ORÍ KẸJỌ
‘Kí Ni Jèhófà Ń Béèrè Lọ́wọ́ Rẹ?’
1, 2. Kí nìdí tí mímọ ohun tí Jèhófà ṣe pẹ̀lú bí ìwà àwọn èèyàn rẹ̀ ayé ọjọ́un ṣe burú tó fi lè múni lọ́kàn yọ̀?
FOJÚ inú wo ìran yìí ná: Àyà ọmọbìnrin kan já bó ṣe gbọ́ tẹ́nì kan ń fagbára gbá ilẹ̀kùn gbà-gbà-gbà. Oníṣòwò kan, agbàlọ́wọ́-mérìí tó máa ń wá sin òbí rẹ̀ ní gbèsè ló rò pé ó ń gbá ilẹ̀kùn. Àìmọye èèyàn ni oníṣòwò yìí ti rẹ́ jẹ nípa lílo òṣùwọ̀n tí kò péye àti bíbu owó èlé tí kò bófin mu lé wọn. Kí gbogbo ìwà màkàrúrù tó ń hù lè jẹ́ àṣegbé, ó máa ń fún àwọn aláṣẹ lábẹ̀tẹ́lẹ̀ kí wọ́n lè máa kọ etí ikún sí igbe àwọn tó bá wá fẹjọ́ rẹ̀ sùn. Ọmọbìnrin náà mọ̀ pé kò sí olùgbèjà; bàbá rẹ̀ ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ó sì ti bá ọmọge lọ. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ta òun àti ìyá rẹ̀ lẹ́rú.
2 Ìran yẹn jẹ́ àkópọ̀ díẹ̀ lára ìwàkiwà táwọn wòlíì méjìlá náà sọ pé kò dára. (Ámósì 5:12; 8:4-6; Míkà 6:10-12; Sefanáyà 3:3; Málákì 2:13-16; 3:5) Ká sọ pé o wà láyé nígbà yẹn, kí lò bá ṣe nítorí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yẹn? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun tó ń ṣelẹ̀ nígbà ayé àwọn wòlíì méjìlá náà lè bà ọ́ lọ́kàn jẹ́ gidigidi, ọ̀nà rere tí Jèhófà gbà bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò lákòókò náà lè mú ọ lọ́kàn yọ̀. Dájúdájú, wàá rí i nínú àwọn ìwé méjìlá náà pé Jèhófà tẹnu mọ́ ìwà tó dára gan-an àti ànímọ́ rere. Ìṣírí rẹ̀ lè mú kí ìwà rẹ dára sí i, ó lè mú kó o máa ṣe ohun tó dára, ó sì lè mú kó o máa yìn ín. Níwọ̀n bí ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà ti ń yára sún mọ́lé, tó o bá gbé àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fúnni níṣìírí tó wà nínú àwọn ìwé náà yẹ̀ wò, wàá lè mọ ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ rẹ. Wàyí o, bẹ̀rẹ̀ nípa gbígbé àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Míkà ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni yẹ̀ wò.
Jèhófà rí ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà ìrẹ́jẹ táwọn èèyàn ń hù
KÍ NI JÈHÓFÀ Ń BÉÈRÈ LỌ́WỌ́ RẸ?
3, 4. (a) Àrọwà tó fani wọni lọ́kàn wo ló wà lára àwọn ohun tí ìwé Míkà sọ? (b) Báwo ni ìbéèrè tó wà nínú Míkà 6:8 ṣe kàn ọ́?
3 Tó o bá ń ka ìwé Míkà, ẹ̀sùn rẹpẹtẹ ni wàá kọ́kọ́ rò pé ó ń kà sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì oníwàkiwà lọ́rùn. Òótọ́ ni pé Jèhófà rí ìwà ìbàjẹ́ táwọn èèyàn rẹ̀ ń hù, títí kan ìwàkiwà tí àwọn tó pè ní “olùkórìíra ohun rere àti olùfẹ́ ìwà búburú” ń hù. (Míkà 3:2; 6:12) Àmọ́ ṣá o, yàtọ̀ sí pé ìwé Míkà dá àwọn èèyàn náà lẹ́bi, ó tún sọ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ ìṣílétí tó wọni lọ́kàn jù lọ tó sì ń múni gbégbèésẹ̀, tá a rí nínú Bíbélì. Míkà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ dá lórí Ọlọ́run tó jẹ́ Orísun àwọn ìlànà òdodo, ó sì béèrè ìbéèrè tí ń múni ronú jinlẹ̀ yìí pé: “Kí sì ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?”—Míkà 6:8.
4 Ǹjẹ́ o rí àrọwà tí Ẹlẹ́dàá wa ń pa nínú ẹsẹ Bíbélì yìí? Ẹlẹ́dàá fìfẹ́ rán wa létí àwọn ànímọ́ àtàtà tó yẹ ká gbìyànjú láti ní dípò ká jẹ́ kí ìwà ibi tó gbayé kan sọ wá di oníwàkiwà. Jèhófà mọ̀ pé níwọ̀n bá a ti jẹ́ adúróṣinṣin sí òun, ó wù wá láti ní àwọn ànímọ́ rere bíi tòun, ó sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé a lè ṣe bẹ́ẹ̀. Báwo ni wàá ṣe dáhùn tí wọ́n bá bi ọ́ pé: ‘Kí ni Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ rẹ?’ Ǹjẹ́ wàá lè tọ́ka sí àwọn ìhà kan nínú ìgbésí ayé rẹ tí àwọn ìlànà Ọlọ́run nípa irú ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù ti ń tún ìwà rẹ ṣe tàbí àwọn ìhà kan tó yẹ kó ti máa tún ìwà rẹ ṣe? Bó o ṣe ń sapá láti máa gbé ìgbé ayé rẹ níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà wọ̀nyẹn, àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run yóò máa dára sí i, ìgbésí ayé rẹ yóò sì túbọ̀ nítumọ̀. Bó ṣe kù dẹ̀dẹ̀ kí Párádísè dé yìí, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìyànjú kan tí Bíbélì sọ fún ọ níṣìírí. Ọ̀rọ̀ ìyànjú ọ̀hún ni pé: “Ẹ fún irúgbìn fún ara yín ní òdodo; ẹ kárúgbìn ní ìbámu pẹ̀lú inú-rere-onífẹ̀ẹ́. Ẹ ro ilẹ̀ adárafọ́gbìn fún ara yín nígbà tí àkókò wà fún wíwá Jèhófà, títí yóò fi dé, tí yóò sì fún yín ní ìtọ́ni ní òdodo.” (Hóséà 10:12) Ní báyìí, jẹ́ ká gbé kókó pàtàkì díẹ̀ yẹ̀ wò nínú ìmọ̀ràn tí Míkà 6:8 gbà wá.
“JẸ́ ẸNI TÍ Ó MẸ̀TỌ́MỌ̀WÀ”
5. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fi ‘ìmẹ̀tọ́mọ̀wà’ bá Ọlọ́run rìn?
5 Ohun tí Míkà sọ ṣe pàtàkì gan-an, ó ní Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ wa pé ‘ká máa fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà’ bá Òun rìn. Tá a bá mẹ̀tọ́mọ̀wà, ìyẹn ni pé tá a mọ̀wọ̀n ara wa, á ṣe wá láǹfààní nítorí pé “ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.” (Òwe 11:2) Ọ̀kan lára àwọn ohun tó máa fi hàn pé a jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà ni pé, ká mọ àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tí ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù mú ká ní. Ohun pàtàkì tá a sì gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe láti máa sá fún ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá ni pé ká gbà pé inú ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n ti bí wa.—Róòmù 7:24, 25.
6. Tá a bá fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà ronú lórí àbájáde ẹ̀ṣẹ̀, báwo ni yóò ṣe ṣe wá láǹfààní?
6 Kí nìdí tí ìmẹ̀tọ́mọ̀wà pa pọ̀ mọ́ ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn fi ṣe pàtàkì gan-an fún èèyàn láti lè yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá? Ìdí ni pé ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà máa ń mọ agbára tí ẹ̀ṣẹ̀ ní. (Sáàmù 51:3) Hóséà jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ máa ń fani mọ́ra, àti pé àbámọ̀ ló máa ń gbẹ̀yìn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ pé láìsí àní-àní, òun á “béèrè ìjíhìn” lọ́wọ́ àwọn èèyàn òun ayé ọjọ́un fún jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ aláìgbọràn. Ǹjẹ́ ìyẹn dún bíi pé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wọ̀nyẹn á bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ń dá? Ó ṣeé ṣe kí wọ́n retí pé àwọn á bọ́, ó ṣe tán, ẹ̀ṣẹ̀ máa ń tan ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹ ó sì máa ń sọ ọ́ di ẹrú. Èyí tó burú jù ni pé, ẹ̀ṣẹ̀ máa ń múni kẹ̀yìn sí Ọlọ́run, kódà ó lè mú kí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà bá a dé ibi tó burú jáì, kí ‘àwọn ìbánilò rẹ̀ má fàyè gbà á láti padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀.’ Ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá á mú kí ìpinnu tí ẹni náà ṣe láti máa hùwà tó dára di èyí tí kò lágbára, á jẹ́ kó sọ ‘ṣíṣe ohun tó ń pani lára’ dàṣà. Kò mọ síbẹ̀ o, ẹ̀ṣẹ̀ máa ń sọ èèyàn di aláìwúlò nígbèésí ayé. Ká sòótọ́, ó lè kọ́kọ́ dà bíi pé nǹkan ń dán fún ẹni tó ń dẹ́ṣẹ̀, àmọ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò bá ronú pìwà dà kò lè rí ojú rere Ọlọ́run. —Hóséà 1:4; 4:11-13; 5:4; 6:8.
7. Báwo làwọn tí wọ́n jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà ṣe máa ń ṣe sí ìtọ́sọ́nà Jèhófà?
7 Àwọn tó mẹ̀tọ́mọ̀wà tún máa ń gbà pé àwọn nílò ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run káwọn tó lè yẹra fún ìbànújẹ́ tó máa ń tìdí ẹ̀ṣẹ̀ yọ. Míkà rí i tẹ́lẹ̀ pé àkókò kan ń bọ̀ tí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn yóò máa fi gbogbo ọkàn wá bí ‘Jèhófà á ṣe fún wọn ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀’ àti bí wọ́n á ṣe máa “rìn ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀.” Àkókò wa yìí gan-an sì ni àkókò náà. Irú àwọn ọlọ́kàn tútù bẹ́ẹ̀ ń wá “òfin” àti “ọ̀rọ̀ Jèhófà.” Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà láyọ̀ pé o wà lára àwọn tó fẹ́ láti máa “rìn ní orúkọ Jèhófà” nípa ṣíṣe àwọn ohun tó béèrè. Kódà bó o tiẹ̀ wà lára wọn, o ṣì lè fẹ́ láti “mọ́ níwà” láwọn ọ̀nà mìíràn bíi ti Míkà. (Míkà 4:1-5; 6:11) Tó o bá ń fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà wá bí wàá ṣe máa ṣe ohun tí Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ rẹ, ìyẹn á ràn ọ́ lọ́wọ́ gidigidi.
JẸ́ KÍ ÌWÀ TÌRẸ YÀTỌ̀
8. Kí lo kíyè sí nípa bí ìwà ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe rí láyé lónìí?
8 Nítorí pé Jèhófà ń wá ire wa nípa tara àti nípa tẹ̀mí, ó béèrè pé ká jẹ́ oníwà mímọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà tí ń tini lójú pọ̀ láyé bí nǹkan míì. (Málákì 2:15) Àwọn nǹkan tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ ni wọ́n dá lé pọ̀ jaburata. Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé kò sóhun tó burú nínú káwọn máa wo àwọn ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe nínú ìwé àti fídíò, wọ́n rò pé kò sóhun tó burú nínú káwọn máa kà nípa báwọn èèyàn ṣe ń ṣèṣekúṣe, tàbí káwọn máa gbọ́ àwọn orin tó máa ń múni ròròkurò. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan wà tí wọn ò bọ̀wọ̀ fáwọn obìnrin rárá, wọ́n kà wọ́n sí ohun èlò ìbálòpọ̀ lásán-làsàn. Àwọn ọmọ ilé ìwé sì máa ń sọ ọ̀rọ̀ rírùn àti ọ̀rọ̀ tó dá lórí ìṣekúṣe. Báwo lo ṣe lè gbéjà ko àwọn ohun tó lè sọni di oníwàkiwà yìí?
9. Báwo lọ̀pọ̀ èèyàn kò ṣe tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà nígbà ayé àwọn wòlíì méjìlá náà?
9 Àwọn wòlíì méjìlá náà sọ ọ̀rọ̀ ìṣílétí tó ṣe pàtàkì gan-an fún wa. Lákòókò tí wọ́n gbé láyé, kò tíì sí tẹlifíṣọ̀n, sinimá àti fídíò tí wọn ti lè máa wo ìwòkuwò, àmọ́ àwọn àwòrán tó ṣàpẹẹrẹ ẹ̀yà ìbímọ wà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìṣekúṣe aláìnítìjú bí ajá àti ọ̀kan táwọn tó ń ṣe é ń pè ní iṣẹ́ aṣẹ́wó mímọ́. (1 Àwọn Ọba 14:24; Aísáyà 57:3, 4; Hábákúkù 2:15) Wàá rí i pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí tó o bá wo ohun táwọn wòlíì náà kọ. Ọ̀kan lára wọn kọ̀wé pé: “Ní ti àwọn ọkùnrin wọnnì, àwọn aṣẹ́wó ni wọ́n ya ara wọn sápá kan fún, wọ́n sì ń bá àwọn kárùwà obìnrin inú tẹ́ńpìlì rúbọ.” Òmíràn tún kọ̀wé pé: “Ọkùnrin kan àti baba rẹ̀ sì ti lọ sọ́dọ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin kan náà, fún ète sísọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́.” Àwọn kan máa ń “sanwó fún àwọn aṣẹ́wó” lákòókò tí wọ́n bá ń ṣe ààtò ìbímọlémọ.a Ìwà panṣágà gbalé gbòde, àwọn tó jẹ́ aláìṣòótọ́ sí ọkọ wọn àti aya wọn ‘ń tọ àwọn olùfẹ́ wọn onígbòónára lẹ́yìn.’—Hóséà 2:13; 4:2, 13, 14; Ámósì 2:7; Míkà 1:7, ìtumọ̀ Bíbélì Contemporary English Version.
10. (a) Kí ni lájorí ohun tó máa ń fa ìwà àìmọ́? (b) Báwo làwọn èèyàn Ọlọ́run ayé ọjọ́un ṣe ṣe àgbèrè tẹ̀mí?
10 Ó ṣeé ṣe kó o mọ̀ pé tẹ́nì kan bá ṣèṣekúṣe, èrò rẹ̀ àtohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ nìyẹn fi hàn. (Máàkù 7:20-22) Jèhófà sọ nípa àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n ya oníwà ìbàjẹ́ pé “ẹ̀mí àgbèrè [“ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ fún ìbálòpọ̀,” ìtumọ̀ Bíbélì CEV] gan-an ti mú kí wọ́n rìn gbéregbère lọ” àti pé “kìkì ìwà àìníjàánu ni wọ́n ń bá a lọ ní híhù.” (Hóséà 4:12; 6:9)b Sekaráyà sọ pé wọ́n ní “ẹ̀mí ìwà àìmọ́.” (Sekaráyà 13:2) Ńṣe làwọn èèyàn náà ń ṣàyàgbàǹgbà hùwàkiwà wọn, wọn ò tiẹ̀ bọ̀wọ̀ kankan fún àwọn ìlànà àti àṣẹ Jèhófà, kódà wọ́n ń tẹ́ńbẹ́lú àwọn ìlànà àti àṣẹ ọ̀hún. Nítorí náà, ẹni tó bá fẹ́ yí padà lára wọn gbọ́dọ̀ yí ọ̀nà tó gbà ń ronú àtohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ padà pátápátá. Mímọ̀ táwa Kristẹni mọ èyí yẹ kó mú ká túbọ̀ mọyì ìrànlọ́wọ́ tá à ń rí gbà láti máa yẹra fún ìṣekúṣe àti àbámọ̀ tó máa ń gbẹ̀yìn rẹ̀.
JẸ́ ONÍWÀ MÍMỌ́
11. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tó máa ń jẹ́ àbájáde ìṣekúṣe?
11 Ó ṣeé ṣe kó o ti rí i pé ìṣekúṣe máa ń tú ìdílé ká, pé kì í jẹ́ káwọn ọmọ lè rí àbójútó òbí, pé ó máa ń fa àìsàn tó ń kóni nírìíra, àti pé ó máa ń mú káwọn èèyàn máa ṣẹ́yún, èyí tó jẹ́ ìpànìyàn. Àwọn tí kì í ka ọ̀rọ̀ Ẹlẹ́dàá nípa ìbálòpọ̀ sí máa ń jìyà rẹ̀, ó máa ń kó bá ìlera wọn ó sì máa ń fa ìrònú fún wọn. Míkà kọ̀wé pé: “Nítorí òtítọ́ náà pé [ẹnì kan] ti di aláìmọ́, ìfọ́bàjẹ́ wà; iṣẹ́ ìfọ́bàjẹ́ náà sì ń roni lára.” (Míkà 2:10) Bí àwọn tí wọ́n ń hùwà tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe mọ èyí ń fún wọn lágbára láti máa yẹra fún ohun tí kò tọ́. Wọn kì í fàyè gba ìròkurò kí ọkàn wọn má bàa di ẹlẹ́gbin.—Mátíù 12:34; 15:18.
12. Àǹfààní wo ló máa ṣe wá tá a bá ń fi ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìbálòpọ̀ wò ó?
12 Kì í ṣe ìbẹ̀rù pé ó ṣeé ṣe ká kó àrùn tàbí pé ó ṣeé ṣe ká bímọ àlè ló mú káwa Kristẹni máa sá fún ìṣekúṣe o. Ńṣe la rí i pé àǹfààní wà nínú kéèyàn nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run àti kéèyàn máa fi ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìbálòpọ̀ wò ó. Jèhófà dá ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ mọ́ èèyàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí ọkùnrin kan àti obìnrin kan tí wọ́n ti ṣègbéyàwó lè gbà fìfẹ́ hàn sí ara wọn. Ìyẹn jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn tó fi dá akọ àti abo. Tí ìbálòpọ̀ bá mọ sí àárín tọkọtaya nìkan, àǹfààní wà ńbẹ̀. Ó máa ń mú kí tọkọtaya wà níṣọ̀kan ó sì lè yọrí sí ọmọ bíbí nígbà mìíràn. Àmọ́ aburú ni ìbálòpọ̀ láàárín àwọn tí wọn kì í ṣe tọkọtaya máa ń fà, gẹ́gẹ́ bí ohun táwọn wòlíì méjìlá náà sọ ṣe fi hàn. Nígbà táwọn èèyàn Ọlọ́run ayé ọjọ́un ṣèṣekúṣe, wọ́n pàdánù ojú rere Ọlọ́run. Nǹkan ńlá tí ìṣekúṣe ná wọn láyé ìgbà yẹn nìyẹn, ohun kan náà ló sì máa ná àwọn tó ń ṣèṣekúṣe lóde òní.
13. Lọ́nà kan, báwo la ṣe lè ‘mú ìwà àgbèrè kúrò níwájú ara wa’ ká sì yẹra fún ìdẹwò?
13 Hóséà bẹ àwọn èèyàn ìgbà ayé rẹ̀ pé kí wọ́n ‘mú ìwà àgbèrè wọn kúrò níwájú ara wọn,’ èyí tó fi hàn pé wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe àwọn nǹkan kan pàtó láti pa ìwà mímọ́ wọn mọ́. (Hóséà 2:2) Ní tiwa, ìwà ọgbọ́n ló jẹ́ tá a bá ń yàgò fún àwọn ipò tó lè dẹni wò láti ṣèṣekúṣe. Bí àpẹẹrẹ, o lè máa rí ìdẹwò ní gbogbo ìgbà ní ilé ìwé tàbí ládùúgbò rẹ. Ó lè má ṣeé ṣe fún ọ láti pa ilé ìwé náà tì kó o sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí òmíràn tàbí kó o kó kúrò níbi tó ò ń gbé. Àmọ́ àwọn ọ̀nà mìíràn wà tó o lè gbà ta kété sí àwọn ipò tó lè dẹ ọ́ wò kó o sì tipa bẹ́ẹ̀ ‘mú ìwà àgbèrè kúrò níwájú ara rẹ.’ Jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé o jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Kristẹni tòótọ́, pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ́. Lọ́nà tó máa yé wọn yékéyéké tó sì máa fọ̀wọ̀ hàn, ṣàlàyé ìlànà ìwà híhù tí ìwọ ń tẹ̀ lé àti ohun tó o gbà gbọ́. Rí i dájú pé àwọn mìíràn mọ̀ pé ìpinnu tìẹ ni láti máa pa àwọn ìlànà Jèhófà mọ́. (Ámósì 5:15) Ọ̀nà mìíràn tó o lè gba ‘mú ìwà àgbèrè kúrò níwájú ara rẹ’ ni pé kó o máa yẹra fún wíwo àwọn ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe àti ṣíṣe eré ìnàjú tó jẹ́ ti ìwà àìmọ́. Ìyẹn lè gba pé kó o kó àwọn ìwé ìròyìn kan dà nù tàbí pé kó o wá àwọn mìíràn tí wàá máa bá kẹ́gbẹ́, ìyẹn àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì gbà pé ó yẹ kó o ṣe ohun tó ń béèrè lọ́wọ́ rẹ. (Míkà 7:5) Dájúdájú, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, o lè yẹra fún dídi ẹni tí ìwà àìmọ́ tó wà láyé sọ di oníwàkiwà!
Tó o bá ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tó o gbà gbọ́ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, ìyẹn á máa dáàbò bò ọ́
“NÍFẸ̀Ẹ́ INÚ RERE”
14, 15. (a) Kí ló túmọ̀ sí láti “nífẹ̀ẹ́ inú rere”? (b) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ inú rere, báwo nìyẹn ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe ṣe ohun tó lè fa ẹ̀gàn?
14 Míkà tẹnu mọ́ ọn pé Jèhófà béèrè pé ká “nífẹ̀ẹ́ inú rere.” Tẹ́nì kan bá jẹ́ onínúure, ẹni náà á máa ṣe rere sáwọn èèyàn, kò ní máa ṣe ohunkóhun tó lè pa wọ́n lára. Ọmọ ìyá ìṣoore àti ìwà ọmọlúwàbí ni inú rere. Ká tó lè jẹ́ onínú rere, a ò gbọ́dọ̀ máa rẹ́ àwọn ẹlòmíràn jẹ, a ò sì gbọ́dọ̀ máa fi dúdú pe funfun fún wọn. Ní Orí Kẹfà ìwé yìí, a ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìhà tó ti ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ olóòótọ́ àti ẹni tí kì í rẹ́ àwọn ẹlòmíràn jẹ, irú bíi lẹ́nu iṣẹ́ ajé àti nínú ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ owó. Àmọ́ kì í ṣe àwọn ìhà yẹn nìkan ló ti yẹ ká jẹ́ olóòótọ́, onínú rere àti ẹni tí kì í rẹ́ àwọn ẹlòmíràn jẹ.
15 Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ inú rere tí wọ́n sì máa ń ṣe rere sáwọn ẹlòmíràn máa ń sapá láti má ṣe ṣe ohunkóhun tó lè fa ẹ̀gàn. Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọn kì í fi ohun ìní wọn ṣe ìtìlẹ́yìn fún ìjọsìn mímọ́ pé: “Ẹ ń jà mí lólè.” (Málákì 3:8) Ǹjẹ́ o lè fòye gbé àwọn ọ̀nà tẹ́nì kan lè máa gbà ja Ọlọ́run lólè lónìí? Ká sọ pé arákùnrin kan ń mójú tó owó táwọn ará nínú ìjọ tàbí àwọn mìíràn fi ṣe ìtìlẹyìn fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, ta ló ni owó náà? Jèhófà ló ni irú owó bẹ́ẹ̀, nítorí pé ńṣe ni wọ́n fi ṣe ọrẹ kí ìjọsìn mímọ́ lè máa tẹ̀ síwájú. (2 Kọ́ríńtì 9:7) Ǹjẹ́ ó yẹ kí ẹnikẹ́ni rò pé òun lè “yá” irú owó bẹ́ẹ̀ láti fi bójú tó nǹkan pàjáwìrì kan láìgbàṣẹ? Rárá o. Ńṣe nìyẹn máa dà bí ẹní ja Ọlọ́run lólè! Tẹ́nì kan bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, ẹni náà kò fi inú rere tàbí ẹ̀tọ́ bá àwọn tó fi owó náà ṣe ọrẹ fún iṣẹ́ Ọlọ́run lò nìyẹn.—Òwe 6:30, 31; Sekaráyà 5:3.
16, 17. (a) Báwo làwọn kan ṣe fi hàn pé àwọn jẹ́ oníwọra nígbà ayé Ámósì àti Míkà? (b) Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ojúkòkòrò?
16 Kò mọ síbẹ̀ o, inú rere àti ìṣoore máa ń mú kí Kristẹni máa sá fún ojúkòkòrò. Nígbà ayé Ámósì, ìwà ìwọra gbilẹ̀. Àwọn aláìláàánú agbàlọ́wọ́-mérìí ò kọ̀ láti ‘ta olódodo fún owó fàdákà lásán-làsàn,’ bẹ́ẹ̀ olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn ní í ṣe! (Ámósì 2:6) Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yẹn jọ ti ìgbà ayé Míkà táwọn ọlọ́rọ̀ ní Júdà ń já ohun ìní àwọn tí kò ní olùgbèjà gbà, kódà wọ́n tún máa ń fi ipá gbà á. (Míkà 2:2; 3:10) Bí àwọn oníwọra yẹn ṣe ń já ilẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ẹlẹgbẹ́ wọn gbà, Òfin Jèhófà ni wọ́n ń rú: títí kan èyí tó gbẹ̀yìn nínú Òfin Mẹ́wàá tó sọ pé ẹnikẹ́ni nínú wọn ò gbọ́dọ̀ ta ilẹ̀ tó jogún láìní gbà á padà.—Ẹ́kísódù 20:13, 15, 17; Léfítíkù 25:23-28.
17 Ó lè máà wọ́pọ̀ lónìí pé kí wọ́n máa ta èèyàn tàbí kí wọ́n máa sọ èèyàn di ẹrú bíi ti ìgbà ayé àwọn wòlíì náà. Àmọ́ ṣé kò wọ́pọ̀ pé káwọn èèyàn máa dọ́gbọ́n jẹ lára àwọn mìíràn tàbí kí wọ́n máa fọgbọ́n rẹ́ni jẹ? Kristẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ inú rere kò ní máa dọ́gbọ́n jẹ lára àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó máa rí i pé kò ní bójú mu kóun dá iṣẹ́ kan sílẹ̀ tàbí kóun polongo okòwò kan tó jẹ́ pé àwọn ará nìkan ló máa jẹ́ oníbàárà òun. Téèyàn bá ń wá ọ̀nà bó ṣe máa tètè rí owó nípa dídọ́gbọ́n jẹ lára àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ìwà ìwọra nìyẹn, Ọlọ́run sì kìlọ̀ fáwa Kristẹni pé ká yàgò fún ìwà ìwọra. (Éfésù 5:3; Kólósè 3:5; Jákọ́bù 4:1-5) Àwọn ohun tó lè fi hàn pé ẹnì kan jẹ́ oníwọra ni ìfẹ́ owó, ìfẹ́ láti dé ipò agbára tàbí ipò tí yóò ti máa rí èrè, kódà ara ìwà ìwọra ni kéèyàn kúndùn oúnjẹ àti ọtí ju bó ti yẹ lọ, tàbí kéèyàn ní ìfẹ́ àníjù fún ìbálòpọ̀ àtàwọn nǹkan mìíràn. Míkà fi hàn pé àwọn oníwọra, tó jẹ́ pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, kò ‘ní yó.’ Bó ṣe rí fáwọn oníwọra lónìí náà nìyẹn o.—Míkà 6:14.
Ọ̀pọ̀ Kristẹni ń fìfẹ́ ran àwọn àjèjì lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà
18, 19. (a) Kí làwọn kan lára àwọn wòlíì méjìlá náà sọ nípa ìgbatẹnirò tí Jèhófà ní fún àwọn “àtìpó”? (b) Báwo ni fífi ìfẹ́ hàn sáwọn ẹlòmíràn ṣe lè jẹ́ kí àjọṣe tó wà láàárín onílé àtàlejò dára sí i níbi tó ò ń gbé?
18 Jèhófà sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n ‘má ṣe lu àtìpó ní jìbìtì.’ Ó sì tún gbẹnu Málákì kéde pé: ‘Èmi yóò sún mọ́ yín fún ìdájọ́, lòdì sí àwọn tí ń lé àtìpó dà nù.’ (Sekaráyà 7:10; Málákì 3:5) Ṣé ìyípadà ń dé bá àgbègbè ibi tó ò ń gbé nítorí àwọn tó ń rọ́ wá síbẹ̀ láti orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, tàbí ìlú mìíràn tí ìṣe àti àṣà wọn yàtọ̀ sí ti ibi tó ò ń gbé? Bóyá nítorí ààbò, iṣẹ́ tàbí torí kí nǹkan lè túbọ̀ rọrùn fún wọn ni wọ́n ṣe wá síbẹ̀. Ojú wo lo fi máa ń wo àwọn tí èdè wọn àti ọ̀nà tí wọ́n gbà ń gbé ìgbésí ayé yàtọ̀ sí tìrẹ? Ṣé o ò ní ẹ̀tanú, èyí tó jẹ́ ìdàkejì inú rere?
19 Ronú nípa bí inú àwọn èèyàn níbi tó ò ń gbé yóò ṣe dùn tó tí wọ́n bá rí i pé àtọmọ ìbílẹ̀ àtàwọn tí kì í ṣọmọ ìbílẹ̀ lò ń sọ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì fún. Inú rere ò ní jẹ́ ká máa rò pé àwọn tó kó wá yìí ò ní jẹ́ ká gbádùn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa tàbí àwọn nǹkan mìíràn. Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn Kristẹni kan tó jẹ́ Júù ní ẹ̀tanú díẹ̀ sí àwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù, ni Pọ́ọ̀lù bá rán wọn létí pé, ní tòdodo, kò sẹ́nì kan tó yẹ; inú-rere-àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run ló mú kó ṣeé ṣe fún ẹnikẹ́ni nínú wọn láti rí ìgbàlà. (Róòmù 3:9-12, 23, 24) Inú rere á mú kí inú wa máa dùn pé ìfẹ́ Ọlọ́run ti ń dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn tó jẹ́ pé àǹfààní díẹ̀ ni wọ́n ní láti gbọ́ ìhìn rere níbi tí wọ́n ti wá. (1 Tímótì 2:4) Àwọn tí wọ́n wá láti ibòmíràn sábà máa ń ṣaláìní. Nítorí náà, ó yẹ ká máa fi ìgbatẹnirò àti inú rere hàn sí wọn, ká gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀, ká máa bá ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lò gẹ́gẹ́ bí “ọmọ ìbílẹ̀.”—Léfítíkù 19:34.
BÁ ỌLỌ́RUN TÒÓTỌ́ RÌN
20. Ọ̀dọ̀ àwọn wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ń wá ìtọ́sọ́nà lọ?
20 Míkà tún tẹnu mọ́ bíbá Ọlọ́run rìn, kéèyàn gbẹ́kẹ̀ lé e gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tòótọ́, kéèyàn máa wá ìtọ́sọ́nà rẹ̀. (Òwe 3:5, 6; Hóséà 7:10) Lẹ́yìn táwọn Júù ti ìgbèkùn dé, àwọn kan lára wọn lọ ń bá àwọn woṣẹ́woṣẹ́, àwọn tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ oríire, àtàwọn ọlọ́run èké, bóyá káwọn yẹn lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nítorí ọ̀dá. Wọ́n ń pe àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú láti ràn wọ́n lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ketekete ni Jèhófà sọ pé irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ kò dára. (Diutarónómì 18:9-14; Míkà 3:6, 11; 5:12; Hágáì 1:10, 11; Sekaráyà 10:1, 2) Àwọn Júù wọ̀nyẹn ń bá àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tí wọ́n ń ta ko Ọlọ́run tòótọ́ lò!
21, 22. (a) Àwọn oríṣi ìbẹ́mìílò wo ló wọ́pọ̀ ládùúgbò rẹ? (b) Kí nìdí táwọn ojúlówó ìránṣẹ́ Jèhófà kì í fi í lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òkùnkùn?
21 Lóde òní, àwọn kan rò pé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú tí Bíbélì mẹ́nu kàn kì í ṣe ẹni gidi, pé ńṣe ni wọ́n wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ èrò ibi. Àmọ́, Bíbélì fi hàn pé ẹni gidi làwọn ẹ̀mí èṣù àti pé àwọn ni wọ́n wà lẹ́yìn ìwòràwọ̀, iṣẹ́ àjẹ́, àti oríṣiríṣi iṣẹ́ òkùnkùn mìíràn. (Ìṣe 16:16-18; 2 Pétérù 2:4; Júúdà 6) Ewu ń bẹ nínú ìbẹ́mìílò o. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àwọn èèyàn máa ń lọ bá àwọn adáhunṣe tàbí àwọn babaláwo tí wọ́n sọ pé àwọn ní agbára abàmì, tàbí kí wọ́n lọ bá àwọn oníṣẹ́ oṣó. Àwọn mìíràn máa ń wá ìtọ́sọ́nà látinú ìràwọ̀ ọjọ́ ìbí tàbí káàdì ìwoṣẹ́, ọpọ́n tàbí ọ̀pá ìwoṣẹ́, tàbí dígí tí wọ́n máa ń wò sọ àsọtẹ́lẹ̀. Kódà ó wọ́pọ̀ pé káwọn èèyàn máa gbìyànjú láti bá òkú sọ̀rọ̀. Ìròyìn fi hàn pé àwọn aláṣẹ kan lo ìwòràwọ̀ wọ́n sì lọ bá àwọn abẹ́mìílò láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú ìpinnu tí wọ́n fẹ́ ṣe. Ó ṣe kedere pé gbogbo èyí lòdì sí ìmọ̀ràn tí Míkà gbà wá pé ká bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn, ká máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀.
22 Dájúdájú, ìwọ tó o jẹ́ ojúlówó ìránṣẹ́ Jèhófà kò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ nínú irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀. Jẹ́ kó dá ọ lójú pé Ọlọ́run kì í lo agbára rẹ̀ nípasẹ̀ iṣẹ́ òkùnkùn, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í lo iṣẹ́ òkùnkùn láti fi sọ ohun tó fẹ́ ṣe fún àwọn èèyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ámósì 3:7 mú un dá wa lójú pé Jèhófà ‘ń ṣí àwọn ọ̀ràn àṣírí rẹ̀ payá fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.’ Téèyàn bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òkùnkùn, ẹni náà á bọ́ sábẹ́ ìdarí Sátánì tí í ṣe alákòóso àwọn ẹ̀mí èṣù. Òpùrọ́ ni Sátánì, ó sì ń fi ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí tan àwọn èèyàn jẹ. Ìkà lòun àtàwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀, wọ́n sì ti pinnu láti máa ṣe àwọn èèyàn léṣe, kódà láti máa pa wọ́n. (Jóòbù 1:7-19; 2:7; Máàkù 5:5) Abájọ tí Míkà fi sọ pé iṣẹ́ wíwò àti iṣẹ́ oṣó kò dára nígbà tó rọ̀ wá pé ká bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.
Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí iṣẹ́ òkùnkùn
23. Ta lẹnì kan ṣoṣo tó lè fún wa ní àwọn ohun tó tọ́ tá a bá béèrè?
23 Ọ̀dọ̀ Jèhófà àti inú ìjọsìn mímọ́ rẹ̀ nìkan la ti lè rí ojúlówó ìtọ́sọ́nà. (Jòhánù 4:24) Wòlíì Sekaráyà kọ̀wé pé ọwọ́ Jèhófà ni kó o ti máa béèrè ohun tó o bá fẹ́. (Sekaráyà 10:1) Kódà bí àwọn ẹ̀mí búburú bá gbéjà kò ọ́ tàbí tí wọ́n dẹ ọ́ wò, rántí pé “olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni yóò yè bọ́.” (Jóẹ́lì 2:32) Ìfinilọ́kànbalẹ̀ yìí ṣe pàtàkì bá a ṣe ń fi ọjọ́ ńlá Jèhófà sọ́kàn.
24. Àwọn ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú Míkà 6:8?
24 Dájúdájú, Míkà 6:8 sọ ọ̀pọ̀ nǹkan tá a lè ronú lé lórí. Ká tó lè jẹ́ alágbára nínú híhu ìwà tó mọ́, a ní láti ní èrò tó tọ́ àti àwọn ànímọ́ bíi ti Ọlọ́run. Hóséà fún àwa tá à ń gbé ní “apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́” níṣìírí. Ó sọ pé nígbà tiwa yìí, àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run yóò máa wá oore Jèhófà. (Hóséà 3:5) Ámósì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé nǹkan tí Ọlọ́run sọ fún wa pé ká ṣe gan-an nìyẹn, ó ní: “Ẹ máa wá ohun rere, . . . kí ẹ bàa lè máa wà láàyè nìṣó.” Ó tún rọ̀ wá pé: ‘Ẹ nífẹ̀ẹ́ ohun rere.’ (Ámósì 5:14, 15) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìtura ni ṣíṣe ohun tí Jèhófà ń béèrè lọ́wọ́ wa yóò jẹ́ fún wa.
a Joseph Rotherham tó jẹ́ atúmọ̀ Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa orílẹ̀-èdè Kénáánì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ́ ìṣe wọn, ó ní: “Ìjọsìn wọn kún fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìwà ìkà tó burú jáì. Àwọn obìnrin wọn sọ ìwà mímọ́ nù láti bọ̀wọ̀ fún àwọn òrìṣà wọn. Bí ilé aṣẹ́wó làwọn ibi mímọ́ wọn rí. Gbangba-gbàǹgbà ni wọ́n fi àwọn àmì tí ń tini lójú ṣe àpẹẹrẹ ẹ̀yà ìbímọ ọkùnrin àti obìnrin. Àní wọ́n tún ní àwọn tí wọ́n kà sí aṣẹ́wó mímọ́ (!) lọ́kùnrin àti lóbìnrin.”
b Àwọn èèyàn Ọlọ́run ayé ọjọ́un tún ṣe àgbèrè tẹ̀mí. Wọ́n ń wá àjọṣe tí kò bófin mu pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè Kèfèrí, wọ́n sì ń ṣe àmúlùmálà ìjọsìn, wọ́n pa ìjọsìn Báálì pọ̀ mọ́ ìjọsìn mímọ́.