Ayé Tuntun Kan Tí Ọlọ́run Ṣèlérí
BÍBÉLÌ, tí í ṣe àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, fún wa ní ìrètí nígbà tó sọ pé: “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.”—2 Pétérù 3:13.
Kí ni “ọ̀run tuntun”? Bíbélì máa ń lo ọ̀run fún ìṣàkóso. (Ìṣe 7:49) “Ọ̀run tuntun” jẹ́ ìjọba tuntun tó máa ṣàkóso lórí ayé. Ó jẹ́ tuntun nítorí pé yóò rọ́pò ètò ìṣàkóso tó wà báyìí; ó tún jẹ́ ìgbésẹ̀ tuntun nínú bí ète Ọlọ́run ṣe ń ní ìmúṣẹ nìṣó. Òun ni Ìjọba tí Jésù Kristi kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà fún. (Mátíù 6:10) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ni Ẹni tó gbé e kalẹ̀ tó sì jẹ́ pé ọ̀run ló ń gbé, Bíbélì pè é ní “ìjọba ọ̀run.”—Mátíù 7:21.
Kí ni “ayé tuntun”? Kì í ṣe ilé ayé tuntun, níwọ̀n bí Bíbélì ti sọ ọ́ ní kedere pé títí láé làwọn èèyàn yóò máa gbé orí ilẹ̀ ayé. “Ayé tuntun” jẹ́ àwùjọ èèyàn tuntun. Yóò jẹ́ tuntun nítorí pé a óò ti ké àwọn ẹni burúkú kúrò nínú rẹ̀. (Òwe 2:21, 22) Gbogbo àwọn tó bá ń gbé láyé nígbà yẹn ni yóò máa bọlá fún Ẹlẹ́dàá tí wọn yóò sì máa ṣègbọràn sí i. (Sáàmù 22:27) Àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè gbogbo ni à ń ké sí báyìí láti wá kọ́ nípa àwọn òfin òdodo yẹn kí wọ́n sì máa gbé ìgbésí ayé wọn níbàámu pẹ̀lú rẹ̀ nísinsìnyí. Ṣé o ti ń ṣe èyí?
Nínú ayé tuntun Ọlọ́run, gbogbo èèyàn ni yóò bọ̀wọ̀ fún ìṣàkóso Rẹ̀. Ṣé ìfẹ́ fún Ọlọ́run ń sún ọ láti máa ṣègbọ́ràn sí i? (1 Jòhánù 5:3) Ṣé ìyẹn hàn kedere ní ilé rẹ? ní ibi iṣẹ́ tàbí ní iléewé? nínú ọ̀nà tó ò ń gbà lo ìgbésí ayé rẹ?
Nínú ayé tuntun yẹn, àwùjọ èèyàn yóò ṣọ̀kan nínú ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ náà. Ṣé ò ń jọ́sìn Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé? Ṣé ìjọsìn rẹ mú ọ wà níṣọ̀kan lóòótọ́ pẹ̀lú gbogbo àwọn olùjọ́sìn ẹlẹgbẹ́ rẹ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, gbogbo ẹ̀yà, gbogbo èdè?—Sáàmù 86:9, 10; Aísáyà 2:2-4; Sefanáyà 3:9.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]
Ọlọ́run Tó Ṣèlérí Àwọn Nǹkan Wọ̀nyí
Òun ni Ẹlẹ́dàá gbogbo ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run àti pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé. Òun ni ẹni tí Jésù Kristi pè ní “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.”—Jòhánù 17:3.
Èyí tó pọ̀ jù nínú aráyé ló jẹ́ pé ọlọ́run àtọwọ́dá ni wọ́n ń bọlá fún. Ọ̀kẹ́ àìmọye ló ń júbà fún àwọn ère tí kò lẹ́mìí. Àwọn àjọ tí ẹ̀dá èèyàn gbé kalẹ̀, ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì tàbí ìfẹ́ inú ara wọn làwọn mìíràn ń gbé lárugẹ. Kódà kì í ṣe gbogbo àwọn tó sọ pé Bíbélì làwọn gbé ìjọsìn àwọn kà pàápàá ló ń bọlá fún orúkọ ẹni tí Bíbélì pè ní “Ọlọ́run tòótọ́.”—Diutarónómì 4:35.
Ẹlẹ́dàá sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi.” (Aísáyà 42:5, 8) Nǹkan bí ìgbà ẹgbẹ̀rún méje ni orúkọ yìí fara hàn nínú Bíbélì tí wọ́n fi àwọn èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ kọ. Jésù Kristi kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.”—Mátíù 6:9.
Irú ẹni wo ni Ọlọ́run tòótọ́ jẹ́? Ó júwe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ‘aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, tó ń lọ́ra láti bínú, tó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́’ àti gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kì í jẹ́ kí àwọn tó ń mọ̀ọ́mọ̀ rú òfin rẹ̀ lọ láìjìyà. (Ẹ́kísódù 34:6, 7) Ìtàn nípa ọ̀nà tó gbà bá aráyé lò jẹ́rìí sí i pé irú ẹni tó jẹ́ lóòótọ́ gan-an nìyẹn.
A ní láti ya orúkọ yìí àti ẹni tó ni orúkọ náà sí mímọ́. Níwọ̀n bó ti jẹ́ Ẹlẹ́dàá àti Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run, ó yẹ ká máa ṣègbọràn sí i ká sì máa jọ́sìn òun nìkan. Ṣé ìwọ bí ẹnì kan ń ṣe bẹ́ẹ̀?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn Ìyípadà Wo Ni “Ọ̀run Tuntun” àti “Ayé Tuntun” Yóò Mú Wá?
Ayé yóò di Párádísè Lúùkù 23:43
Àwọn èèyàn jákèjádò ayé látinú Jòhánù 13:35;
gbogbo orílẹ̀-èdè, gbogbo ẹ̀yà àti Ìṣípayá 7:9, 10
gbogbo èdè á jẹ́ àwọn tí ìfẹ́
so pọ̀ ṣọ̀kan
Àlàáfíà á wà kárí ayé, ààbò Sáàmù 37:10, 11;
gidi á wà fún gbogbo èèyàn Míkà 4:3, 4
Iṣẹ́ tó tẹ́ni lọ́rùn á wà, oúnjẹ Aísáyà 25:6; 65:17, 21-23
á pọ̀ yanturu
Àìsàn, ìbànújẹ́ àti ikú á di Aísáyà 25:8; Ìṣípayá 21:1, 4
ohun ìgbàgbé
Ayé kan tó wà ní ìṣọ̀kan nínú Ìṣípayá 15:3, 4
ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ náà
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ṣé Wàá Fẹ́ Kí Ire Yìí Kàn Ọ́?
Ọlọ́run kò lè purọ́!—Títù 1:2.
Jèhófà polongo pé: “Ọ̀rọ̀ mi . . . kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.”—Aísáyà 55:11.
Ní báyìí o, Jèhófà ti ń dá “ọ̀run tuntun àti ayé tuntun.” Ìjọba ti ọ̀run ti ń báṣẹ́ lọ ní pẹrẹu. A ti fi ìpìlẹ̀ “ayé tuntun” lélẹ̀.
Lẹ́yìn tí ìwé Ìṣípayá ti sọ díẹ̀ lára àwọn nǹkan àgbàyanu tí “ọ̀run tuntun àti ayé tuntun” yóò mú wá fún aráyé, ó sọ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run, tí í ṣe Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run, fúnra rẹ̀ sọ, pé: “Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.” Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó wí pé: “Kọ̀wé rẹ̀, nítorí pé ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́.”—Ìṣípayá 21:1, 5.
Ìbéèrè pàtàkì tó yẹ ká bi ara wa ni pé, Ṣé à ń ṣe àwọn àtúnṣe tó lè mú wa dẹni tí a ó kà yẹ láti jẹ́ apá kan “ayé tuntun” lábẹ́ “ọ̀run tuntun” náà?