Ẹ̀KỌ́ 37
Mú Kí Kókó Ọ̀rọ̀ Fara Hàn Kedere
KÍ LÀWỌN kókó inú ọ̀rọ̀ kan? Kì í ṣe àwọn ọ̀rọ̀ tó fani mọ́ra tó o kàn sọ mọ́ ọ̀rọ̀ lásán là ń pè ní kókó ọ̀rọ̀. Àwọn èrò pàtàkì tó o ṣàlàyé nínú ọ̀rọ̀ rẹ là ń pè bẹ́ẹ̀. Èrò wọ̀nyí ni òpómúléró ọ̀rọ̀ tó ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ lè sún àwọn èèyàn ṣe ohun tó o fẹ́ kí wọ́n ṣe.
Ohun tí o lè ṣe kí kókó ọ̀rọ̀ rẹ lè fara hàn kedere ni pé kí o yan ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ kí o sì tò ó lẹ́sẹẹsẹ bó ṣe yẹ. Ìsọfúnni tí èèyàn máa ń rí kó jọ tó bá ń ṣèwádìí lórí ọ̀rọ̀ tó fẹ́ sọ sábà máa ń pọ̀ ju ohun tó lè lò lọ. Báwo ni wàá ṣe wá mọ èyí tó yẹ kí o lò?
Àkọ́kọ́, ronú nípa àwùjọ rẹ. Ṣé wọ́n ti mọ̀ nípa ohun tí o fẹ́ sọ dáadáa tàbí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa rẹ̀? Ṣé ọ̀pọ̀ jù lọ wọn fara mọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀ tàbí àwọn kan ṣì ń ṣiyè méjì nípa rẹ̀? Irú ìṣòro wo ni wọ́n ń kò lójoojúmọ́ bí wọ́n ṣe ń gbìyànjú láti fi ohun tí Bíbélì sọ nípa kókó yẹn sílò? Ìkejì, rí i dájú pé ìdí tó o fi fẹ́ sọ̀rọ̀ lórí kókó ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ fún àwùjọ ṣe kedere lọ́kàn rẹ. Wá lo ìlànà méjì yìí láti fi díwọ̀n ìsọfúnni tó o rí kó jọ, kí o sì yan kìkì èyí tó bá yẹ nínú wọn.
Bí a bá fún ọ ní ìlapa èrò tó ti lẹ́ṣin ọ̀rọ̀, tí a sì ti to àwọn kókó ọ̀rọ̀ rẹ̀ síbẹ̀, ìyẹn ni kí o gbájú mọ́. Àmọ́ ṣá, bí o bá fi kókó méjèèjì òkè yìí sọ́kàn nígbà tí o bá ń ṣàlàyé kókó ọ̀rọ̀ rẹ lọ́kọ̀ọ̀kan yóò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ túbọ̀ wúlò sí i. Bí a kò bá fún ọ ní ìlapa èrò, a jẹ́ pé fúnra rẹ lo máa yan àwọn kókó ọ̀rọ̀ rẹ nìyẹn.
Bí àwọn kókó ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣe kedere lọ́kàn rẹ, tí o sì to àlàyé tí o máa ṣe nípa wọn lẹ́sẹẹsẹ sísàlẹ̀ rẹ̀, yóò túbọ̀ rọ̀ ọ́ lọ́rùn láti sọ ọ̀rọ̀ rẹ. Yóò sì tún ṣeé ṣe kí àwùjọ túbọ̀ rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú rẹ̀.
Onírúurú Ọ̀nà Tí O Lè Gbà To Ọ̀rọ̀ Rẹ. O lè lo onírúurú ọ̀nà nígbà tó o bá ń ṣètò àárín ọ̀rọ̀ rẹ. Bí o bá sì ti ń mọwọ́ ọ̀nà wọ̀nyẹn dáadáa, wàá rí i pé bí o bá lo onírúurú ọ̀nà pa pọ̀ yóò dára, àmọ́ ṣá, ó sinmi lórí irú iṣẹ́ tó o fẹ́ fi ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́.
Ọ̀nà kan tó rọrùn ni pé kí o pín ọ̀rọ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí kókó inú rẹ̀ ṣe tẹ̀ léra. (Gbogbo kókó inú rẹ̀ ló ṣe pàtàkì nítorí pé wọ́n máa ń mú kí àwùjọ túbọ̀ lóye ọ̀rọ̀ rẹ tàbí kí wọ́n mú kí ọ̀rọ̀ rẹ lè jíṣẹ́ tí o bá rán an.) Ọ̀nà mìíràn ni pé kí o pín ọ̀rọ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìtàn inú rẹ̀ ṣe tẹ̀ léra. (Bí àpẹẹrẹ, o lè kọ́kọ́ sọ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú Ìkún Omi kí o tó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú ìparun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 70 ṣááju Sànmánì Tiwa, kí o tó wá sọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé ìgbà tiwa yìí.) Ọ̀nà kẹta ni kí o sọ ohun tó fa ọ̀ràn àti ibi tó yọrí sí. (O lè kọ́kọ́ ṣàlàyé èyíkéyìí nínú méjèèjì. Bí àpẹẹrẹ, o lè bẹ̀rẹ̀ látorí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́, tó jẹ́ ibi tí ọ̀ràn yọrí sí, kí o tó wá sọ ohun tó fa ọ̀ràn náà.) Ọ̀nà kẹrin ni ti sísọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín oríṣi ọ̀ràn méjì. (O lè sọ ìyàtọ̀ tó wà nínú ṣíṣe ohun rere àti ṣíṣe ohun búburú tàbí kí o sọ ibi tí ohun kan dára sí àti ibi tó burú sí.) Nígbà mìíràn, èèyàn lè lò ju ọ̀nà kan ṣoṣo lọ nínú ọ̀rọ̀ ẹni.
Nígbà tí àwọn kan purọ́ mọ́ Sítéfánù níwájú àjọ Sànhẹ́dírìn àwọn Júù, ọ̀nà bí ìtàn ọ̀rọ̀ ṣe tẹ̀ léra ni Sítéfánù lò nígbà tó ń sọ gbankọgbì ọ̀rọ̀ tó sọ. Bí o bá ka Ìṣe 7:2-53, wàá rí i pé ńṣe ló dìídì yan àwọn ọ̀rọ̀ tó ń sọ. Sítéfánù kọ́kọ́ fi yé àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé ìtàn tòótọ́ pọ́ńbélé lòun ń sọ. Ó wá fi hàn pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù kọ Jósẹ́fù, òun ṣì ni Ọlọ́run pàpà lò láti gbà wọ́n sílẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó fi hàn pé àwọn Júù ṣàìgbọràn sí Mósè, ẹni tí Ọlọ́run ń lò. Paríparí rẹ̀ ló wá sọ ojú abẹ níkòó fún wọn pé irú ẹ̀mí kan náà yìí tí ìran àwọn Júù àtẹ̀yìnwá ní náà làwọn tó pa Jésù Kristi ní.
Má Ṣe Jẹ́ Kí Kókó Ọ̀rọ̀ Rẹ Pọ̀ Jù. Ìwọ̀nba kókó díẹ̀ lèèyàn nílò láti fi ṣàlàyé ẹṣin ọ̀rọ̀ èyíkéyìí. Kókó yẹn kì í ju ẹyọ márùn-ún lọ lọ́pọ̀ ìgbà. Ọ̀rọ̀ rẹ ì báà jẹ́ fún ìṣẹ́jú márùn-ún, tàbí mẹ́wàá, tàbí ọgbọ́n ìṣẹ́jú, tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, kókó yẹn kò yẹ kó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Má ṣe gbìyànjú láti pe àfiyèsí sí iye kókó ọ̀rọ̀ tó pọ̀ púpọ̀ jù. Ìwọ̀nba kókó bíi mélòó kan péré làwùjọ máa ń lè dì mú nínú ọ̀rọ̀ tẹ́nì kan sọ. Bí ọ̀rọ̀ ẹni bá sì ṣe gùn tó ni kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ ṣe ní láti rinlẹ̀ kí o sì túbọ̀ yéni yékéyéké tó.
Iye kókó yòówù kí o lò, rí i dájú pé o ṣe àlàyé wọn kúnnákúnná lọ́kọ̀ọ̀kan. Fún àwọn olùgbọ́ rẹ láyè tí ó tó láti fi yiiri kókó kọ̀ọ̀kan wò, kó lè wọ̀ wọ́n lọ́kàn ṣinṣin.
Ó yẹ kí ọ̀rọ̀ rẹ rọrùn fáwọn èèyàn láti lóye. Kì í ṣe bí ìsọfúnni tí a gbé jáde ṣe pọ̀ tó ló ń pinnu èyí o. Bí o bá to èrò rẹ lẹ́sẹẹsẹ sábẹ́ ìwọ̀n ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ mélòó kan, tí o sì ṣe àlàyé wọn lọ́kọ̀ọ̀kan, ọ̀rọ̀ rẹ a rọrùn fáwọn èèyàn láti lóye, kò sì ní ṣeé gbàgbé.
Jẹ́ Kí Àwọn Kókó Ọ̀rọ̀ Rẹ Hàn Kedere. Bí o bá to ọ̀rọ̀ tí o fẹ́ sọ lẹ́sẹẹsẹ kò ní ṣòro fún ọ láti lè gbé àwọn kókó inú ọ̀rọ̀ rẹ yọ dáadáa nígbà tó o bá ń sọ̀rọ̀.
Ọ̀nà pàtàkì tó o lè gbà mú kí kókó ọ̀rọ̀ hàn kedere ni pé kí o mú ẹ̀rí jáde, kí o ka Ìwé Mímọ́, kí o sì ṣàlàyé àwọn ìsọfúnni yòókù lọ́nà tí yóò gbé èrò pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ yọ ní tààràtà àti lọ́nà tí yóò mú kó túbọ̀ yéni yékéyéké. Ńṣe ló yẹ kí àwọn kókó yòókù tó jẹ́ ìsọ̀ǹgbè túbọ̀ ṣàlàyé kókó ọ̀rọ̀ rẹ, kí wọ́n fi ẹ̀rí tì í lẹ́yìn tàbí kí wọ́n túbọ̀ gbé e yọ. Má kàn tìtorí pé kókó tí kò jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ rẹ wù ọ́ gan-an kí o wá fi kún un. Nígbà tí o bá ń ṣàlàyé àwọn ìsọ̀ǹgbè kókó ọ̀rọ̀, fi bí wọ́n ṣe wé mọ́ kókó ọ̀rọ̀ tí wọ́n tì lẹ́yìn hàn. Má ṣe fi í sílẹ̀ fún àwùjọ láti máa fúnra wọn fòye gbé e. O lè fi bí wọ́n ṣe so pọ̀ mọ́ra hàn nípa títún àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì tó wà nínú kókó ọ̀rọ̀ yẹn sọ tàbí nípa títún ẹ̀kọ́ tí kókó ọ̀rọ̀ yẹn ń kọ́ni sọ látìgbàdégbà.
Àwọn olùbánisọ̀rọ̀ kan máa ń sọ iye kókó tó wà nínú ọ̀rọ̀ wọn ní ení, èjì láti mú wọn ṣe kedere. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà yìí jẹ́ ọ̀nà kan tó dára láti gbà gbé kókó ọ̀rọ̀ yọ, kì í ṣe pé kó o wá fi ìyẹn rọ́pò fífarabalẹ̀ yan ọ̀rọ̀ tí o fẹ́ lò àti ṣíṣàlàyé ọ̀rọ̀ lọ́nà tó dára.
O tiẹ̀ lè yàn láti kọ́kọ́ sọ àwọn kókó ọ̀rọ̀ rẹ ná kí o tó wá fi àlàyé tì wọ́n lẹ́yìn. Èyí máa ń mú kí àwùjọ mọ bí ohun tí o sọ nípa wọn ṣe wúlò tó, ó sì tún jẹ́ ọ̀nà tá a lè gbà tẹnu mọ́ kókó ọ̀rọ̀ ẹni. Ó lè túbọ̀ gbé kókó ọ̀rọ̀ yọ tí o bá ṣe àkópọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn tí o bá ṣàlàyé rẹ̀ tán.
Ní Òde Ẹ̀rí. Kì í ṣe ìgbà tí a bá fẹ́ sọ̀rọ̀ lórí pèpéle nìkan la lè lo àwọn ìlànà tí a mẹ́nu kàn lókè yìí o, ó tún kan àwọn ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wa lóde ẹ̀rí pẹ̀lú. Nígbà tí o bá ń múra òde ẹ̀rí sílẹ̀, ronú nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tó lè wà lọ́kàn àwọn èèyàn nínú ìpínlẹ̀ rẹ. Wá yan ẹṣin ọ̀rọ̀ kan tí yóò jẹ́ kí o lè fi ohun tí Bíbélì ní ká máa retí pé yóò yanjú ìṣòro yẹn hàn wọ́n. Yan nǹkan bíi kókó méjì láti fi ṣàlàyé ẹṣin ọ̀rọ̀ yẹn. Kí o yan àwọn ẹsẹ Bíbélì tí o máa lò láti fi ti kókó wọ̀nyẹn lẹ́yìn. Sì wá ronú lórí bí o ṣe máa bẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yẹn. Irú ìmúrasílẹ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ kéèyàn lè yíwọ́ padà láàárín ọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ kó rí nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀. Yóò sì tún jẹ́ kí o lè sọ ọ̀rọ̀ tí onílé kò ní gbàgbé.