ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ẹ̀kọ́ 40 ojú ìwé 223-ojú ìwé 225 ìpínrọ̀ 3
  • Ọ̀rọ̀ Tó Jóòótọ́ Délẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀rọ̀ Tó Jóòótọ́ Délẹ̀
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀rọ̀ Tó Péye Tó sì Ń Yíni Lérò Pa Dà
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Bí A Ṣe Ń Ṣe Ìwádìí
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Jàǹfààní Kíkún Látinú Kíka Bíbélì Déédéé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Wàásù Láti Sọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ẹ̀kọ́ 40 ojú ìwé 223-ojú ìwé 225 ìpínrọ̀ 3

Ẹ̀KỌ́ 40

Ọ̀rọ̀ Tó Jóòótọ́ Délẹ̀

Kí ló yẹ kí o ṣe?

Ó yẹ kí o jẹ́ kí ohun tí o máa sọ jẹ́ òótọ́ ọ̀rọ̀ délẹ̀.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

Bí ọ̀rọ̀ rẹ bá jẹ́ òótọ́ délẹ̀, ojú yìí làwọn èèyàn á máa fi wo ìwọ, ètò àjọ tó ò ń dara pọ̀ mọ́ àti Ọlọ́run tó ò ń sìn.

KÍ LÓ lè mú kí Kristẹni kan sọ ọ̀rọ̀ tí kì í ṣòótọ́? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àgbọ́sọ lásán ló ń tún sọ láìṣe ìwádìí bóyá ọ̀rọ̀ náà jóòótọ́ tàbí kì í ṣòótọ́. Tàbí kí ó ṣe àbùmọ́ ọ̀rọ̀ nítorí pé ó ṣi ibi tí ó kà lóye. Bí a bá ń fara balẹ̀ rí i pé ọ̀rọ̀ wa jẹ́ òótọ́ délẹ̀, àní nínú àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèké pàápàá, àwọn olùgbọ́ wa á fọkàn tán wa pé àwọn apá tó ṣe kókó nínú ọ̀rọ̀ tí a bá àwọn sọ jẹ́ òótọ́ ọ̀rọ̀ pẹ̀lú.

Lóde Ẹ̀rí. Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń lọ́ tìkọ̀ láti bẹ̀rẹ̀ sí jáde òde ẹ̀rí torí wọ́n gbà pé ìmọ̀ àwọn kò tíì tó nǹkan kan. Ṣùgbọ́n kì í pẹ́ tí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ fi máa ń rí i pé àwọn tiẹ̀ lè wàásù dáadáa bó tilẹ̀ jẹ́ pé òye àwọn ohun téèyàn máa ń kọ́kọ́ mọ̀ nípa òtítọ́ nìkan ni àwọn ṣì ní. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe é? Ìmúrasílẹ̀ loògùn rẹ̀.

Kí o tó lọ sóde ẹ̀rí, kọ́kọ́ rí i pé o mọ kókó ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ fi báni sọ̀rọ̀ dáadáa. Gbìyànjú láti ronú nípa àwọn ìbéèrè tó ṣeé ṣe kí ẹni tí o bá wàásù fún béèrè. Wá àwọn ìdáhùn tó lè tẹ́ ẹ lọ́rùn látinú Bíbélì. Èyí á jẹ́ kí o ti wà ní sẹpẹ́ láti fọkàn balẹ̀ fún wọn ní ìdáhùn tó jóòótọ́ délẹ̀. Ṣé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lo fẹ́ lọ darí? Fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ibi tí o fẹ́ fi kọ́ni. Rí i dájú pé o lóye ìdí tí àwọn ìdáhùn ìbéèrè ibẹ̀ fi bá Ìwé Mímọ́ mu.

Bí onílé tàbí ará ibi iṣẹ́ yín kan bá wá bi ọ́ ní ìbéèrè tí o kò múra sílẹ̀ fún ńkọ́? Bí kò bá dá ọ lójú pé o mọ ìdáhùn tó jóòótọ́ má ṣe méfò rárá. Bíbélì ní: “Ọkàn-àyà olódodo máa ń ṣe àṣàrò láti lè dáhùn.” (Òwe 15:28) O lè rí ohun tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú ìwé Reasoning From the Scriptures tàbí “Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò” bí wọ́n bá wà ní èdè tó o lè kà. Bí o kò bá ní èyíkéyìí nínú méjèèjì yìí, sọ fún onítọ̀hún pé o fẹ́ lọ ṣe ìwádìí ná kí o wá padà sọ ìdáhùn. Bó bá jẹ́ pé òótọ́ inú lẹni náà fi béèrè ìbéèrè rẹ̀ kò ní janpata rárá, yóò dúró dìgbà tó o bá lè fún un ní ìdáhùn tó tọ̀nà. Kódà, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó o ní tiẹ̀ tún lè wú u lórí pàápàá.

Bí o bá ń bá àwọn akéde tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù jáde òde ẹ̀rí, yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dẹni tó mọ bí a ti ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kíyè sí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n ń lò àti bí wọ́n ṣe ń ṣàlàyé. Fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gba ìmọ̀ràn tàbí ìtọ́sọ́nà yòówù kí wọ́n fún ọ. Ápólò, ọmọ ẹ̀yìn tó jẹ́ onítara, jàǹfààní ìrànlọ́wọ́ tó rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Lúùkù sọ pé Ápólò jẹ́ “sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀,” “ògbóǹkangí nínú Ìwé Mímọ́,” tí ‘iná ẹ̀mí ń jó nínú rẹ̀,’ tó sì “ń fi àwọn nǹkan nípa Jésù kọ́ni pẹ̀lú ìpérẹ́gí.” Síbẹ̀, ó ṣì ku àwọn nǹkan kan tí kò mọ̀. Nígbà tí Pírísílà àti Ákúílà kíyè sí èyí, wọ́n “mú un wọ àwùjọ ẹgbẹ́ wọn, wọ́n sì làdí ọ̀nà Ọlọ́run fún un lọ́nà tí ó túbọ̀ pé rẹ́gí.”—Ìṣe 18:24-28.

Ẹni Tó “Ń Di Ọ̀rọ̀ Ṣíṣeégbíyèlé Mú Ṣinṣin.” Ọ̀nà tí a gbà ń sọ̀rọ̀ wa nípàdé yẹ kó fi hàn pé a fọwọ́ pàtàkì mú jíjẹ́ tí ìjọ jẹ́ “ọwọ̀n àti ìtìlẹyìn òtítọ́.” (1 Tím. 3:15) Ó yẹ kí á rí i pé òye àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a fẹ́ lò nínú ọ̀rọ̀ wa yé àwa fúnra wa kí á bàa lè rọ̀ mọ́ òtítọ́. Kí á ronú nípa àlàyé ọ̀rọ̀ tí Ìwé Mímọ́ bá débi ẹsẹ yẹn àti ìdí tí a fi sọ̀rọ̀ yẹn níbẹ̀.

Ohun tó o sọ nípàdé lè di ohun táwọn èèyàn ń tún sọ. Òótọ́ ni pé “a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.” (Ják. 3:2) Ṣùgbọ́n bí o bá jẹ́ kó mọ́ ọ lára láti máa ṣe ohun tí wàá fi lè máa sọ ohun tó jóòótọ́ délẹ̀, yóò ṣe ọ́ láǹfààní. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn arákùnrin tó forúkọ sílẹ̀ nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ni yóò di alàgbà bó pẹ́ bó yá. Ojúṣe tí a sì ń retí pé kí ẹni tí a bá gbé irú ẹrù iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lé lọ́wọ́ máa ṣe yóò pọ̀ ‘púpọ̀ ju èyí tó ti ń ṣe látẹ̀yìnwá lọ.’ (Lúùkù 12:48) Bí alàgbà kan kò bá kíyè sára tó sì lọ fúnni nímọ̀ràn tó lọ yọrí sí ìṣòro ńlá fún àwọn ará nínú ìjọ, alàgbà ọ̀hún lè rí ìbínú Ọlọ́run. (Mát. 12:36, 37) Nípa bẹ́ẹ̀, ẹni tó máa tóótun láti di alàgbà ní láti jẹ́ ẹni tá a mọ̀ pé ó “ń di ọ̀rọ̀ ṣíṣeégbíyèlé mú ṣinṣin ní ti ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.”—Títù 1:9.

Rí i pé èrò tí o bá ń mú jáde bá “àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera” tó hàn jálẹ̀ òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ lódindi mu. (2 Tím. 1:13) Má ṣe jẹ́ kí èyí dẹ́rù bà ọ́ o. Bóyá o lè máà tíì ka Bíbélì tán látòkèdélẹ̀. Máa kà á nìṣó títí wàá fi kà á tán. Ṣùgbọ́n ní báyìí ná, kíyè sí bí àwọn àbá tó tẹ̀ lé e yìí yóò ṣe ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lè ṣàyẹ̀wò ìsọfúnni tí o fẹ́ lò láti fi kọ́ni.

Lákọ̀ọ́kọ́, bi ara rẹ léèrè pé: ‘Ǹjẹ́ ìsọfúnni yìí bá ohun tí mo ti kọ́ nínú Bíbélì mu? Ṣé yóò mú kí àwọn olùgbọ́ mi sún mọ́ Jèhófà, àbí ọgbọ́n ayé yìí ni yóò gbé lárugẹ, tí yóò máa gba àwọn èèyàn níyànjú láti máa fi í ṣamọ̀nà ara wọn?’ Jésù sọ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòh. 17:17; Diu. 13:1-5; 1 Kọ́r. 1:19-21) Lẹ́yìn náà wá lo àwọn ohun tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ tí ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye pèsè. Yàtọ̀ sí pé èyí á mú kí o lóye Ìwé Mímọ́ bó ṣe tọ́, yóò tún jẹ́ kí o lè ṣàlàyé wọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Bí o bá gbé ọ̀rọ̀ tí ò ń sọ karí “àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera” tí o sì gbára lé ipa ọ̀nà tí Jèhófà ń lò láti fi tọ́ wa nígbà tó o bá ń ṣe àlàyé Ìwé Mímọ́ tàbí nígbà tó o bá ń sọ ìlò rẹ̀, ọ̀rọ̀ rẹ á jóòótọ́ délẹ̀.

Ṣíṣèwádìí Nípa Bí Ìsọfúnni Tó O Rí Ṣe Jóòótọ́ Sí. Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́, ìsọfúnni tó o fà yọ látinú ibì kan àtàwọn ìrírí mìíràn lè wúlò gan-an bó o bá ń ṣe àpèjúwe ọ̀rọ̀ tàbí tí ò ń sọ bí a ṣe lè lo àwọn kókó kan. Báwo ni wàá ṣe mọ̀ pé ohun tó jóòótọ́ délẹ̀ lò ń sọ? Ọ̀nà kan tó o lè gbà ṣe é ni pé kí o rí i pé ibi tó o ti mú irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ ṣeé gbára lé. Má gbàgbé láti wádìí bóyá ìsọfúnni yẹn bá ìgbà mu tàbí kò bá a mu. Àwọn àkọsílẹ̀ oníṣirò lè máà bágbà mu mọ́; àlàyé tuntun ti lè wà lórí àwọn àwárí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì; bí aráyé sì ṣe túbọ̀ ń lóye ìtàn àti àwọn èdè ayé àtijọ́ sí i ni àtúnṣe ṣe ń dé bá àwọn àlàyé tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe. Ṣọ́ra gidigidi bí o bá ń gbèrò láti lo ìsọfúnni tó o rí nínú ìwé ìròyìn, tàbí èyí tó o gbọ́ lórí tẹlifíṣọ̀n, lórí rédíò, nínú lẹ́tà látorí ẹ̀rọ̀ kọ̀ǹpútà tàbí èyí tó o rí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Òwe 14:15 gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” Bí ara rẹ léèrè pé: ‘Ǹjẹ́ àwọn tó sọ ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ lò yìí jẹ́ àwọn tí a mọ̀ mọ́ sísọ ohun tó jóòótọ́ ọ̀rọ̀ délẹ̀? Ǹjẹ́ ọ̀nà mìíràn wà tí mo tún fi lè wádìí ìsọfúnni yìí wò láti mọ̀ bóyá ó jóòótọ́?’ Bí o bá ṣiyè méjì nípa bóyá ọ̀rọ̀ kan jóòótọ́, á dára kó o máà kúkú lò ó.

Yàtọ̀ sí wíwádìí nípa bóyá ìsọfúnni yẹn ṣeé gbára lé tàbí pé kò ṣeé gbára lé, fara balẹ̀ ronú nípa bí o ṣe fẹ́ lo ìsọfúnni yẹn. Rí i dájú pé bí o ṣe fẹ́ lo àwọn ọ̀rọ̀ tó o fà yọ tàbí àwọn àkọsílẹ̀ oníṣirò tó o fẹ́ lò kò yàtọ̀ sí àlàyé inú ibi tó o ti mú un wá. Bí o bá ń gbìyànjú láti tẹnu mọ́ kókó kan, má ṣe sọ ohun tá a kàn sọ pé “àwọn èèyàn kan” ń ṣe di ohun tí “ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn” ń ṣe, tàbí kí “ọ̀pọ̀ èèyàn” wá di “gbogbo èèyàn,” tàbí kó o wá sọ “nígbà mìíràn” di “ìgbà gbogbo.” Sísọ àsọdùn nípa ọ̀ràn kan tàbí ṣíṣe àbùmọ́ nínú ìròyìn tó jẹ mọ́ iye nọ́ńbà kan tàbí bí nǹkan kan ṣe tó tàbí bí ọ̀ràn kan ṣe le tó yóò mú káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí kọminú sí ọ̀rọ̀ tó ò ń sọ.

Bó o bá ń sọ ohun tó jóòótọ́ délẹ̀ nígbà gbogbo, wàá dẹni táwọn èèyàn mọ̀ sí ẹni tó fẹ́ràn òtítọ́. Ojú iyì yẹn ni wọ́n á sì máa fi wo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lápapọ̀. Paríparì rẹ̀ ni pé ó ń buyì kún “Jèhófà Ọlọ́run òtítọ́.”—Sm. 31:5.

BÍ O ṢE LÈ ṢE É

  • Má ṣe dáhùn ọ̀rọ̀ tí ìdáhùn rẹ̀ kò bá dá ọ lójú.

  • Gbé àlàyé ọ̀rọ̀ rẹ karí “àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera” tó wà nínú Bíbélì.

  • Ṣèwádìí lórí kókó ọ̀rọ̀ rẹ.

  • Ṣèwádìí láti mọ̀ bóyá àkọsílẹ̀ oníṣirò, ọ̀rọ̀ tó o fà yọ wá láti ibì kan, tàbí àwọn ìrírí tó o fẹ́ sọ, jóòótọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí o sì lò wọ́n láìsí àbùmọ́ kankan. Yẹra fún míméfò nípa àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé tí o kò rántí dáadáa.

ÌDÁNRAWÒ: Bẹ Ẹlẹ́rìí kan tó dàgbà dénú pé kó tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ láti wo bó ṣe jóòótọ́ sí, bí o ṣe ń fi ọ̀rọ̀ ara rẹ ṣàlàyé nípa: (1) Irú ẹni wo ni Jèhófà jẹ́, báwo lo sì ṣe mọ̀? (2) Kí nìdí tí Jésù fi fẹ̀mí ara rẹ̀ rúbọ, báwo ni a sì ṣe lè jàǹfààní nínú èyí? (3) Látìgbà tí Jésù Kristi ti gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba, kí ló ti ń ṣe?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́