Ori 4
“Babiloni” Alailaabo Ni A Ti Ṣedajọ Iparun Fún
1. (a) Ki ni ohun ti ọ̀rọ̀ naa “babiloni” tumọsi, ta ni ó si tẹ ilu-nla ti a ń fi orukọ yẹn pè dó? (b) Akanṣe iṣẹ ile kikọ wo ni Nimrodu olulepa aṣeyọri bẹrẹ rẹ̀, pẹlu iyọrisi wo si ni?
IDARUDAPỌ jẹ ami ti ó han kedere ninu ayé lonii—niti iṣelu, ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, ati ìsìn. Itumọ ede Gẹẹsi fun ọ̀rọ̀ Heberu ti inu Bibeli naa fun idarudapọ ni “babylon.” Ninu Genesisi, Babiloni ni a sọrọ rẹ̀ gẹgẹ bi Babeli, orukọ kan ti ó tun tumọsi “idarudapọ.” Nimrodu, ọlọ̀tẹ̀ kan lodisi Jehofa, ni ó tẹ ilu-nla ti a fi orukọ yẹn pè dó. (Genesisi 10:8-10) Nibẹ, awọn eniyan labẹ ipo aṣaaju naa Nimrodu olulepa aṣeyọri dawọle kikọ ile-iṣọ kan ti yoo roke lala dé ọ̀run ní iṣayagbangba sí Jehofa. Jehofa mu akanṣe iṣẹ ile kikọ ti ó tabuku si Ọlọrun yii kùnà nipa dída ede kanṣoṣo ti awọn olukọle naa rú, ki wọn ma baa loye araawọn ẹnikinni keji mọ́ bi wọn ti ń gbiyanju lati ṣiṣẹ papọ̀.—Genesisi 11:1-9.
2. (a) Ki ni ṣẹlẹ si agbara ayé Babiloni ní 539 B.C.E., eyiini ha si samisi opin ilu-nla naa ti ń jẹ orukọ yẹn bi? (b) Ki ni ilu-nla Babiloni igbaani yẹn kii ṣe?
2 Ní ìgbà pipẹ lẹhin naa, ilu-nla titun kan ti ń jẹ orukọ naa Babiloni ni a ṣakọsilẹ pe ó ń bẹ ní Odò Euferate. (2 Ọba 17:24; 1 Kronika 9:1) Ní 539 B.C.E. Kirusi Nla, olu-ọba Medo-Persia, bi Agbara Ayé Babiloni ṣubu ní imuṣẹ asọtẹlẹ Jehofa ní Isaiah 45:1-6. Bi o tilẹ jẹ pe Babiloni jiya iṣubu kíkàmàmà, a yọọda fun un lati wà niṣo gẹgẹ bi ilu-nla kan. A rohin rẹ̀ pe ó wà àní titi di ìlàjì ti ó kẹhin ninu ọrundun kìn-ín-ní Sanmani Tiwa. (1 Peteru 5:13) Bi o ti wu ki o ri, ilu-nla igbaani yẹn kii ṣe “Babiloni Nla,” eyi ti aposteli Johannu kọwe nipa rẹ̀ ninu iwe Ìfihàn ori 17.
3. Ki ni ami ìdánimọ̀ tootọ Babiloni Nla?
3 “Babiloni Nla” ti inu Ìfihàn, ti a ṣapejuwe rẹ̀ gẹgẹ bi obinrin oniwa palapala ti ó gun “ẹranko alawọ ododo kan,” duro fun ilẹ-ọba isin eke agbaye, titikan gbogbo awọn isin ti a fẹnulasan pe ni Kristẹndọm.a (Ìfihàn 17:3-5) Ní ibamu pẹlu ohun ti aposteli Johannu sọ nipa rẹ̀, ètò-àjọ iṣapẹẹrẹ yii ti ṣe agbere nipa tẹmi pẹlu gbogbo awọn alakooso oṣelu ti ilẹ̀-ayé. Ilẹ-ọba isin eke agbaye naa, Babiloni Nla, ṣì ń fi aṣẹ lo agbara idari ti ó kàmàmà.
“Ọ̀rẹ́ Ayé”—Kii Ṣe Ti Ọlọrun
4. Lakooko Ogun Agbaye I, bawo ni Babiloni Nla ṣe fikun awọn ìwà ọdaran rẹ̀ lodisi idile eniyan?
4 Bi o ti wu ki o ri, ipo elewu gidigidi ni Babiloni Nla wà, bi ọran naa ni pataki si ti jẹ́ niyi lati opin Ogun Agbaye I. Lakooko iforigbari yẹn, o fikun awọn ìwà ọdaran rẹ̀ lodisi idile eniyan. Ẹgbẹ alufaa Kristẹndọm, ti wọn fẹnujẹwọ pe awọn jẹ́ ọmọlẹhin Jesu Kristi, fi iwaasu rọ awọn ọdọkunrin lati lọ sójú pápá ijagun. Oloogbe Harry Emerson Fosdick, alufaa ṣọọṣi Protẹstant kan ti ó gbajumọ, ti isapa ogun lẹhin ṣugbọn ó gbà lẹhin naa pe: “Ani a gbe awọn asia ogun sinu awọn ṣọọṣi wa paapaa . . . A ti fi kọ̀rọ̀ ẹ̀rẹ̀kẹ́ wa kan yin Ọmọ-Aládé Alaafia a si ti fi ekeji fi ogo fun ogun.” Awọn alufaa ati ẹgbẹ alufaa Kristẹndọm miiran maa ń gbadura fun awọn agbo ọmọ-ogun ajagun nibi awọn apejọ isin, wọn si ń ṣiṣẹsin gẹgẹ bi alufaa ti ẹgbẹ-ogun fun awọn ọmọ-ogun ori ilẹ, ti oju omi, ati ti oju ofuurufu.b
5. (a) Awọn ọ̀rọ̀ Jakọbu 4:4 wo ni Kristẹndọm kò fi si ọkàn? (b) Ki ni gbọdọ jẹ́ idajọ atọrunwa lori rẹ̀?
5 Kristẹndọm, labẹ itọsọna awọn aṣaaju isin wọnyi, kò fi awọn ọ̀rọ̀ Jakọbu 4:4, si ọkàn: “Ẹyin panṣaga ọkunrin ati panṣaga obinrin, ẹ kò mọ̀ pe ìbárẹ́ ayé iṣọta Ọlọrun ni? Nitori naa, ẹnikẹni ti ó bá fẹ lati jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé di ọta Ọlọrun.” Nipa bayii Kristẹndọm ń baa niṣo gẹgẹ bi ọta Ọlọrun Ọga-Ogo titi di akoko yii gan-an. Dajudaju oun kò ní idaabobo atọrunwa, ati nitori idi ṣiṣe pataki gidi yii iwalaaye rẹ̀ gan-an wà ninu ewu. Awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ oloṣelu kò ṣee fọkàntán, itẹsi siha iṣodisi isin si ń baa lọ lati maa di alagbara sii. Kii ṣe nitori tirẹ̀ ni Ọlọrun fi sọ pe: “Ẹ maṣe fi ọwọ́ kan ẹni-ororo mi.”—1 Kronika 16:22.
“Ẹ Ti Inu Rẹ̀ Jade, Ẹyin Eniyan Mi”
6, 7. (a) Ìpè kanjukanju wo ni ó dún jade ninu Ìfihàn 18:4, awọn wo ni a sì dari rẹ̀ sí? (b) Nigba wo ni iru ìpè iṣaaju kan bẹẹ bẹrẹsii ni imuṣẹ sara awọn Ju ti ń ráre ní Babiloni igbaani?
6 Sí awọn ẹni-ami-ororo wọnyi ati awọn olubakẹgbẹpọ wọn ní akoko ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan yii, ni ìpè atọrunwa naa ń ró gbọnmọgbọnmọ ní kanjukanju pe: “Ẹ ti inu rẹ̀ jade, ẹyin eniyan mi, ki ẹ má baa ṣe alabaapin ninu ẹṣẹ rẹ̀.” (Ìfihàn 18:4) Bẹẹni, jade kuro ninu ilẹ-ọba isin eke agbaye, Babiloni Nla.
7 Ìpè yii ṣàtúnsọ awọn ọ̀rọ̀ Jeremiah 50:8 ati 51:6, 45, ti a dari sí àṣẹ́kù awọn Ju ti Jehofa dajọ ijiya fun lati lọ lo 70 ọdun ni oko òǹdè ati ìgbèkùn ní ilẹ̀ awọn ara Babiloni. Awọn ọ̀rọ̀ wọnni bẹrẹsii ni imuṣẹ sara awọn Ju ti ń ráre ní ilẹ awọn ara Babiloni ní 537 B.C.E., lẹhin ti Kirusi Nla ti a ti sọtẹlẹ naa kó awọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun Medo-Persia rẹ̀ yan gba isalẹ Odò Euferate ti ó ti fẹrẹẹ gbẹ tan naa kọja ti wọn sì wọ inu ilu-nla Babiloni.
8. (a) Bawo ni Kirusi Nla naa ṣe mu Isaiah 45:1-6 ṣẹ? (b) Eeṣe ti ẹni ti Kirusi Nla jẹ́ awojiji iṣaaju fun fi yẹ ki ó gbe igbesẹ ní ibamu pẹlu àwòkọ́ṣe alasọtẹlẹ awọn nǹkan yii?
8 Ní ọdun akọkọ iṣakoso rẹ̀, Kirusi Nla gbe igbesẹ ní imuṣẹ asọtẹlẹ ti ó wà ní Isaiah 45:1-6. Lọna ti ó farajọra, ẹni naa ti Kirusi Olu-Ọba jẹ awojiji iṣaaju fun, ṣugbọn ti ó jẹ́ alagbara-nla pupọpupọ ju u lọ, Jesu Kristi, gbe igbesẹ ní ibamu pẹlu àwòkọ́ṣe alasọtẹlẹ ti awọn nǹkan yii. Eyi jẹ́ ní akoko yiyẹ lẹhin ti oun ti bọ́ sinu iṣakoso ti ọba rẹ̀ ní ọ̀run ní ọwọ́ ọtun Jehofa Ọlọrun, nigba ti “akoko awọn Keferi” pari ní October 1914. (Luku 21:24) Nigba ogun agbaye kìn-ín-ní ti 1914 si 1918, àṣẹ́kù awọn Israeli tẹmi niriiri ìkónígbèkùn ní ọwọ́ Babiloni Nla ati awọn àlè rẹ̀ oloṣelu.
9, 10. (a) Igbesẹ wo ni a gbé lodisi mẹmba mẹjọ ninu awọn oṣiṣẹ orile-iṣẹ Society? (b) Ẹri wo ni ó fihan pe Babiloni Nla ni ó wà nidi igbesẹ naa lati dá iṣẹ awọn eniyan Jehofa duro?
9 Fun apẹẹrẹ, ní United States iwe ti a tẹ̀jade kẹhin nigba naa lati ọwọ́ Watch Tower Society, The Finished Mystery, ni a fofinde pe ó lè fa iṣọtẹ si ijọba. Awọn mejeeji ti wọn ṣe iwe naa ni a mú wá sí ile-ẹjọ apapọ ní Brooklyn, New York, a si ṣe idajọ àhámọ́ 20 ọdun ní ile ẹwọn ti ijọba apapọ ní Atlanta, Georgia, fun wọn laitọ. Bakan naa pẹlu ni aarẹ ẹgbẹ oluṣewejade, akọwe olutọju iṣura, ati awọn mẹta miiran lara oṣiṣẹ orile-iṣẹ. Olutumọ kan ti ó jẹ́ alabaaṣiṣẹpọ ni a ṣe idajọ idaji iye iwọn akoko yẹn fun ní ile ẹwọn ti ijọba apapọ.
10 Nitori naa ní July 4, 1918, awọn Kristian oluṣeyasimimọ mẹjọ wọnyi ni a ko sinu ọkọ̀ ojú irin lọ si Atlanta, Georgia, nibi ti a ó ti fi ominira wọn dù wọn. Awọn mẹmba orile-iṣẹ Watch Tower Society ní Brooklyn nigba naa nilati wá bojuto eto nǹkan dé iwọn ibi ti agbara iṣe wọn de. Ta ni ó ni ẹbi fun bí ipo nǹkan ti rí yii? Iwe naa Preachers Present Arms dahun pe: “Ìlàlẹ́sẹẹsẹ gbogbo ọran naa sinnilọ sori ipari ero naa pe awọn ṣọọṣi ati awọn alufaa ni wọn wà nidi igbesẹ naa lati ibẹrẹpẹpẹ lati tẹ awọn atẹ̀lé Russell [awọn Ẹlẹ́rìí] ní àtẹ̀rẹ́. . . . Nigba ti irohin idajọ ológún ọdun naa de eti ìgbọ́ awọn onkọwe alatun-unṣe ile ìtẹ̀wé awọn onisin, o fẹrẹẹ jẹ́ gbogbo awọn itẹjade wọnyi lọkọọkan, nla ati kekere, ni wọn yọ̀ lori iṣẹlẹ naa. Kò ṣeeṣe fun mi lati ṣawari awọn ọ̀rọ̀ ibanikẹdun eyikeyii kankan ninu awọn iwe irohin isin ti gbogbogboo tẹwọgba.”—Ray H. Abrams, oju-iwe 183, 184.
Iṣubu Kan—Ṣugbọn Kii Ṣe Sinu Iparun
11, 12. (a) Ki ni Babiloni Nla ti gbèrò lati ṣe? (b) Bawo ni ó ṣe jiya iṣubu gigadabu kan, bi o tilẹ jẹ pe kii ṣe sinu iparun? (c) Ipa wo ni eyi ní lori awọn eniyan Jehofa ti a ti tú sílẹ̀?
11 Ṣugbọn ayọ̀ yiyọ naa ninu Babiloni Nla kii ṣe fun igba pipẹtiti. Ní ìgbà iruwe ọdun 1919, Babiloni Nla jiya iṣubu gigadabu kan, eyi ti awọn idagbasoke kan lọna ti isin yoo tẹ̀lé ṣaaju ki a tó pa a run patapata. Èròǹgbà Babiloni Nla ni lati tẹ awọn eniyan Jehofa mọ́lẹ̀ ninu igbekun titi lae. Ṣugbọn ní March 1919 awọn ilẹkun ọgba ẹwọn ni a fi ipá ṣí silẹ fun awọn aṣoju mẹjẹẹjọ ti Watch Tower Society, wọn sì jade lẹhin gbigba iduro fun wọn. Lẹhin naa, a da wọn lare patapata ninu gbogbo ẹ̀sùn.
12 Ayọ̀ yíyọ̀ Babiloni Nla ti poora nisinsinyi! Iwe naa Preachers Present Arms sọ nipa ipinnu ile ẹjọ lati dá awọn Ẹlẹ́rìí naa silẹ pe: “Ìparọ́rọ́ ni a fi kí idajọ yii kaabọ ninu awọn ṣọọṣi.” Ṣugbọn ayọ̀ awọn eniyan Jehofa pọ̀ pupọ. A tun ètò-àjọ wọn kárí-ayé ṣe. Ninu apejọpọ wọn ti 1919 ní Cedar Point, Ohio, aarẹ Society ru ẹgbẹẹgbẹrun awọn ti wọn pejọpọ soke si iṣẹ ni pẹrẹu nipasẹ asọye rẹ̀ “Kikede Ijọba Naa.” Lẹẹkan sii awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tun ti wà lominira ti wọn ń fi tigboya tigboya polongo Ijọba Ọlọrun ní gbangba! Babiloni Nla ti jiya iṣubu, bi o tilẹ jẹ pe kii ṣe sinu iparun. Kirusi Gigaju naa, Jesu Kristi, ti ṣẹgun rẹ̀ ó si ti tú awọn ọmọlẹhin rẹ̀ oloootọ silẹ.
13. Nigba ti Imulẹ Awọn Orilẹ-Ede farahan lori iran ayé, ki ni ohun ti Babiloni Nla ṣe?
13 Nipa bayii a gba Babiloni Nla laaye lati laaja bọ́ sinu sanmani ọdun ẹhin ogun naa. Nigba ti a dábàá Imulẹ Awọn Orilẹ-Ede gẹgẹ bi ètò-àjọ agbaye kan fun pipa alaafia mọ, Igbimọ Apapọ Awọn Ṣọọṣi Kristi ní America fi itilẹhin rẹ̀ han fun un gbangba-gbàǹgbà, ni kikede ní gbangba pe Imulẹ Awọn Orilẹ-Ede “ni ifarahan Ijọba Ọlọrun lori ilẹ̀-ayé lọna iṣelu.” Nigba ti Imulẹ ti a dàbàá naa di eyi ti a gbé kalẹ nikẹhin, Babiloni Nla gun lé e lẹhin o si tipa bayii bẹrẹ gigun rẹ̀ lori “ẹranko alawọ òdòdó” iṣapẹẹrẹ yii.—Ìfihàn 17:3.
14. (a) Lakooko Ogun Agbaye II, ki ni ipa ọna igbesẹ Babiloni Nla? (b) Nigba ti ohun-eelo atọwọda eniyan fun pipa alaafia mọ jade wá lati inu ọgbun lẹhin Ogun Agbaye II, ki ni ohun ti Babiloni Nla ṣe?
14 Nigba ti ohun-eelo fun pipa alaafia mọ́ alaigbeṣẹ yii lọ sinu ọgbun ti aisi igbokegbodo nigba ti Ogun Agbaye II bẹsilẹ, kò si ohun ti Babiloni Nla ní lati gun lé lori mọ́. (Ìfihàn 17:8) Ṣugbọn oun naa wa nita nibẹ pẹlu awọn orilẹ-ede 57 ti wọn wọ iwaya ija ninu Ogun Agbaye II. Pe o ń beere fun pipin iduroṣinṣin rẹ̀ laaarin awọn ẹgbẹẹgbẹ ogun ti ń ba araawọn jà kò yọ ọ lẹnu, gan-an gẹgẹ bi pipin yẹ́lẹyẹ̀lẹ rẹ̀ si ọgọrọọrun awọn ẹya isin ati ẹka isin ti wọn dojúrú kò ti fi igba kan rí dà á laamu. Nigba ti ohun-eelo atọwọda eniyan fun pipa alaafia mọ́ naa, ní àwọ̀ Iparapọ Awọn Orilẹ-Ede, jade wá lati inu ọgbun ti aisi igbokegbodo naa ní opin Ogun Agbaye II, lẹsẹkẹsẹ ni Babiloni Nla gun ẹhin rẹ̀ ti ó si bẹrẹsii lo agbara idari lori rẹ̀.
Awọn Alaṣẹ Oṣelu Yoo Yijupada si Babiloni
15, 16. (a) Araye ti wá wà ní ìfojúkojú pẹlu iṣẹlẹ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ wo nisinsinyi? (b) Ki ni Ọlọrun Olodumare ti pinnu, ní ibamu pẹlu Ìfihàn 17:15-18?
15 Gbogbo ayé araye fẹrẹẹ dojukọ iṣẹlẹ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ kan nisinsinyi. Eyi yoo jẹ́ iyijupada awọn alaṣẹ oṣelu si Babiloni Nla, pẹlu ète lati pa a run patapata. Eyi lè dun bi ohun ti ń mu irẹwẹsi ọkan-aya wá fun awọn eniyan ti wọn fi pẹlu otitọ-inu gbagbọ pe gbogbo isin ni o dara. Ṣugbọn Ọba-Alaṣẹ Agbaye naa, Jehofa Ọlọrun, ti pinnu pe Babiloni Nla kò ní àyè kankan ninu gbogbo agbaye ati pe ó ti ba agbegbe ilẹ ìṣẹ̀dá jẹ́ jìnnà pẹ́ tó. A gbọdọ fi pẹlu ipá ṣa a balẹ sinu iparun yán-án-yán-án.
16 Awọn ikọ̀ alagbara ti wà ní arọwọto nisinsinyi ti Ọlọrun lè gbà laaye lati mu iparun rẹ̀ ṣẹ, iyẹn ni, ẹgbẹ oloṣelu ayé. Iwe Ìfihàn naa ti Ọlọrun misi sọ asọtẹlẹ pe Jehofa yoo yiju awọn ololufẹ rẹ̀ pada si i, wọn yoo si tu u si ihoho, ní fifi ohun ti ó jẹ́ gan-an han gbangba—onijibiti ẹlẹmii eṣu! Nigba naa, wọn yoo fi ina jo o run wọn yoo si sọ ọ di okiti eeru, ki a sọ ọ lọna bẹẹ. Wọn yoo ba a lò lọna kan naa ti ó gba bá awọn olujọsin Ọlọrun otitọ alaijuwọsilẹ lò.—Ìfihàn 17:15-18; 18:24.
17. Njẹ igbesẹ akọni awọn alaṣẹ oṣelu lodisi Babiloni ha yí wọn pada si ijọsin Jehofa Ọlọrun bi, bawo ni a si ṣe mọ?
17 Igbesẹ oniwa ipa yii lodisi isin niha ọdọ awọn alaṣẹ oṣelu kò tumọsi pe wọn yoo wá yipada si ijọsin Jehofa Ọlọrun lẹhin naa. Igbesẹ mimuna wọn lodisi Babiloni ko tumọsi pe wọn yoo wá di ọ̀rẹ́ Ọlọrun nisinsinyi. Bi bẹẹkọ, wọn kò ní gbe igbesẹ ti ó tẹ̀lé e ti iwe Ìfihàn fihan pe wọn yoo gbé. (Ìfihàn 17:12-14) Wọn lè kun fun ayọ̀ gidigidi ni rírí iwa akọni wọn lodisi isin tí Jehofa Ọlọrun ti gbà wọn laaye lati ṣe aṣeyọri rẹ̀, ṣugbọn Satani Eṣu, “Ọlọrun ayé yii,” ti ń sa gbogbo agbara rẹ̀ lati doju ija kọ Jehofa Ọlọrun láìkáàárẹ̀ yoo ṣi maa baa lọ ní títàn wọn jẹ.—2 Korinti 4:4.
18, 19. (a) Ta ni ki yoo laaja lati rí idalare ipo ọba-alaṣẹ agbaye Jehofa nipasẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa? (b) Ṣugbọn awọn wo ni yoo jẹ́ awọn ẹlẹ́rìí titi lọ gbére sí idalare Jehofa lori Babiloni Nla?
18 Babiloni Nla ki yoo laaja lati rí otente titobilọla naa, idalare ipo ọba-alaṣẹ agbaye Jehofa nipasẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia,” ẹni ti o jẹ “Ọlọrun Alagbara” nisinsinyi ní ọwọ́ ọtun Olodumare, ati Ọlọrun Giga Julọ Kanṣoṣo naa, Jehofa.—Isaiah 9:6.
19 Ní iha awọn onworan, ṣugbọn labẹ aabo atọrunwa ti kò ṣee jáwọ̀, ni awọn Ẹlẹ́rìí fun Jehofa yoo wà. (Isaiah 43:10, 12) Labẹ aṣẹ lati awọn ọ̀run ododo wá, wọn yoo ti fi pẹlu igbọran jade kuro ninu Babiloni Nla. (Ìfihàn 18:4) Igbadun ododo wọn ki yoo láàlà lati inu awọn ohun ti ó ṣoju wọn. Lẹhin naa titi lae ni wọn yoo maa jẹ́ ẹlẹ́rìí fun Jehofa ti wọn yoo sì lè maa jẹ́rìí titi ayeraye sí idalare oun fúnraarẹ̀ lori Babiloni Nla.—Ìfihàn 19:1-3.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lati lè mọ ọn ni kulẹkulẹ, wo iwe naa “Babylon the Great Has Fallen!” God’s Kingdom Rules!, oju-iwe 468-500, ti a tẹjade lati ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
b Ẹkunrẹrẹ ijiroro nipa itilẹhin ẹgbẹ alufaa fun Ogun Agbaye I ni a fifunni ninu iwe naa Preachers Present Arms, lati ọwọ́ Ray H. Abrams (New York, 1933). Iwe naa wi pe: “Awọn alufaa fun ogun naa ní ijẹpataki tẹmi ati isunniṣe onigbonara rẹ̀. . . . Ogun naa fúnraarẹ̀ jẹ́ ogun mímọ́ lati gbé Ijọba Ọlọrun lori ilẹ̀-ayé ga. Lati fi ẹmi ẹni lélẹ̀ nitori orilẹ-ede ẹni jẹ́ lati fi i fun Ọlọrun ati Ijọba Rẹ̀. Ọlọrun ati orilẹ-ede wá di bakan naa. . . . Awọn ara Germany ati awọn Orilẹ-Ede Aládèéhùn Ifọwọsowọpọ jẹ́ bakan naa ninu ọran yii. Ìhà kọọkan gbà pe oun nikanṣoṣo lo ni Ọlọrun . . . Ọpọ julọ ninu awọn ẹlẹkọọ isin ni wọn kò ní iṣoro eyikeyii ní gbigbe Jesu ka apa iwaju patapata ninu ija ti ó kira julọ ti ń ṣamọna awọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun rẹ̀ lọ si ijagunmolu. . . . Ṣọọṣi tipa bayii di apakan timọtimọ fun eto-igbekalẹ ogun. . . . Awọn aṣaaju [ṣọọṣi] kò fi akoko kankan ṣofo ní ṣiṣeto ara wọn jọ daradara bi akoko bá tó fun ogun. Laaarin wakati mẹrinlelogun lẹhin ipolongo ogun, Igbimọ Apapọ Awọn Ṣọọṣi Kristi ní America gbe awọn iwewee kalẹ fun ifọwọsowọpọ kikunrẹrẹ julọ. . . . Ọpọ ninu awọn ṣọọṣi tun ṣe rekọja ohun ti a beere lọwọ wọn. Wọn di ibudo igbanisiṣẹ fun wiwọ iṣẹ ologun.”—Oju-iwe 53, 57, 59, 63, 74, 80, 82.