyè ó sì lò ó lati mú awọn angẹli ati araye wá si ìyè. (Owe 8:30, 31; Kolose 1:13-17) Ọlọrun fun wa ni ìyè ati èémí ati ohun gbogbo, papọ pẹlu ojo lati ọrun ati awọn ìgbà eleso, ni fifi ọ̀yàyà pupọ kún ọkan-aya wa. (Iṣe 14:17; 17:25) Nitootọ, Ọlọrun ati Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi, jẹ́ olufunni ọlọ́yàyà. Wọn fi tayọtayọ funni pẹlu ẹmi aimọtara-ẹni-nikan. Jehofa nífẹ̀ẹ́ araye tó bẹẹ gẹẹ debi pe “ó fi fi Ọmọkunrin bibi-kanṣoṣo rẹ̀ funni, ki olukuluku ẹni ti ó ba lo igbagbọ ninu rẹ̀ ma baa parun ṣugbọn ki o lè ni ìyè ainipẹkun.” Jesu sì fi aidi kùnrùngbùn ‘fi ọkàn rẹ̀ ṣe irapada ni pàṣípààrọ̀ fun ọpọlọpọ.’—Johanu 3:16, NW; Matiu 20:28.

2. Gẹgẹ bi Pọọlu ti wi, iru olufunni wo ni Ọlọrun nífẹ̀ẹ́?

2 Nitori naa, awọn iranṣẹ Ọlọrun ati Kristi gbọdọ jẹ́ olufunni ọlọ́yàyà. Iru fifunni bẹẹ ni a fun niṣiiri ninu lẹta keji apọsiteli Pọọlu si awọn Kristẹni ni Kọrinti, ti a kọ ni nǹkan bii 55 C.E. Ni titọka si ọrẹ owo ti a fínnúfíndọ̀ṣe ti ó sì jẹ́ ni ìdákọ́ńkọ́ ti a ṣe ni pataki lati ran awọn Kristẹni ti wọn ṣalaini ni Jerusalẹmu ati Judia lọwọ, Pọọlu wi pe: “Ki olukuluku ṣe gan-an gẹgẹ bi oun ti pinnu ni ọkan-aya rẹ̀, kii ṣe pẹlu kùnrùngbùn tabi labẹ àfipáṣe, nitori Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ olufunni olọ́yàyà.” (2 Kọrinti 9:7, NW; Roomu 15:26; 1 Kọrinti 16:1, 2; Galatia 2:10) Bawo ni awọn eniyan Ọlọrun ti ṣe huwa pada si awọn anfaani lati funni? Ki sì ni a lè kẹkọọ lati inu imọran Pọọlu lori fifunni?

A Sún Wọn Nipasẹ Ọkan-Aya Ti O Muratan

3. Dé aye wo ni awọn ọmọ Isirẹli ti kikọ agọ-isin fun ijọsin Jehofa lẹhin?

3 Ọkan-aya ti ó muratan sún awọn eniyan Ọlọrun lati fi araawọn ati awọn ohun àmúṣọrọ̀ wọn funni ni itilẹhin fun ète atọrunwa. Fun apẹẹrẹ, awọn ọmọ Isirẹli ni ọjọ Mose fi tayọtayọ ti kíkọ́ àgọ́-ìsìn fun ijọsin Jehofa lẹhin. Ọkan-aya awọn obinrin melookan sún wọn lati hun irun ewurẹ, nigba ti awọn ọkunrin kan ṣiṣẹ gẹgẹ bii oníṣọ̀nà. Awọn eniyan naa fi ọ̀yàyà funni ni wura, fadaka, igi, aṣọ-ọ̀gbọ̀, ati awọn ohun miiran gẹgẹ bi ‘ọrẹ atinuwa fun OLUWA [“Jehofa,” NW].’ (Ẹkisodu 35:4-35) Wọn jẹ́ ọlọ́làwọ́ tó bẹẹ debi pe awọn ohun èèlò to wọn fi tọrẹ “tó fun gbogbo iṣẹ naa, lati fi ṣe e, ó sì pọju.”—Ẹkisodu 36:4-7.

4. Pẹlu iṣarasihuwa wo ni Dafidi ati awọn miiran fi ṣetọrẹ siha tẹmpili?

4 Ni ọpọ ọrundun lẹhin naa, Ọba Dafidi ṣetọrẹ ńláǹlà siha tẹmpili Jehofa tí Solomọni ọmọkunrin rẹ̀ yoo kọ́. Niwọn bi Dafidi ‘ti ni inudidun ninu ile Ọlọrun,’ o fi “akanṣe ohun-ìní” rẹ̀ ti wura ati fadaka funni. Awọn ọmọ-alade, awọn oloye, ati awọn miiran ‘fi ẹbun fun Jehofa kún ọwọ wọn.’ Pẹlu iyọrisi wo? Họwu, “awọn eniyan naa bú sí yíyọ̀ lori ṣiṣe awọn ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe, nitori pe pẹlu ọkan-aya pipe ni wọn fi ṣetọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe fun Jehofa”! (1 Kironika 29:3-9, NW) Wọn jẹ́ olufunni ọlọ́yàyà.

5. Bawo ni awọn ọmọ Isirẹli ṣe ti ijọsin tootọ lẹhin la ọpọ ọrundun já?

5 La ọpọ ọrundun já, awọn ọmọ Isirẹli lanfaani lati ṣetilẹhin fun àgọ́-ìsìn, awọn tẹmpili lẹhin naa, ati iṣẹ-isin awọn alufaa ati awọn ọmọ Lefi nibẹ. Fun apẹẹrẹ, ni ọjọ Nehemaya awọn Juu pinnu lati ṣe awọn itọrẹ lati pa ijọsin mimọ gaara mọ́, ni mímọ̀ pe awọn kò gbọdọ ṣainaani ile Ọlọrun. (Nehemaya 10:32-39) Bakan naa lonii, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà ṣe awọn itọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe lati kọ́ awọn ibi ipade ki wọn sì pa a mọ ati lati ti ijọsin tootọ lẹhin.

6. Funni ni apẹẹrẹ ifunni ọlọ́yàyà nipasẹ awọn Kristẹni?

6 Awọn Kristẹni ijimiji jẹ́ olufunni ọlọ́yàyà. Fun apẹẹrẹ, Gayọsi ń ṣe “awọn iṣẹ oloootọ” ni jíjẹ́ ẹlẹmii alejo si awọn wọnni ti ń rinrin-ajo nitori awọn ire Ijọba naa, ani gẹgẹ bi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe ń nawọ ẹmi alejo ṣiṣe si awọn alaboojuto arinrin-ajo ti a rán jade nisinsinyi lati ọdọ Watch Tower Bible and Tract Society. (3 Johanu 5-8) Ó náni ni ohun kan lati jẹ́ ki awọn arakunrin wọnyi rinrin-ajo lọ si awọn ijọ ati lati mu ẹmi alejo ṣiṣe gbooro dé ọdọ wọn, ṣugbọn ẹ wo bi eyi ti ṣanfaani tó nipa tẹmi!—Roomu 1:11, 12.

7. Bawo ni awọn ara Filipi ṣe lo awọn ohun àmúṣọrọ̀ wọn nipa ti ara?

7 Awọn ijọ lodindi ti lo awọn ohun àmúṣọrọ̀ wọn lati fi gbe awọn ire Ijọba naa ga siwaju. Fun apẹẹrẹ, Pọọlu sọ fun awọn onigbagbọ ni Filipi pe: “Nitori ni Tẹsalonika gidi, ẹyin ranṣẹ, ẹ sì tun ranṣẹ fun aini mi. Kii ṣe nitori ti emi ń fẹ ẹbun naa: ṣugbọn emi ń fẹ eso ti yoo maa di pupọ nitori yin.” (Filipi 4:15-17) Awọn ara Filipi fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà funni, ṣugbọn awọn idi wo ni ó ṣokunfa iru fifunni ọlọ́yàyà bẹẹ?

Ki Ni Ń Súnni Sí Ṣiṣe Ifunni Ọlọ́yàyà?

8. Bawo ni o ṣe lè fihan pe ẹmi Ọlọrun ń sún awọn eniyan rẹ̀ lati jẹ́ olufunni ọlọ́yàyà?

8 Ẹmi mímọ́, tabi ipa agbekankanṣiṣẹ Jehofa ń sún awọn eniyan rẹ̀ lati jẹ́ olufunni ọlọ́yàyà. Nigba ti awọn Kristẹni ni Judia wà ninu aini, ẹmi Ọlọrun sún awọn onigbagbọ miiran lati ràn wọ́n lọ́wọ́ niti ohun ti ara. Lati fun awọn Kristẹni ni Kọrinti niṣiiri lati sa gbogbo ipa wọn ninu ṣiṣe iru itọrẹ bẹẹ, Pọọlu tọka si apẹẹrẹ awọn ijọ ni Makedonia. Bi o tilẹ jẹ pe awọn onigbagbọ ni Makedonia ń niriiri inunibini ati òṣì, wọn fi ifẹ ará han nipa fifunni kọja agbara wọn niti gidi. Wọn tilẹ bẹ̀bẹ̀ fun anfaani fifunni! (2 Kọrinti 8:1-5) Ipa-ọna Ọlọrun kò sinmi lori itọrẹ awọn ọlọ́rọ̀ nikan. (Jakobu 2:5) Awọn iranṣẹ rẹ̀ oluṣeyasimimọ ti wọn jẹ́ alaini niti ohun ti ara ti jẹ alatilẹhin pataki ninu pipese owo fun iṣẹ iwaasu Ijọba naa. (Matiu 24:14) Sibẹ, wọn kò jiya nitori iwa ọlawọ wọn, nitori pe Ọlọrun ń pese fun aini awọn eniyan rẹ̀ ninu iṣẹ yii laikuna, ipá ti o sì wà lẹhin biba a lọ ati ìbísí rẹ̀ jẹ́ ẹmi Rẹ̀.

9. Bawo ni igbagbọ, ìmọ̀, ati ifẹ ṣe tanmọ́ ifunni ọlọ́yàyà?

9 Ifunni ọlọ́yàyà ni a ń sún ṣiṣẹ nipasẹ igbagbọ, imọ, ati ifẹ. Pọọlu wi pe: “Gan-an gẹgẹ bi ẹyin [ará Kọrinti] ti ń pọ̀ gidigidi ninu ohun gbogbo, ninu igbagbọ ati ọ̀rọ̀ ati ìmọ̀ ati ifọkansi gbogbo ati ninu ifẹ wa yii fun yin, ki ẹ pọ̀ gidigidi ninu ififunni oninurere yii pẹlu. Kii ṣe ni ọna pipaṣẹ fun yin, ṣugbọn nitori ifọkansi awọn ẹlomiran, ati lati dán bi ifẹ yin ti jẹ́ ojulowo sí wò, ni mo fi ń sọ.” (2 Kọrinti 8:7, 8, NW) Ṣiṣetilẹhin fun ipa-ọna ti Jehofa, paapaa julọ nigba ti olufunni naa bá ni àlùmọ́ọ́nì mimọniwọn, beere fun igbagbọ ninu awọn ipese Ọlọrun fun ọjọ-ọla. Awọn Kristẹni ti wọn ń pọ sii ni imọ fẹ́ lati ṣiṣẹsin fun ete Jehofa, awọn wọnni ti wọn sì pọ̀ gidigidi ní ifẹ fun un ati fun awọn eniyan rẹ̀ fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà lo awọn ohun àmúṣọrọ̀ wọn lati mu ète rẹ̀ tẹsiwaju.

10. Eeṣe ti a fi lè sọ pe apẹẹrẹ Jesu sún awọn Kristẹni lati fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà funni?

10 Apẹẹrẹ Jesu sún awọn Kristẹni lati funni tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Lẹhin rirọ awọn ara Kọrinti lati funni nititori ifẹ, Pọọlu sọ pe: “Ẹyin mọ inurere ailẹtọọsi ti Oluwa wa Jesu Kristi, pe bi o tilẹ jẹ́ ọlọ́rọ̀ ó di otoṣi nitori yin, ki ẹyin lè di ọlọrọ nipasẹ òṣì rẹ̀.” (2 Kọrinti 8:9, NW) Bí ó ti jẹ́ ọlọ́rọ̀ ninu ọrun ju ọmọkunrin Ọlọrun eyikeyii miiran lọ, Jesu sọ araarẹ dofo niti gbogbo eyi ó si gbe iwalaaye eniyan wọ̀. (Filipi 2:5-8) Bi o ti wu ki o ri, nipa didi otoṣi ni ọna alaimọtara-ẹni-nikan yii, Jesu ṣetilẹhin fun ìsọdimímọ́ orukọ Jehofa ó sì fi ẹmi rẹ̀ lélẹ̀ gẹgẹ bi ẹbọ irapada fun anfaani awọn eniyan ti wọn yoo tẹ́wọ́gbà á. Ni ibamu pẹlu apẹẹrẹ Jesu, kò ha yẹ ki a funni tọ̀yàyàtọ̀yàyà lati ran awọn ẹlomiran lọwọ ki a sì ṣetilẹhin fun ìsọdimímọ́ orukọ Jehofa?

11, 12. Bawo ni iwewee rere ṣe lè mu wa di olufunni ọlọ́yàyà?

11 Iṣeto rere mu ki ifunni ọlọ́yàyà ṣeeṣe. Pọọlu sọ fun awọn ara Kọrinti pe: “Ni ọjọ kìn-ín-ní ọsẹ ki ẹnikọọkan yin ni ile araarẹ ya ohun kan sọtọ gédégbé ni ipamọ gẹgẹ bi nǹkan ba ti ń lọ deedee fun un tó, ki o lè jẹ́ pe nigba ti mo ba dé akojọ ki yoo ṣẹlẹ nigba naa.” (1 Kọrinti 16:1, 2, NW) Ni iru ọna ìdákọ́ńkọ́ ati àfínnúfíndọ̀ṣe bẹẹ, awọn wọnni ti wọn fẹ́ lati ṣe itọrẹ lati mu iṣẹ Ijọba naa tẹsiwaju lonii yoo ṣe daradara lati ya diẹ ninu awọn owo ti ń wọle fun wọn sọtọ gédégbé fun ète yẹn. Gẹgẹ bi iyọrisi iru iṣeto rere bẹẹ, awọn Ẹlẹ́rìí, idile ati ijọ kọọkan lè ṣe itọrẹ lati gbé ijọsin tootọ ga.

12 Fifi awọn iṣeto lati ṣetilẹhin silo yoo mu wa jẹ́ ọlọ́yàyà. Gẹgẹ bi Jesu ti wi, “ayọ pupọ ń bẹ ninu fifunni ju eyi ti ó wà ninu ririgba lọ.” (Iṣe 20:35, NW) Nitori naa awọn ara Kọrinti lè mu ayọ wọn pọ̀ sii nipa titẹle imọran Pọọlu lati fi iwewee ọlọdun kan wọn lati fi awọn owo àkànlò ranṣẹ si Jerusalẹmu silo. Ó sọ pe, “ó jẹ́ itẹwọgba ni pataki gẹgẹ bi ohun ti eniyan ní kii ṣe gẹgẹ bi ohun ti eniyan kò ní.” Nigba ti ẹnikan ba ṣe itilẹhin ni ibamu pẹlu ohun ti ó ní, a gbọdọ kà á si iyebiye gidigidi. Bi a bá nigbẹkẹle ninu Ọlọrun, oun lè mu awọn nǹkan baradọgba debi pe awọn wọnni ti wọn ni pupọ jẹ́ ọlọ́làwọ́, kii ṣe olùfiṣòfò, ti awọn wọnni ti wọn ni diẹ ki yoo ṣalaini debi pe yoo dín okun ati agbara wọn lati ṣiṣẹsin in kù.—2 Kọrinti 8:10-15.

Ṣiṣabojuto Fifunni Tiṣọratiṣọra

13. Eeṣe ti awọn ara Kọrinti fi lè ni igbọkanle ninu abojuto awọn itọrẹ tí Pọọlu ń ṣe?

13 Bi o tilẹ jẹ pe Pọọlu bojuto iṣeto ọrẹ ki awọn onigbagbọ alaini baa lè gbadun itura alaafia niti awọn ohun ti ara ki wọn sì kopa ninu iṣẹ wiwaasu tokuntokun sii, yala oun tabi awọn ẹlomiran kò mu eyikeyii ninu awọn owo àkànlò naa fun ìlò ti araawọn. (2 Kọrinti 8:16-24; 12:17, 18) Pọọlu ṣiṣẹ lati kunju awọn aini ohun ti ara tirẹ funraarẹ dipo didi ẹru iṣunna owo lé ori ijọ eyikeyii. (1 Kọrinti 4:12; 2 Tẹsalonika 3:8) Nitori naa, ni kíkó awọn ọrẹ naa lé e lọwọ, awọn ara Kọrinti ń kó wọn lé iranṣẹ Ọlọrun aṣeefọkantan, oṣiṣẹ kára lọwọ.

14. Niti ìlò awọn ọrẹ, otitọ ti a mọ daradara wo ni Watch Tower Society ni?

14 Lati igba sisọ Watch Tower Bible and Tract Society di àjọ ẹgbẹ́ ni 1884, awọn olutọrẹ ti ni ẹ̀rí naa pe ó jẹ́ oluṣabojuto aṣeéfọkàntán fun gbogbo awọn ọrẹ ti a fi si ikawọ rẹ̀ nititori iṣẹ Ijọba Jehofa. Gẹgẹ bi iwe aṣẹ idasilẹ naa ti sọ, Ẹgbẹ naa ń lakaka lati kun aini titobi julọ ti gbogbo awọn eniyan, aini fun awọn ohun tẹmi. Eyi ni a ṣe ni iru ọna iwe ikẹkọọ Bibeli ati itọni lori bi a ṣe lè jere igbala. Lonii, Jehofa ń mu ikojọ awọn ẹni-bi-agutan sinu eto-ajọ rẹ̀ ti ń gbooro yára kánkán, ibukun rẹ̀ lori ìlò ọlọgbọn ti awọn ọrẹ ninu iṣẹ iwaasu Ijọba naa sì jẹ́ ẹ̀rí ti ó ṣe kedere ti ifọwọsi atọrunwa. (Aisaya 60:8, 22) A ni igbọkanle pe oun yoo maa baa lọ lati sún ọkan-aya awọn olufunni ọlọ́yàyà.

15. Eeṣe ti iwe irohin yii ṣe ń mẹnukan itọrẹ lẹẹkọọkan?

15 Society lẹẹkọọkan maa ń lo apakan iwe irohin yii lati mu awọn onkawe rẹ̀ wà lojufo si anfaani wọn ti ṣiṣe itọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe fun iṣẹ iwaasu Ijọba yika ayé. Eyi kii ṣe titọrọ, ṣugbọn ó jẹ́ irannileti fun gbogbo awọn ti wọn ń fẹ́ lati ti “iṣẹ mímọ́ ti ihinrere” lẹhin bí Ọlọrun ti ń mú wọn ṣaṣeyọrisirere tó. (Roomu 15:16; 3 Johanu 2) Society ń lo gbogbo owo ti a fi tọrẹ naa ni ọna ìṣúnwóná julọ ki a baa lè sọ orukọ ati Ijọba Jehofa di mímọ̀. Gbogbo awọn ọrẹ ni a fi imoore tẹwọgba, ti a sì jẹwọ riri wọn gba, ti a sì lo wọn lati tan ihinrere Ijọba Ọlọrun kalẹ. Fun apẹẹrẹ, ni awọn ọna wọnyi igbokegbodo awọn ojihin iṣẹ Ọlọrun ni a ń gbéró ni ọpọlọpọ orilẹ-ede, awọn ohun eelo iwe títẹ̀ ti wọn ṣekoko fun pipin ìmọ̀ Bibeli fun awọn eniyan ni a sì ń pamọ ti a sì ń mu gbooro. Siwaju sii, awọn ọrẹ fun iṣẹ yika ayé ni a ń lo lati kaju iye-owo ti ń ga sii fun mímú Bibeli ati awọn itẹjade ti nsọrọ nipa Bibeli ati awọn kasẹẹti afetigbọ ati ti fidio jade. Ni iru awọn ọna bẹẹ awọn ire Ijọba ni a ń gbé ga nipasẹ awọn olufunni ọlọ́yàyà.

Kii ṣe Lati Inu Àfipáṣe

16. Bi o tilẹ jẹ pe iwọnba diẹ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́ ọlọ́rọ̀ nipa ti ara, eeṣe ti a fi mọriri awọn ọrẹ wọn?

16 Iwọnba diẹ ninu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni wọn jẹ́ ọlọ́rọ̀ niti ohun ti ara. Bi o tilẹ jẹ pe wọn lè funni ni iye tí kò pọ lati gbé awọn ire Ijọba ga, awọn ọrẹ wọn ni kò salai ṣe pataki. Nigba ti Jesu rí opó alaini kan ti ó ju awọn owo ẹyọ wẹ́wẹ́ meji ti iniyelori rẹ̀ kéré pupọ sinu apoti iṣura tẹmpili kan, ó wi pe: “Opó yii, bi o tilẹ jẹ òtòṣì, fi sinu rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ. Nitori gbogbo awọn wọnyi [awọn olùtọrẹ miiran] fi awọn ẹbun sinu rẹ̀ lati inu àṣẹ́kù wọn, ṣugbọn obinrin yii lati inu aini rẹ̀ fi gbogbo ohun ìní igbesi-aye ti o ní sinu rẹ̀.” (Luuku 21:1-4, NW) Bi o tilẹ jẹ pe ẹbun rẹ̀ kere, ó jẹ́ olufunni ọlọ́yàyà—ọrẹ rẹ̀ ni a sì mọriri.

17, 18. Ki ni ijẹpataki awọn ọrọ Pọọlu ni 2 Kọrinti 9:7, ki sì ni a tọka si nipa ọrọ Giriiki naa ti a tumọsi “ọlọ́yàyà”?

17 Nipa ti iṣẹ itura alaafia nititori awọn Kristẹni ni Judia, Pọọlu wi pe: “Ki olukuluku ṣe gan-an gẹgẹ bi oun ti pinnu ní ọkan-aya rẹ̀, kii ṣe pẹlu kùnrùngbùn tabi labẹ àfipáṣe, nitori Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ olufunni ọlọ́yàyà.” (2 Kọrinti 9:7, NW) Apọsiteli naa lè ti sọrọ bá apakan Owe 22:8 ninu ẹ̀dà itẹjade Septuagint, eyi ti ó sọ pe: “Ọlọrun bukun olufunni ọlọ́yàyà; yoo sì pese fun àìkúnjú-ìwọ̀n awọn iṣẹ rẹ̀.” (The Septuagint Bible, ti a tumọ lati ọwọ Charles Thomson) Pọọlu fi “bukun” rọpo “nífẹ̀ẹ́,” ṣugbọn isokọra kan wà, nitori ikore awọn ibukun jẹ jade lati inu ifẹ Ọlọrun.

18 Olufunni ọlọ́yàyà layọ lati funni nitootọ. Họwu, lati inu ede isọrọ Giriiki naa ti a tumọsi “ọlọ́yàyà” ni 2 Kọrinti 9:7 ni ọrọ èdè Gẹẹsi naa “hilarious” [múnirẹ́rìn-ín kẹmuyẹ] ti wa! Lẹhin titọka eyi jade, ọmọwe R. C. H. Lenski sọ pe: “Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ olufunni oninudidun, alayọ, onidunnu . . . [ẹni ti] a wé igbagbọ rẹ̀ mọ́ ẹ̀rín musẹ nigba ti anfaani miiran fun fifunni ba wọle tọ ọ.” Eniyan kan ti ó ni iru ẹmi alayọ bẹẹ kii funni pẹlu kùnrùngbùn tabi labẹ àfipáṣe ṣugbọn ó ni ọkan-aya rẹ̀ ninu fifunni rẹ̀. Iwọ ha lọ́yàyà bẹẹ nipa fifunni ni itilẹhin nipa ire Ijọba bi?

19. Bawo ni awọn Kristẹni ijimiji ṣe ń ṣe itọrẹ?

19 Awọn Kristẹni ijimiji kii gbé igbá ọrẹ tabi ṣe ìdámẹ́wàá nipa dídá ìdákan ninu mẹwaa owo ti ń wọle fun wọn fun awọn ète onisin. Kaka bẹẹ, awọn ọrẹ wọn jẹ́ àfínnúfíndọ̀ṣe patapata. Tertullian, ẹni ti a yi lọkan pada si isin Kristẹni ni nǹkan bii 190 C.E., kọwe pe: “Bi o tilẹ jẹ pe a ni apoti-iṣura wa, kò papọ jẹ́ owo ti a fi ń ra ìgbàlà, gẹgẹ bi isin kan ti o ni iye-owo rẹ̀. Ni ọjọ oṣooṣu naa [ti o han gbangba pe ó jẹ́ ẹ̀ẹ̀kan loṣu], bi o bá fẹ́, ẹnikọọkan ń fi ìdáwó táṣẹ́rẹ́ sinu rẹ̀; ṣugbọn kiki ti ó bá jẹ ayọ rẹ̀, ati kiki bi o bá lagbara rẹ̀; nitori pe kò sí àfipáṣe kankan; gbogbo rẹ̀ jẹ́ àfínnúfíndọ̀ṣe.”—Apology, Ori XXXIX.

20, 21. (a) Ki ni itẹjade iṣaaju iwe irohin yii sọ nipa anfaani titi ipa-ọna Ọlọrun lẹhin lọna ti owo, bawo sì ni eyi ṣe ṣee fisilo nisinsinyi? (b) Ki ni o ń ṣẹlẹ nigba ti a ba bọla fun Jehofa pẹlu awọn ohun iyebiye wa?

20 Ifunni àfínnúfíndọṣe ti saba maa ń jẹ́ aṣa laaarin awọn iranṣẹ Jehofa ni ode oni. Bi o ti wu ki o ri, nigba miiran, awọn kan kò tii lo anfaani kikun wọn ti titi ipa-ọna Ọlọrun lẹhin nipa ṣiṣe ìtọrẹ. Ni February 1883, fun apẹẹrẹ, iwe irohin yii sọ pe: “Awọn kan ń ru ẹrù inira ti owo [ti ó jẹ mọ́ owo] pupọ gan-an nititori awọn miiran, debi pe ọna itilẹhin wọn niti ọran owo ń jorẹhin lati inu iṣẹ aṣeju ati àárẹ̀, ati nipa bayii ìwúlò wọn ni a palara; kii sì ṣe kiki bẹẹ nikan, ṣugbọn awọn wọnni ti . . . wọn kò loye ipo naa ni kikun, ti padanu anfaani gbigba ibukun nitori aini ẹmi ọ̀làwọ́ wọn ni ṣiṣe itọrẹ niti owo.”

21 Gẹgẹ bi awọn ogunlọgọ nla ti ń dà girigiri wọnu eto-ajọ Jehofa lonii, ati bi iṣẹ Ọlọrun ti ń gbooro wọnu Ila-oorun Europe ati awọn agbegbe ti a ti kalọwọko ni iṣaaju miiran, aini kan ti ń pọ sii wà fun imugbooro awọn ile-iṣẹ itẹwe ati awọn eelo miiran. Bibeli pupọ sii ati awọn itẹjade miiran ni a gbọdọ tẹ̀. Ọpọlọpọ awọn idawọle ti iṣakoso Ọlọrun ń bọ lọna; bi o ti wu ki o ri, awọn kan lè tẹsiwaju kánmọ́kánmọ́ sii bi awọn owo àkànlò ti ó tó bá wà. Nitootọ, a ni igbagbọ pe Ọlọrun yoo pese ohun ti a nilo, a sì mọ pe awọn wọnni ti wọn ‘ń bọla fun Jehofa pẹlu awọn ohun iyebiye wọn’ ni a ó bukun. (Owe 3:9, 10) Dajudaju, “ẹni ti o bá . . . fúnrúgbìn ni yanturu yoo ká ni yanturu pẹlu.” Jehofa yoo ‘sọ wa di ọlọ́rọ̀ fun oriṣiriṣi ọ̀làwọ́ gbogbo,’ fifunni ọlọ́yàyà wa yoo sì mu ki ọpọlọpọ dupẹ lọwọ rẹ̀ ki wọn sì yìn ín.—2 Kọrinti 9:6-14, NW.

Fi Imoore Rẹ Han fun Awọn Ẹbun Ọlọrun

22, 23. (a) Ki ni ẹbun ọ̀fẹ́ alaiṣee ṣapejuwe ti Ọlọrun? (b) Niwọn bi a ti mọriri awọn ẹbun Jehofa, ki ni a gbọdọ ṣe?

22 Bi a ti sún un nipasẹ imoore jijinlẹ, Pọọlu funraarẹ sọ pe: “Ọpẹ ni fun Ọlọrun fun ẹbun ọ̀fẹ́ rẹ̀ alaiṣee ṣapejuwe.” (2 Kọrinti 9:15, NW) Gẹgẹ bi “ẹbọ etutu ipẹtu” fun ẹṣẹ awọn Kristẹni ẹni ami ororo ati fun awọn wọnni ni ayé, Jesu ni ipilẹ ati ọna fun ẹbun ọ̀fẹ́ alaiṣee ṣapejuwe Jehofa. (1 Johanu 2:1, 2) Ẹbun yẹn ni “inurere ailẹtọọsi titayọ ti Ọlọrun” ti o ti fihan fun awọn eniyan rẹ̀ lori ilẹ ayé nipasẹ Jesu Kristi, ó sì pọ̀ yanturu fun igbala wọn ati si ogo ati idalare Jehofa.—2 Kọrinti 9:14.

23 Imoore jijinlẹ wa lọ sọdọ Jehofa fun ẹbun ọ̀fẹ́ alaiṣee ṣapejuwe rẹ̀ ati ọpọlọpọ awọn ẹbun tẹmi ati ti ara miiran fun awọn eniyan rẹ̀. Họwu, isoore Baba wa ọrun fun wa jẹ́ agbayanu gan-an debi pe ó kọja awọn agbara eniyan lati fi i han! Dajudaju ó nilati sún wa lati jẹ́ olufunni ọlọ́yàyà. Pẹlu imọriri atọkanwa, nigba naa, ẹ jẹ ki a ṣe gbogbo ohun ti a lè ṣe lati gbé ipa-ọna Ọlọrun wa, Jehofa, Olufunni akọkọ ati agbapò iwaju julọ ga!

Iwọ Ha Ranti Bi?

◻ Ọkan-aya ti ó muratan ti sún awọn eniyan Jehofa lati ṣe ki ni?

◻ Ki ni ń súnni sí ṣiṣe ifunni ọlọ́yàyà?

◻ Bawo ni Watch Tower Society ṣe ń lo awọn ọrẹ ti ó ń rígbà?

◻ Iru olufunni wo ni Ọlọrun nífẹ̀ẹ́, bawo sì ni a ṣe gbọdọ fi imoore wa han fun ọpọlọpọ awọn ẹbun Rẹ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Nigba ti a ń kọ́ àgọ́-ìsìn, awọn ọmọ Isirẹli ṣiṣẹ kárakára wọn sì ṣe itọrẹ ọlọlawọ fun Jehofa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Awọn ọrẹ bii ti opó alaini naa ni a mọriri wọ́n sì ṣe pataki

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́