Ikora-ẹni-nijaanu—Eeṣe Ti Ó Fi Ṣe Pataki Tobẹẹ?
“Ni fifi gbogbo isapa onifọkansi yin ṣeranlọwọ afikun ni idahun pada, ẹ fi iwa funfun kun igbagbọ yin, imọ kun iwa funfun yin, ikora-ẹni-nijaanu kun imọ yin.” —2 PETERU 1:5, 6, NW.
1. Ifihan pipẹtẹri ti ikora-ẹni-nijaanu ti ara wo ni ó ṣẹlẹ ni ọgọrun-un ọdun Kọkandinlogun?
LAISI iyemeji, ọ̀kan lara awọn ifihan iko nijaanu ti ara ìyára yiyanilẹnu julọ ni a fifunni nipasẹ Charles Blondin ni ilaji ti ó kẹhin ọgọrun-un ọdun Kọkandinlogun. Gẹgẹ bi irohin kan ti wí, o sọda Itakiti omi Niagara [Niagara Falls] ni ọpọ ìgbà, akọkọ ni 1859, lori okun nínà tantan ti ó gùn tó 1,100 ẹsẹ bata ti ó sì ga tó 160 ẹsẹ bata lori omi naa. Lẹhin iyẹn, ó ṣe bẹẹ nigba kọọkan pẹlu ifihan ọtọọtọ ti agbara iṣe rẹ̀: ni bíboju, ninu apo, ní titi kẹkẹ-ikẹru kan, lori àgéré, ati gbigbe ọkunrin kan kọ́rùn. Ninu awọn igbekalẹ miiran, lori àgéré ó tàkìtì lori okùn ti a nà ni 170 ẹsẹ bata ga silẹ. Lati pa iru iwadeedee bẹẹ mọ beere fun ikora-ẹni-nijaanu ti ara ìyára nla oniwọn giga julọ. Gẹgẹ bi isanpada, Blondin ni a san èrè fun pẹlu aasiki ati ọpọ jaburata owó.
2. Iru igbokegbodo miiran wo ni ó wà ti ó beere fun ikonijaanu ara ìyára?
2 Nigba ti ó jẹ́ pe iwọnba diẹ ni o tilẹ lè sunmọ ṣíṣe ẹ̀dà awọn ifihan wọnni, ijẹpataki ikora-ẹni-nijaanu ti ara ìyára ninu lilo awọn ọgbọn iṣẹ akọmọọṣe tabi ninu eré idaraya ni ó ṣe kedere si gbogbo wa. Fun apẹẹrẹ, ni ṣiṣapejuwe iwọn mimọọṣe giga ti aluduuru olokiki naa Vladimir Horowitz, olorin kan wi pe: “Fun emi ohun ti ó fanimọra naa ni òye ikonijaanu patapata kan . . . , òye okun yiyanilẹnu ti a lò.” Irohin miiran lori Horowitz sọrọ nipa “aadọrin ọdun ti awọn ìka yiyara ti a nṣakoso lọna pipe.”
3. (a) Iru ikonijaanu wo ni ó nbeere isapa pupọ julọ, bawo ni a sì ti tumọ rẹ̀? (b) Ki ni itumọ ọrọ Giriiki naa ti a tumọsi “ikora-ẹni-nijaanu” ninu Bibeli?
3 Ó gba isapa gidigidi lati mu iru awọn òye bẹẹ dagba. Bi o ti wu ki o ri, ani ikora-ẹni-nijaanu ṣe pataki ó sì npeninija ju paapaa. A ti tumọ rẹ̀ gẹgẹ bi “ikalọwọko ti a lò lori òòfà ọkàn, imọlara, tabi awọn ifẹ ọkàn ara ẹni.” Ninu Iwe mimọ Kristẹni lede Giriiki, ọrọ ti a tumọsi “ikora-ẹni-nijaanu” ni 2 Peteru 1:6 ati nibomiran, ni a ti tumọ gẹgẹ bi “agbara ẹnikan ti o ṣakoso awọn ifẹ ọkàn ati ifẹ àìníjàánu rẹ̀, ni pataki awọn ìyánhànhàn fun igbadun ti ara.” Ikora-ẹni-nijaanu ẹnikọọkan ni a ti pe ni “koko gigajulọ ninu aṣeyọri eniyan.”
Idi Ti Ikora-ẹni-nijaanu Fi Ṣe Pataki Tobẹẹ
4. Aini ikora-ẹni-nijaanu ti ká awọn eso buburu wo?
4 Iru irè wo ni aini ikora-ẹni-nijaanu ti ńká! Ọpọlọpọ ìyọnu ninu aye lonii ni ó jẹ nitori aini ikora-ẹni-nijaanu ni ipilẹ. Loootọ, a wà ni “ikẹhin ọjọ,” nigba ti ‘igba lilekoko ti ó ṣoro lati bá lò wà nihin-in.’ Awọn eniyan jẹ́ “alaile-koraawọn-nijaanu” niye ìgbà nitori iwọra, iru kan ti ó jẹ́ jíjẹ́ “olufẹ faaji ju olufẹ Ọlọrun lọ.” (2 Timoti 3:1-5) Otitọ amunironujinlẹ yii ni a ti fipa mu ṣe kedere fun wa nipa iyọkuro iye ti o ju 40,000 awọn ẹnikọọkan ti wọn jẹ oluṣaitọ kuro ninu ibakẹgbẹ pẹlu ijọ Kristẹni ni ọdun iṣẹ isin ti ó kọja, ni pataki julọ nitori iwa aitọ lọna wiwuwo. Ọpọlọpọ ti a fun ni ibawi, ni pataki julọ nitori iwa palapala ti ibalopọ takọtabo ṣugbọn ti gbogbo rẹ̀ jẹ́ nitori ikuna lati lo ikora-ẹni-nijaanu ni a gbọdọ fikun awọn wọnyi pẹlu. Amunidorikodo tun ni otitọ naa pe awọn alagba ọlọjọ pipẹ diẹ ti sọ gbogbo anfaani wọn nù gẹgẹ bi alaboojuto fun idi kan naa.
5. Bawo ni a ṣe le ṣapejuwe ijẹpataki ikora-ẹni-nijaanu?
5 Ijẹpataki ikora-ẹni-nijaanu ni a lè fi ọkọ irinna kan ṣapejuwe rẹ̀. Ó ni àgbá kẹ̀kẹ́ mẹrin ti o mu ki ó ṣeeṣe lati rin, ẹrọ alagbara kan ti ó lè yi awọn àgbá kẹ̀kẹ́ wọnni pẹlu ìyára kánkán gan-an, ati ìjánu ti ó lè da wọn duro. Bi o ti wu ki o ri, ajalu ibi lè ṣẹlẹ ayafi bi ẹnikan bá wà ni ipo awakọ lati pinnu ibi ti awọn àgbá kẹ̀kẹ́ wọnni nlọ, bi wọn ti nyara yí sí, ati ìgbà ti wọn yoo duro, nipa mimu ìlò àgbá ìtọ́kọ̀, ohun eelo ìgbọ́kọ̀sáré, ati awọn ìjánu wà labẹ akoso.
6. (a) Ilana wo nipa ifẹ ni a lè fisilo fun ikora-ẹni-nijaanu? (b) Imọran siwaju sii wo ni a gbọdọ fi sọkan?
6 Yoo ṣoro lati tẹnumọ ijẹpataki ikora-ẹni-nijaanu ju. Ohun ti apọsiteli Pọọlu sọ ni 1 Kọrinti 13:1-3 nipa ijẹpataki ifẹ ni a lè sọ bakan naa nipa ikora-ẹni-nijaanu. Laika bi a ti lè lẹbun ọrọ sisọ gẹgẹ bi olubanisọrọ itagbangba tó sí, laika bi imọ ati igbagbọ ti a ti lè jere nipasẹ aṣa ikẹkọọ rere ti pọ̀ tó sí, laika awọn iṣẹ ti a lè maa ṣe lati ṣanfaani fun awọn ẹlomiran sí, ayafi bi a ba lo ikora-ẹni-nijaanu, gbogbo eyi jẹ́ asan. A gbọdọ ni awọn ọrọ Pọọlu lọkan pe: “Ẹyin kò ha mọ pe awọn saresare ninu eré-ìje gbogbo wọn ni nsare, ṣugbọn ẹnikanṣoṣo nii gba ẹbun eré-ìje naa? Ẹ sare ni iru ọna bẹẹ ki ẹyin baa lè ri i gba. Ju bẹẹ lọ, olukuluku ọkunrin ti nnipa ninu eré idije kan a maa lo ikora-ẹni-nijaanu ninu ohun gbogbo.” (1 Kọrinti 9:24, 25, NW) Ikilọ Pọọlu ni 1 Kọrinti 10:12 pe: “Nitori naa ẹni ti ó ba rò pe oun duro, ki ó kiyesara, ki ó ma baa ṣubu” ńràn wá lọ́wọ́ lati lo ikora-ẹni-nijaanu ninu ohun gbogbo.
Awọn Apẹẹrẹ Onikilọ
7. (a) Bawo ni aini ikora-ẹni-nijaanu ṣe mu iran eniyan bẹrẹ loju ipa-ọna ilọsilẹ rẹ̀? (b) Awọn apẹẹrẹ ti ijimiji miiran wo ti aini ikora-ẹni-nijaanu ni Iwe mimọ fifun wa?
7 Nipa fifayegba imọlara dipo ironu lati ṣakoso awọn igbesẹ rẹ̀, Adamu kuna lati lo ikora-ẹni-nijaanu. Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀, “ẹṣẹ . . . wọ aye, ati iku nipa ẹṣẹ.” (Roomu 5:12) Ipaniyan akọkọ tun jẹ́ nitori aini ikora-ẹni-nijaanu, nitori Jehofa Ọlọrun ti kilọ fun Keeni pe: ‘Eeṣe ti o fi rorò fun ibinu eesitiṣe ti irisi oju rẹ fi rẹwẹsi? Ẹṣẹ ńba si abawọle, iwọ yoo ha sì lè káwọ́ rẹ̀ bi?’ Nitori pe Keeni kò ṣekawọ ẹṣẹ, ó pa arakunrin rẹ̀ Ebẹli. (Jẹnẹsisi 4:6-12, NW) Aya Lọti tun kuna lati lo ikora-ẹni-nijaanu. Oun kò wulẹ lè dena idẹwo lati wo ẹhin. Ki ni aini ikora-ẹni-nijaanu rẹ̀ ná an? Họwu, iwalaaye rẹ̀ gan-an!—Jẹnẹsisi 19:17, 26.
8. Iriri awọn ọkunrin mẹta igbaani wo ni ó pese ikilọ fun wa niti aini fun ikora-ẹni-nijaanu?
8 Rubẹni, ọmọkunrin akọbi Jakọbu, padanu ogún ìbí nitori aini ikora-ẹni-nijaanu rẹ̀. O ba ẹní baba rẹ̀ jẹ́ nipa nini ibalopọ takọtabo pẹlu ọ̀kan lara awọn àlè Jakọbu. (Jẹnẹsisi 35:22; 49:3, 4; 1 Kironika 5:1) Nitori pe Mose kuna lati pa ibinu rẹ̀ mọ́ lori ọna ti awọn ọmọ Isirẹli gba dan an wo pẹlu kíkùn, ṣiṣaroye, ati ìṣọ̀tẹ̀ wọn, a fi anfaani ti ó fẹ́ pupọpupọ naa ti wiwọnu Ilẹ Ileri dù ú. (Numeri 20:1-13; Deutaronomi 32:50-52) Ani Ọba Dafidi oluṣotitọ, ‘ọkunrin ti ó ṣe itẹwọgba si ọkan-aya Ọlọrun funraarẹ,’ bọ́ sinu ijangbọn gbígbópọn nitori aini ikora-ẹni-nijaanu rẹ̀ ni akoko kan. (1 Samuẹli 13:14; 2 Samuẹli 12:7-14) Gbogbo iru awọn apẹẹrẹ bẹẹ pese awọn ikilọ ṣiṣanfaani ti a nilo lati lo ikora-ẹni-nijaanu.
Ohun Ti A Nilati Konijaanu
9. Awọn Iwe mimọ diẹ wo ni wọn tẹnumọ ijẹpataki ikora-ẹni-nijaanu?
9 Lakọọkọ, ikora-ẹni-nijaanu wémọ́ awọn ironu ati ero imọlara wa. Iwọnyi ni a saba maa ntọkasi ninu Iwe mimọ nipa lilo iru awọn ọrọ bii “ọkan-aya” ati “kindinrin” lọna iṣapẹẹrẹ. Ohun ti a jẹ́ ki ọkan wa ṣe àṣàrò lé lori nran wa lọwọ tabi ńdí wa lọwọ ninu isapa wa lati wu Jehofa. Ikora-ẹni-nijaanu ni a nilo bi awa yoo ba nilati kọbiara si imọran Iwe mimọ ti a ri ninu Filipi 4:8, lati maa baa lọ ni gbigbe awọn ohun ti ó jẹ́ otitọ, oniwa mimọ, ati oniwa funfun yẹwo. Dafidi onisaamu naa sọ ero ti ó farapẹ ẹ jade ninu adura, ni wiwi pe: “Jẹ ki . . . iṣaro ọkàn mi, ki ó ṣe itẹwọgba ni oju rẹ, Oluwa [“Jehofa,” NW], agbara mi, ati oludande mi.” (Saamu 19:14) Ofin kẹwaa—lati maṣe ni ìfásí ọkàn lilagbara si ohunkohun tii ṣe ti ẹnikeji ẹni—beere ikonijaanu awọn ero inu ẹni. (Ẹkisodu 20:17) Jesu tẹnumọ ijẹpataki kiko awọn ironu ati imọlara wa nijaanu nigba ti ó wi pe: “Ẹnikẹni ti ó bá wo obinrin kan lati ṣe ifẹkufẹ sii, ó ti ba a ṣe panṣaga tan ni ọkàn rẹ̀.”—Matiu 5:28.
10. Awọn ẹsẹ Iwe mimọ wo ni ó tẹnumọ ijẹpataki kiko ọrọ sisọ wa nijaanu?
10 Ikora-ẹni-nijaanu tun wémọ́ awọn ọrọ wa, ọrọ sisọ wa. Nitootọ ọpọlọpọ awọn iwe mimọ ti wọn gba wa nimọran lati ko ahọn wa nijaanu ni ó wà. Fun apẹẹrẹ: “Ọlọrun nbẹ ni ọrun, iwọ sì nbẹ ni ayé: nitori naa jẹ ki ọrọ rẹ ki ó mọ ni iwọn.” (Oniwaasu 5:2) “Ninu ọrọ pupọ, a kò lè fẹ́ ẹṣẹ kù: ṣugbọn ẹni ti ó fi ètè mọ ètè ni ó gbọ́n.” (Owe 10:19) “Ẹ maṣe jẹ ki ọrọ idibajẹ kan ti ẹnu yin jade, ṣugbọn iru eyi ti o dara fun ẹkọ . . . Gbogbo . . . ariwo, ati ọrọ buburu ni ki a mu kuro lọdọ yin, pẹlu gbogbo arankan.” Pọọlu sì nbaa lọ lati funni nimọran lati mu isọrọ were ati iṣẹfẹ awọn ohun ti kò tọ́ kuro laaarin wa.—Efesu 4:29, 31; 5:3, 4.
11. Bawo ni Jakọbu ṣe bojuto iṣoro kiko ahọn nijaanu?
11 Jakọbu, ọbàkan Jesu, dẹbi fun ọrọ sisọ ti a kò konijaanu ó sì fihan bi ó ti le tó lati ko ahọn nijaanu. Ó wi pe: “Ahọn jẹ́ ẹya ara kekere sibẹ a sì maa ṣe awọn ifọnnu nla. Wò ó! Bi a kò ti fẹ́ ju ina kekere lọ lati dá ina sun igbo ti ó tobi tobẹẹ! Too, ahọn jẹ́ ina kan. Ahọn ni a sì sọ di ayé aiṣododo lara awọn ẹ̀yà ara wa, nitori ó ntabuku si gbogbo ara o sì ntẹnabọ kẹ̀kẹ́ igbesi-aye ẹ̀dà Gẹhẹna sì tẹnabọ oun naa. Nitori olukuluku awọn oniruuru ẹranko ẹhanna ati ẹyẹ ati ohun ti ńrákò ati ẹ̀dá inu okun ni a nilati tù loju ti a sì ti tuloju lati ọwọ araye. Ṣugbọn ahọn, kò si ẹnikan ninu araye ti ó lè tù ú loju. Ohun kan ti o ya ewèlè ti nṣe ipalara, ó kun fun májèlé ti nṣekupani. Oun ni a fi nfi ibukun fun Jehofa, ani Baba, ati sibẹ oun ni a fi nṣẹ èpè fun awọn eniyan awọn ti a dá ‘ni jíjọ Ọlọrun.’ Lati ẹnu kan naa ni ibukun ati èpè ti njade wá. Kò yẹ bẹẹ, ẹyin arakunrin mi, ki nǹkan wọnyi maa ṣẹlẹ niṣo ni ọna yii.”—Jakobu 3:5-10, NW.
12, 13. Awọn iwe mimọ diẹ wo ni ó fi ijẹpataki kiko awọn igbesẹ ati iwa wa nijaanu han?
12 Dajudaju, ikora-ẹni-nijaanu wémọ́ awọn igbegbeesẹ wa. Agbegbe kan ninu eyi ti a ti nilo ikora-ẹni-nijaanu gidigidi niiṣe pẹlu ibatan wa pẹlu awọn wọnni ti wọn jẹ́ ẹ̀yà keji. Awọn Kristẹni ni a pasẹ fun pe: “Ẹ sá fun iwa palapala takọtabo.” (1 Kọrinti 6:18, New International Version) Awọn ọkọ ni a gbaniyanju lati fi ifẹ ibalopọ mọ sọdọ awọn aya wọn, nigba ti a sọ fun wọn ni apa kan pe: “Mu omi lati inu àmù rẹ, ati omi ti ńṣàn lati inu kanga rẹ.” (Owe 5:15-20) A sọ fun wa ni kedere pe “Awọn agbere ati awọn panṣaga ni Ọlọrun yoo dá lẹ́jọ́.” (Heberu 13:4) Ikora-ẹni-nijaanu ni awọn wọnni ti wọn yoo mu ẹbun ipò àpọ́n dagba nilo ni pataki.—Matiu 19:11, 12; 1 Kọrinti 7:37.
13 Jesu ṣakopọ gbogbo ọran nipa awọn igbegbeesẹ wa si awọn eniyan ẹlẹgbẹ wa nigba ti ó funni ni ohun ti a mọ ni gbogbogboo si “Ofin Oniwura,” ni wiwi pe: “Nitori naa gbogbo ohunkohun ti ẹyin ba nfẹ ki eniyan ki o ṣe si yin, bẹẹ ni ki ẹyin ki o si ṣe sí wọn gẹgẹ; nitori eyi ni ofin ati awọn wolii.” (Matiu 7:12) Loootọ, ó gba ikora-ẹni-nijaanu lati maṣe jẹ ki itẹsi onimọtara-ẹni-nikan tiwa tabi awọn ikimọlẹ ẹhin ode tabi awọn idẹwo mu ki a bá awọn ẹlomiran lò lọna ti ó yatọ si bi awa yoo ṣe fẹ ki wọn bá wa lò.
14. Imọran wo ni Ọrọ Ọlọrun fifunni nipa jíjẹ ati mímu?
14 Lẹhin naa ọran ti ikora-ẹni-nijaanu nipa ounjẹ ati ohun mimu wà. Ọrọ Ọlọrun fi ọgbọn gbaninimọran pe: “Maṣe wà ninu awọn ọmuti, ninu awọn ti ó ńjẹ ẹran ni àjẹkì.” (Owe 23:20) Ni pataki nipa ọjọ wa, Jesu kilọ pe: “Ẹ maa kiyesara yin, ki ọkàn yin ki ó maṣe kun fun wọbia, ati fun ọti amupara, ati fun aniyan ayé yii, ti ọjọ naa yoo sì fi dé ba yin lojiji bi ikẹkun.” (Luuku 21:34, 35) Bẹẹni, ikora-ẹni-nijaanu wémọ́ awọn ironu wa ati imọlara wa, ati awọn ọrọ ati igbegbeesẹ wa bakan naa.
Idi Ti Ikora-ẹni-nijaanu Fi Jẹ Iru Ipenija Kan Bẹẹ
15. Bawo ni Iwe mimọ ṣe fi ijotiitọ atako Satani han si lilo ikora-ẹni-nijaanu Kristẹni?
15 Ikora-ẹni-nijaanu kii fi tirọruntirọrun wá nitori pe, gẹgẹ bi gbogbo awọn Kristẹni ti mọ, a ni awọn ipá lilagbara mẹta ti wọn tò gbágbágbá lodisi lilo ikora-ẹni-nijaanu wa. Lakọọkọ ná, Satani ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀ wà. Iwe mimọ kò fi iyemeji kankan silẹ niti wíwà wọn. Nipa bayii, a kà pe “Satani wọ inu” Judasi “lọ” kété ṣaaju ki ó tó jade lọ lati fi Jesu han. (Johanu 13:27) Apọsiteli Peteru beere lọwọ Anania pe: “Eeṣe ti Satani fi kún ọ ni ọkàn lati ṣeke si ẹmi mimọ?” (Iṣe 5:3) Lọna ti o ṣe rẹgi julọ, Peteru tun kilọ pe: “Ẹ maa wà ni airekọja, ẹ maa ṣọra; nitori Eṣu, ọta yin, bii kinniun ti nke ramuramu, ó nrin kaakiri, o nwa ẹni ti yoo pajẹ kiri.”—1 Peteru 5:8.
16. Eeṣe ti awọn Kristẹni fi gbọdọ lo ikora-ẹni-nijaanu niti aye yii?
16 Ninu isapa wọn lati fi ikora-ẹni-nijaanu han, awọn Kristẹni gbọdọ wọ̀jà pẹlu ayé yii ti ó wà “labẹ agbara ẹni buburu nì,” Satani Eṣu. Nipa rẹ̀, apọsiteli Johanu kọwe pe: “Ẹ maṣe fẹran ayé, tabi ohun ti nbẹ ninu ayé. Bi ẹnikẹni ba fẹran ayé, ifẹ ti Baba kò si ninu rẹ̀. Nitori ohun gbogbo ti nbẹ ni ayé, ifẹkufẹẹ ara, ati ifẹkufẹẹ oju, ati irera aye, kii ṣe ti Baba, bikoṣe ti ayé. Aye sì nkọja lọ, ati ifẹkufẹẹ rẹ̀: ṣugbọn ẹni ti ó ba nṣe ifẹ Ọlọrun ni yoo duro laelae.” Ayafi bi a ba lo ikora-ẹni-nijaanu ti a si fi tagbaratagbara dena itẹsi eyikeyii lati nifẹẹ ayé, awa yoo jọ̀wọ́ ara wa silẹ fun agbara idari rẹ̀, gẹgẹ bi Demasi oṣiṣẹ ẹlẹgbẹ Pọọlu nigbakan ri ti ṣe.—1 Johanu 2:15-17; 5:19; 2 Timoti 4:10.
17. Pẹlu iṣoro wo niti ikora-ẹni-nijaanu ni a bi wa?
17 Gẹgẹ bii Kristẹni, a tun nilo ikora-ẹni-nijaanu bi awa yoo bá wọ̀jà lọna aṣeyọri si rere pẹlu awọn aipe ati aidoju iwọn tiwa funraawa ti a ti jogunba. Awa kò lè bọ́ lọwọ otitọ naa pe “ìrò ọkàn eniyan ibi ni lati ìgbà ewe rẹ̀ wá.” (Jẹnẹsisi 8:21) Bii ti Ọba Dafidi, ‘ninu aiṣedeedee ni a gbé bí wa: ati ninu ẹṣẹ ni iya wa sì loyun wa.’ (Saamu 51:5) Ọmọ kan ti a ṣẹṣẹ bí kò mọ ohunkohun nipa ikora-ẹni-nijaanu. Nigba ti ó ba nfẹ ohun kan, yoo wulẹ maa ké ni titi yoo fi ri i gbà. Irohin kan lori ọmọ títọ́ wi pe: ‘Awọn ọmọde nronu ni ọna kan ti ó yatọ patapata si ti awọn agbalagba. Awọn ọmọde jẹ́ olufẹ ti ara wọn nikan wọn sì jẹ́ alaile dahunpada si iyinileropada ti ó bọgbọnmu julọ niye igba nitori pe wọn kò lè “fi araawọn si ipo ẹlomiran.”’ Loootọ, “ní àyà ọmọde ni were dì sí.” Bi o ti wu ki o ri, pẹlu ifisilo “paṣan itọni,” oun yoo kẹkọọ ni kẹrẹkẹrẹ pe awọn ofin idiwọn ti oun gbọdọ ṣegbọran si wà ati pe imọtara-ẹni-nikan ni a gbọdọ konijaanu.—Owe 22:15.
18. (a) Gẹgẹ bi Jesu ti wi, awọn itẹsi wo ni ó ngbe ninu ọkan-aya iṣapẹẹrẹ wa? (b) Awọn ọrọ Pọọlu wo ni ó fi han pe ó mọ nipa iṣoro lilo ikora-ẹni-nijaanu?
18 Bẹẹni, awọn itẹsi abinibi onimọtara-ẹni-nikan wa gbé ipenija kan kalẹ fun wa nigba ti ó ba kan ikora-ẹni-nijaanu. Awọn itẹsi wọnni ngbe ninu ọkan-aya iṣapẹẹrẹ, nipa eyi ti Jesu wi pe: “Lati inu ọkàn [“ọkan-aya,” NW] ni ìrò buburu ti njade wá, ipaniyan, panṣaga, agbere, olè, ẹ̀rí èké, ati ọrọ buburu.” (Matiu 15:19) Idi niyẹn ti Pọọlu fi kọwe pe: “Nitori ire ti emi fẹ emi kò ṣe: ṣugbọn buburu ti emi kò fẹ, eyiini ni emi nṣe. Ṣugbọn bi ó ba ṣe pe ohun ti emi kò fẹ, eyiini ni emi nṣe, emi ki nṣe e mọ́, bikoṣe ẹṣẹ ti ngbe inu mi.” (Roomu 7:19, 20) Bi o ti wu ki o ri, eyi kii ṣe ipo ainireti kan nitori Pọọlu tun kọwe pe: “Emi npọn ara mi loju, mo sì nmu un wa sabẹ itẹriba: pe lẹhin ti mo ti waasu fun awọn ẹlomiran, nitori ohunkohun, ki emi tikaraami maṣe di ẹni ìtanù.” Pipọn ara rẹ̀ loju beere fun lilo ikora-ẹni-nijaanu.—1 Kọrinti 9:27.
19. Eeṣe ti Pọọlu fi lè sọ ni ọna ti ó baamu pe oun pọn ara oun loju?
19 Pọọlu lè sọ lọna ti ó baamu pe oun npọn ara oun loju, nitori lilo ikora-ẹni-nijaanu ni a mu ki o nira nipasẹ ọpọlọpọ awọn agbara idari ti ara, iru bii ẹjẹ ríru, awọn iṣan imọlara buburu, airi orun sun, ẹfọri, àìdà ounjẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ninu ọrọ-ẹkọ ti o tẹle, awa yoo gbe awọn animọ ati aranṣe ti yoo ràn wa lọwọ lati lo ikora-ẹni-nijaanu yẹwo.
Iwọ Ha Ranti Bi?
◻ Eeṣe ti ikora-ẹni-nijaanu fi ṣe pataki?
◻ Ki ni awọn apẹẹrẹ diẹ nipa awọn wọnni ti wọn padanu nitori aini ikora-ẹni-nijaanu?
◻ Ni awọn agbegbe wo ni a ti gbọdọ fi ikora-ẹni-nijaanu silo?
◻ Awọn ọ̀tá mẹta wo ni wọn mu ki ó ṣoro fun wa lati lo ikora-ẹni-nijaanu?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Awọn Kristẹni nilo lati lo ikora-ẹni-nijaanu niti jíjẹ ati mímu
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Ikora-ẹni-nijaanu yoo ran wa lọwọ lati fasẹhin kuro ninu òfófó ti npanilara
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]
Historical Pictures Service