Kọ́ Bí A Ṣe Ń Jẹ́ Olùkọ́ Tó Múná Dóko
KÍ NI ohun tí ìwọ tó o jẹ́ olùkọ́ ń lépa? Bí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde Ìjọba Ọlọ́run, ó dájú pé wàá fẹ́ mọ bí a ṣe ń bá àwọn èèyàn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílé wọn, nítorí pé àṣẹ tí Jésù pa fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni pé kí wọ́n lọ máa sọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20) Bí o bá sì jẹ́ ẹni tó ti mọwọ́ ìgbòkègbodò yìí dáadáa ni, ó ṣeé ṣe kí ohun tí ò ń lépa jẹ́ bí wàá ṣe máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tí yóò túbọ̀ wọ àwọn tí o fẹ́ ṣèrànwọ́ fún lọ́kàn. Bí o bá jẹ́ òbí, dájúdájú wàá fẹ́ jẹ́ irú olùkọ́ tí yóò lè sún àwọn ọmọ rẹ̀ láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run. (3 Jòh. 4) Bí o bá jẹ́ alàgbà tàbí bí o bá ń nàgà láti di alàgbà, bóyá wàá fẹ́ di ẹni tó lè sọ àsọyé lọ́nà tó lè gbin ìmọrírì tó túbọ̀ jinlẹ̀ nípa Jèhófà àti àwọn ọ̀nà rẹ̀ sọ́kàn àwọn olùgbọ́ rẹ. Báwo ni ọwọ́ rẹ yóò ṣe tẹ àwọn ohun tí ò ń lépa yìí?
Fi Jésù Kristi tó jẹ́ Ọ̀gá Olùkọ́ ṣe àwòṣe. (Lúùkù 6:40) Ì báà jẹ́ àwùjọ kan tó pé jọ sí ẹ̀bá òkè ní Jésù ń bá sọ̀rọ̀, tàbí àwọn èèyàn mélòó kan tó ń rìn lọ lójú ọ̀nà, ohun tó bá sọ àti ọ̀nà tó bá gbà sọ ọ́ kì í tètè kúrò lọ́kàn wọn. Jésù máa ń ta èrò inú àti èrò ọkàn àwọn olùgbọ́ rẹ̀ jí, ó sì máa ń ṣàlàyé ọ̀nà tí wọ́n lè gbà fi ohun tí wọ́n gbọ́ sílò lọ́nà tó lè yé wọn. Ǹjẹ́ o lè ṣe bẹ́ẹ̀?
Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
Ohun tó jẹ́ kí agbára ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Jésù túbọ̀ dára sí i ni àjọṣe tímọ́tímọ́ tí ń bẹ láàárín òun àti Bàbá rẹ̀ ọ̀run, àti pé ẹ̀mí Ọlọ́run tún ràn án lọ́wọ́. Ǹjẹ́ o máa ń gbàdúrà sí Jèhófà tọ́kàn tara pé kí o lè báni ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́nà tó múná dóko? Bí o bá jẹ́ òbí, ǹjẹ́ o máa ń gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run déédéé nígbà tó o bá ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ? Ǹjẹ́ o máa ń gbàdúrà àtọkànwá nígbà tó o bá ń múra ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ fún ìjọ tàbí tí o bá máa darí ìpàdé? Fífi tàdúràtàdúrà gbára lé Jèhófà lọ́nà bẹ́ẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti di olùkọ́ tó múná dóko.
Béèyàn ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tó tún máa ń hàn nínú bí èèyàn ṣe gbára lé Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nínú àdúrà tí Jésù gbà lálẹ́ ọjọ́ tó lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí èèyàn pípé, ó sọ fún Bàbá rẹ̀ pé: “Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn.” (Jòh. 17:14) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ní ìrírí tó pọ̀ jaburata, síbẹ̀ kò jẹ́ gbé àdábọwọ́ ara rẹ̀ kalẹ̀ nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀. Ohun tí Bàbá rẹ̀ kọ́ ọ ló ń sọ nígbà gbogbo, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa láti tẹ̀ lé. (Jòh. 12:49, 50) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tó wà nínú Bíbélì, lágbára láti darí àwọn èèyàn, ìyẹn láti darí ìwà wọn, èrò tó wà lódò ikùn wọn àti bí ọ̀ràn ṣe ń rí lára wọn. (Héb. 4:12) Bí ìmọ̀ rẹ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá ṣe ń pọ̀ sí i, tí o sì túbọ̀ ń mọ bí a ṣe ń lò ó dáadáa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ lo ṣe túbọ̀ máa mọ bí a ṣe ń kọ́ni lọ́nà tó ń mú kí àwọn èèyàn fà mọ́ Ọlọ́run.—2 Tím. 3:16, 17.
Bọlá fún Jèhófà
Kì í ṣe kéèyàn sáà ti lè sọ àsọyé alárinrin ló ń mú kó jẹ́ olùkọ́ tó ń tẹ̀ lé àwòṣe Kristi. Òótọ́ ni pé ẹnu ya àwọn èèyàn nítorí “àwọn ọ̀rọ̀ alárinrin” tó ń tẹnu Jésù jáde. (Lúùkù 4:22) Ṣùgbọ́n kí ni ohun tí Jésù ń lépa tó fi ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dùn mọ́ni? Jèhófà ló fẹ́ fi bọlá fún, kì í ṣe pé ó fẹ́ fi pe àfiyèsí sí ara rẹ̀. (Jòh. 7:16-18) Ó sì rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín, kí wọ́n sì lè fi ògo fún Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mát. 5:16) Ó yẹ kí ìmọ̀ràn yẹn ní ipa lórí ọ̀nà tí a gbà ń kọ́ni. Ó yẹ kó máa ró lọ́kàn wa pé a fẹ́ máa yàgò fún ohunkóhun tí yóò bá mú wa ṣe ohun tó yàtọ̀ sí ìyẹn. Nípa bẹ́ẹ̀, bí a bá ń múra ohun tí a máa sọ tàbí ọ̀nà tí a máa gbà sọ ọ́, ó dára ká bi ara wa pé, ‘Ṣé èyí á mú kí àwọn èèyàn túbọ̀ mọyì Jèhófà ni tàbí èmi ló máa pe àfiyèsí sí?’
Bí àpẹẹrẹ, tí a bá ń kọ́ni a lè lo àwọn àpèjúwe àti ìrírí ayé lọ́nà tó gbéṣẹ́. Àmọ́, tí a bá lọ ń lo àpèjúwe tó gùn bí ilẹ̀ bí ẹni tàbí ká wá sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìrírí títí dórí ìdodo ẹ̀fọn, ẹ̀kọ́ tá a fẹ́ kọ́ni lè dàrú mọ́ wọn lójú. Bákan náà, sísọ àwọn ìtàn aláwàdà máa ń yí àfiyèsí kúrò lórí ohun tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa wà fún. Olùkọ́ tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ara rẹ̀ ló ń pe àfiyèsí sí dípò ṣíṣe ohun tí a torí rẹ̀ ń gba ẹ̀kọ́ ìjọba Ọlọ́run.
“Fi Ìyàtọ̀” Hàn
Kí èèyàn tó di ọmọ ẹ̀yìn lóòótọ́, ohun tó ń kọ́ ní láti yé e yékéyéké. Ó ní láti gbọ́ òtítọ́, kó sì rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín òtítọ́ àti àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn yòókù. Fífi òtítọ́ àti ẹ̀kọ́ ìsìn yòókù wéra ni yóò fi ìyàtọ̀ náà hàn.
Jèhófà rọ àwọn èèyàn rẹ̀ léraléra pé kí wọ́n “fi ìyàtọ̀” sáàárín ohun tó mọ́ àti ohun tí kò mọ́. (Léf. 10:9-11) Ó ní àwọn tó bá máa ṣiṣẹ́ ìsìn nínú tẹ́ńpìlì ńlá rẹ̀ nípa tẹ̀mí yóò fún àwọn èèyàn ní ìtọ́ni “nípa ìyàtọ̀ láàárín ohun mímọ́ àti ohun tí a ti sọ di àìmọ́.” (Ìsík. 44:23) Ìwé Òwe sì kún fún ọ̀rọ̀ nípa ìyàtọ̀ tí ń bẹ láàárín òdodo àti ìwà burúkú, láàárín ìwà ọgbọ́n àti ìwà òmùgọ̀. Kódà a tiẹ̀ lè fìyàtọ̀ sáàárín àwọn ohun tó fara jọ ara wọn pàápàá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìyàtọ̀ sáàárín olódodo àti ènìyàn rere, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Róòmù 5:7. Ó sọ bí iṣẹ́ àlùfáà àgbà ti Kristi ṣe lọ́lá ju ti Áárónì lọ nínú ìwé Hébérù. Ní tòdodo, bí John Amos Comenius tó jẹ́ olùkọ́ni kan ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún ṣe wí lọ̀ràn kíkọ́ni ṣe rí, ó kọ̀wé pé: “Ohun tí kíkọ́ni kàn túmọ̀ sí ni pé ká fi bí àwọn nǹkan ṣe yàtọ̀ síra wọn hàn, ìyẹn ohun ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n wà fún, bí wọ́n ṣe jẹ́ oríṣiríṣi, àti bí wọ́n ṣe ní ìpìlẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. . . . Nítorí náà, ẹni tó bá ṣàlàyé ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn nǹkan lọ́nà tó dáa ló kọ́ni dáadáa.”
Bí àpẹẹrẹ, ká ní pé ò ń kọ́ ẹnì kan nípa Ìjọba Ọlọ́run. Tónítọ̀hún bá jẹ́ ẹni tí kò mọ ohun tí Ìjọba yẹn jẹ́, o lè ṣàlàyé bí ohun tí Bíbélì sọ nípa Ìjọba yẹn ṣe yàtọ̀ sí èrò àwọn kan pé Ìjọba yẹn kàn jẹ́ ipò kan nínú ọkàn èèyàn ni. Tàbí kí o sọ bí Ìjọba yẹn ṣe yàtọ̀ sí àwọn ìjọba èèyàn. Ṣùgbọ́n tí àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀ bá ti mọ gbogbo ìwọ̀nyẹn tẹ́lẹ̀, o lè wá ṣe àlàyé tó túbọ̀ kún rẹ́rẹ́ sí i. O lè ṣàlàyé nípa bí Ìjọba Mèsáyà ṣe yàtọ̀ sí jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ ọba aláṣẹ lórí ohun gbogbo, gẹ́gẹ́ bí Sáàmù 103:19 ṣe sọ, tàbí bí ó ṣe yàtọ̀ sí ‘ìjọba Ọmọ ìfẹ́ Ọlọ́run’ tí Kólósè 1:13 sọ, tàbí bí ó ṣe yàtọ̀ sí “iṣẹ́ àbójútó” tí Éfésù 1:10 mẹ́nu kàn. Sísọ àwọn ohun tí wọ́n fi yàtọ̀ síra lè mú kí òye ẹ̀kọ́ pàtàkì inú Bíbélì yìí túbọ̀ yé àwọn olùgbọ́ rẹ.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni Jésù máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó bá ń kọ́ni. Ó ṣàlàyé nípa bí òye ọ̀pọ̀ èèyàn nípa Òfin Mósè ṣe yàtọ̀ sí ohun tí Òfin yẹn wà fún ní ti gidi. (Mát. 5:21-48) Ó sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín bí a ṣe ń fọkàn sin Ọlọ́run lóòótọ́ àti ìwà àgàbàgebè àwọn Farisí. (Mát. 6:1-18) Ó ṣàlàyé ìyàtọ̀ tí ń bẹ́ láàárín ‘ẹ̀mí jíjẹ ọ̀gá lé àwọn èèyàn lórí’ tí àwọn kan ń lò àti ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ yóò ní. (Mát. 20:25-28) Gẹ́gẹ́ bí Mátíù 21:28-32 ṣe sọ, ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Jésù sọ pé kí àwọn olùgbọ́ òun pàápàá fúnra wọn sọ ìyàtọ̀ tí ń bẹ láàárín ẹni tó ka ara rẹ̀ sí olódodo àti ẹni tó ronú pìwà dà lóòótọ́. Ìyẹn ló mú wa dórí apá pàtàkì mìíràn nípa bí a ṣe lè kọ́ni lọ́nà tó dára.
Mú Kí Àwọn Olùgbọ́ Rẹ Ronú
A kà á nínú Mátíù 21:28 pé nígbà tí Jésù fẹ́ fi ìyàtọ̀ kan hàn, ìbéèrè ló kọ́kọ́ béèrè, ó ní: “Kí ni ẹ̀yin rò?” Olùkọ́ tó tóótun kò ní kàn mẹ́nu kan àwọn kókó ọ̀rọ̀ tàbí kó kàn sáà máa dáhùn àwọn ìbéèrè. Káká bẹ́ẹ̀, ńṣe ni yóò ran àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti kọ́ bí a ṣe ń ronú. (Òwe 3:21; Róòmù 12:1) Ọ̀nà kan láti gbà ṣe èyí ni nípa bíbéèrè ìbéèrè. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Mátíù 17:25, Jésù béèrè pé: “Kí ni ìwọ rò, Símónì? Lọ́wọ́ ta ni àwọn ọba ilẹ̀ ayé ti ń gba owó ibodè tàbí owó orí? Ṣé lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn ni tàbí lọ́wọ́ àwọn àjèjì?” Àwọn ìbéèrè amúnironújinlẹ̀ tí Jésù béèrè yìí mú kí Pétérù wá ronú kan ìgbésẹ̀ tó tọ́ láti gbé nípa sísan owó orí inú tẹ́ńpìlì. Bákan náà, nígbà tí Jésù máa fèsì ọ̀rọ̀ ẹni tó béèrè pé, “Ní ti gidi ta ni aládùúgbò mi?,” ó jẹ́ kó rí ìyàtọ̀ tí ń bẹ láàárín ohun tí àlùfáà kan àti ọmọ Léfì kan ṣe, àti èyí tí ará Samáríà kan ṣe. Lẹ́yìn náà, ó wá béèrè pé: “Lójú tìrẹ, ta ni nínú àwọn mẹ́ta wọ̀nyí ni ó ṣe ara rẹ̀ ní aládùúgbò fún ọkùnrin tí ó bọ́ sí àárín àwọn ọlọ́ṣà?” (Lúùkù 10:29-36) Níhìn-ín pẹ̀lú, dípò tí Jésù yóò fi máa ṣàlàyé gbogbo ọ̀rọ̀ láìjẹ́ kí ẹni tó ń bá sọ̀rọ̀ ronú, ńṣe ló ní kó fúnra rẹ̀ dáhùn ìbéèrè ara rẹ̀.—Lúùkù 7:41-43.
Mú Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn
Àwọn olùkọ́ni tí òye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yé mọ̀ pé ìjọsìn tòótọ́ kò mọ sí pé ká sáà ti kọ́ àwọn òtítọ́ ọ̀rọ̀ kan ní àkọ́sórí kí a sì tẹ̀ lé àwọn ìlànà kan. Ìjọsìn tòótọ́ sinmi lórí níní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà àti mímọrírì àwọn ọ̀nà rẹ̀. Irú ìjọsìn bẹ́ẹ̀ gba pé ká fi ọkàn ṣe é. (Diu. 10:12, 13; Lúùkù 10:25-27) Nínú Ìwé Mímọ́, gbólóhùn náà “ọkàn-àyà” sábà máa ń tọ́ka sí ẹni tá a jẹ́ gan-an nínú lọ́hùn-ún, títí kan àwọn nǹkan tó ń wuni, ohun téèyàn fẹ́ràn, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ẹni, àti ẹ̀mí tó ń súnni ṣe àwọn nǹkan.
Jésù mọ̀ pé ohun tó fara hàn sójú làwọn èèyàn máa ń wò nígbà tó jẹ́ pé ohun tí ọkàn ẹni jẹ́ ni Ọlọ́run ń wò. (1 Sám. 16:7) Ó yẹ kó jẹ́ pé fífẹ́ tá a fẹ́ràn Ọlọ́run ló ń sún wa ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, kó máà jẹ́ nítorí ṣekárími. (Mát. 6:5-8) Àmọ́ àṣehàn pọ̀ gan-an nínú ohun tí àwọn Farisí ṣe ní tiwọn. Pípa gbogbo ọ̀rínkinniwín Òfin mọ́ àti títẹ̀lé àwọn ìlànà àdábọwọ́ wọn ni wọ́n rin kinkin mọ́. Ṣùgbọ́n tó bá di pé kí wọ́n hùwà tí yóò fi hàn pé òótọ́ ni wọ́n sún mọ́ Ọlọ́run tí wọ́n láwọn ń sìn, wọ́n á kùnà. (Mát. 9:13; Lúùkù 11:42) Jésù kọ́ni pé òótọ́ ló ṣe pàtàkì pé kéèyàn ṣe ohun tí Ọlọ́run wí, àmọ́ ohun tí ń bẹ lọ́kàn ẹni gan-an ló ń pinnu bóyá ìgbọràn yẹn dénú ẹni tàbí kò débẹ̀. (Mát. 15:7-9; Máàkù 7:20-23; Jòh. 3:36) Ìgbà tí a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù ni ẹ̀kọ́ tá a fi ń kọ́ni yóò lè ṣe àwọn èèyàn láǹfààní jù lọ. Ó ṣe pàtàkì pé kí á ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ kí wọ́n máa ṣe. Ṣùgbọ́n ó tún ṣe pàtàkì pé kí wọ́n mọ Jèhófà kí wọ́n sì wá dìídì fẹ́ràn rẹ̀, débi pé yóò hàn nínú ìwà wọn pé wọ́n ka àjọṣe dídán mọ́rán láàárín àwọn àti Ọlọ́run tòótọ́ sí ohun iyebíye.
Àmọ́, kí irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ tó lè ṣeni láǹfààní, èèyàn ní láti kọ́kọ́ gbé ohun tí ń bẹ lọ́kàn rẹ̀ karí ìwọ̀n. Jésù rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n ṣàyẹ̀wò ìdí tí wọ́n fi fẹ́ ṣe nǹkan kan kí wọ́n sì yẹ èrò inú wọn wò. Tó bá fẹ́ kí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ yìí èrò òdì kan padà, ó máa ń kọ́kọ́ béèrè ìdí tí wọ́n fi ro ohun tí wọ́n rò, ìdí tí wọ́n fi sọ ohun tí wọ́n sọ, tàbí ìdí tí wọ́n fi ṣe ohun tí wọ́n ṣe lọ́wọ́ wọn. Ṣùgbọ́n, kó má bàa di pé Jésù kàn fi wọ́n sílẹ̀ lágbedeméjì, á fi àwọn àlàyé kan, àpèjúwe kan tàbí àwọn ìgbésẹ̀ kan kún ìbéèrè rẹ̀ tí yóò mú kí wọ́n lè ní èrò tí ó tọ̀nà nípa ọ̀ràn ọ̀hún. (Máàkù 2:8; 4:40; 8:17; Lúùkù 6:41, 46) Àwa náà lè ran àwọn olùgbọ́ wa lọ́wọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀ nípa dídábàá pé kí wọ́n bi ara wọn ní irú ìbéèrè bíi: ‘Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ohun yìí gan-an ló ń wù mí láti ṣe? Kí nìdí tí mo fi ṣe ohun tí mo ṣe nípa ọ̀ràn yìí?’ Lẹ́yìn náà, wá sọ ohun tí yóò jẹ́ kí wọ́n lè fi irú ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀ràn náà wò ó.
Sọ Bí Wọ́n Ṣe Lè Lò Ó
Olùkọ́ tó gbó ṣáṣá mọ̀ pé “ọgbọ́n ni ohun ṣíṣe pàtàkì jù lọ.” (Òwe 4:7) Ohun tí ń jẹ́ ọgbọ́n ni pé kéèyàn lè lo ìmọ̀ tí ó ní láti fi yanjú àwọn ìṣòro, láti fi yàgò fún ewu, láti fi lé àwọn ohun kan bá, àti láti fi ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Ojúṣe olùkọ́ ni pé kí ó ran àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti lè lo ìmọ̀ lọ́nà bẹ́ẹ̀, àmọ́ kò ní ṣe ìpinnu fún wọn. Tó o bá ń ṣàlàyé onírúurú ìlànà Bíbélì, ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ láti ronú. O lè sọ àpẹẹrẹ ohun kan tó máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé, kí o wá bi akẹ́kọ̀ọ́ rẹ léèrè nípa bí ìlànà Bíbélì tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ yóò ṣe ràn án lọ́wọ́ tí irú ohun tó o sọ bá ṣẹlẹ̀ sí i.—Héb. 5:14.
Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń sọ àsọyé nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ọ̀nà tó gbà fi hàn pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kan àwọn olùgbọ́ rẹ̀ tí ìyẹn sì wá ní ipá lórí ìgbésí ayé wọn jẹ́ àpẹẹrẹ tó wúlò gan-an. (Ìṣe 2:14-36) Lẹ́yìn tí Pétérù sọ̀rọ̀ nípa àyọkà mẹ́ta nínú Ìwé Mímọ́ tí àwùjọ tó wà níbẹ̀ sọ pé àwọn gbà gbọ́, ó wá sọ bí wọ́n ṣe kan àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ níṣojú gbogbo wọn. Ìyẹn mú kí àwùjọ náà rí i pé ó yẹ kí àwọn ṣíṣẹ lórí ohun tí àwọn gbọ́. Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀kọ́ tí ò ń kọ́ni ṣe ń wọ àwọn èèyàn lọ́kàn? Yàtọ̀ sí mímẹ́nu kan àwọn kókó ọ̀rọ̀, ǹjẹ́ o tún máa ń jẹ́ kí àwọn èèyàn lóye ìdí tí àwọn ohun tó o sọ fi rí bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ o máa ń gbà wọ́n níyànjú láti ronú nípa bó ṣe yẹ kí àwọn ohun tí wọ́n ń kọ́ ní ipa lórí ìgbésí ayé wọn? Wọ́n lè ṣàìsọ pé, “Kí ni kí àwa ṣe?,” gẹ́gẹ́ bíi ti àwùjọ ìgbà Pẹ́ńtíkọ́sì yẹn, ṣùgbọ́n tó o bá mú kí ìlò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí o kà yéni yékéyéké, yóò sún wọn láti gbìyànjú láti ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe.—Ìṣe 2:37.
Nígbà tí ẹ̀yin òbí àti àwọn ọmọ yín bá jọ ń ka Bíbélì, àǹfààní tó dára lẹ ní yẹn láti kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè máa ronú nípa ọ̀nà tí wọ́n lè gbà lo àwọn ìlànà Bíbélì nínú ìgbésí ayé wọn. (Éfé. 6:4) Bí àpẹẹrẹ, o lè yan àwọn ẹsẹ Bíbélì mélòó kan látinú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà ti ọ̀sẹ̀ yẹn, kí o ṣàlàyé ìtumọ̀ rẹ̀, kí o sì wá béèrè àwọn ìbéèrè bí ìwọ̀nyí: ‘Báwo ni èyí ṣe pèsè ìtọ́sọ́nà fún wa? Ọ̀nà wo la lè gbà lo ẹsẹ wọ̀nyí lóde ẹ̀rí? Kí ni wọ́n fi hàn nípa Jèhófà àti ọ̀nà tó gbà ń ṣe àwọn nǹkan, báwo ni ìyẹn sì ṣe mú kí a túbọ̀ mọyì rẹ̀?’ Gba ìdílé rẹ níyànjú pé kí wọ́n sọ̀rọ̀ lórí kókó wọ̀nyí nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ẹsẹ tí wọ́n bá ti fúnra wọn sọ̀rọ̀ lé lórí nílé ni wọ́n á rántí.
Fi Àpẹẹrẹ Rere Lélẹ̀
Ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan kọ́ lo fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ o, ìṣe rẹ ń kọ́ni pẹ̀lú. Ní ti gidi, ìṣe rẹ ń fi àpẹẹrẹ béèyàn ṣe máa lo àwọn ohun tí o sọ hàn. Ọ̀nà tí àwọn ọmọdé sì gbà ń kẹ́kọ̀ọ́ nìyẹn. Bí wọ́n bá ti ń ṣàfarawé àwọn òbí wọn, wọ́n ń fi hàn nìyẹn pé àwọn fẹ́ dà bíi tiwọn. Wọ́n ń fẹ́ mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ bí àwọn bá ṣe ohun tí òbí àwọn ń ṣe. Bákan náà, bí àwọn tí ò ń kọ́ bá di ‘aláfarawé rẹ, àní gẹ́gẹ́ bí o ṣe ń ṣàfarawé Kristi,’ wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí gba ìbùkún tí ń bẹ nínú rírìn ní ọ̀nà Jèhófà. (1 Kọ́r. 11:1) Ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń bá wọn lò á wá di apá kan àwọn ìrírí tiwọn pẹ̀lú.
Ìránnilétí ń jẹ́ ká rí bí ó tí ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn fi àpẹẹrẹ tí ó tọ́ lélẹ̀. Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni “irú ènìyàn [tí a] jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run” ń ṣe nínú fífi àpẹẹrẹ ọ̀nà tí a ó gbà lo àwọn ìlànà Bíbélì han àwọn tí a ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. (2 Pét. 3:11) Bí o bá gba akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ níyànjú pé kó máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, kí ìwọ náà máa ṣakitiyan láti kà á. Bí o bá ń fẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ máa ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn ìlànà Bíbélì ṣe wí, ìwọ náà rí i dájú pé ìṣe tìrẹ bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Bí o bá kọ́ ìjọ pé kí wọ́n jẹ́ onítara nínú iṣẹ́ ìsìn, ìwọ náà rí i pé o ń kópa kíkún nínú iṣẹ́ yẹn. Bí o bá ń fi ohun tí ò ń kọ́ni sílò, wàá lè túbọ̀ sún àwọn ẹlòmíràn láti fi í sílò pẹ̀lú.—Róòmù 2:21-23.
Láti lè mú kí ọ̀nà tí ò ń gbà kọ́ni sunwọ̀n sí i, bi ara rẹ léèrè pé: ‘Nígbà tí mo bá ń fúnni ní ìtọ́ni, ǹjẹ́ mo máa ń sọ ọ́ lọ́nà tí àwọn tó bá gbọ́ ọ yóò fi rí i pé ó yẹ kí àwọn yí ìwà, ọ̀nà ìgbàsọ̀rọ̀, tàbí ìṣesí àwọn padà lóòótọ́? Ǹjẹ́ mo máa ń ṣàlàyé ohun tí èrò tàbí ìgbésẹ̀ kan fi yàtọ̀ sí ìkejì kí ohun tí mò ń sọ lè yéni yékéyéké? Kí ni mo máa ń ṣe láti fi ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi, ọmọ mi, tàbí àwọn olùgbọ́ mi nípàdé lọ́wọ́ láti rántí ohun tí mo sọ? Ǹjẹ́ mo ń jẹ́ kí àwọn olùgbọ́ mi mọ ọ̀nà tí wọn yóò gbà lo ohun tí wọ́n ń kọ́ ní àmọ̀dunjú? Ṣé wọ́n lé fi àpẹẹrẹ tèmi ṣe àwòṣe? Ǹjẹ́ wọ́n mọ bí ìhà tí àwọn bá kọ sí ohun tí à ń sọ̀rọ̀ lé lórí yóò ṣe nípa lórí àjọṣe àwọn pẹ̀lú Jèhófà?’ (Òwe 9:10) Máa rántí nǹkan wọ̀nyí bí o ṣe ń ṣakitiyan láti lè kọ́ni lọ́nà tó múná dóko. “Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ. Dúró nínú nǹkan wọ̀nyí, nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.”—1 Tím. 4:16.