ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • th ẹ̀kọ́ 14 ojú ìwé 17
  • Jẹ́ Kí Kókó Ọ̀rọ̀ Fara Hàn Kedere

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Kí Kókó Ọ̀rọ̀ Fara Hàn Kedere
  • Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mú Kí Kókó Ọ̀rọ̀ Fara Hàn Kedere
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ṣíṣe Ìlapa Èrò
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ṣíṣàlàyé Ẹṣin Ọ̀rọ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Máa Ṣàtúnyẹ̀wò Ẹ̀kọ́ Pàtàkì Tó O Kọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
Àwọn Míì
Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
th ẹ̀kọ́ 14 ojú ìwé 17

Ẹ̀KỌ́ 14

Jẹ́ Kí Kókó Ọ̀rọ̀ Fara Hàn Kedere

Ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí

Hébérù 8:1

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Jẹ́ kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ máa fọkàn bá ẹ lọ, kó o sì jẹ́ kí wọ́n rí bí kókó ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan ṣe tan mọ́ ohun tó o fẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe àti ohun tí ọ̀rọ̀ rẹ dá lé.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Mọ ohun tó o fẹ́ fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣe. Ṣé o fẹ́ fún wọn ní ìsọfúnni kan ni? Ṣé o fẹ́ fi ohun kan dá wọn lójú ni? Àbí o fẹ́ gbà wọ́n níyànjú? Rí i pé o múra ọ̀rọ̀ rẹ sílẹ̀ lọ́nà táá fi lè ṣe iṣẹ́ tó o fẹ́ kó ṣe. Kó o sì rí i dájú pé gbogbo kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ ló bá ohun tó o fẹ́ fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣe mu.

    Àwọn àbá

    Bi ara rẹ pé: ‘Ìbéèrè wo ló ṣeé ṣe kó wà lọ́kàn àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi? Àwọn kókó wo ni wọ́n lè má fara mọ́? Tí mo bá dáhùn ìbéèrè kan, ìbéèrè wo ló tún lè wà lọ́kàn wọn? Kó o wá to ọ̀rọ̀ rẹ lọ́nà tí wọ́n á fi lè máa fọkàn bá ẹ lọ, tí ọ̀rọ̀ rẹ á yé wọn, tí wọ́n á sì fara mọ́ ọ̀rọ̀ rẹ.

  • Tẹnu mọ́ ohun tí ọ̀rọ̀ rẹ dá lé. Jálẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ, máa tẹnu mọ́ ohun tí ọ̀rọ̀ rẹ dá lé. O lè máa tún àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì inú rẹ̀ sọ tàbí kó o lo àwọn ọ̀rọ̀ míì tó ní ìtúmọ̀ kan náà.

  • Jẹ́ kí àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ ṣe kedere kó sì rọrùn. Àwọn kókó pàtàkì tó bá ọ̀rọ̀ rẹ mu tó o sì mọ̀ pé wàá lè ṣàlàyé dáadáa láàárin àkókò tó o máa fi sọ̀rọ̀ nìkan ni kó o yàn. Ìwọ̀nba kókó pàtàkì ni kó o yàn, jẹ́ kí kókó pàtàkì kọ̀ọ̀kan ṣe kedere, máa dánu dúró díẹ̀ bó o ṣe ń sọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, kó o sì ṣàlàyè kókó kan yanjú kó o tó bọ́ sórí èyí tó kàn.

    Àwọn àbá

    O lè sọ àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ láti ìbẹ̀rẹ̀ kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ lè máa fọkàn bá ẹ lọ tàbí kó o tún un sọ ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ kí wọ́n lè rántí wọn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́