ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • T-25 ojú ìwé 2-6
  • Ǹjẹ́ Ẹ̀mí Èèyàn Máa Ń Kú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ẹ̀mí Èèyàn Máa Ń Kú?
  • Ǹjẹ́ Ẹ̀mí Èèyàn Máa Ń Kú?
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Ẹ̀mí?
  • ‘Ìwọ Yóò Padà sí Ekuru’
  • Ẹ̀mí Náà ‘Yóò Padà Sọ́dọ̀ Ọlọ́run Tòótọ́’
  • Ìrètí Tó Dájú
  • Ǹjẹ́ Ẹ̀mí Èèyàn Máa Ń Kú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Kí Ni “Ọkàn” àti “Ẹ̀mí” Jẹ́ Gan-an?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Ọkàn Nígbà Ikú?
    Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
  • Awọn Ẹmi Ko Gbe Ki Wọn si Kú Rí Lori Ilẹ Aye
    Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha wa Niti Gidi Bi?
Àwọn Míì
Ǹjẹ́ Ẹ̀mí Èèyàn Máa Ń Kú?
T-25 ojú ìwé 2-6

Ǹjẹ́ Ẹ̀mí Èèyàn Máa Ń Kú?

ṢÉ ÈÈYÀN tún máa ń wà láàyè lẹ́yìn tó bá kú ni? Ìbéèrè yẹn ti ń jà gùdù lọ́kàn aráyé fún ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rún ọdún. Látọdún gbọ́nhan làwọn èèyàn ní oríṣiríṣi àwùjọ ti ronú jinlẹ̀ lórí kókó ọ̀rọ̀ yìí, èyí sì ti mú kí wọ́n ní onírúurú ìgbàgbọ́.

Jákèjádò ayé, títí kan agbègbè Pàsífíìkì ní Polynesia, Melanesia, àti Micronesia, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ pé béèyàn bá tiẹ̀ kú, “ẹ̀mí” rẹ̀ ṣì wà láàyè. Àmọ́, ǹjẹ́ ohun kan tó wà nínú èèyàn máa ń fi ara sílẹ̀ béèyàn bá kú tí á sì máa wà láàyè nìṣó? Kí ni ẹ̀mí tó wà nínú ènìyàn? Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí i bí a bá kú? Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí, fún wa láwọn ìdáhùn tòótọ́ sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí, àwọn ìdáhùn náà sì ǹ tẹ́ni lọ́rùn.

Kí Ni Ẹ̀mí?

Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà táa tú sí “ẹ̀mí” wulẹ̀ túmọ̀ sí “èémí.” Àmọ́ èyí ju kìkì ọ̀ràn mímí lọ. Fún àpẹẹrẹ, òǹkọ̀wé Bíbélì náà Jákọ́bù sọ pé: “Ara láìsí . . . ẹ̀mí jẹ́ òkú.” (Jákọ́bù 2:26) Nítorí náà, ẹ̀mí ni ohun tó ń mú kí ara ṣiṣẹ́.

Ipá tó ń mú kí ara ṣiṣẹ́ yìí kò wulẹ̀ lè jẹ́ èémí, tàbí atẹ́gùn, tó ń lọ káàkiri inú ẹ̀dọ̀fóró. Kí ló dé tí kò fi lè jẹ́ èémí? Nítorí pé bí èémí bá dáwọ́ dúró, ìwàláàyè á ṣì wà nínú àwọn sẹ́ẹ̀lì ara fún ìgbà díẹ̀—“fún ìṣẹ́jú bíi mélòó kan,” gẹ́gẹ́ bí The World Book Encyclopedia ṣe sọ. Fún ìdí yìí, ó ṣì ṣeé ṣe láti mú un sọjí, wọ́n sì lè yọ àwọn ẹ̀yà ara ẹnì kan kí wọ́n fi sára ẹlòmíràn. Àmọ́ bí ẹ̀mí tó ń mú kí ìwàláàyè ṣeé ṣe bá kúrò nínú àwọn sẹ́ẹ̀lì ara, òfúùtùfẹ́ẹ̀tẹ̀ ni gbogbo akitiyan láti mú ẹni yẹn sọ jí máa já sí. Kò sí iye èémí tó lè mú sẹ́ẹ̀lì kan péré sọ jí. Nígbà náà, ẹ̀mí jẹ́ agbára ìwàláàyè tí kò ṣeé fojú rí—ohun tó mú kí ìwàláàyè ṣeé ṣe—tó ń mú kí àwọn sẹ́ẹ̀lì ṣiṣẹ́. Èémí ló ń gbé agbára ìwàláàyè yìí ró.—Jóòbù 34:14, 15.

Ṣé inú èèyàn nìkan ni ẹ̀mí yẹn ti ń ṣiṣẹ́ ni? Bíbélì ràn wá lọ́wọ́ láti ní èrò tó tọ̀nà nípa ọ̀ràn yìí. Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba kọ̀wé pé: “Ta ní ń bẹ tí ó mọ ẹ̀mí àwọn ọmọ aráyé, bóyá ó ń gòkè lọ sókè; àti ẹ̀mí ẹranko, bóyá ó ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sísàlẹ̀ ilẹ̀?” (Oníwàásù 3:21) Nítorí náà, àtèèyàn àtẹranko la sọ pé wọ́n ní ẹ̀mí. Báwo ló ṣe lè jẹ́ bẹ́ẹ̀?

A lè fi ẹ̀mí, tàbí agbára ìwàláàyè wé agbára iná mànàmáná tó ń lọ tó ń bọ̀ nínú ẹ̀rọ kan tàbí nínú ohun èèlò tó ń lo iná. Iná mànàmáná tí a kò lè rí náà ni a lè lò fún oríṣiríṣi nǹkan, ó sinmi lórí irú ohun èèlò tó ń mú ṣiṣẹ́. Fún àpẹẹrẹ, ó lè mú kí sítóòfù mú nǹkan gbóná, ó lè mú kí ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà pèsè àwọn ìsọfúnni kó sì ṣe àwọn ìṣirò, ó sì lè mú kí tẹlifíṣọ̀n mú àwòrán àti ohùn jáde. Síbẹ̀, agbára iná mànàmáná yìí kò lè wá sọ ara rẹ̀ di ohun èèlò tí ó ń mú ṣiṣẹ́. Agbára tó ń mú nǹkan ṣiṣẹ́ ni. Bákan náà, agbára ìwàláàyè kì í sọ ara rẹ̀ di èyíkéyìí lára àwọn ẹ̀dá tó ń mú wà láàyè. Kò mọ béèyàn ṣe ń hùwà, kò sì mọ inú rò. Àtèèyàn àtẹranko ‘ẹ̀mí kan ṣoṣo ni gbogbo wọ́n ní.’ (Oníwàásù 3:19) Nítorí náà, bí ẹnì kan bá kú, ẹ̀mí rẹ̀ kì í lọ gbé ní ibòmíràn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí.

Ipò wo wá làwọn òkú wà? Kí ló sì máa ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀mí nígbà tí ẹnì kan bá kú?

‘Ìwọ Yóò Padà sí Ekuru’

Nígbà tí ọkùnrin àkọ́kọ́ náà, Ádámù, mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí òfin Ọlọ́run, Jèhófà sọ fún un pé “Inú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò ti máa jẹ oúnjẹ títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí láti inú rẹ̀ ni a ti mú ọ jáde. Nítorí ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Ibo ni Ádámù wà kí Jèhófà tó dáa láti inú ekuru? Kò mà sí níbì kankan o! Àní kò fìgbà kankan wà rí. Nítorí náà nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run sọ pé Ádámù yóò “padà sí ilẹ̀,” ohun tí ó ń sọ ni pé Ádámù yóò kú. Kì í ṣe pé Ádámù yóò ré kọjá sí ilẹ̀ ẹ̀mí. Nígbà tó bá kú yóò padà di aláìlẹ́mìí, kò ní sí mọ́. Ikú ni ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀—tí í ṣe àìsí—kì í ṣe ìpapòdà sí ibòmíràn.—Róòmù 6:23.

Àwọn tí wọ́n ti kú ńkọ́? A mú ipò táwọn òkú wà ṣe kedere nínú Oníwàásù 9:5, 10, níbi tí a ti kà pé “Òkú kò mọ nǹkan kan . . . Kò sí ìlépa ohunkóhun, kò sí ìpète, kò sí ìmọ̀ tàbí làákàyè kankan nínú ibojì.” (Moffatt) Nípa bẹ́ẹ̀, ikú jẹ́ àìsí. Onísáàmù náà kọ ọ́ pé nígbà tí ẹnì kan bá kú, “ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.”—Sáàmù 146:4.

Ó hàn gbangba pé, àwọn òkú kò mọ ohunkóhun, wọn ò lè ta pútú. Wọn kò lè rí ọ, wọn kò lè gbọ́ ohun tí o ń sọ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè bá ọ sọ̀rọ̀. Wọn kò lè ràn ọ́ lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè pa ọ́ lára. Dájúdájú, kò yẹ kí o máa bẹ̀rù àwọn òkú. Àmọ́ báwo lẹ̀mí ẹnì kan ṣe lè “jáde lọ” nígbà tí onítọ̀hún bá kú?

Ẹ̀mí Náà ‘Yóò Padà Sọ́dọ̀ Ọlọ́run Tòótọ́’

Bíbélì sọ pé nígbà tí ẹnì kan bá kú, ‘ẹ̀mí yóò padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ tí ó fi í fúnni.’ (Oníwàásù 12:7) Èyí ha túmọ̀ sí pé ńṣe ni ẹ̀mí kan máa ń gba òfuurufú lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run ní ti gidi bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́ o! Ọ̀nà tí Bíbélì gbà lo ọ̀rọ̀ náà “padà” kò béèrè pé kí nǹkan rìn láti ibì kan lọ sí ibòmíràn ní ti gidi. Fún àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ pé: “‘Ẹ padà sọ́dọ̀ mi, dájúdájú, èmi yóò sì padà sọ́dọ̀ yín,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.” (Málákì 3:7) ‘Pípadà’ tí Ísírẹ́lì yóò padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run túmọ̀ sí pípadà kúrò nínú ipa ọ̀nà tó lòdì kí wọ́n sì wá mú ara wọn bá ipa ọ̀nà òdodo Ọlọ́run mu lẹ́ẹ̀kan sí i. ‘Pípadà’ tí Jèhófà náà yóò padà sọ́dọ̀ Ísírẹ́lì túmọ̀ sí pípadà fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní àfiyèsí tí yóò ṣe wọ́n láǹfààní lẹ́ẹ̀kan sí i. Nínú àwọn ọ̀ràn méjèèjì, “padà” ní í ṣe pẹ̀lú ìwà, kì í ṣe rírìn láti àgbègbè kan lọ sí òmíràn.

Bákan náà, nígbà téèyàn bá kú, kò sí gbígbéra láti ayé lọ sí ọ̀run nígbà tí ẹ̀mí bá “padà” sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Rántí pé, ẹ̀mí jẹ́ agbára ìwàláàyè. Bí agbára yẹn bá ti kúrò lára ẹnì kan, Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló ní agbára láti dá a padà fún ẹni náà. Nítorí náà, ẹ̀mí “padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́” ní ti pé ọwọ́ Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni ìrètí èyíkéyìí wà pé onítọ̀hún lè padà wà láàyè lọ́jọ́ ọ̀la.

Fún àpẹẹrẹ, ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa ikú Jésù. Òǹkọ̀wé ìhìn rere náà Lúùkù sọ pé: “Jésù sì fi ohùn rara kígbe, ó sì wí pé: ‘Baba, ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.’ Nígbà tí ó ti sọ èyí, ó gbẹ́mìí mì.” (Lúùkù 23:46) Bí ẹ̀mí Jésù ṣe fi ara rẹ̀ sílẹ̀, kì í ṣe pé ó lọ sí ọ̀run. Ọjọ́ kẹta la tó jí Jésù dìde nínú ikú. Ogójì ọjọ́ gbáko ló sì lò kó tó gòkè lọ sí ọ̀run. (Ìṣe 1:3, 9) Bó ti wù kó rí, nígbà ikú rẹ̀, pẹ̀lú ìgbọ́kànlé ni Jésù fi fi ẹ̀mí rẹ̀ síkàáwọ́ Bàbá rẹ̀, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ní kíkún pé ó ní agbára láti mú òun padà wà láàyè.

Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọlọ́run nìkan ló lè mú kéèyàn padà wà láàyè. (Sáàmù 104:30) Àǹfààní ìrètí gígadabú mà lèyí ṣí sílẹ̀ fún wa o!

Ìrètí Tó Dájú

Bíbélì sọ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù] wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù Kristi ṣèlérí pé gbogbo àwọn tó wà ní ìrántí Jèhófà la óò jí dìde, tàbí mú padà wà láàyè. Dípò ṣíṣe ìkéde tó ń bani nínú jẹ́ pé àwọn èèyàn kú, ìkéde tó ń múni yọ̀ pé a ti jí àwọn èèyàn dìde la óò máa gbọ́. Ẹ ò rí bí yóò ṣe dùn tó láti kí àwọn èèyàn wa káàbọ̀ láti inú sàréè!

Ṣé o fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí o ṣe lè jàǹfààní nínú ìrètí tí Ọlọ́run fúnni yìí? A rọ̀ ọ́ láti kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ fún ẹ̀dà kan ìwé pẹlẹbẹ Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?

Bí a kò bá fi hàn pé ó yàtọ̀, gbogbo ẹsẹ Bíbélì wá láti inú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́