Ìhìn Rere Tí Wọ́n Ń Fẹ́ Kí O Gbọ́
NÍGBÀ tí Jésù wà ní ayé, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá wọ́n sì bi í léèrè pé: “Kí ni yóò . . . jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” Ó dáhùn pé ogun yóò pọ̀ gan-an ni, tí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè yóò máa bá ara wọn jà, àìtó oúnjẹ, àjàkálẹ̀ àrùn, àti ìsẹ̀lẹ̀ yóò wà, ìwà àìlófin yóò máa pọ̀ sí i, àwọn tí ń fi ẹ̀sìn èké kọ́ni yóò máa ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà, àti pé wọn yóò kórìíra àwọn ọmọlẹ́yìn òun tòótọ́, wọn yóò sì máa ṣe inúnibíni sí wọn, àti pé ìfẹ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní fún òdodo yóò di tútù. Bí nǹkan wọ̀nyí bá ti wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ, a jẹ́ pé Kristi ti wà níhìn-ín lọ́nà kan tí a kò lè fojú rí nìyẹn àti pé Ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀. Ìhìn tí ó tó ròyìn mà ni o, àní, ìhìn rere! Nípa bẹ́ẹ̀, Jésù fi gbólóhùn yìí kún ara àmì náà, ó ní: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mát. 24:3-14.
Lóòótọ́, àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí burú gan-an ni, àmọ́ àmì ohun tó jẹ́, ìyẹn wíwàníhìn-ín Kristi, jẹ́ nǹkan rere. Ọdún tí a kéde rẹ̀ nílé lóko yẹn, ọdún 1914, mà ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ táa mẹ́nu kàn lókè yìí bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀ o! Ìyẹn ló jẹ́ àmì pé Àkókò Àwọn Kèfèrí ti dópin, pé a sì ti bọ́ sí sáà ìgbáradì láti tinú ìṣàkóso ènìyàn bọ́ sínú Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi.
Sáàmù àádọ́fà, ẹsẹ kìíní àti kejì, àti Ìṣípayá orí kejìlá, ẹsẹ keje sí ìkejìlá ló fi hàn pé sáà ìgbáradì kan yóò wà. Ó hàn níbẹ̀ pé Kristi yóò jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run ní ọ̀run títí dìgbà tí yóò fi di Ọba. Lẹ́yìn náà, ogun ní ọ̀run yóò wá yọrí sí fífi Sátánì sọ̀kò sí ilẹ̀ ayé, tí yóò kó ègbé bá ayé, Kristi yóò sì máa ṣàkóso láàárín àwọn ọ̀tá rẹ̀. Nígbà “ìpọ́njú ńlá” tí yóò yọrí sí ogun Ha-Mágẹ́dọ́nì ni òpin yóò dé bá ìwà ibi pátápátá, tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso alálàáfíà ti Kristi yóò sì tẹ̀ lé e.—Mátíù 24:21, 33, 34; Ìṣípayá 16:14-16.
Bíbélì sọ pé: “Ṣùgbọ́n mọ èyí, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀; yà kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.”—2 Tímótì 3:1-5.
Àwọn kan lè sọ pé ṣebí ọjọ́ pẹ́ tí nǹkan wọ̀nyí ti ń ṣẹlẹ̀ láàárín ọmọ aráyé, ṣùgbọ́n, òdodo ọ̀rọ̀ ibẹ̀ ni pé kò tíì pọ̀ tó báyìí rí. Bí àwọn òpìtàn àti alálàyé ọ̀ràn ṣe wí, kò tíì sígbà kan rí láyé yìí tí nǹkan rí bó ṣe rí láti ọdún 1914 wá. (Wo ojú ewé 7.) Àwọn ègbé yẹn pọ̀ rẹ́kẹrẹ̀kẹ ju tàtẹ̀yìnwá lọ. Ẹ̀wẹ̀, ní ti àwọn ẹ̀ka mìíràn lára àmì ti Kristi fúnni nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ká má ṣe gbàgbé kókó yìí pẹ̀lú, pé: Kò tíì sígbà kankan rí láyé yìí tí wọ́n tíì polongo wíwà níhìn-ín Kristi àti Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé tó ti ìsinsìnyí. Inúnibíni tí wọ́n ti ń ṣe sí àwọn èèyàn nítorí iṣẹ́ ìwàásù látẹ̀yìnwá kò tó èyí tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fojú winá rẹ̀ rárá. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún wọn ni wọ́n dájọ́ ikú fún, tí wọ́n sì pa nínú àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìjọba Násì. Dòní olónìí, wọ́n ṣì fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àwọn ibì kan, níbòmíràn wọ́n ń fàṣẹ ọba mú wọn, wọ́n ń jù wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n ń dá wọn lóró, wọ́n sì ń pa wọ́n. Gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ ara àmì tí Jésù fúnni.
Gẹ́gẹ́ bí Ìṣípayá 11:18 ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ‘àwọn orílẹ̀-èdè ti kún fún ìrunú’ sí àwọn olóòótọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èyí sì fi hàn pé “ìrunú” ti Jèhófà alára máa tó dé sórí àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan náà yìí sọ pé Ọlọ́run yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” Kò tíì ṣẹlẹ̀ rí láyé yìí pé kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí kó agbára tí ilẹ̀ ayé ní láti fi pèsè ohun ìgbẹ́mìíró sínú ewu. Àmọ́, nǹkan ti yàtọ̀ báyìí! Ọ̀pọ̀lọpọ̀ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ló ti kìlọ̀ pé bí aráyé bá ń bá a lọ láti sọ ayé dìbàjẹ́, yóò di ibi tí kò ní ṣeé gbé mọ́. Bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà “ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀,” nípa bẹ́ẹ̀ yóò mú àwọn ọ̀bàyéjẹ́ wọ̀nyẹn kúrò kí wọ́n tó run ilẹ̀ ayé tán poo.—Aísáyà 45:18.
ÀWỌN ÌBÙKÚN ILẸ̀ AYÉ LÁBẸ́ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN
Èrò pé àwọn èèyàn yóò máa gbé lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lè dà bí ohun àjèjì sí ọ̀pọ̀ àwọn tó gba Bíbélì gbọ́ tí wọ́n rò pé ọ̀run ni gbogbo àwọn tó rí ìgbàlà yóò wà. Bíbélì fi hàn pé kìkì ìwọ̀nba èèyàn kéréje lo ń lọ sí ọ̀run, àti pé àwọn tí yóò wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé yóò jẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá tí kò níye. (Sáàmù 37:11, 29; Ìṣípayá 7:9; 14:1-5) Àsọtẹ́lẹ̀ kan nínú ìwé Dáníẹ́lì nínú Bíbélì fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run lábẹ́ Kristi yóò gba gbogbo ayé yóò sì máa ṣàkóso rẹ̀.
Nínú ìwé Dáníẹ́lì yìí, wọ́n fi Ìjọba Kristi wé òkúta kan tí wọ́n gé láti ara òkè tó jẹ́ ipò ọba aláṣẹ Jèhófà. Ó kọlu ère tó dúró fún àwọn orílẹ̀-èdè alágbára ní ayé, ó sì pa wọ́n run, “òkúta tí ó kọlu ère náà . . . di òkè ńlá tí ó tóbi, ó sì kún gbogbo ilẹ̀ ayé.” Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tẹ̀ síwájú pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 2:34, 35, 44.
Ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba yìí àti ìrètí tí Ìwé Mímọ́ tì lẹ́yìn, ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tó di mímọ́ tónítóní tí ó sì lẹ́wà, ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fẹ́ láti sọ fún ọ. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn tí ń bẹ láàyè nísinsìnyí, àti ẹgbàágbèje tí ń bẹ nínú ibojì wọn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí yóò láǹfààní láti gbé inú rẹ̀ títí láé. Lẹ́yìn náà, lábẹ́ Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi Jésù, ète tí Jèhófà ní nípilẹ̀ṣẹ̀ tó fi dá ayé, tó sì fi tọkọtaya àkọ́kọ́ sórí rẹ̀ yóò wá ṣẹ. Párádísè ilẹ̀ ayé kò ní súni láé. Bí Ọlọ́run ṣe yan iṣẹ́ fún Ádámù láti bójú tó nínú ọgbà Édẹ́nì, bẹ́ẹ̀ ni aráyé yóò ṣe ní àwọn iṣẹ́ takuntakun tí wọn yóò gbé ṣe lẹ́nu bíbójútó ilẹ̀ ayé àti àwọn ewéko àti ẹranko inú rẹ̀. Wọn “yóò gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ wọn kánrin kése.”—Aísáyà 65:22, Revised Standard Version; Jẹ́nẹ́sísì 2:15.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ la lè tọ́ka sí láti fi hàn bí ipò nǹkan yóò ṣe rí nígbà tí Ọlọ́run bá dáhùn àdúrà tí Jésù fi kọ́ wa, pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Àmọ́, ẹ jẹ́ ká fi mọ sórí eléyìí tó kà pé: “Mo gbọ́ tí ohùn rara láti orí ìtẹ́ náà wí pé: ‘Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.’ Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ sì wí pé: ‘Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.’ Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó wí pé: ‘Kọ̀wé rẹ̀, nítorí pé ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́.’”—Ìṣípayá 21:3-5.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 15]
“Àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò,”
ṢÙGBỌ́N “nígbà náà ni òpin yóò sì dé”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Netherlands
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Nàìjíríà