ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ẹ̀kọ́ 52 ojú ìwé 265-ojú ìwé 267 ìpínrọ̀ 4
  • Gbígbani-níyànjú Lọ́nà Tó Múná Dóko

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbígbani-níyànjú Lọ́nà Tó Múná Dóko
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wàásù Pẹ̀lú Ìjẹ́kánjúkánjú!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Ìfẹ́ Ará Jẹ́ Agbékánkánṣiṣẹ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • ‘Gbigbani Niyanju Lori Ipilẹ Ifẹ’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Títù, Fílémónì àti Hébérù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ẹ̀kọ́ 52 ojú ìwé 265-ojú ìwé 267 ìpínrọ̀ 4

Ẹ̀KỌ́ 52

Gbígbani-níyànjú Lọ́nà Tó Múná Dóko

Kí ló yẹ kí o ṣe?

Ó yẹ kí o lo àlàyé ọ̀rọ̀ tàbí ìmọ̀ràn láti orísun kan tó ṣeé gbára lé, tó sì ń yíni lọ́kàn padà, láti fi sún àwọn èèyàn ṣiṣẹ́ lórí nǹkan kan. Èyí ń béèrè pé kéèyàn fi ìtara ọkàn sọ̀rọ̀.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

Bí a bá ń gbani níyànjú lọ́nà tó múná dóko, ó máa ń jẹ́ kí àwọn èèyàn rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn máa ṣe nǹkan tí yóò mú inú Jèhófà dùn.

Ó YẸ kí àwọn Kristẹni alàgbà lè lo “ẹ̀kọ́ afúnni-nílera” láti fi “gbani níyànjú.” (Títù 1:9) Nígbà mìíràn ó lè jẹ́ àkókò ìṣòro lílekoko ni a óò ní láti gbani níyànjú. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó ṣe pàtàkì pé kí ìmọ̀ràn tí a máa fúnni bá ìlànà Ìwé Mímọ́ mu. Nípa bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí àwọn alàgbà kọbi ara sí ìmọ̀ràn tó sọ pé: “Máa bá a lọ ní fífi ara rẹ . . . fún ìgbani-níyànjú.” (1 Tím. 4:13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alàgbà tàbí àwọn tó ń nàgà láti di alàgbà ni à ń darí ọ̀rọ̀ wa ibí yìí sí ní tààràtà, ìgbà mìíràn máa ń wà tí àwọn òbí ní láti gba ọmọ wọn níyànjú tàbí kí ẹni tó ń báni ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rí i pé ó yẹ kí òun gba ẹni tóun ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níyànjú. Ní irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀, àwọn ìlànà yìí kan náà la ó lò.

Àwọn Ipò Tó Ti Yẹ Ká Gbani Níyànjú. Láti lè mọ ìgbà tó yẹ ká gbani níyànjú, ó dára ká gbé àwọn ipò tí a ti gbani níyànjú nínú Bíbélì yẹ̀ wò. Àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn alàgbà níyànjú pé kí wọ́n túbọ̀ jára mọ́ ṣíṣe ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run. (1 Pét. 5:1, 2) Pọ́ọ̀lù gba Títù nímọ̀ràn pé kí ó gba àwọn ọ̀dọ́kùnrin níyànjú láti “yè kooro ní èrò inú.” (Títù 2:6) Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n “máa sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan” kí wọ́n sí yẹra fún àwọn tó bá fẹ́ máa fa ìyapa láàárín àwọn ará. (1 Kọ́r. 1:10; Róòmù 16:17; Fílí. 4:2) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù yin àwọn ará inú ìjọ Tẹsalóníkà fún ohun rere tí wọ́n ń ṣe, ó gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n túbọ̀ máa tẹ̀ lé ìtọ́ni tí wọ́n gbà ní kíkún. (1 Tẹs. 4:1, 10) Pétérù rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n “máa ta kété sí àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ara.” (1 Pét. 2:11) Júúdà gba àwọn arákùnrin rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n “máa ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́” nítorí kí àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n ń hùwà àìníjàánu má bàa kéèràn ràn wọ́n. (Júúdà 3, 4) A rọ gbogbo àwọn Kristẹni lápapọ̀ pé kí wọ́n máa gba ara wọn níyànjú kí ìtannijẹ ẹ̀ṣẹ̀ má bàa sọ ẹnikẹ́ni nínú wọn di aláyà líle. (Héb. 3:13) Pétérù gba àwọn Júù tí wọn kò tíì gba Kristi gbọ́ níyànjú pé: “Ẹ gba ara yín là kúrò lọ́wọ́ ìran oníwà wíwọ́ yìí.”—Ìṣe 2:40.

Irú ànímọ́ wo ló yẹ kí èèyàn ní kí ó tó lè gbani níyànjú dáadáa nínú irú àwọn ipò wọ̀nyẹn? Báwo ni ẹni tó ń gbani níyànjú yóò ṣe fi hàn pé ọ̀rọ̀ náà jẹ́ kánjúkánjú láìbú mọ́ àwùjọ tàbí kí ó dá wọn lágara?

“Nítorí Ìfẹ́.” Bí kì í bá ṣe “nítorí ìfẹ́” la fi ń gbani níyànjú, ọ̀rọ̀ wa lè le koko. (Fílém. 9) Lóòótọ́, bí ọ̀ràn kan bá gba gbígbé ìgbésẹ̀ lójú-ẹsẹ̀, ó yẹ kí ọ̀nà tí olùbánisọ̀rọ̀ máa gbà sọ̀rọ̀ fi hàn pé ọ̀ràn yẹn jẹ́ kánjúkánjú. Bí ó bá fi ohùn tó dẹ̀ sọ ọ́, ńṣe ni yóò dà bí pé ó ń tu àwùjọ lójú kí wọ́n máà bínú. Síbẹ̀ ó yẹ kí á fi ìtara ọkàn àti ìgbatẹnirò rọ àwùjọ ni. Tí a bá rọ àwùjọ tìfẹ́tìfẹ́, ìyẹn lè túbọ̀ ta wọ́n jí. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ fún àwọn ará Tẹsalóníkà nípa ohun tí òun àtàwọn ẹlẹgbẹ́ òun ń ṣe, ó ní: “Ẹ̀ mọ̀ dáadáa bí a tí ń bá a nìṣó ní gbígba ẹnì kọ̀ọ̀kan yín níyànjú, . . . bí baba ti ń ṣe sí àwọn ọmọ rẹ̀.” (1 Tẹs. 2:11) Tìfẹ́tìfẹ́ làwọn Kristẹni alábòójútó wọ̀nyẹn fi pàrọwà fún àwọn arákùnrin wọn. Nípa báyìí, ẹ̀mí pé ọ̀ràn àwọn olùgbọ́ rẹ jẹ ọ́ lógún gidigidi ló yẹ kó sún ọ sọ̀rọ̀.

Lo ọgbọ́n inú. Má ṣe dá àwọn tí ò ń rọ̀ láti ṣe nǹkan kan lágara. Lẹ́sẹ̀ kan náà, má ṣe fà sẹ́yìn “nínú sísọ gbogbo ìpinnu Ọlọ́run” fún àwọn olùgbọ́ rẹ. (Ìṣe 20:27) Àwọn tó mọrírì ohun tó o sọ nínú àwùjọ kò ní bínú sí ọ tàbí kí wọ́n má fi bẹ́ẹ̀ fẹ́ràn rẹ mọ́ tìtorí pé o fi inúure rọ̀ wọ́n láti ṣe ohun tó tọ́.—Sm. 141:5.

Ó sábà máa ń dára pé ká kọ́kọ́ gbóríyìn fúnni tọkàntọkàn lórí nǹkan pàtó tónítọ̀hún ṣe kí ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wá tẹ̀ lé e. Ronú nípa àwọn nǹkan rere tí àwọn arákùnrin rẹ ń ṣe, ìyẹn àwọn nǹkan tó mú inú Jèhófà dùn dáadáa, irú bíi: bí wọ́n ṣe fi ìgbàgbọ́ hàn nínú iṣẹ́ wọn, bí ìfẹ́ ṣe ń sún wọn láti máa sapá nínú ìjọsìn wọn àti ìfaradà wọn nínú ìpọ́njú. (1 Tẹs. 1:2-8; 2 Tẹs. 1:3-5) Èyí á jẹ́ kí àwọn arákùnrin rẹ mọ̀ pé o fọwọ́ pàtàkì mú àwọn àti pé o mọ bí nǹkan ṣe rí fún wọn, ìyẹn á sì jẹ́ kí wọ́n ṣe tán láti kọbi ara sí ọ̀rọ̀ ìyànjú tí o bá sọ lẹ́yìn náà.

“Pẹ̀lú Gbogbo Ìpamọ́ra.” Ńṣe ló yẹ ká máa gbani níyànjú “pẹ̀lú gbogbo ìpamọ́ra.” (2 Tím. 4:2) Báwo la ó ṣe ṣe èyí? Lára ohun tó so mọ́ ìpamọ́ra ni pé ká fi sùúrù fara da ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́nì kan ṣẹ̀ wá tàbí ohun tó ṣe tó bí wa nínú. Ẹni tó bá ní ìpamọ́ra kò ní fìgbà kankan sọ̀rètí nù nípa pé àwọn olùgbọ́ òun yóò fi ohun tóun sọ sílò. Bí o bá fi ẹ̀mí ìpamọ́ra gbani níyànjú, kò ní jẹ́ kí àwọn olùgbọ́ rẹ máa rò ó pé o kúkú ti gbà pé àwọn ò wúlò rárá. Fífi tí o fi ìdánilójú hàn pé àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ ń fẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti sin Jèhófà yóò mú kó wù wọ́n láti ṣe ohun tó tọ́.—Héb. 6:9.

“Pẹ̀lú Ẹ̀kọ́ Afúnni-nílera.” Báwo ni alàgbà kan ṣe lè “gbani níyànjú pẹ̀lú ẹ̀kọ́ afúnni-nílera”? Ó jẹ́ nípa dídi “ọ̀rọ̀ ṣíṣeégbíyèlé mú ṣinṣin ní ti ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.” (Títù 1:9) Dípò tí wàá fi máa sọ èrò ara rẹ, fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe agbára ọ̀rọ̀ ìyànjú rẹ. Jẹ́ kí Bíbélì là ọ́ lóye ohun tó yẹ kí o sọ. Sọ àwọn àǹfààní tó wà nínú fífi ohun tí Bíbélì sọ nípa kókó tó ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí sílò. Jẹ́ kí ìyọnu tó lè dé báni nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú nítorí àìhùwà tó bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu yé ọ dáadáa. Kí o sì wá lò ó láti mú kí àwùjọ rí i pé ó ṣe pàtàkì lóòótọ́ pé káwọn gbé ìgbésẹ̀ tí ó tọ́.

Rí i dájú pé àlàyé rẹ nípa ohun tó yẹ kí àwọn olùgbọ́ ṣe àti bí wọ́n ṣe máa ṣe é yé wọn yékéyéké. Mú kó ṣe kedere pé orí Ìwé Mímọ́ lo gbé àlàyé rẹ kà délẹ̀délẹ̀. Bí Ìwé Mímọ́ bá gbà kí kálukú ṣe ìpinnu tó bá wù ú lórí ọ̀ràn náà, sọ ìwọ̀n ibi tó yọ̀ǹda dé. Níparí ọ̀rọ̀ rẹ kí o wá rọ àwọn olùgbọ́ rẹ dáadáa kí ìpinnu wọn láti ṣiṣẹ́ lórí ohun tó o sọ fi lè túbọ̀ lágbára sí i.

Pẹ̀lú “Òmìnira Ọ̀rọ̀ Sísọ.” Láti lè gbani níyànjú lọ́nà tó múná dóko, ẹni tó ń gbani níyànjú ní láti ní “òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ńláǹlà nínú ìgbàgbọ́.” (1 Tím. 3:13) Kí ló máa ń jẹ́ kí èèyàn lè fi òmìnira sọ̀rọ̀? Òun ni pé kí “àpẹẹrẹ àwọn iṣẹ́ àtàtà” ẹni náà fúnra rẹ̀ bá ohun tó ń rọ àwọn ará láti ṣe mu. (Títù 2:6, 7; 1 Pét. 5:3) Bó bá lè rí bẹ́ẹ̀, àwọn tó ń gbà níyànjú yóò rí i pé kì í ṣe pé ó ń fẹ́ kí àwọn máa ṣe ohun tí òun fúnra rẹ̀ kì í ṣe. Wọ́n á rí i pé àwọn lè fara wé ìgbàgbọ́ rẹ̀ bí òun pẹ̀lú ṣe ń ṣakitiyan láti fara wé Kristi.—1 Kọ́r. 11:1; Fílí. 3:17.

Bí a bá gbé ọ̀rọ̀ ìyànjú wa karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a sì sọ ọ́ tìfẹ́tìfẹ́, yóò súnni ṣiṣẹ́ gan-an ni. Ǹjẹ́ kí àwọn tí a fún ní ẹrù iṣẹ́ gbígbani-níyànjú máa làkàkà láti ṣe ojúṣe wọn dáadáa.—Róòmù 12:8.

BÍ O ṢE LÈ ṢE É

  • Lo ìfẹ́ àti ìpamọ́ra, kí o sì fi ìtara ọkàn sọ̀rọ̀.

  • Gbé ọ̀rọ̀ ìyànjú rẹ karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀.

  • Fi àpẹẹrẹ rere rẹ ṣètìlẹ́yìn gbígbani tí ò ń gbani níyànjú.

ÌDÁNRAWÒ: Ka ìwé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sí Fílémónì. Wá kókó wọ̀nyí níbẹ̀: (1) bí ó ṣe gbóríyìn fúnni dáadáa níbẹ̀, (2) ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi ń bẹ̀bẹ̀ nítorí Ónẹ́símù, (3) àlàyé tí Pọ́ọ̀lù ṣe láti jẹ́ kí Fílémónì rí ìdí tó fi yẹ kó tẹ́wọ́ gba ẹrú rẹ̀ tó padà wálé, àti (4) bí Pọ́ọ̀lù ṣe ní ìdánilójú pé Fílémónì yóò ṣe ohun tó tọ́. Ronú nípa bí o ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ yìí nígbà tí o bá ń gbani níyànjú.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́