ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ẹ̀kọ́ 11 ojú ìwé 118-ojú ìwé 120 ìpínrọ̀ 5
  • Fífi Ọ̀yàyà Sọ̀rọ̀ Àti Fífi Bí Nǹkan Ṣe Rí Lára Ẹni Hàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fífi Ọ̀yàyà Sọ̀rọ̀ Àti Fífi Bí Nǹkan Ṣe Rí Lára Ẹni Hàn
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀yàyà àti Ìfọ̀rọ̀rora-Ẹni-Wò
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Ẹ Jẹ́ Ki Ikora-Ẹni-Nijaanu Yin Wà Ki Ó Sì Kún Àkúnwọ́sílè
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Máa Fàyè Gba Èrò Òdì?
    Jí!—2005
  • Máa Gba Tàwọn Míì Rò
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ẹ̀kọ́ 11 ojú ìwé 118-ojú ìwé 120 ìpínrọ̀ 5

Ẹ̀KỌ́ 11

Fífi Ọ̀yàyà Sọ̀rọ̀ Àti Fífi Bí Nǹkan Ṣe Rí Lára Ẹni Hàn

Kí ló yẹ kí o ṣe?

Ó yẹ kí o sọ̀rọ̀ látọkànwá lọ́nà tí yóò fi bí nǹkan ṣe rí lára hàn lóòótọ́.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

Ó ṣe pàtàkì tó o bá fẹ́ kí ohun tó ò ń sọ wọ àwọn olùgbọ́ rẹ lọ́kàn.

KÉÈYÀN fi bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ hàn jẹ́ apá pàtàkì nínú ìgbésí ayé. Nígbà tí èèyàn bá fi bí nǹkan ṣe rí lára hàn, ńṣe ló ń jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀, irú ẹni tó jẹ́ nínú lọ́hùn-ún, àti bó ṣe máa ń ronú nípa àwọn nǹkan àtàwọn èèyàn. Àwọn èèyàn kan máa ń fi bí nǹkan ṣe rí lára wọn pa mọ́ nítorí ohun tójú wọ́n ti rí ní ìgbésí ayé, tàbí nígbà mìíràn, nítorí ipa tí àṣà ilẹ̀ wọn ní lórí wọn. Ṣùgbọ́n Jèhófà gbà wá níyànjú pé ká fi àwọn ànímọ́ rere kọ́ra, kí wọ́n sì máa hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣesí wa.—Róòmù 12:10; 1 Tẹs. 2:7, 8.

Nígbà tí a bá sọ̀rọ̀, a lè lo ọ̀rọ̀ tó sọ bí nǹkan ṣe rí lára wa lóòótọ́. Bí ọ̀rọ̀ wa bá dà bí ọ̀rọ̀ orí ahọ́n lásán, àwọn tó ń gbọ́ wa lè ṣiyè méjì pé bóyá lohun tá a ń sọ tọkàn wa wá. Ṣùgbọ́n, bí a bá sọ ọ́ bó ṣe rí lára gan-an, ọ̀rọ̀ wa á lárinrin á sì dùn-ún gbọ́ débi tí yóò fi wọ àwọn tó ń gbọ́ ọ lọ́kàn.

Fífi Ọ̀yàyà Sọ̀rọ̀. Ohun tá a bá rò nípa àwọn èèyàn ló máa ń jẹ́ kí ara wa yá mọ́ wọn. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ fífanimọ́ra tí Jèhófà ní, àti nígbà tí a bá ń dúpẹ́ oore tí Jèhófà ṣe, ohùn ọ̀yàyà ló yẹ ká lò. (Aísá. 63:7-9) Nígbà tí a bá sì ń bá àwọn èèyàn bíi tiwa sọ̀rọ̀, ọ̀nà tí a gbà ń sọ̀rọ̀ tún gbọ́dọ̀ fi ẹ̀mí ọ̀yàyà hàn.

Adẹ́tẹ̀ kan wá sọ́dọ̀ Jésù, ó sì bẹ̀ ẹ́ pé kó wo òun sàn. Sáà ronú nípa irú ohùn tí Jésù fi dá a lóhùn, ó sọ pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.” (Máàkù 1:40, 41) Tún fojú inú wo ìran yìí, obìnrin tí àìsàn ìṣàn ẹ̀jẹ̀ ń ṣe fún ọdún méjìlá sún mọ́ Jésù látẹ̀yìn, ó sì fọwọ́ kan etí ẹ̀wù àwọ̀lékè Jésù. Bí obìnrin náà ṣe rí i pé Jésù mọ nǹkan tí òun ṣe, ó bọ́ síwájú ó sì ń wárìrì, ó wólẹ̀ níbi ẹsẹ̀ Jésù, ó sì ṣàlàyé níwájú gbogbo èèyàn, ìdí tí òun fi fọwọ́ kan ẹ̀wù Jésù àti bí a ṣe mú òun lára dá. Ronú nípa ọ̀nà tí Jésù gbà sọ fún un pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá; máa bá ọ̀nà rẹ lọ ní àlàáfíà.” (Lúùkù 8:42b-48) Ohùn títura tí Jésù lò ní àwọn àkókò wọ̀nyẹn ṣì máa ń wọ̀ wá lọ́kàn títí di òní olónìí.

Bíi ti Jésù, nígbà tí a bá fi ìyọ́nú hàn sí àwọn èèyàn tí a sì fẹ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ ní tòótọ́, ó máa ń hàn nínú ọ̀nà tí à ń gbà bá wọn sọ̀rọ̀. Irú ohùn tó tura bẹ́ẹ̀ máa ń ti ọkàn wá ni, kì í ṣe ti ṣekárími. Bí a ṣe ń fi ohùn tó tura sọ̀rọ̀ lè pinnu bí àwọn èèyàn ṣe máa tẹ̀ lé ohun tí a sọ tó. Ọ̀pọ̀ nǹkan tá a máa ń sọ lóde ẹ̀rí ni a lè fi ohùn tó tura sọ, ní pàtàkì nígbà tí a bá ń fèrò wérò, tí à ń fúnni níṣìírí, tí à ń gbani níyànjú, tí a sì ń báni kẹ́dùn.

Tí ọkàn rẹ bá yá mọ́ èèyàn, jẹ́ kí ó hàn lójú rẹ. Bí ara rẹ bá yá mọ́ni, ńṣe làwọn olùgbọ́ rẹ yóò fà mọ́ ọ bí ìgbà téèyàn bá sún mọ́ ìdí iná tó fẹ́ yá nígbà òtútù. Bí o bá rojú koko, ó lè ṣàìdá àwọn olùgbọ́ rẹ lójú pé lóòótọ́ lo bìkítà nípa wọn. Bó bá jẹ́ ọ̀yàyà tí kò dénú lo fi hàn, kíá làwọn èèyàn á mọ̀. Nítorí náà, ọ̀yàyà tó o fi hàn gbọ́dọ̀ jẹ́ ojúlówó.

Ohùn rẹ tún gbọ́dọ̀ fi ọ̀yàyà hàn. Bí o bá ní ohùn líle tó ń tani létí, ó lè ṣòro fún ọ láti fi ohùn tó tura sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n bí àkókò ti ń lọ, tí o sì ń sapá tọkàntọkàn, wàá lè máa fi ohun tó tura sọ̀rọ̀. Ohun kan tó lè ṣèrànwọ́, tó jẹ́ ọgbọ́n tí o lè dá sí i, ni pé kí o máa rántí pé bí èèyàn bá ń yára sọ̀rọ̀, tó dà bíi pé ọ̀rọ̀ ń jó o lẹ́nu, ńṣe ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò máa ta àwọn èèyàn létí. Yóò dára kí o kọ́ bí wọ́n ṣe máa ń fa ọ̀rọ̀ olóhùn ìsàlẹ̀ gùn láàárín ọ̀rọ̀. Èyí á jẹ́ kí o lè máa fi ohùn tó tura sọ ọ̀rọ̀ rẹ.

Ṣùgbọ́n, ohun kan tí ó tiẹ̀ wá ṣe pàtàkì ju ni ohun tó o nífẹ̀ẹ́ sí. Bí o bá ń ronú gidigidi nípa àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀ ní tòótọ́, tí o sì fi tọkàntọkàn fẹ́ láti sọ ohun kan tí yóò ṣe wọ́n láǹfààní fún wọn, ohun tó o ní lọ́kàn yẹn yóò hàn nínú bí o ṣe ń sọ̀rọ̀.

Ọ̀rọ̀ tí a fi ara yíyá gágá sọ máa ń tani jí, ṣùgbọ́n a tún ní láti sọ̀rọ̀ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Wíwulẹ̀ sọ̀rọ̀ láti fi yíni lérò padà nìkan kì í fi ìgbà gbogbo tó; ọ̀rọ̀ wa tún gbọ́dọ̀ gún ọkàn onítọ̀hún ní kẹ́sẹ́.

Fífi Bí Nǹkan Ṣe Rí Lára Ẹni Hàn Làwọn Ọ̀nà Mìíràn. Yóò hàn lára ẹni tí wàhálà bá bá pé ó ń ṣàníyàn, pé ẹ̀rù ń bà á, àti pé ó sorí kọ́. Ìdùnnú jẹ́ ẹ̀mí tó yẹ kó gba ipò pàtàkì nínú ìgbésí ayé wa, èyí ló sì yẹ kó máa hàn fàlàlà nígbà tí a bá ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀. Àmọ́ ṣá o, àwọn ẹ̀mí kan wà tó yẹ ká kápá. Wọn kò bá ẹ̀mí Kristẹni mu. (Éfé. 4:31, 32; Fílí. 4:4) A lè fi irú ọ̀rọ̀ tí a lò, ìró ohùn wa, bí ohùn wa ṣe rinlẹ̀ tó, ìrísí ojú wa, àti ìfaraṣàpèjúwe láti fi sọ gbogbo bí nǹkan ṣe rí lára wa.

Bíbélì ṣàlàyé nípa onírúurú ìṣarasíhùwà tó fi bí nǹkan ṣe ń rí lára èèyàn hàn. Nígbà mìíràn, ńṣe ló kúkú sọ bí nǹkan ṣe rí lára àwọn èèyàn ní pàtó. Àmọ́ nígbà mìíràn, ó máa ń ṣàlàyé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tàbí kó fa àwọn gbólóhùn kan yọ tó fi hàn bí nǹkan ṣe rí lára àwọn èèyàn. Nígbà tó o bá ka irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ sókè, ó máa ní ipa ńláǹlà lórí ìwọ àti àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí o bá lo ohùn tó fi hàn bí nǹkan ṣe rí lára àwọn tí ò ń kà nípa wọn. Láti lè ṣe ìyẹn, o gbọ́dọ̀ fi ara rẹ sí ipò àwọn tí ò ń kà nípa wọn. Ṣùgbọ́n àsọyé kì í ṣe eré orí ìtàgé o. Nítorí náà, ṣọ́ra kí o má ṣe àṣerégèé. Mú kí ibi tí ò ń kà wọ àwọn tó ń gbọ́ ọ lọ́kàn.

Ó Bá Ọ̀rọ̀ Mu. Gẹ́gẹ́ bí ìtara, ohun tí o bá ń sọ̀rọ̀ lé lórí ló máa pinnu bó o ṣe máa fi ọ̀yàyà àti àwọn ànímọ́ mìíràn tó fi bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ hàn.

Ṣí Mátíù 11:28-30, kí o sì kíyè sí ohun tó sọ. Lẹ́yìn náà, ka àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù fi dá àwọn akọ̀wé àti Farisí lẹ́bi ní Mátíù orí kẹtàlélógún. A kò lè fojú inú wò ó pé ńṣe ni Jésù á kàn sọ̀rọ̀ lóhùn ṣákálá lọ́nà àìbìkítà nígbà tó ń kéde ìdálẹ́bi gbígbóná janjan yìí.

Irú ànímọ́ wo lo rò pé ó yẹ láti fi ka irú àkọsílẹ̀ tó wà ní Jẹ́nẹ́sísì orí kẹrìnlélógójì nípa ẹ̀bẹ̀ tí Júdà bẹ̀ nítorí Bẹ́ńjámínì àbúrò rẹ̀? Ṣàkíyèsí ìṣarasíhùwà tó fi bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ hàn ní Jẹ́ 44 ẹsẹ ìkẹtàlá, ohun tí Jẹ́ 44 ẹsẹ ìkẹrìndínlógún fi hàn nípa ohun tí Júdà ronú pé ó fa àjálù náà, àti bí Jósẹ́fù alára ṣe ṣe, gẹ́gẹ́ bí Jẹ́nẹ́sísì 45:1 ṣe sọ.

Nítorí náà, bóyá à ń kàwé tàbí à ń sọ̀rọ̀, láti lè ṣe é dáadáa, kì í ṣe ọ̀rọ̀ àti èrò nìkan ló yẹ ká ronú nípa rẹ̀, ó tún yẹ ká ronú nípa bó ṣe yẹ kí ọ̀ràn náà rí lára.

BÍ A ṢE LÈ FI Í HÀN

  • Pọkàn pọ̀ sórí fífẹ́ tí o fẹ́ láti ran àwọn olùgbọ́ rẹ lọ́wọ́ dípò ṣíṣàníyàn jù nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí o fẹ́ lò.

  • Ìró ohùn rẹ àti ìrísí ojú rẹ gbọ́dọ̀ fi bí ọ̀rọ̀ tí ò ń sọ ṣe rí lára rẹ gan-an hàn.

  • Kọ́ bí a ṣe ń ṣe é nípa fífarabalẹ̀ kíyè sí àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dá-ń-tọ́.

ÌDÁNRAWÒ: Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tò tẹ̀ lé e yìí sókè, kí o kà á bó ṣe rí gan-an lára àwọn èèyàn ibẹ̀: Mátíù 20:29-34; Lúùkù 15:11-32.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́