Wàásù Pẹ̀lú Ìjẹ́kánjúkánjú!
1. Ọ̀rọ̀ ìyànjú Pọ́ọ̀lù wo ló yẹ ká fún láfiyèsí lóde òní?
1 “Wàásù ọ̀rọ̀ náà, wà lẹ́nu rẹ̀ ní kánjúkánjú.” (2 Tím. 4:2) Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ ìyànjú Pọ́ọ̀lù yìí fi ṣe pàtàkì fún wa lónìí? Báwo ni ọ̀rọ̀ yìí ṣe lè nípa lórí ìgbésí ayé wa àti tàwọn ẹlòmíì?
2. Kí nìdí tá a fi ń sapá láti wá àwọn tí kò tíì gbọ́ ìhìn rere?
2 Ọ̀ràn Ẹ̀mí Ni: Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kárí ayé ni kò tíì gbọ́ ìhìn rere tó lè mú kí wọ́n rí ìgbàlà. (Róòmù. 10:13-15; 1 Tím. 4:16) A máa ń rí ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ọkàn láwọn ìpínlẹ̀ tá a ti máa ń wàásù déédéé. Tá a bá lọ wàásù nírú ìpínlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ tàbí àkókò tó yàtọ̀ sí èyí tá a máa ń lọ wàásù níbẹ̀, ó ṣeé ṣe ká pàdé àwọn tá a kì í sábà rí níbẹ̀ tẹ́lẹ̀. Tá a bá sapá láti wá àwọn èèyàn lọ́nà yìí, ẹ̀rí ọkàn wa kò ní máa dá wa lẹ́bi, a ò sì ní jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀.—Ìṣe 20:26.
3. Báwo la ṣe lè fi ọgbọ́n lo àkókò wa lóde ẹ̀rí?
3 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní dojú kọ àtakò gbígbóná janjan, síbẹ̀ wọ́n ‘fi ẹ̀kọ́ wọn kún Jerúsálẹ́mù.’ (Ìṣe 5:28) Ṣé àwa náà ti pinnu “láti jẹ́rìí kúnnákúnná”? (Ìṣe 10:42) Tá a bá wà lóde ẹ̀rí, ṣé a máa ń fọgbọ́n lo àkókò wa? Tó bá ṣẹlẹ̀ pé à ń dúró de àwọn ará tó kù nítorí àwọn ìdí kan, ǹjẹ́ a máa ń lo ìdánúṣe láti fi àkókò yẹn bá àwọn tó ń kọjá lọ sọ̀rọ̀?
4. Báwo ni wíwàásù pẹ̀lú ìjẹ́kánjúkánjú ṣe ń mú ká máa ṣọ́nà?
4 Ó Ń Jẹ́ Ká Túbọ̀ Wà Lójúfò: Bí òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ti ń sún mọ́lé, a gbọ́dọ̀ wà lójúfò, ká sì máa ṣọ́nà. (1 Tẹs. 5:1-6) Tá a bá ń fìgbà gbogbo bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ìrètí Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn kò ní jẹ́ ká dẹni tí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí dẹrù pa. (Lúùkù 21:34-36) Kàkà bẹ́ẹ̀, bá a bá ń fi ọjọ́ Jèhófà “sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí,” èyí á mú ká lè máa fi kún ipa tá à ń kó nínú iṣẹ́ ìwàásù tó jẹ́ iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà.—2 Pét. 3:11, 12.
5. Báwo ni ọ̀wọ̀ fún ìwàláàyè ṣe ń nípa lórí iṣẹ́ ìwàásù wa?
5 Tá a bá ń wàásù pẹ̀lú ìjẹ́kánjúkánjú, ìyẹn ń fi hàn pé ojú tí Jèhófà fi ń wo ìwàláàyè làwa náà fi ń wò ó. Bíbélì sọ pé: “Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pét. 3:9; Ìsík. 33:11) Ǹjẹ́ ká fi ṣe àfojúsùn wa pé a óò wá gbogbo àwọn tó bá ṣeé ṣe fún wa láti rí kàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, sí ìyìn Jèhófà!—Sm. 109:30.