ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • kp ojú ìwé 6-8
  • Kí Ni Gbogbo Rẹ̀ Túmọ̀ sí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Gbogbo Rẹ̀ Túmọ̀ sí?
  • Ẹ Máa Ṣọ́nà!
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn” La Wà Yìí?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ète Ọlọrun Yoo Ní Imuṣẹ Laipẹ
    Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?
  • Ìhìn Rere Tí Wọ́n Ń Fẹ́ Kí O Gbọ́
    Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n? Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́?
  • Àwọn Àmì Wo Ló Fi Hàn Pé A Ti Wà Ní “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn,” Tàbí “Òpin Ayé”?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Ẹ Máa Ṣọ́nà!
kp ojú ìwé 6-8

Kí Ni Gbogbo Rẹ̀ Túmọ̀ sí?

JÉSÙ KRISTI sọ pé ogun, àìtó oúnjẹ, àjàkálẹ̀ àrùn àti ìsẹ̀lẹ̀ la ó fi mọ̀ pé a ti wà ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.”—Mátíù 24:1-8; Lúùkù 21:10, 11.

Láti ọdún 1914, ogun láàárín orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè àti ogun ẹlẹ́yàmẹ̀yà ò yéé ba ìgbésí ayé jẹ́ fáwọn èèyàn, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì máa ń jẹ́ nítorí pé àwọn aṣáájú ìsìn ń dá sí ìṣèlú, àmọ́ báyìí, wàhálà àwọn apániláyà ló gbayé kan.

Pẹ̀lú gbogbo ìtẹ̀síwájú tó ń wáyé lágbo ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, ìyàn tó mú hánhán ṣì ń fojú ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn rí màbo jákèjádò ayé. Ọdọọdún ni ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ń kú nítorí àìrí oúnjẹ jẹ tó.

Àjàkálẹ̀ àrùn tún wà lára àmì tí Jésù sọ. Àwọn èèyàn tí àrùn gágá gbẹ̀mí wọn lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kìíní parí lé ní mílíọ̀nù mọ́kànlélógún. Láìdàbí àwọn àrùn tó kàn máa ń jà láàárín àwọn àgbègbè kan nígbà kan sẹ́yìn, gbogbo orílẹ̀-èdè pátá làrùn náà jà dé, kódà kò yọ àwọn erékúṣù jíjìnnà réré sílẹ̀. Àrùn éèdì ló wá ń gbẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn káàkiri ayé báyìí, bẹ́ẹ̀ sì làwọn àrùn bí ikọ́ ẹ̀gbẹ, ibà, ìfọ́jú inú odò àti àrùn sunrunsunrun kò yéé ṣàwọn èèyàn lọ́ṣẹ́ láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà.

Ìròyìn sọ pé ẹgbẹẹgbàárùn-ún ìsẹ̀lẹ̀ tó rinlẹ̀ jura wọn lọ ló ń ṣẹlẹ̀ lọ́dọọdún. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn irinṣẹ́ wà, tí àwọn ọ̀nà tó túbọ̀ dára gan-an sì wà láti fi máa sọ àwọn ibi tí ìsẹ̀lẹ̀ á ti wáyé, ìgbà gbogbo là ń gbọ́ ìròyìn nípa àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ láwọn àgbègbè tèèyàn pọ̀ sí gan-an.

Bíbélì tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Mọ èyí, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀; yà kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.”—2 Tímótì 3:1-5.

Ǹjẹ́ ìwọ náà ò gbà pé “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” là ń gbé yìí?

Ṣé o ti kíyè sí i pé, dé ìwọ̀n tó ré kọjá ààlà làwọn èèyàn fi jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, tí ìgbéraga sì ti wọ̀ wọ́n lẹ́wù?

Ta ló máa jiyàn rẹ̀ pé àwọn anìkànjọpọ́n èèyàn tí wọn ò tún mọ ọpẹ́ dá, tí wọn ò ṣeé bá ṣe àdéhùn kankan tí wọ́n sì jẹ́ aláìdúróṣinṣin, ló kúnnú ayé báyìí?

Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ṣíṣàìgbọràn sí òbí àti ṣíṣàìnífẹ̀ẹ́ ẹlòmíràn ti pọ̀ sí i, kì í ṣe níwọ̀nba ibi díẹ̀ péré, àmọ́ káàkiri ayé?

Ó dájú pé ìwọ náà mọ̀ pé inú ayé tí ìfẹ́ adùn ti gba àwọn èèyàn lọ́kàn pátápátá tí wọn ò sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere là ń gbé yìí. Bí Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe irú ìwà tó máa gbayé kan ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” nìyẹn.

Ǹjẹ́ a tún nílò ẹ̀rí mìíràn láti lè dá irú àkókò tá à ń gbé yìí mọ̀? Jésù tún sọ tẹ́lẹ̀ pé ní àkókò yìí kan náà, ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run yóò di èyí tá à ń wàásù rẹ̀ ní gbogbo ibi téèyàn ń gbé lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 24:14) Ṣé èyí ń ṣẹlẹ̀?

Ilé Ìṣọ́, ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà tá a gbé ka Bíbélì tó wà fún pípolongo ìhìn rere Ìjọba Jèhófà, ni à ń tẹ̀ jáde déédéé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè ju ti ìwé ìròyìn èyíkéyìí mìíràn lọ.

Lọ́dọọdún, ó ju bílíọ̀nù kan wákàtí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò láti jẹ́rìí fáwọn èèyàn nípa Ìjọba Ọlọ́run.

Ní báyìí, àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ń ṣàlàyé Bíbélì là ń tẹ̀ jáde ní nǹkan bí irínwó èdè, títí kan àwọn èdè táwọn èèyàn tó ń gbé ibi jíjìnnà réré àtàwọn àwùjọ kéékèèké ń sọ. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti mú ìhìn rere náà dé gbogbo orílẹ̀-èdè; wọ́n tún ti wàásù ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù àtàwọn ìpínlẹ̀ tó kéré, àní àwọn tó kéré débi pé àwọn ìjọba ayé ò tiẹ̀ kà wọ́n sí pàápàá. Ọ̀pọ̀ jù lọ ilẹ̀ ni wọ́n ti ní ètò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ń ṣe déédéé.

Lódodo, gbogbo ibi téèyàn ń gbé lórí ilẹ̀ ayé ni ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ti ń lọ ní pẹrẹu, kì í ṣe láti yí ayé padà o, àmọ́ kó lè jẹ́ ẹ̀rí ni. Gbogbo èèyàn níbi gbogbo là ń fún ní àǹfààní láti fi hàn bóyá ẹni tó dá ọ̀run àti ayé ṣe pàtàkì sí wọn àti bóyá wọ́n á bọ̀wọ̀ fún àwọn òfin rẹ̀ kí wọ́n sì fi ìfẹ́ hàn sí ọmọnìkejì wọn.—Lúùkù 10:25-27; Ìṣípayá 4:11.

Láìpẹ́ sí àkókò yìí, Ìjọba Ọlọ́run máa palẹ̀ gbogbo àwọn ẹni ibi mọ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé tí yóò sì sọ ayé di Párádísè níbi tí òdodo yóò máa gbé.—Lúùkù 23:43.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Kí Ni?

Kì í ṣe àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ìran èèyàn. Ní tàwọn tó ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, Bíbélì sọ pé ìyè àìnípẹ̀kun ń bẹ fún wọn.—Jòhánù 3:16, 36; 1 Jòhánù 2:17.

Kì í ṣe ọjọ́ ìkẹyìn ilẹ̀ ayé wa. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèlérí pé títí láé ni ilẹ̀ ayé téèyàn ń gbénú rẹ̀ yìí yóò wà.—Sáàmù 37:29; 104:5; Aísáyà 45:18.

Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan oníwà-ipá àti aláìnífẹ̀ẹ́ yìí àti ti gbogbo àwọn tí ìṣe ayé yìí ti mọ́ lára.—Òwe 2:21, 22.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ṣé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ni Bíbélì Lóòótọ́?

Léraléra làwọn wòlíì inú Bíbélì kọ̀wé pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí.” (Aísáyà 43:14; Jeremáyà 2:2) Kódà, Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, tẹnu mọ́ ọn pé òun ‘kò sọ̀rọ̀ látinú àpilẹ̀ṣe ti ara òun.’ (Jòhánù 14:10) Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ ọ́ kedere pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.”—2 Tímótì 3:16.

Kò sí ìwé mìíràn tí wọ́n tẹ̀ ní èdè tó pọ̀ tó èyí tí a fi tẹ Bíbélì—ó ju ẹgbọ̀kànlá [2,200] èdè lọ, gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ United Bible Societies ṣe sọ. Kò sí ìwé mìíràn tí wọ́n tíì pín kiri tó bẹ́ẹ̀ rí—ó ti lé ní bílíọ̀nù mẹ́rin ẹ̀dà báyìí. Ǹjẹ́ kì í ṣe ohun tí wàá retí pé kó ṣẹlẹ̀ nípa ìsọfúnni kan látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó wà fún gbogbo ọmọ aráyé nìyẹn?

Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìsọfúnni nípa àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run mí sí Bíbélì, wo ìwé pẹlẹbẹ náà Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

Bó o bá ka Bíbélì tó o sì gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni lóòótọ́, yóò ṣe ọ́ láǹfààní gidigidi.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Ó jẹ́ ìjọba àrà ọ̀tọ̀ kan tí Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, tí í ṣe Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé, gbé kalẹ̀.—Jeremáyà 10:10, 12.

Jésù Kristi ni ẹni tí Bíbélì dárúkọ pé Ọlọ́run gbé ìṣàkóso yẹn lé lọ́wọ́. (Ìṣípayá 11:15) Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi hàn pé Ọlọ́run ti fún òun ní ọlá àṣẹ tó ga, ìyẹn ọlá àṣẹ tó fi kápá àwọn nǹkan bí ipò ojú ọjọ́, afẹ́fẹ́ àti òkun. Ọlá àṣẹ tó fi wo onírúurú àìsàn sàn, kódà tó fi jí òkú dìde. (Mátíù 9:2-8; Máàkù 4:37-41; Jòhánù 11:11-44) Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tí a mí sí sọ pé Ọlọ́run yóò tún fún un ní “agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè máa sin àní òun.” (Dáníẹ́lì 7:13, 14) Ìjọba yẹn là ń pè ní Ìjọba ọ̀run; Jésù sì ti ń ṣàkóso látọ̀run báyìí.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Wíwàásù ìhìn rere kárí ayé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́