ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 11/15 ojú ìwé 13-18
  • Mímú Eso Ikora-ẹni-Nijaanu Dàgbà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mímú Eso Ikora-ẹni-Nijaanu Dàgbà
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bibẹru Ọlọrun ati Kikoriira Ohun Ti Ó Jẹ́ Ibi
  • Ikora-ẹni-nijaanu, Ipa-ọna Ọgbọn
  • Ifẹ Aimọtara-ẹni-nikan Nṣeranlọwọ
  • Igbagbọ ati Ẹmi-irẹlẹ Gẹgẹ bi Olurannilọwọ
  • Ikora-ẹni-nijaanu Laaarin Agbo Idile
  • Lilo Iranlọwọ Ti Ọlọrun Npese
  • Ikora-ẹni-nijaanu—Eeṣe Ti Ó Fi Ṣe Pataki Tobẹẹ?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Kó Ara Rẹ Níjàánu Kí o Lè Gba Èrè Náà!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ẹ Fi Ìkóra-ẹni-níjàánu Kún Ìmọ̀ Yín
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Máa Kó Ara Rẹ Níjàánu
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 11/15 ojú ìwé 13-18

Mímú Eso Ikora-ẹni-Nijaanu Dàgbà

“Eso ti ẹmi ni ifẹ, ayọ, alaafia, ipamọra, inurere, iwarere iṣeun, igbagbọ, iwapẹlẹ, ikora-ẹni-nijaanu. Kò si ofin kankan lodi si iru nǹkan wọnyi.”—GALATIA 5:22, 23, NW.

1. Ta ni ó ti fun wa ni awọn apẹẹrẹ didara julọ ti ikora-ẹni-nijaanu, gẹgẹ bi a ti ri i nipasẹ awọn iwe mimọ wo?

JEHOFA ỌLỌRUN ati Jesu Kristi ti fun wa ni awọn apẹẹrẹ didara julọ ti ikora-ẹni-nijaanu. Lati ìgbà aigbọran eniyan ninu ọgba Edeni, Jehofa ti nbaa lọ ni lilo animọ yii. (Fiwe Aisaya 42:14.) Ni ìgbà mẹsan-an ninu Iwe mimọ lede Heberu ni a kà pe oun jẹ́ “onipamọra.” (Ẹkisodu 34:6) Iyẹn gba ikora-ẹni-nijaanu. Ó sì daju pe Ọmọkunrin Ọlọrun lo ikora-ẹni-nijaanu nla, nitori “nigba ti a nkẹgan rẹ̀, oun ko lọ maa kẹgan ni idapada.” (1 Peteru 2:23, NW) Sibẹ, Jesu ti le beere lọwọ Baba rẹ̀ ọrun fun itilẹhin “awọn angẹli ti wọn pọ ju legioni mejila lọ.”—Matiu 26:53.

2. Awọn apẹẹrẹ Iwe mimọ rere wo ni a ni niti lilo ti awọn eniyan alaipe lo ikora-ẹni-nijaanu?

2 A tun ni awọn apẹẹrẹ rere diẹ ninu Iwe mimọ nipa ikora-ẹni-nijaanu ti awọn eniyan alaipe lò. Fun apẹẹrẹ, animọ yii ni a fihan lakooko iṣẹlẹ pataki kan ninu igbesi-aye Josẹfu, ọmọkunrin babanla naa Jakọbu. Ẹ wo ikora-ẹni-nijaanu ti Josẹfu lò nigba ti aya Pọtifa gbiyanju lati yi i lero pada ṣagbere! (Jẹnẹsisi 39:7-9) Apẹẹrẹ rere ti awọn ọdọ Heberu mẹrin ti wọn lo ikora-ẹni-nijaanu nipa kíkọ̀ lati jẹ awọn mindinmínìndìn ọba Babiloni nitori ikaleewọ Ofin Mose tun wa pẹlu.—Daniẹli 1:8-17.

3. Awọn wo ni a ṣakiyesi fun ihuwa rere wọn, gẹgẹ bi a ti ri i nipasẹ ẹ̀rí wo?

3 Fun apẹẹrẹ ode oni nipa ikora-ẹni-nijaanu, a lè tọka si awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lodindi. Wọn lẹtọọ si oriyin ti New Catholic Encyclopedia fifun wọn—pe wọn jẹ́ “ọ̀kan lara awọn awujọ ti ó mọ̀wàáhù julọ ninu ayé.” Olukọni ile-ẹkọ yunifasiti ti Philippine kan wi pe “awọn Ẹlẹ́rìí nfi tiṣọratiṣọra ati tọkantọkan ṣe ohun ti wọn kẹkọọ rẹ̀ lati inu Iwe mimọ.” Niti apejọpọ awọn Ẹlẹ́rìí ni Warsaw ni 1989, onirohin ara Poland kan kọwe pe: “Awọn 55,000 eniyan kò mu ẹyọ siga kanṣoṣo fun ọjọ mẹta! . . . Ifihan ibara-ẹni-wi ti o ju ti awọn eniyan miiran lọ yii wú mi lori pẹlu ifanimọra ti ó papọ pẹlu ọ̀wọ̀.”

Bibẹru Ọlọrun ati Kikoriira Ohun Ti Ó Jẹ́ Ibi

4. Ki ni ọ̀kan lara awọn aranṣe titobi julọ ninu lilo ikora-ẹni-nijaanu?

4 Ọ̀kan lara awọn aranṣe titobi julọ ninu mimu ikora-ẹni-nijaanu dagba ni ibẹru Ọlọrun, ifoya pipeye lati maṣe ṣe ohun ti ko wu Baba wa ọrun onifẹẹ. Bi ibẹru ọlọwọ fun Ọlọrun ṣe nilati jẹ pataki fun wa tó ni a lè rí nipa otitọ naa pe Iwe mimọ mẹnukan an ni ọpọlọpọ ìgbà. Nigba ti Aburahamu ṣetan lati fi ọmọkunrin rẹ̀ Isaaki rubọ, Ọlọrun wi pe: “Maṣe fọwọkan ọmọde nì, bẹẹ ni iwọ kò gbọdọ ṣe e ni nǹkan: nitori nisinsinyi emi mọ pe iwọ bẹru Ọlọrun, nigba ti iwọ kò ti dù mi ni ọmọ rẹ, ọmọ rẹ naa kanṣoṣo.” (Jẹnẹsisi 22:12) Pakanleke niti ero imọlara pupọ wà laiṣiyemeji, nitori naa ó ti gbọdọ gba ọpọ ikora-ẹni-nijaanu giga ni apa ọdọ Aburahamu lati tẹsiwaju pẹlu aṣẹ Ọlọrun dé ori koko gbigbe ọbẹ rẹ̀ soke lati gbẹ̀mí Isaaki ọmọkunrin rẹ̀ aayo-olufẹ. Bẹẹni, ibẹru Ọlọrun yoo ràn wá lọ́wọ́ lati lo ikora-ẹni-nijaanu.

5. Ipa wo ni kikoriira ibi kó ninu ilo ikora-ẹni-nijaanu wa?

5 Eyi ti ó tan pẹkipẹki mọ ibẹru Jehofa ni ikoriira ibi. A kà ni Owe 8:13 pe: “Ibẹru Oluwa [“Jehofa,” NW] ni ikoriira ibi.” Ẹ̀wẹ̀, ikoriira ohun ti ó jẹ́ ibi tun ńràn wá lọ́wọ́ lati lo ikora-ẹni-nijaanu. Leralera, Iwe mimọ sọ fun wa lati koriira—bẹẹni, fi tẹgantẹgan koriira—ohun ti ó jẹ́ ibi. (Saamu 97:10; Amosi 5:14, 15; Roomu 12:9) Ohun ti ó jẹ́ buburu saba maa ngbadunmọni gan-an, dẹniwo gan-an, fanimọra gan-an debi pe a wulẹ gbọdọ koriira rẹ̀ ni ki a baa lè daabobo ara wa lodisi i. Gbogbo iru kikoriira ohun ti ó jẹ́ ibi bẹẹ ni iyọrisi ti fifun ipinnu wa lati lo ikora-ẹni-nijaanu lokun ó sì ntipa bayii ṣiṣẹ gẹgẹ bi aabo fun wa.

Ikora-ẹni-nijaanu, Ipa-ọna Ọgbọn

6. Eeṣe ti o fi jẹ́ ipa-ọna ọgbọn lati kamba awọn itẹsi ọkan onimọtara-ẹni-nikan wa nipa lilo ikora-ẹni-nijaanu?

6 Aranṣe titobi miiran ninu pe ki a sọ ikora-ẹni-nijaanu daṣa ni lati mọrírì ọgbọn fifi animọ yii han. Jehofa beere lọwọ wa lati lo ikora-ẹni-nijaanu fun anfaani araawa. (Fiwe Aisaya 48:17, 18.) Ọrọ rẹ̀ ní imọran pupọ ninu ti nfihan bi ó ti bọgbọnmu tó lati kó awọn ifẹ ọkan onimọtara-ẹni-nikan wa nijaanu nipa sisọ ikora-ẹni-nijaanu daṣa. Awa kò wulẹ le moribọ lọwọ awọn ofin Ọlọrun ti kò ṣee yipada. Ọrọ rẹ̀ sọ fun wa pe: “Ohunkohun ti eniyan ba funrugbin, oun ni yoo sì ka. Nitori ẹni ti ó ba nfunrugbin sipa ti ara rẹ̀, nipa ti ara ni yoo ká idibajẹ; ṣugbọn ẹni ti ó ba nfunrugbin sipa ti ẹmi, nipa ti ẹmi ni yoo ká ìyè ainipẹkun.” (Galatia 6:7, 8) Apẹẹrẹ kan ti ó han gbangba ni ti jíjẹ ati mímu. Ọpọlọpọ ipalara ni ó njẹyọ nititori pe awọn eniyan jẹ ajẹju tabi mu amuju. Gbogbo iru ijuwọsilẹ fun imọtara-ẹni-nikan bẹẹ ńja ẹnikan lole ọ̀wọ̀ ara ẹni. Ju iyẹn lọ, ẹnikẹni kò le juwọsilẹ fun imọtara-ẹni-nikan laiba ipo ibatan rẹ̀ pẹlu awọn ẹlomiran jẹ́. Eyi ti ó buru julọ ninu gbogbo rẹ̀ ni pe, aini ikora-ẹni-nijaanu nba ipo ibatan wa pẹlu Baba wa ọrun jẹ́.

7. Ki ni ẹṣin-ọrọ pataki kan ninu iwe Owe, gẹgẹ bi a ti fihan nipa awọn ẹsẹ Bibeli wo?

7 Nitori naa, a gbọdọ maa baa lọ ni sisọ fun araawa pe imọtara-ẹni-nikan jẹ́ ipara ẹni láyò. Ẹṣin ọrọ titayọ kan ti iwe Owe, eyi ti ó tẹnumọ ibara-ẹni-wi, ni pe imọtara-ẹni-nikan kò wulẹ lérè ati pe ọgbọn wà ninu lilo ikora-ẹni-nijaanu. (Owe 14:29; 16:32) Ẹ sì jẹ ki a fi i sọkan pe ibara-ẹni-wi wémọ́ ohun pupọ ju wiwulẹ yẹra fun ohun ti ó jẹ ibi. Ibara-ẹni-wi, tabi ikora-ẹni-nijaanu, ni a tun nilo lati ṣe ohun ti ó tọ́, eyi ti ó lè nira nitori pe eyi lodisi awọn itẹsi ifẹ ọkan wa ti o kun fun ẹṣẹ.

8. Iriri wo ni ó tẹnumọ ọgbọn lilo ikora-ẹni-nijaanu?

8 Ọran ọkan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ó wà lori ìlà ni ile ifowopamọ kan nigba ti ọkunrin kan gba iwaju rẹ̀ ṣapejuwe ọgbọn ti ó wà ninu lilo ikora-ẹni-nijaanu. Bi o tilẹ jẹ pe Ẹlẹ́rìí naa binu diẹ, o lo ikora-ẹni-nijaanu. Ni ọjọ yẹn gan-an oun nilati ri onimọ iṣẹ ẹrọ kan lati fọwọsi awọn aworan ilẹ Gbọngan Ijọba melookan. Ta si ni onimọ iṣẹ-ẹrọ yii jasi? Ọkunrin naa gan-an ti ó ti sare gba iwaju rẹ̀ ni ile ifowopamọ! Kii ṣe kiki pe onimọ iṣẹ-ẹrọ naa jẹ́ ẹni bi ọrẹ gan-an nikan ni ṣugbọn ó dáye ti ó kere si idamẹwaa iye owo ti wọn ngba deedee lé Ẹlẹ́rìí naa. Bawo ni Ẹlẹ́rìí naa ti layọ tó pe oun ti lo ikora-ẹni-nijaanu ṣaaju ni ọjọ yẹn, ni ṣiṣai jẹ ki a mu un binu!

9. Ki ni ipa-ọna ọgbọn nigba ti a ba ṣalabaapade awọn iṣarasihuwa eléèébú ninu iṣẹ-ojiṣẹ?

9 Leralera nigba ti a ba lọ lati ẹnu ọna de ẹnu ọna ni wiwaasu ihinrere Ijọba Ọlọrun tabi duro ni igun opopona ni gbigbiyanju lati mu ki awọn ti nkọja nifẹẹ ninu ihin-iṣẹ wa, a nṣalabaapade ọrọ eebu. Ki ni ipa-ọna ọgbọn? Ọrọ ọlọgbọn yii ni a sọ ni Owe 15:1 pe: “Idahun pẹlẹ yí ibinu pada.” Ni ede miiran, a nilati lo ikora-ẹni-nijaanu. Kii sì ṣe kiki pe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ri i pe eyi jẹ́ otitọ nikan ni ṣugbọn awọn miiran ti ri i bẹẹ pẹlu. Iniyelori iwonisan ti ikora-ẹni-nijaanu ni iṣẹ akọmọọṣe iṣegun ti mọriri pupọpupọ sii.

Ifẹ Aimọtara-ẹni-nikan Nṣeranlọwọ

10, 11. Eeṣe ti ifẹ fi jẹ́ iranlọwọ gidi ninu lilo ikora-ẹni-nijaanu?

10 Apejuwe ifẹ ti Pọọlu ṣe ni 1 Kọrinti 13:4-8 fihan pe agbara rẹ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ lati lo ikora-ẹni-nijaanu. “Ifẹ a maa ni ipamọra.” Lati jẹ́ onipamọra gba ikora-ẹni-nijaanu. “Ifẹ kii jowu, kii fọnnu, kii wú fùkẹ̀.” Animọ ifẹ ńràn wá lọ́wọ́ lati ṣakoso awọn ironu ati imọlara wa, lati kó itẹsi eyikeyii lati jẹ́ ojowu, lati fọnnu, tabi lati wú fùkẹ̀ nijaanu. Ifẹ nsun wa lati jẹ́ odikeji gan-an, ni mimu wa jẹ́ onirẹlẹ, elero inu rirẹlẹ, gẹgẹ bi Jesu ti jẹ́.—Matiu 11:28-30.

11 Pọọlu nbaa lọ lati wi pe ifẹ “kii huwa lọna aibojumu.” Ó tun gba ikora-ẹni-nijaanu lati huwa lọna ti ó bojumu ni gbogbo ìgbà. Animọ ifẹ npa wa mọ kuro lọwọ iwọra, kuro lọwọ ‘wiwa ire tiwa funraawa’ nikan. ‘A kii tán ifẹ ni suuru.’ Bawo ni ó ti rọrun tó lati di ẹni ti a tán ni suuru nitori ohun ti awọn ẹlomiran sọ tabi ṣe! Ṣugbọn ifẹ yoo ràn wá lọ́wọ́ lati lo ikora-ẹni-nijaanu ki a ma sì sọ tabi ṣe awọn ohun ti a o kabaamọ nigbẹhin. Ifẹ “kii kọ akọsilẹ nipa iṣeleṣe.” Iwa ẹda eniyan ní itẹsi lati di kùnrùngbùn sinu tabi ni ikunsinu. Ṣugbọn ifẹ yoo ràn wá lọ́wọ́ lati tú iru awọn ironu bẹẹ ká kuro ninu ero inu wa. Ifẹ “kii yọ̀ lori aiṣododo.” Ó gba ikora-ẹni-nijaanu lati maṣe ni idunnu ninu ohun ti ó jẹ́ aiṣododo, iru bii aworan ti nru ifẹ iṣekuṣe soke tabi ọ̀wọ́ ere awokẹkọọ ọran idile ori tẹlifiṣọn ti nrẹnisilẹ. Ifẹ tun “nmu ohun gbogbo mọra” o sì “nfarada ohun gbogbo.” Ó gba ikora-ẹni-nijaanu lati gba awọn nǹkan mọra, lati farada awọn ohun adanniwo tabi ti ó nira laisi jẹ́ ki wọn kó irẹwẹsi bá wa, mu wa fi oró ya oró, tabi sun wa lati pa ṣiṣiṣẹsin Jehofa tì.

12. Ki ni ọna kan lati gba fi imọriri wa han fun gbogbo ohun ti Jehofa Ọlọrun ati Jesu Kristi ti ṣe fun wa?

12 Bi awa bá nifẹẹ Baba wa ọrun nitootọ ti a sì mọriri awọn animọ agbayanu rẹ̀ ati gbogbo ohun ti ó ti ṣe fun wa, awa yoo fẹ́ lati wù ú nipa lilo ikora-ẹni-nijaanu ni gbogbo ìgbà. Pẹlupẹlu, bi awa ba nifẹẹ Oluwa ati Ọga wa, Jesu Kristi, ti a sì mọriri gbogbo ohun ti ó ti ṣe fun wa, awa yoo kọbiara si aṣẹ rẹ̀ ‘lati gbe igi idaloro wa ki a sì maa tẹle e lẹhin nigba gbogbo.’ (Maaku 8:34) Iyẹn ni dajudaju beere pe ki a lo ikora-ẹni-nijaanu. Ifẹ fun awọn Kristẹni arakunrin ati arabinrin wa yoo tun pa wa mọ kuro ninu pipa wọn lara nipa titẹle awọn ipa ọna onimọtara-ẹni-nikan.

Igbagbọ ati Ẹmi-irẹlẹ Gẹgẹ bi Olurannilọwọ

13. Eeṣe ti igbagbọ fi lè ràn wá lọ́wọ́ lati lo ikora-ẹni-nijaanu?

13 Iranlọwọ titobi miiran ninu lilo ikora-ẹni-nijaanu ni igbagbọ ninu Ọlọrun ati ileri rẹ̀. Igbagbọ yoo fun wa lagbara iṣe lati nigbẹkẹle ninu Jehofa ki a sì duro di igba ti akoko tirẹ ba tó lati mu awọn ọran tọ́. Apọsiteli Pọọlu sọ koko kan naa nigba ti ó sọ ni Roomu 12:19 pe: “Olufẹ, ẹ maṣe gbẹsan ara yin, . . . nitori a ti kọ ọ pe, Oluwa [“Jehofa,” NW] wi pe, Temi ni ẹsan, emi yoo gbẹsan.” Ni ọna yii, ẹmi-irẹlẹ tun lè ràn wá lọ́wọ́. Bi awa bá jẹ́ onirẹlẹ, awa ki yoo yára nimọlara pe a ti ṣẹ wa nitori èṣe ti a tànmọ́-ọ̀n tabi ti ó jẹ́ gidi. Awa ki yoo ṣaika ofin sí lọna aironu ki a sì huwa lọna ominira lati mu ọran tọ́, ki a wi bẹẹ, ṣugbọn awa yoo lo ikora-ẹni-nijaanu a o sì ṣetan lati duro de Jehofa.—Fiwe Saamu 37:1, 8.

14. Iriri wo ni ó fihan pe awọn wọnni ti wọn ṣalaini ikora-ẹni-nijaanu lọna titobi paapaa lè ni i?

14 Pe a lè kẹkọọ lati lo ikora-ẹni-nijaanu ni a mu ṣe kedere ninu iriri ti ó wémọ́ ọkunrin kan ti o ni iṣarasihuwa oniwa ipa. Họwu, ó ni iru iṣarasihuwa kan bẹẹ debi pe nigba ti a pe awọn ọlọpaa nitori rukerudo tí oun ati baba rẹ̀ ńfà, ó lu awọn ọlọpaa mẹta bolẹ ṣaaju ki awọn ti ó kù tó bori rẹ̀! Bi o ti wu ki o ri, bi akoko ti nlọ, ó pade awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ó sì kẹkọọ lati lo ikora-ẹni-nijaanu, ọ̀kan lara eso ẹmi Ọlọrun. (Galatia 5:22, 23) Lonii, 30 ọdun lẹhin naa, ọkunrin yii ṣì jẹ́ oluṣotitọ sibẹ ni ṣiṣiṣẹsin Jehofa.

Ikora-ẹni-nijaanu Laaarin Agbo Idile

15, 16. (a) Ki ni yoo ran ọkọ kan lọwọ lati lo ikora-ẹni-nijaanu? (b) Ikora-ẹni-nijaanu ni pataki ni a nilo ninu ipo wo, gẹgẹ bi a ti ri i lati inu iriri wo? (c) Eeṣe ti aya kan fi nilo ikora-ẹni-nijaanu?

15 Ikora-ẹni-nijaanu ni a nilo dajudaju laaarin agbo idile. Fun ọkọ kan lati nifẹẹ aya rẹ̀ gẹgẹ bi oun tikaraarẹ beere pe ki ó ko awọn ironu, ọrọ, ati igbesẹ rẹ̀ nijaanu lọpọlọpọ. (Efesu 5:28, 29) Bẹẹni, ó gba ikora-ẹni-nijaanu fun awọn ọkọ lati kọbiara si awọn ọrọ apọsiteli Peteru ni 1 Peteru 3:7 pe: “Ẹyin ọkọ, ẹ maa fi òye bá awọn aya yin gbé.” Ni pataki nigba ti aya rẹ̀ kìí bá ṣe onigbagbọ ni ọkọ ti ó gbagbọ nilati lo ikora-ẹni-nijaanu.

16 Lati ṣapejuwe: Alagba kan wà ti ó ni aya alaigbagbọ kan ti ó jẹ́ oníjà gidigidi. Sibẹ, ó lo ikora-ẹni-nijaanu, eyi sì ṣanfaani fun un pupọpupọ gan-an debi pe dokita rẹ̀ sọ fun un pe: “John, yala iwọ lọna adanida jẹ́ onisuuru eniyan gan-an tabi bikoṣe bẹẹ iwọ ni isin alagbara kan.” Nitootọ a ni isin alagbara kan, nitori “Ọlọrun kò fun wa ni ẹmi ibẹru; bikoṣe ti agbara, ati ti ifẹ, ati ti inu ti ó yè kooro,” ti nfun wa lagbara iṣe lati lo ikora-ẹni-nijaanu. (2 Timoti 1:7) Ni afikun, ó gba ikora-ẹni-nijaanu ni apa ọdọ aya kan lati jẹ́ onitẹriba, ni pataki nigba ti ọkọ rẹ̀ kii ba ṣe onigbagbọ.—1 Peteru 3:1-4.

17. Eeṣe ti ikora-ẹni-nijaanu fi ṣe pataki ninu ipo ibatan obi si ọmọ?

17 Ikora-ẹni-nijaanu ni a tun nilo ninu ipo ibatan obi si ọmọ. Lati ni awọn ọmọ ti wọn ni ikora-ẹni-nijaanu, awọn obi funraawọn gbọdọ kọkọ gbé apẹẹrẹ rere kalẹ. Nigba ti awọn ọmọ bá sì yẹ fun ibawi iru kan tabi omiran, a gbọdọ ṣe e ni pẹlẹtu ati ni ifẹ, eyi ti ó gba ikora-ẹni-nijaanu gidi. (Efesu 6:4; Kolose 3:21) Lẹhin naa lẹẹkan sii, fun awọn ọmọ lati fihan pe wọn nifẹẹ awọn obi wọn niti gidi beere fun igbọran, lati ṣegbọran dajudaju sì beere fun ikora-ẹni-nijaanu.—Efesu 6:1-3; fiwe 1 Johanu 5:3.

Lilo Iranlọwọ Ti Ọlọrun Npese

18-20. Awọn ipese ti ẹmi mẹta wo ni a gbọdọ lo anfaani rẹ̀ ki a baa le mu awọn animọ ti yoo ràn wá lọ́wọ́ lati lo ikora-ẹni-nijaanu dagba?

18 Lati dagba ninu ibẹru Ọlọrun, ninu ifẹ ainimọtara-ẹni-nikan, ninu igbagbọ, ninu ikoriira awọn ohun ti ó jẹ́ ibi, ati ninu ikora-ẹni-nijaanu, a nilati lo anfaani gbogbo iranlọwọ tí Jehofa Ọlọrun ti pese. Ẹ jẹ ki a gbe awọn ipese mẹta tẹmi yẹwo ti ó lè ràn wá lọ́wọ́ lati lo ikora-ẹni-nijaanu. Akọkọ ninu gbogbo rẹ̀, anfaani ṣiṣeyebiye ti adura wà. Awa kò fẹ lati jẹ ki ọwọ wa dí jù lae lati gbadura. Bẹẹni, a gbọdọ fẹ́ lati “gbadura ni aisinmi,” lati “ni iforiti ninu adura.” (1 Tẹsalonika 5:17; Roomu 12:12, NW) Ẹ jẹ ki a sọ mimu ikora-ẹni-nijaanu dagba di ọran adura. Ṣugbọn nigba ti a kò bá dójú iwọn ninu lilo ikora-ẹni-nijaanu, ẹ jẹ ki a fi irobinujẹ rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Baba wa ọrun fun idariji.

19 Agbegbe keji ninu fifi ikora-ẹni-nijaanu han ni gbigba iranlọwọ ti nwa lati inu jijẹun lati inu Ọrọ Ọlọrun ati iwe ikẹkọọ ti o nmu ki o ṣeeṣe fun wa lati loye ki a sì fi Iwe mimọ silo. Ó rọrun gidi gan-an lati ṣainaani apa iṣẹ-isin mimọ wa yii! A gbọdọ lo ikora-ẹni-nijaanu ki a sì maa baa lọ ni sisọ fun araawa pe ko sí iwe kíkà kankan ti ó ṣe pataki ju Bibeli ati awọn ohun ti “ẹru oluṣotitọ ati ọlọgbọn inu” pese, a sì tipa bayii gbọdọ fun un ni afiyesi akọkọ. (Matiu 24:45-47) A ti sọ ọ lọna ti ó baamu pe igbesi-aye kii ṣe eyi ati iyẹn rara ṣugbọn eyi tabi iyẹn. Awa ha jẹ ọkunrin ati obinrin tẹmi nitootọ bi? Bi awa ba nimọlara aini wa nipa tẹmi, awa yoo lo ikora-ẹni-nijaanu ti a beere fun lati yí tẹlifiṣọn pa ki a sì murasilẹ fun awọn ipade tabi ka Ilé-ìṣọ́nà ti a lè ṣẹṣẹ rígbà nipasẹ ifiweranṣẹ.

20 Ẹkẹta, ọran mimọ ijẹpataki awọn ipade ijọ ati awọn apejọ ati apejọpọ nla wà. Njẹ gbogbo iru awọn ipade bẹẹ ha jẹ́ aigbọdọmaṣe patapata fun wa bi? Awa ha nmurasilẹ wá lati kópa ki a sì ṣe bẹẹ lẹhin naa gẹgẹ bi a ti lè ni anfaani bi? Dé aye ti a ba mọ iniyelori tootọ ti awọn ipade wa dé, dé iwọn yẹn ni a o fun wa lokun ninu ipinnu wa lati lo ikora-ẹni-nijaanu labẹ gbogbo awọn ipo.

21. Ki ni awọn èrè diẹ ti a lè gbadun fun mimu eso ti ẹmi naa ikora-ẹni-nijaanu dagba?

21 Awọn èrè wo ni a lè reti fun gbigbiyanju kára lati lo ikora-ẹni-nijaanu ni gbogbo ìgbà? Ohun kan niyii, awa ki yoo ká awọn eso kikoro ti imọtara-ẹni-nikan lae. Awa yoo ni ọ̀wọ̀ ara ẹni ati ẹ̀rí ọkàn mimọ kedere. Awa yoo gba araawa kuro lọwọ ọpọlọpọ ìyọnu gan-an awa yoo sì maa baa lọ ni wiwa loju ọna sí ìyè. Siwaju sii, awa yoo lè ṣe rere ti ó ṣeeṣe julọ fun awọn ẹlomiran. Leke gbogbo rẹ̀, awa yoo maa kọbiara si Owe 27:11 pe: “Ọmọ mi, ki iwọ, ki ó gbọ́n, ki o sì mu inu mi dun. Ki emi ki ó lè dá ẹni ti ńgàn mi lohun.” Iyẹn si ni èrè titobi julọ ti ó ṣeeṣe ki awa ni—anfaani mimu ọkan-aya Baba wa ọrun onifẹẹ, Jehofa dun!

Iwọ Ha Ranti Bi?

◻ Bawo ni ibẹru Ọlọrun ṣe ràn wá lọ́wọ́ lati lo ikora-ẹni-nijaanu?

◻ Eeṣe ti ifẹ fi ràn wá lọ́wọ́ lati lo ikora-ẹni-nijaanu?

◻ Bawo ni ikora-ẹni-nijaanu ṣe lè ṣeranwọ ninu ipo ibatan idile?

◻ Awọn ipese wo ni a gbọdọ lò daradara bi awa yoo ba mu ikora-ẹni-nijaanu dagba?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Josẹfu lo ikora-ẹni-nijaanu nigba ti a dan an wo

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ibawi ọmọ ti a fi pẹlẹtu ati ifẹ ṣe gba ikora-ẹni-nijaanu gidi

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́