Ẹ Jẹ́ Ki Ikora-Ẹni-Nijaanu Yin Wà Ki Ó Sì Kún Àkúnwọ́sílè
‘Ẹ fi ikora-ẹni-nijaanu kún igbagbọ yin.’—2 PETERU 1:5, 6, NW.
1. Ni ipo ti o ṣajeji wo ni Kristian kan ti lè funni ni ijẹrii?
JESU sọ pe: “A o sì mu yin lọ siwaju awọn [gomina, NW] ati awọn ọba nitori orukọ mi, fun ẹ̀rí si wọn.” (Matteu 10:18) Bi a bá pè ọ́ wá siwaju gomina, adajọ, tabi ààrẹ kan, ki ni iwọ yoo sọrọ nipa rẹ̀? Boya lakọọkọ ná nipa idi ti o fi wà nibẹ, ẹ̀sùn ti a fi kàn ọ́. Ẹmi Ọlọrun yoo ràn ọ́ lọwọ lati ṣe bẹẹ. (Luku 12:11, 12) Ṣugbọn iwọ ha lè ronu sisọrọ nipa ikora-ẹni-nijaanu bi? Iwọ ha ka iyẹn si apá pataki kan ninu ihin-iṣẹ Kristian wa bi?
2, 3. (a) Bawo ni o ṣe ṣẹlẹ pe Paulu lè jẹrii fun Feliksi ati Drusilla? (b) Eeṣe ti ikora-ẹni-nijaanu fi jẹ́ koko-ọrọ yiyẹ fun Paulu lati sọrọ lé lori ni ipo yẹn?
2 Gbe apẹẹrẹ ohun kan ti o ṣẹlẹ niti gidi yẹwo. Ọ̀kan lara awọn ẹlẹ́rìí Jehofa ni a fàṣẹ-ọba mú ti a sì mú wá si ìgbẹ́jọ́. Nigba ti a fun un ni anfaani lati sọrọ, ó fẹ́ lati ṣalaye igbagbọ rẹ̀ gẹgẹ bi Kristian kan, gẹgẹ bi ẹlẹ́rìí. Iwọ lè ronu akọsilẹ naa wò iwọ yoo sì rí i pe ó funni ni ẹ̀rí ilé-ẹjọ́ “nipa òdodo ati ikora-ẹni-nijaanu ati idajọ ti ń bọ̀.” A ń tọka si iriri aposteli Paulu ni Kesarea. Ifibeere wáni lẹnu wò kọkọ wáyé. “Lẹhin ijọ́ melookan lẹhin naa, Feliksi dé ti oun ti Drusilla obinrin rẹ̀, tíí ṣe Ju, o sì ranṣẹ pe Paulu, ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ lọdọ rẹ̀ nipa igbagbọ ninu Kristi Jesu.” (Iṣe 24:24) Ìtàn rohin pe Feliksi “hu oniruuru ìwà-rírorò ati ifẹkufẹẹ, ni lilo agbara ọba bi ẹrú.” Ó ti gbeyawo rí lẹẹmeji ki o tó wá sún Drusilla lati kọ ọkọ rẹ̀ (ni rírú ofin Ọlọrun) ki ó sì di aya rẹ̀ kẹta. Boya obinrin naa ni ó fẹ́ gbọ́ nipa isin titun naa, isin Kristian.
3 Paulu ń baa lọ lati sọrọ “nipa òdodo ati ikora-ẹni-nijaanu ati idajọ ti ń bọ̀.” (Iṣe 24:25, NW) Eyi yoo ti sọ iyatọ gédégédé ti o wà laaarin awọn ọpa-idiwọn Ọlọrun nipa iduroṣanṣan ati ìwà-rírorò ati ainidaajọ-ododo ti Feliksi ati Drusilla jẹ́ apakan rẹ̀ di híhàn kedere. Paulu ti lè reti lati sún Feliksi lati fi idajọ-ododo hàn ninu ìgbẹ́jọ́ ti ń lọ lọwọ. Ṣugbọn eeṣe ti o fi mú “ikora-ẹni-nijaanu ati idajọ ti ń bọ̀” wọnu ọ̀rọ̀? Awọn oniwa palapala meji yii ń wadii ohun ti “igbagbọ ninu Kristi Jesu” ní ninu. Nitori naa wọn nilati mọ pe titẹle e beere fun kíká awọn ironu, ọrọ-sisọ, ati iṣesi ẹni lọwọko, eyi ti ikora-ẹni-nijaanu tumọsi. Gbogbo eniyan ni yoo jihin fun Ọlọrun fun ironu, ọ̀rọ̀, ati ìṣe wọn. Nipa bayii, eyi ti o ṣe pataki ju idajọ eyikeyii lati ọ̀dọ̀ Feliksi ninu ọ̀ràn Paulu ni idajọ tí gomina naa ati aya rẹ̀ dojukọ niwaju Ọlọrun. (Iṣe 17:30, 31; Romu 14:10-12) A lè loye rẹ̀ pe, lẹhin gbígbọ́ ihin-iṣẹ Paulu, “ẹ̀rù ba Feliksi.”
Ó Ṣe Pataki Ṣugbọn Kò Rọrùn
4. Eeṣe ti ikora-ẹni-nijaanu fi jẹ́ apa pataki isin Kristian tootọ?
4 Aposteli Paulu mọ ikora-ẹni-nijaanu gẹgẹ bi apa ṣiṣekoko kan ninu isin Kristian. Aposteli Peteru, ọ̀kan lara awọn alabaakẹgbẹ timọtimọ Jesu, jẹrii gbe eyi. Nigba ti ó ń kọwe si awọn wọnni ti wọn yoo “di alajọpin ninu iwa-ẹda ọ̀run” ni ọ̀run, Peteru fi tagbaratagbara damọran awọn animọ kan bayii ti o ṣekoko, iru bi igbagbọ, ifẹ, ati ikora-ẹni-nijaanu. Nitori naa imudaniloju yii wémọ́ ikora-ẹni-nijaanu: “Bi awọn ohun wọnyi bá wà ninu yin ti wọn sì kún àkúnwọ́sílẹ̀, wọn kì yoo jẹ́ ki ẹ di alaiṣiṣẹ tabi alaileso niti ìmọ̀ pipeye Jesu Kristi Oluwa wa.”—2 Peteru 1:1, 4-8, NW.
5. Eeṣe ti a fi nilati daniyan ni pataki nipa ikora-ẹni-nijaanu?
5 Bi o ti wu ki o ri, ẹ mọ pe ó tubọ rọrùn lati sọ pe a nilati fi ikora-ẹni-nijaanu hàn ju bi o ti ri niti gidi lati fi ṣewahu ninu igbesi-aye wa ojoojumọ lọ. Idi kan ni pe ikora-ẹni-nijaanu ṣọwọn ni ifiwera. Ni 2 Timoteu 3:1-5 Paulu ṣapejuwe iṣarasihuwa ti yoo gbilẹ ni akoko wa, ni “ikẹhin ọjọ.” Animọ-iwa kan ti yoo fi sáà akoko wa hàn yatọ ni pe ọpọlọpọ yoo jẹ́ “alaile-kora-wọn-nijaanu.” A ri eyi pe o jẹ́ otitọ ni gbogbo ayika wa, àbí bẹẹkọ?
6. Bawo ni aini ikora-ẹni-nijaanu ṣe farahan lonii?
6 Ọpọ eniyan gbagbọ pe ó ń funninilera lati “fi awọn imọlara wa hàn laisi ikalọwọko” tabi “fi ibinu gbigbona janjan hàn pẹlu ipá.” Oju-iwoye wọn ni a ń fun lókun nipasẹ awọn àwòfiṣàpẹẹrẹ tí igba-ojú-mọ̀ awọn ti o dabi ẹni pe wọn ṣá ikora-ẹni-nijaanu iru eyikeyii tì, ti wọn wulẹ ń farajin fun agbara isunniṣe wọn. Lati ṣàkàwé: Ọpọ eniyan ti o nifẹẹ si eré idaraya àfiṣiṣẹ́ṣe ni ìfihànsóde ero-imọlara ẹlẹ́hànnà, àní ibinu-nla oniwa-ipa paapaa ti mọlara. Ṣe iwọ kò ranti ni, ó keretan lati inu irohin, awọn apẹẹrẹ ibi ti ìjà rírorò tabi iran awujọ awọn eniyankeniyan ti ru soke nibi iṣẹlẹ eré idaraya? Ohun ti a ń sọ, bi o ti wu ki o ri, kò beere fun pe ki a yọnda akoko pupọ fun ṣiṣatunyẹwo awọn apẹẹrẹ ainikora-ẹni-nijaanu. Iwọ lè ṣe itolẹsẹẹsẹ awọn agbegbe ninu eyi ti a ti nilati fi ikora-ẹni-nijaanu hàn—ọ̀nà ti a ń gba jẹun ti a ń gbà mu, iṣesi wa pẹlu ẹ̀yà odikeji, ati akoko ati owó ti a ń ná sori awọn eré bọ́wọ́dilẹ̀. Ṣugbọn dipo wíwo ọpọlọpọ iru wọnni gààràgà, ẹ jẹ ki a ṣayẹwo agbegbe pataki kan ninu eyi ti a gbọdọ lo ikora-ẹni-nijaanu.
Ikora-Ẹni-Nijaanu Nipa Awọn Ero-Imọlara Wa
7. Apa iha ikora-ẹni-nijaanu wo ni o yẹ fun akanṣe afiyesi?
7 Ọpọ ninu wa ti ṣaṣeyọri lọna ti o bá ọgbọ́n mu ninu ṣiṣakoso tabi kíká awọn iṣesi wa lọ́wọ́kò. A kìí jalè, juwọsilẹ fun iwapalapala, tabi paniyan; a mọ̀ ohun ti ofin Ọlọrun jẹ́ nipa iru awọn iwa-aitọ bẹẹ. Bi o ti wu ki o ri, bawo ni a ṣe kẹsẹjari tó, niti ṣiṣekawọ awọn ero-imọlara wa? Bi akoko ti ń lọ, awọn wọnni ti wọn kuna lati mú ikora-ẹni-nijaanu ti ero-imọlara dagba sábà maa ń padanu ikora-ẹni-nijaanu niti iṣesi wọn. Nitori naa ẹ jẹ ki a kó afiyesi jọ sori awọn ero-imọlara wa.
8. Ki ni Jehofa reti lọdọ wa nipa awọn ero-imọlara wa?
8 Jehofa Ọlọrun kò reti pe ki a jẹ́ ọmọlangidi, debi pe a kò ní ní ero-imọlara eyikeyii tabi fi í hàn. Nibi iboji Lasaru, Jesu “kerora ni ọkàn rẹ̀, inu rẹ̀ sì bajẹ.” Lẹhin naa “Jesu sọkun.” (Johannu 11:32-38) Ó fi ero-imọlara ti o yatọ patapata hàn nigba ti ó lé awọn onipaṣipaarọ owó jade kuro ninu tẹmpili, laisọ ikora-ẹni-nijaanu nù niti ọ̀nà ti o gbà huwa. (Matteu 21:12, 13; Johannu 2:14-17) Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ aduroṣinṣin pẹlu fi ero-imọlara jijinlẹ hàn. (Luku 10:17; 24:41; Johannu 16:20-22; Iṣe 11:23; 12:12-14; 20:36-38; 3 Johannu 4) Sibẹ, wọn moye aini naa fun ikora-ẹni-nijaanu daju ki ero-imọlara wọn má baa ṣamọna wọn sinu ẹ̀ṣẹ̀. Efesu 4:26 mú eyi ṣe kedere pe: “Ẹ binu; ẹ má sì ṣe ṣẹ̀: ẹ maṣe jẹ ki oorun wọ̀ bá ibinu yin.”
9. Eeṣe ti ṣiṣakoso ero-imọlara wa fi ṣe pataki tobẹẹ?
9 Ewu kan wà pe Kristian kan lè dabi ẹni ti ń fi ikora-ẹni-nijaanu hàn nigba ti o jẹ pe, awọn ero-imọlara rẹ̀ nitootọ kọja iṣakoso. Ranti idahunpada naa nigba ti Ọlọrun fọwọ si ẹbọ Abeli: “Kaini sì binu gidigidi, oju rẹ̀ sì rẹwẹsi. OLUWA sì bi Kaini pe, Eeṣe ti inu fi ń bí ọ? Èésìtiṣe ti oju rẹ fi rẹwẹsi? Bi iwọ bá ṣe rere, ara kì yoo ha yá ọ? Bi iwọ kò bá sì ṣe rere, ẹ̀ṣẹ̀ ba ni ẹnu ọ̀nà, lọdọ rẹ ni ifẹ rẹ̀ yoo maa fà si.” (Genesisi 4:5-7) Kaini kuna lati kó ero-imọlara rẹ̀ nijaanu, eyi ti o sún un lati pa Abeli. Awọn ero-imọlara ti a kò konijaanu ṣamọna si iṣarasihuwa kan ti a kò konijaanu.
10. Ki ni o kẹkọọ rẹ̀ lati inu apẹẹrẹ Hamani?
10 Tun gbe apẹẹrẹ kan yẹwo lati ọjọ Mordekai ati Esteri. Ijoye naa ti ń jẹ́ Hamani binu nitori pe Mordekai kìí tẹ orí ba fun oun. Nigba ti o yá Hamani fi aṣiṣe ronu pe oun ni a o ṣojurere si. “Hamani jade lọ ni ọjọ naa tayọtayọ, ati pẹlu inu didun: ṣugbọn nigba ti Hamani rí Mordekai ni ẹnu ọ̀nà ile ọba pe, kò dide duro, bẹẹ ni kò pa ara rẹ̀ dà fun oun, Hamani kún fun ibinu si Mordekai. Ṣugbọn Hamani kó ara rẹ̀ ni ijanu.” (Esteri 5:9, 10) Oun yára lati nimọlara ero-imọlara ayọ. Sibẹ oun tún yára lati nimọlara irunu ni wiwulẹ ri ẹni ti ó ni ìdikùnrùngbùn sí soju. Iwọ ha ronu pe nigba ti Bibeli sọ pe Hamani “kó ara rẹ̀ ni ijanu” o tumọsi pe oun jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ ninu ikora-ẹni-nijaanu ni bi? Bẹẹkọ rara. Fun akoko yii ná, Hamani kó awọn iṣesi ati ìfihàn ero-imọlara eyikeyii rẹ̀ nijaanu, ṣugbọn ó kuna lati kó irunu owú rẹ̀ nijaanu. Awọn ero-imọlara rẹ̀ ṣamọna rẹ̀ si hihumọ ipaniyan.
11. Ninu ijọ Filippi, iṣoro wo ni ó wà ki sì ni ó ti lè ṣamọna sí i?
11 Bakan naa, ailè kó awọn ero-imọlara nijaanu lonii lè wu awọn Kristian léwu gidigidi. ‘Óò,’ awọn kan lè nimọlara pe, ‘iyẹn kò lè jẹ́ iṣoro ninu ijọ.’ Ṣugbọn ó ti jẹ́ bẹẹ. Awọn Kristian ẹni-ami-ororo meji ni Filippi ní aáwọ̀ lile kan, eyi ti Bibeli kò ṣapejuwe. Ronu eyi gẹgẹ bi ohun kan ti o ṣeeṣe ki o ti ṣẹlẹ: Euodia késí awọn arakunrin ati arabinrin fun ounjẹ tabi ikorajọpọ gbigbadunmọni kan. Sintike ni a kò késí, ó sì dùn ún. Boya ó huwapada nipa ṣiṣai késí Euodia ni akoko iṣẹlẹ kan lẹhin ìgbà naa. Nigba naa ni awọn mejeeji bẹrẹ sii wá aṣiṣe ẹnikinni keji; bi akoko ti ń lọ, ekukaka ni wọn fi ń bá araawọn sọrọ. Ninu apejuwe iṣẹlẹ bi iyẹn, ipilẹ iṣoro naa yoo ha jẹ́ aikesini sibi ounjẹ kan bi? Bẹẹkọ. Iyẹn yoo wulẹ jẹ́ ohun ti ó tanná ràn án ni. Nigba ti awọn arabinrin ẹni-ami-ororo meji wọnyi kuna lati kó ero-imọlara wọn nijaanu, ẹ̀ta-iná naa di iná inu ẹgàn. Iṣoro naa ń baa lọ ó sì ń ga sii titi di ìgbà ti aposteli kan tó dá si i.—Filippi 4:2, 3.
Ero-Imọlara Rẹ ati Awọn Arakunrin Rẹ
12. Eeṣe ti Ọlọrun fi fun wa ni amọran ti a rí ninu Oniwasu 7:9?
12 A gbà pe, kò rọrùn lati kó ero-imọlara ẹni nijaanu nigba ti a bá nimọlara pe a gbójú fò wa dá, mú wa binu, tabi fi ẹtanu bá wa lò. Jehofa mọ iyẹn, nitori pe oun ti wo ibatan eniyan lati ibẹrẹ eniyan wá. Ọlọrun gbà wá nimọran pe: “Maṣe yára ni ọkàn rẹ lati binu, nitori pe ibinu sinmi ni àyà aṣiwere.” (Oniwasu 7:9) Ṣakiyesi pe Ọlọrun kọkọ fi afiyesi fun awọn ero-imọlara ati iṣesi. (Owe 14:17; 16:32; Jakọbu 1:19) Bi araarẹ leere, ‘Emi ha nilati fun ṣiṣakoso awọn ero-imọlara mi ni afiyesi pupọ sii bi?’
13, 14. (a) Ninu ayé, ki ni o sábà maa ń jẹyọ lati inu ikuna lati ṣakoso ero-imọlara? (b) Awọn nǹkan wo ni o lè sun awọn Kristian lati ní ìdikùnrùngbùn?
13 Ọpọ eniyan ninu ayé ti wọn kuna lati ṣakoso ero-imọlara wọn bẹrẹ awọn ìjà ọlọ́jọ́-pípẹ́—ti o korò, àní ti o jẹ́ ti oniwa-ipa paapaa, ìjà laaarin agbo ẹgbẹ́ tabi awujọ meji lori ẹ̀ṣẹ̀ gidi tabi eyi ti wọn ronuwoye rẹ̀ lodisi araawọn tabi ibatan kan. Gbàrà ti ero-imọlara bá ti kọja iṣakoso, wọn lè lo agbara-idari eléwu wọn fun akoko gigun. (Fiwe Genesisi 34:1-7, 25-27; 49:5-7; 2 Samueli 2:17-23; 3:23-30; Owe 26:24-26.) Dajudaju awọn Kristian, laika orilẹ-ede tabi ipo atilẹwa ti iṣẹdalẹ wọn sí, nilati rí iru ikoriira ati ìdikùnrùngbùn kikoro bẹẹ gẹgẹ bi ohun ti kò tọ́, ohun ti o buru, ti a nilati yẹra fun. (Lefitiku 19:17) Iwọ ha wo yiyẹra fun ìdikùnrùngbùn gẹgẹ bi apakan ikora-ẹni-nijaanu rẹ nipa awọn ero-imọlara bi?
14 Gẹgẹ bi o ti ri ninu ọ̀ràn ti Euodia ati Sintike, ikuna lati ṣakoso awọn ero-imọlara lè yọrisi awọn iṣoro nisinsinyi. Arabinrin kan lè nimọlara pe a gbójú fo oun dá nitori pe a kò késí oun sibi àsè igbeyawo kan. Tabi ó lè jẹ́ pé ọmọ rẹ tabi ibatan rẹ̀ kan ni a kò fi kun un. Tabi boya arakunrin kan ra ọkọ̀ àlòkù kan lọwọ Kristian ẹlẹgbẹ rẹ̀ kan, ti o sì wógbá laipẹ ọjọ. Ohun yoowu ki idi naa jẹ́, eyi fa awọn imọlara, ti ń dunni, awọn ero-imọlara ni a kò ṣakoso, awọn ti ọ̀ràn sì kàn ni inu wọn bajẹ. Nigba naa ki ni o lè ṣẹlẹ?
15. (a) Awọn abajade bibanininujẹ wo ni o ti jẹ jade lati inu ìdikùnrùngbùn laaarin awọn Kristian? (b) Imọran Bibeli wo ni o tan mọ́ itẹsi lati ní ìdikùnrùngbùn?
15 Bi ẹnikan ti inu rẹ̀ bajẹ kò bá ṣiṣẹ lori ṣiṣakoso awọn ero-imọlara rẹ̀ ki o sì wá alaafia pẹlu arakunrin rẹ̀, ìdikùnrùngbùn lè dide. Awọn ọ̀ràn ti wà nigba ti Ẹlẹ́rìí kan sọ pe ki a má yan oun si Ikẹkọọ Iwe Ijọ kan bayii nitori pe oun “kò gba” ti awọn Kristian tabi idile kan ti wọn ń lọ sibẹ. Ó ti banininujẹ tó! Bibeli sọ pe yoo jẹ́ ìpaláyò fun awọn Kristian lati gbé araawọn ẹnikinni keji lọ si ilé-ẹjọ́ ayé, ṣugbọn kò ha ni jẹ́ ìpaláyò bakan naa bi a bá yẹra fun arakunrin kan nitori aṣiṣe rẹ̀ si wa tabi si awọn ibatan kan ni ìgbà ti o ti kọja? Awọn ero-imọlara wa ha fihàn pe a gbé ipo-ibatan ti ara lékè alaafia pẹlu awọn arakunrin ati arabinrin wa bi? Awa ha sọ pe awa yoo muratan lati kú fun arabinrin wa, ṣugbọn ti ero-imọlara sún wa debi pe ekukaka ni a fi ń baa sọrọ nisinsinyi bi? (Fiwe Johannu 15:13.) Ọlọrun sọ fun wa ni ṣàkó pe: “Ẹ maṣe fi buburu san buburu fun ẹnikẹni. . . . Bi o lè ṣe, bi o ti wà ni ipa ti yin, ẹ maa wà ni alaafia pẹlu gbogbo eniyan. Olufẹ, ẹ maṣe gbẹsan ara yin, ṣugbọn ẹ fi ààyè silẹ fun ibinu.”—Romu 12:17-19; 1 Korinti 6:7.
16. Apẹẹrẹ rere wo ni Abrahamu fi lélẹ̀ niti bibojuto ero-imọlara?
16 Igbesẹ kan siha jijere akoso ero-imọlara wa ni lati wá alaafia tabi ki a yanju okunfa fun àròyé, dipo jijẹ ki kèéta maa baa lọ. Ranti ìgbà ti ilẹ kò gba agbo-ẹran pupọ rẹpẹtẹ ti Abrahamu papọ pẹlu iwọnyi ti o jẹ ti Loti, ti awọn oṣiṣẹ ti wọn gbà síṣẹ́ sì bẹrẹ sii jà nitori rẹ̀. Ǹjẹ́ Abrahamu ha jẹ́ ki ero-imọlara rẹ̀ bori rẹ̀ bi? Tabi o ha fi ikora-ẹni-nijaanu hàn bi? Lọna ti o yẹ fun igboriyin, ó damọran ojutuu alalaafia kan si iforigbari iṣẹ́-ajé naa; jẹ ki ẹnikọọkan ní ipinlẹ ọtọọtọ. Ó sì gbà ki Loti ṣe yiyan akọkọ. Ni fifihan pe Abrahamu kò ní ikannu kankan ati pe oun kò ni ìdikùnrùngbùn kankan, oun lẹhin naa lọ jà nititori Loti.—Genesisi 13:5-12; 14:13-16.
17. Bawo ni Paulu ati Barnaba ṣe kùnà ni akoko kan, ṣugbọn ki ni o tẹle e lẹhin ìgbà naa?
17 Awa pẹlu lè kẹkọọ nipa ikora-ẹni-nijaanu lati inu iṣẹlẹ kan ti o ní Paulu ati Barnaba ninu. Lẹhin ti wọn ti jọ jẹ́ alájọrìn fun ọpọ ọdun, wọn kò fohunṣọkan lori yala lati mú Marku lọ si irin-ajo kan. “Ìjà naa sì pọ̀ tobẹẹ, ti wọn ya araawọn meji: nigba ti Barnaba sì mú Marku, ó bá ti ọkọ̀ lọ si Kipru.” (Iṣe 15:39) Pe awọn ogboṣaṣa ọkunrin wọnyi kùnà lati ṣakoso ero-imọlara wọn ni akoko iṣẹlẹ yẹn nilati pese ikilọ fun wa. Bi ó bá lè ṣẹlẹ si wọn, ó lè ṣẹlẹ si awa naa. Bi o ti wu ki o ri, wọn kò fààyè gba èdè-àìyédè wiwapẹtiti lati gbèrú tabi ìjà ọlọ́jọ́ pípẹ́ lati dide. Akọsilẹ naa jẹrii sii pe awọn arakunrin ti ọ̀ràn kàn naa jèrè akoso ero-imọlara wọn pada ti wọn sì ṣiṣẹ papọ ni alaafia lẹhinwa ìgbà naa.—Kolosse 4:10; 2 Timoteu 4:11.
18. Bi a bá kó ẹ̀dùn bá ero-imọlara, ki ni Kristian kan ti o dagbadenu lè ṣe?
18 A lè reti pe awọn imọlara ti a kó ẹ̀dùn bá lè wà, àní ìdikùnrùngbùn paapaa, laaarin awọn eniyan Ọlọrun. Wọn wà ni akoko awọn Heberu ati ni ọjọ awọn aposteli. Wọn ti ṣẹlẹ pẹlu laaarin awọn iranṣẹ Jehofa ni akoko wa, nitori gbogbo wa jẹ́ alaipe. (Jakọbu 3:2) Jesu rọ awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lati tètè gbegbeesẹ lati yanju iru awọn iṣoro bẹẹ laaarin arakunrin bẹẹ. (Matteu 5:23-25) Ṣugbọn o tilẹ tun sàn jù lati dí wọn lọwọ lakọọkọ nipa mimu ikora-ẹni-nijaanu wa sunwọn sii. Bi o bá nimọlara pe a gbójú fò ọ́ dá tabi ṣe laifi si ọ nipa ohun kekere kan ni ifiwera ti arakunrin tabi arabinrin rẹ sọ tabi ṣe, eeṣe ti o kò fi ṣakoso ero-imọlara rẹ ki o sì wulẹ gbagbe rẹ̀? O ha pọndandan nitootọ lati gbejako ẹnikeji, bi ẹni pe kò ni tẹ́ ọ lọ́rùn àfìgbà ti ẹni yẹn bá gbà pe oun ṣaitọ? Bawo gan-an ni o ti lè ṣakoso ero-imọlara rẹ tó?
Ó Ṣeeṣe!
19. Eeṣe ti o fi jẹ́ ohun yiyẹ pe ijiroro wa kó afiyesi jọ sori ṣiṣekawọ ero-imọlara wa?
19 A ti bojuto apa iha kan ni pataki nipa ikora-ẹni-nijaanu, ṣiṣakoso ero-imọlara wa. Iyẹn sì jẹ agbegbe pataki kan nitori pe ikuna lati ṣakoso ero-imọlara wa lè ṣamọna si pipadanu akoso ahọ́n wa, isunniṣe ibalopọ takọtabo wa, aṣa ijẹun wa, ati ọpọlọpọ apa-iha miiran ninu igbesi-aye ti a ti gbọdọ fi ikora-ẹni-nijaanu hàn. (1 Korinti 7:8, 9; Jakọbu 3:5-10) Tujuka, bi o ti wu ki o ri, nitori pe o lè sunwọn sii ninu pipa ikora-ẹni-nijaanu mọ.
20. Bawo ni o ṣe lè dá wa loju pe imusunwọn sii ṣeeṣe?
20 Jehofa muratan lati ràn wá lọwọ. Bawo ni a ṣe lè ní idaniloju eyi? Ó dara, ikora-ẹni-nijaanu jẹ́ ọ̀kan lara awọn eso ẹmi rẹ̀. (Galatia 5:22, 23) Nipa bayii, dé ìwọ̀n ti a bá fi ṣiṣẹ lati tootun fun ẹmi mimọ ati lati gbà á lati ọ̀dọ̀ Jehofa ati lati fi iṣupọ-eso rẹ̀ hàn, dé ìwọ̀n yẹn ni a lè reti lati tubọ jẹ́ akora-ẹni-nijaanu. Maṣe gbagbe imudaniloju Jesu: “Baba yin ti ń bẹ ni ọ̀run yoo fi ẹmi mimọ rẹ̀ fun awọn ti o ń beere lọdọ rẹ̀.”—Luku 11:13; 1 Johannu 5:14, 15.
21. Ki ni o pinnu lati ṣe ni ọjọ-iwaju nipa ikora-ẹni-nijaanu ati ero-imọlara rẹ?
21 Maṣe ronu pe yoo rọrùn. Ó sì lè tubọ ṣoro sii fun awọn kan ti a tọ́ dagba láyìíká awọn eniyan ti wọn kìí ṣakoso ero-imọlara wọn, fun awọn kan ti wọn ni inúfùfù, tabi fun awọn kan ti wọn kò wulẹ tii gbiyanju lati fi ikora-ẹni-nijaanu hàn. Fun iru Kristian kan bẹẹ, jijẹ ki ikora-ẹni-nijaanu wà ki o sì kún àkúnwọ́sílẹ̀ lè jẹ́ ipenija nitootọ. Sibẹ ó ṣeeṣe. (1 Korinti 9:24-27) Bi a ti ń sunmọ opin eto-igbekalẹ awọn nǹkan isinsinyi siwaju ati siwaju sii, masunmawo ati ikimọlẹ yoo maa ga sii. Ikora-ẹni-nijaanu ti a nilo kì yoo kere sii ṣugbọn yoo jẹ́ eyi ti o pọ̀, lọpọlọpọ sii! Ṣayẹwo araarẹ niti ikora-ẹni-nijaanu rẹ. Bi o bá rí agbegbe kan ninu eyi ti o ti nilati sunwọn sii, ṣiṣẹ lori rẹ̀. (Orin Dafidi 139:23, 24) Beere lọwọ Ọlọrun fun pupọ sii ninu ẹmi rẹ̀. Oun yoo gbọ́ ọ oun yoo sì ràn ọ́ lọwọ ki ikora-ẹni-nijaanu rẹ baa lè wà ki o sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.—2 Peteru 1:5-8.
Awọn Koko fun Ironujinlẹ
◻ Eeṣe ti iṣakoso ero-imọlara rẹ fi ṣe pataki tobẹẹ?
◻ Ki ni o ti kẹkọọ rẹ̀ lati inu apẹẹrẹ Hamani ati ti Euodia ati Sintike?
◻ Ki ni iwọ yoo fi ailabosi gbiyanju lati ṣe bi okunfa fun láìfí bá wáyé?
◻ Bawo ni ikora-ẹni-nijaanu ṣe lè ràn ọ́ lọwọ lati yẹra fun níní ìdikùnrùngbùn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Nigba ti ó wà niwaju Feliksi ati Drusilla, Paulu sọrọ nipa òdodo ati ikora-ẹni-nijaanu