“Wákàtí Ìdájọ́” Ti Dé
ÌWÉ Ìṣípayá, tó kẹ́yìn nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, áńgẹ́lì kan tó ń fò lágbedeméjì ọ̀run ní “ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo gẹ́gẹ́ bí làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀.” Ó kígbe ní ohun rara pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí wákàtí ìdájọ́ láti ọwọ́ rẹ̀ ti dé.” (Ìṣípayá 14:6, 7) Lára ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní “wákàtí ìdájọ́” yẹn ni pípolongo ìdájọ́ Ọlọ́run àti mímú ìdájọ́ náà ṣẹ. “Wákàtí” kan kì í ṣe àkókò tó gùn lọ títí. Mímú ìdájọ́ ṣẹ yìí ni yóò fi òpin pátápátá sí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ti à ń gbé yìí.—2 Tímótì 3:1.
Ìhìn rere ni “wákàtí ìdájọ́” yìí jẹ́ fún àwọn olùfẹ́ òdodo. Ó jẹ́ àkókò tí Ọlọ́run máa mú ìtura wá fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ojú wọ́n ti rí màbo nínú ètò àwọn nǹkan oníwà ipá àti aláìnífẹ̀ẹ́ yìí.
Ní báyìí, kí wákàtí ìdájọ́ tó dópin nígbà ìparun ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí, a rọ̀ wá pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un.” Ṣé ò ń ṣe ìyẹn? Èyí kọjá wíwulẹ̀ sọ pé, “Mo gba Ọlọ́run gbọ́” o. (Mátíù 7:21-23; Jákọ́bù 2:19, 20) Ó yẹ kí ìbẹ̀rù Ọlọ́run mú ká máa bọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ gan-an fún un. Ó yẹ kó mú wa yà kúrò nínú ìwà búburú. (Òwe 8:13) Ó yẹ kó mú ká nífẹ̀ẹ́ ohun tó dára ká sì kórìíra ohun tó burú. (Ámósì 5:14, 15) Bá a bá bọlá fún Ọlọ́run, a óò máa fetí sílẹ̀ sí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. A ò ní jẹ́ kí àwọn nǹkan mìíràn máa dí wa lọ́wọ́ débi tá ò fi ní ráyè ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì, déédéé. A óò máa fi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kẹ̀ lé e ní gbogbo ìgbà. (Sáàmù 62:8; Òwe 3:5, 6) Àwọn tí wọ́n ń bọ̀wọ̀ fún un lóòótọ́ mọ̀ pé, níwọ̀n bó ti jẹ́ Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé, òun ni Ọba Aláṣẹ láyé àti lọ́run, tìfẹ́tìfẹ́ sì ni wọ́n fi ń fi ara wọn sábẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ẹni tó ní ẹ̀tọ́ láti ṣàkóso ìgbésí ayé wọn. Bá a bá rí i pé ó yẹ ká túbọ̀ fún àwọn nǹkan wọ̀nyí láfiyèsí, ẹ jẹ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀ láìfi àkókò ṣòfò.
Àkókò ìdájọ́ tí áńgẹ́lì náà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ la tún mọ̀ sí “ọjọ́ Jèhófà.” Irú “ọjọ́” yìí dé bá Jerúsálẹ́mù ìgbàanì lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Tiwa nítorí pé àwọn èèyàn rẹ̀ dágunlá sí àwọn ìkìlọ̀ Jèhófà látẹnu àwọn wòlíì rẹ̀. Nípa ríronú lọ́kàn wọn pé ọjọ́ Jèhófà ṣì jìn, ńṣe ni wọ́n túbọ̀ fi ẹ̀mí wọn sínú ewu. Jèhófà ti kìlọ̀ ṣáájú pé: “Ó sún mọ́lé, ìyára kánkán rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.” (Sefanáyà 1:14) “Ọjọ́ Jèhófà” mìíràn dé bá Bábílónì ìgbàanì lọ́dún 539 ṣáájú Sànmánì Tiwa. (Aísáyà 13:1, 6) Àwọn ará Bábílónì gbẹ́kẹ̀ lé àwọn odi wọn àtàwọn òrìṣà wọn, wọn ò ka ìkìlọ̀ àwọn wòlíì Jèhófà sí. Àmọ́ òru ọjọ́ kan ni Bábílónì ńlá ṣubú sọ́wọ́ àwọn ará Mídíà àti Páṣíà.
Kí ló dojú kọ wá lónìí? “Ọjọ́ Jèhófà” mìíràn tó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀ ju ìyẹn lọ ni. (2 Pétérù 3:11-14) A ti kéde ìdájọ́ Ọlọ́run sórí “Bábílónì Ńlá.” Ìṣípayá 14:8 sọ pé áńgẹ́lì kan ní ọ̀run kéde pé: “Bábílónì Ńlá ti ṣubú.” Ìyẹn sì ti ṣẹlẹ̀. Kò tún ṣeé ṣe fún un mọ́ láti ṣèdíwọ́ fún àwọn olùjọsìn Jèhófà. Ìwà ìbàjẹ́ rẹ̀ àti lílọ́wọ́ tó ń lọ́wọ́ sí ogun ti hàn fáyé rí. Báyìí, ìparun rẹ̀ ti sún mọ́lé. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi ń rọ àwọn èèyàn níbi gbogbo pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ [Bábílónì Ńlá] . . . bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀. Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti wọ́ jọpọ̀ títí dé ọ̀run, Ọlọ́run sì ti mú àwọn ìṣe àìṣèdájọ́ òdodo rẹ̀ wá sí ìrántí.”—Ìṣípayá 18:4, 5.
Kí ni Bábílónì Ńlá? Ó jẹ́ ètò ìsìn àgbáyé èyí tí àwọn ìṣe rẹ̀ jọ ti Bábílónì ìgbàanì. (Ìṣípayá orí 17, 18) Ìwọ wo díẹ̀ nínú àwọn ohun tí wọ́n fi jọra:
• Àwọn àlùfáà Bábílónì ìgbàanì máa ń kópa lójú méjèèjì nínú ọ̀ràn ìṣèlú orílẹ̀-èdè náà. Bí ọ̀pọ̀ ìsìn ṣe rí gẹ́lẹ́ lónìí nìyẹn.
• Àwọn àlùfáà Bábílónì sábà máa ń ṣagbátẹrù ogun orílẹ̀-èdè náà. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìsìn ọjọ́ òní ló máa ń jẹ́ òléwájú nínú àwọn tó máa ń gbàdúrà fún àwọn sójà báwọn orílẹ̀-èdè bá ń lọ sógun.
• Àwọn ẹ̀kọ́ àtàwọn àṣà Bábílónì ìgbàanì sún orílẹ̀-èdè náà sínú ìwà ìṣekúṣe tó burú jáì. Níwọ̀n bí àwọn aṣáájú ìsìn lónìí ti fọwọ́ rọ́ ìlànà Bíbélì lórí ìwà rere sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ṣe ni ìwà pálapàla ń gbilẹ̀ láàárín àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ ìjọ. Ohun tó tún yẹ fún àfiyèsí ni pé, nítorí pé Bábílónì Ńlá ti sọ ara rẹ̀ di aṣẹ́wó fún ayé àti ètò ìṣèlú rẹ̀, Ìṣípayá ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́wó.
• Bíbélì tún sọ pé Bábílónì Ńlá ń gbé “nínú fàájì aláìnítìjú.” Ní Bábílónì ìgbàanì, àwọn òṣìṣẹ́ tẹ́ńpìlì máa ń gba ilẹ̀ lọ rẹpẹtẹ, àwọn àlùfáà sì di ògúnnágbòǹgbò nínú ètò ọrọ̀ ajé. Lóde òní, yàtọ̀ sáwọn ilé ìjọsìn tí Bábílónì Ńlá ní, ó tún láwọn iléeṣẹ́ okòwò lọ bí ilẹ̀ bí ẹní. Àwọn ohun tó fi ń kọ́ni àtàwọn àjọ̀dún rẹ̀ mú kí òun àtàwọn mìíràn tí wọ́n jọ ń ṣòwò pa pọ̀ lágbàáyé ní ọrọ̀ rẹpẹtẹ.
• Lílo ère, ṣíṣe iṣẹ́ òkùnkùn, àjẹ́ àti ṣíṣe oṣó tún wọ́pọ̀ ní Bábílónì ìgbàanì, bí wọ́n ṣe wọ́pọ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi lónìí. Wọ́n gbà pé ikú jẹ́ ọ̀nà láti sọdá sínú ìgbésí ayé mìíràn. Àwọn tẹ́ńpìlì àti ilé ìjọsìn kéékèèké tí wọ́n fi ń bọlá fún àwọn ọlọ́run wọn kún Bábílónì nígbà yẹn, àmọ́ ńṣe làwọn ará Bábílónì máa ń ṣàtakò àwọn olùjọsìn Jèhófà. Irú àwọn ìgbàgbọ́ àtàwọn àṣà kan náà hàn gbangba gbàǹgbà nínú Bábílónì Ńlá.
Láyé ìgbàanì, Jèhófà lo àwọn orílẹ̀-èdè jagunjagun tí ìjọba wọn lágbára gan-an láti fìyà jẹ àwọn tó ṣàìkà á sí tí wọn ò sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ìyẹn ni àwọn ará Ásíríà fi pa Samáríà run lọ́dún 740 ṣáájú Sànmánì Tiwa. Àwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Tiwa bákan náà làwọn ará Róòmù tún pa á run lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa. Bábílónì fúnra rẹ̀ di èyí táwọn ará Mídíà àti Páṣíà ṣẹ́gun lọ́dún 539 ṣáájú Sànmánì Tiwa. Bíbélì sàsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ wa pé, bí ẹranko ẹhànnà làwọn ìjọba ayé yóò ṣe kọjú sí “aṣẹ́wó náà,” wọn yóò tú u sí ìhòòhò, wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ohun tó jẹ́ gan-an hàn. Wọ́n á pá a run pátápátá.—Ìṣípayá 17:16.
Ǹjẹ́ àwọn ìjọba ayé yóò ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lóòótọ́? Bíbélì sọ pé ‘Ọlọ́run yóò fi sínú ọkàn-àyà wọn.’ (Ìṣípayá 17:17) Òjijì lèyí yóò ṣẹlẹ̀, yóò jẹ́ ìyàlẹ́nu gidigidi, yóò burú jáì, wọn ò sì ní rí i tẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣẹlẹ̀ díẹ̀díẹ̀.
Ìgbésẹ̀ wo ló yẹ kó o gbé? Bi ara rẹ léèrè: ‘Ṣé mo ṣì rọ̀ mọ́ ètò ìsìn tó láwọn ẹ̀kọ́ àtàwọn àṣà tó fi hàn pé ó jẹ́ apá kan Bábílónì Ńlá?’ Ká tiẹ̀ ní o kì í ṣe ara wọn, o lè bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mo ti jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ ràn mí?’ Irú ẹ̀mí wo? Ẹ̀mí fífàyè gba ìṣekúṣe, ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì àti ìfẹ́ adùn dípò ìfẹ́ fún Ọlọ́run tàbí mímọ̀ọ́mọ̀ ṣàìka Ọ̀rọ̀ Jèhófà sí (kódà nínú àwọn ohun tó dà bíi pé kò tó nǹkan). Ronú dáadáa lórí ìdáhùn rẹ.
Ká tó lè rí ojú rere Jèhófà, ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ kó hàn nínú ìwà wa àtàwọn ìfẹ́ ọkàn wa pé a kì í ṣe apá kan Bábílónì Ńlá. A kò gbọ́dọ̀ jáfara o. Nígbà tí Bíbélì ń jẹ́ ká mọ̀ pé òjijì ni òpin yóò dé, ó sọ pé: “Lọ́nà kan náà, pẹ̀lú ìgbésọnù yíyára ni a ó fi Bábílónì ìlú ńlá títóbi náà sọ̀kò sísàlẹ̀, a kì yóò sì tún rí i mọ́ láé.”—Ìṣípayá 18:21.
Àmọ́ ó tún kù o. Nínú apá mìíràn nínú “wákàtí ìdájọ́” yẹn, Jèhófà Ọlọ́run yóò ṣèdájọ́ gbogbo ètò ìṣèlú ayé, àwọn olùṣàkóso rẹ̀ àti gbogbo àwọn tó dágunlá sí ẹ̀tọ́ Ọlọ́run láti ṣàkóso nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ ọ̀run èyí tó ti fà lé Jésù Kristi lọ́wọ́. (Ìṣípayá 13:1, 2; 19:19-21) Ìran tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Dáníẹ́lì 2:20-45 ṣàpèjúwe àwọn ìjọba láti àkókò Bábílónì ìgbàanì títí di àkókò tá a wà yìí gẹ́gẹ́ bí ère gàgàrà kan tí wọ́n fi wúrà, fàdákà, bàbà, irin àti amọ̀ ṣe. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ wa pé: “Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé.” Nígbà tí Bíbélì sì ń sọ nípa ohun tí Ìjọba yẹn á ṣì gbé ṣe lákòókò “wákàtí ìdájọ́” Jèhófà, ó polongo pé: “Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 2:44.
Bíbélì kìlọ̀ fún àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ láti má ṣe nífẹ̀ẹ́ “àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé,” ìyẹn irú ìgbésí ayé tí ayé tó kẹ̀yìn sí Ọlọ́run tòótọ́ yìí ń gbé lárugẹ. (1 Jòhánù 2:15-17) Ṣé àwọn ìpinnu rẹ àtàwọn ìṣesí rẹ fi hàn pé o fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run pátápátá? Ṣé lóòótọ́ lò ń fi ṣáájú nínú ìgbésí ayé rẹ?—Mátíù 6:33; Jòhánù 17:16, 17.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]
Ìgbà Wo Lòpin Máa Dé?
“Ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀.”—Mátíù 24:44.
“Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.”—Mátíù 25:13.
“Kì yóò pẹ́.”—Hábákúkù 2:3.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]
Ká Ní O Mọ Ìgbà Tí Òpin Á Dé, Ṣé Wàá Yí Ìgbésí Ayé Rẹ Padà?
Bó bá dá ọ lójú pé ìmúṣẹ ìdájọ́ Ọlọ́run tó ń bọ̀ kò ní ṣẹlẹ̀ níwọ̀n ọdún díẹ̀ sí i, ṣé ìyẹn á mú kó o yí bó o ṣe ń gbé ìgbésí ayé rẹ padà? Bí òpin ètò àwọn nǹkan yìí bá ti pẹ́ ju bó o ṣe rò lọ, ṣé o ti jẹ́ kí èyí wá mú ọ dẹwọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?—Hébérù 10:36-38.
Ńṣe ni mímọ̀ tá ò mọ àkókò náà gan-an tí òpin máa dé fún wa ní àǹfààní láti fi hàn pé tinútinú la fi ń sin Ọlọ́run. Àwọn tó mọ Jèhófà mọ̀ pé kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí kó ìtara bolẹ̀ nígbà tó kù díẹ̀ kí òpin dé kò ní jẹ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run, ẹni tó mọ ohun tí ọkàn jẹ́.—Jeremáyà 17:10; Hébérù 4:13.
Ní ti àwọn tó fẹ́ràn Jèhófà tinútinú, òun ni wọ́n máa ń fi sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wọn. Bíi ti gbogbo èèyàn, àwọn Kristẹni lè ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, àmọ́ ìdí tí wọ́n fi ń ṣe é kì í ṣe torí àtidolówó bí kò ṣe pé kí wọ́n lè ní àwọn nǹkan tara tí wọ́n nílò àti ìwọ̀nba ohun díẹ̀ láti fún àwọn ẹlòmíràn. (Éfésù 4:28; 1 Tímótì 6:7-12) Wọ́n tún máa ń gbádùn eré ìtura tó bojú mu àti àwọn eré ìnàjú mìíràn, àmọ́ ohun tó ń mú wọn ṣe èyí ni pé kí ara lè tù wọ́n, kì í ṣe pé wọ́n wulẹ̀ fẹ́ máa ṣe ohun tí gbogbo èèyàn ń ṣe. (Máàkù 6:31; Róòmù 12:2) Ó máa ń dùn mọ́ wọn láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run bó ṣe dùn mọ́ Jésù Kristi.—Sáàmù 37:4; 40:8.
Àwọn Kristẹni tòótọ́ fẹ́ láti wà láàyè kí wọ́n sì máa sin Jèhófà títí ayé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní láti dúró díẹ̀ sí i ju bí àwọn kan ṣe rò lọ kọ́wọ́ wọn tó lè tẹ àwọn ìbùkún kan, èyí kò dín bí ìrètí yẹn ṣe ṣeyebíye sí wọn tó kù.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ọ̀ràn Ipò Ọba Aláṣẹ
Láti lè lóye ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìnira tó pọ̀ tó báyìí, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ lóye ọ̀ràn ta ló jẹ́ ọba aláṣẹ lọ́run òun ayé.
Nítorí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá, ó láṣẹ láti ṣàkóso lórí ilẹ̀ ayé àti gbogbo àwọn tó ń gbé inú rẹ̀. Àmọ́ Bíbélì ṣàlàyé pé, ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìtàn ẹ̀dá èèyàn, ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ di èyí tí a ta kò. Sátánì Èṣù sọ pé Jèhófà ń ká èèyàn lọ́wọ́ kò láìyẹ, pé ńṣe ni Ọlọ́run parọ́ fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ bí wọ́n bá ṣàìka òfin Ọlọ́run sí tí wọ́n sì ń ṣe ohun tó wù wọ́n, àti pé nǹkan yóò túbọ̀ dára fún wọn bí wọ́n bá ń ṣàkóso ara wọn láìfi ti Ọlọ́run ṣe.—Jẹ́nẹ́sísì, orí 2 àti 3.
Bí Ọlọ́run bá ti pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọ̀nyí run lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni, ì bá fi bí agbára rẹ̀ ṣe tó hàn, àmọ́ ìyẹn ì bá tí yanjú ọ̀ràn tí wọ́n dá sílẹ̀. Dípò kí Jèhófà pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà run lójú ẹsẹ̀, ńṣe ló fi wọ́n sílẹ̀ kí gbogbo ìṣẹ̀dá olóye láyé àti lọ́run lè fojú ara wọn rí ohun tó máa ń jẹ́ àbájáde ìṣọ̀tẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí mú ìnira lọ́wọ́, síbẹ̀ ó ṣí àǹfààní sílẹ̀ kí wọ́n lè bí wa.
Kò tán síbẹ̀ o, bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ńláǹlà ló ná Jèhófà, ó fi ìfẹ́ ṣètò pé kí àwọn ẹ̀dá èèyàn tó bá ṣègbọràn sí i tí wọ́n sì lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀ lè di òmìnira kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àtàwọn àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ kí wọ́n sì gbé nínú Párádísè. Bó bá pọn dandan, èyí lè jẹ́ nípasẹ̀ àjíǹde látinú ikú.
Àyè tí Ọlọ́run ti fi sílẹ̀ láti yanjú ọ̀ràn yìí tún ti fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láǹfààní láti fi hàn pé àwọn náà lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn kí àwọn sì pa ìwà títọ́ mọ́ sí Jèhófà lábẹ́ ipòkípò. Kí àwọn tó wà láyé àti lọ́run lè ní ọ̀wọ̀ tó yẹ fún òfin, ó ṣe pàtàkì láti yanjú ọ̀ràn ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀ràn ìṣòtítọ́ ẹ̀dá èèyàn tó so mọ́ ọn. Láìsí ọ̀wọ̀ fún òfin, kò lè sí àlááfíà gidi.a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ọ̀ràn wọ̀nyí àtàwọn ohun tó wé mọ́ wọn nínú ìwé Sún Mọ́ Jèhófà, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
[Àwòrán]
Onírúurú ètò ìṣàkóso ayé yóò dópin