APÁ 2
“JÈHÓFÀ NÍFẸ̀Ẹ́ ÌDÁJỌ́ ÒDODO”
Ìwà ìrẹ́jẹ wọ́pọ̀ gan-an láyé yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì gbà pé Ọlọ́run ló fà á. Síbẹ̀, Bíbélì kọ́ wa ní òótọ́ kan tó fini lọ́kàn balẹ̀. Òótọ́ náà ni pé “Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo.” (Sáàmù 37:28) Nínú apá yìí, a máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo lóòótọ́ àti pé òun máa mú ìwà ìrẹ́jẹ kúrò títí láé.