ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yp2 orí 18 ojú ìwé 150-155
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Lówó?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Lówó?
  • Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bó O Ṣe Lè Wá Iṣẹ́ Ṣe
  • Má Ṣàṣejù
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Wá Owó?
    Jí!—1998
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́ Owó Ná?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Èrò Tó Yẹ Ká Ní Nípa Owó
    Jí!—2015
  • Kí Ló Burú Nínú Wíwá Owó?
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
yp2 orí 18 ojú ìwé 150-155

ORÍ 18

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Lówó?

“Mo Nílò Owó láti fi ra mọ́tò.”—Sergio.

“Mo fẹ́ ra oríṣiríṣi nǹkan lọ́jà.”—Laurie-Ann.

“Àwọn nǹkan kan wà tó dáa tó wù mí pé kí n ní, àmọ́ àwọn òbí mi ò lówó tí wọ́n lè fi rà á fún mi.”—Mike.

Ó LÈ jẹ́ torí àwọn nǹkan tí ìwọ náà ṣe fẹ́ lówó lọ́wọ́ nìyẹn. Ó sì lè jẹ́ pé o fẹ́ ṣiṣẹ́ owó kó o lè fi ran ìdílé ẹ lọ́wọ́. Bó bá tiẹ̀ jẹ́ páwọn òbí ẹ ló ń dá gbọ́ bùkátà ìdílé, tó o bá ń ra aṣọ tàbí àwọn nǹkan míì fúnra ẹ, ìyẹn á dín owó tí wọ́n ń ná kù.

Kò sóhun tó o fẹ́ rà, bóyá fúnra ẹ tàbí fáwọn ará ilé ẹ, tó ò ní náwó lé lórí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù sọ pé Ọlọ́run máa pèsè fáwọn tó bá ‘ń wá ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́,’ Kristẹni kan ṣì ní láti lo ìdánúṣe láti pèsè fúnra ẹ̀. (Mátíù 6:33; Ìṣe 18:1-3; 2 Tẹsalóníkà 3:10) Torí náà, báwo lo ṣe lè lówó lọ́wọ́? Kí lo lè ṣe tó ò fi ní jẹ́ kó dí ẹ lọ́wọ́ láti máa jọ́sìn Ọlọ́run?

Bó O Ṣe Lè Wá Iṣẹ́ Ṣe

Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lo nílò nǹkan kan tágbára dádì tàbí mọ́mì ẹ ò gbé, o lè wáṣẹ́ ṣe kó o lè rà á fúnra ẹ. Sọ fún dádì tàbí mọ́mì ẹ pé o fẹ́ ṣiṣẹ́. Ó ṣeé ṣe kínú wọn dùn sí i. Bí wọ́n bá gbà pé o lè ṣiṣẹ́, àwọn àbá mẹ́rin kan rèé, tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ríṣẹ́.

Sọ fáwọn èèyàn. Sọ fáwọn ará ilé, àwọn olùkọ́ àtàwọn mọ̀lẹ́bí yín pé ò ń wáṣẹ́. Tójú bá ń tì ẹ́ láti sọ fún wọn, o lè dọ́gbọ́n bi wọ́n pé irú iṣẹ́ wo làwọn náà ṣe nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé bíi tìẹ. Báwọn èèyàn bá ṣe mọ̀ pé ò ń wáṣẹ́ tó, lo ṣe máa láǹfààní láti ríṣẹ́ tó.

Gbogbo àǹfààní tó bá wà ni kó o lò. Kọ̀wé sáwọn ilé iṣẹ́ tó bá polówó pé àwọn ń wá òṣìṣẹ́ nínú ìwé ìròyìn, lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, lára àwọn pátákó tí wọ́n ń kọ ìsọfúnni sí láwọn ilé ìtajà ńláńlá, níléèwé yín àti láwọn ibòmíì. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Dave sọ pé: “Bí mo ṣe ríṣẹ́ tí mò ń ṣe nìyẹn. Inú ìwé ìròyìn ni mo ti rí i pé wọ́n ń wá òṣìṣẹ́, ni mo bá fi ìwé ti mo kọ̀rọ̀ sí nípa iṣẹ́ tí mo lè ṣe ránṣẹ́ sí wọn, mo sì tún pè wọ́n lórí fóònù.” Bí ìyẹn ò bá sì bọ́ sí i, o lè jẹ́ káwọn tó lè gbà ẹ́ síṣẹ́ mọ̀ pé o níṣẹ́ tó o lè bá wọn ṣe.

Kọ àwọn ẹ̀rí tó wà pé o lè ṣiṣẹ́ sórí ìwé, kó o sì fún àwọn èèyàn. Kọ bí wọ́n ṣe lè kàn sí ẹ, iṣẹ́ tó o lè ṣe àtèyí tó o ti ṣe rí sórí ìwé kan. Àbí o rò pé kò sí nǹkan tó o lè kọ? Tún rò ó wò ná. Ṣé ìgbà kan wà, tí mọ́mì àti dádì ẹ ò sí nílé, tó o ti bójú tó àwọn àbúrò ẹ tàbí tó o ti bá ẹnì kan bójú tó ọmọ ẹ̀? Ìyẹn fi hàn pé o ṣeé fọkàn tán. Ṣó o ti bá dádì ẹ tún mọ́tò ṣe rí? Ìyẹn fi hàn pé o mọ ẹ̀rọ tún ṣe. Ṣó o lè fi ẹ̀rọ tẹ̀wé, àbí o mọ kọ̀ǹpútà lò? Àbí o ti gba máàkì tó pọ̀ rí níléèwé fún iṣẹ́ ọpọlọ kan tó o ṣe? Àwọn nǹkan rere táwọn tó fẹ́ gbà ẹ́ síṣẹ́ máa fẹ́ mọ̀ nípa ẹ nìyẹn. Kọ gbogbo ẹ̀ sórí ìwé tó o kọ àwọn ẹ̀rí tó o ní láti fi hàn pé o lè ṣiṣẹ́. Mú ìwé yẹn lọ fáwọn tó ṣeé ṣe kó gbà ẹ́ síṣẹ́, kó o sì tún fáwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn mọ̀lẹ́bí yín pé kí wọ́n bá ẹ fún ẹnikẹ́ni tó bá ń wá òṣìṣẹ́.

Ṣe iṣẹ́ tára ẹ. Ronú nípa àwọn ará àdúgbò yín. Ṣé iṣẹ́ kan wà tí kò sẹ́ni tó ń bá wọn ṣe é? Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o fẹ́ràn ohun ọ̀sìn, o lè ra àwọn òròmọdìyẹ, kó o máa sìn wọ́n, kó o sì tà wọ́n bí wọ́n bá dàgbà. Àbí àwọn nǹkan tí wọ́n fi ń kọrin lo mọ̀ ọ́n lò. Ṣó o lè kọ́ àwọn ẹlòmíì bí wọ́n ṣe lè lò ó? O sì lè lọ máa ṣiṣẹ́ táwọn èèyàn kì í sábà fẹ́ ṣe, irú bíi kó o máa báwọn èèyàn tún bàtà ṣe. Kò yẹ kójú ti Kristẹni láti fọwọ́ ara ẹ̀ ṣiṣẹ́. (Éfésù 4:28) Bó o bá fẹ́ máa ṣiṣẹ́ tara ẹ, o gbọ́dọ̀ máa fúnra ẹ níṣìírí, kó o máa kóra ẹ níjàánu, kó o sì máa lo ìdánúṣe.

Àmọ́ ṣá o, o gbọ́dọ̀ mọ nǹkan tí iṣẹ́ kan máa ná ẹ, kó o tó tọrùn bọ̀ ọ́! (Lúùkù 14:28-30) Kọ́kọ́ sọ fún dádì tàbí mọ́mì ẹ ná. Kó o sì tún béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíì tó ti ṣerú iṣẹ́ yẹn rí. Ṣó o máa ní láti sanwó orí? Àbí ìwé àṣẹ kan wà tó yẹ kó o gbà látọ̀dọ̀ ìjọba? Lọ béèrè ní ọ́fíìsì ìjọba tó bá wà ládùúgbò yín.—Róòmù 13:1.

Má Ṣàṣejù

Jẹ́ ká sọ pé o fẹ́ gun kẹ̀kẹ́, o sì láwọn ẹrù tó o fẹ́ gbé dání, bíi báàgì iléèwé, bọ́ọ̀lù, àtàwọn báàgì míì tó o kó àwọn ẹrù tó o rà lọ́jà sí. Báwọn ẹrù tó o bá fẹ́ kó bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa ṣòro fún ẹ tó láti gun kẹ̀kẹ́ yẹn! Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn tó o bá lọ ń ṣe iṣẹ́ tó ju agbára ẹ lọ. Bó o bá ń lo àkókò àti agbára tó pọ̀ jù lẹ́nu iṣẹ́ owó lẹ́yìn tó o bá dé láti iléèwé, ìyẹn lè ṣàkóbá fún ìlera àti iṣẹ́ iléèwé ẹ. Pàtàkì jù lọ ni pé, iṣẹ́ owó tó bá ń gbàkókò jù lè dí ẹ lọ́wọ́ láti máa lọ sáwọn ìpàdé ìjọ, ó lè dí ẹ lọ́wọ́ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì lè dí ẹ lọ́wọ́ òde ẹ̀rí. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Michèle sọ pé, “Mo ti pa ìpàdé jẹ rí dáadáa torí pé ó máa ń rẹ̀ mí tí n bá fi máa dé láti iléèwé àti ibiṣẹ́.”

Má ṣe jẹ́ kí ojú tó o fi ń wo owó sọ ẹ́ di aláṣejù! Jésù sọ pé “àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn” máa ní ojúlówó ayọ̀. (Mátíù 5:3) Ó tún sọ pé: “Nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.” (Lúùkù 12:15) Ìmọ̀ràn yìí ni ọ̀dọ́ Kristẹni kan tó ń jẹ́ Maureen fi sọ́kàn. Ó sọ pé: “Mi ò fẹ́ káwọn nǹkan tara gbà mí lọ́kàn jù. Ohun tí mo mọ̀ ni pé bí mo bá jẹ́ kí iṣẹ́ ajé gbà mí lọ́kàn jù, àjọṣe mi pẹ̀lú Ọlọ́run ló máa jìyà ẹ̀.”

Ká sòótọ́, láwọn ìlú kan lágbàáyé, àwọn ọ̀dọ́ ní láti ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ wákàtí, kí wọ́n lè ran dádì àti mọ́mì wọn lọ́wọ́ láti gbọ́ bùkátà ìdílé. Bí nǹkan ò bá burú tó bẹ́ẹ̀ yẹn níbi tó ò ń gbé, kí nìdí tó o fi wá fẹ́ sọra ẹ di aláṣejù? Àwọn ọ̀mọ̀wé kan tiẹ̀ sọ pé, èèyàn máa di aláṣejù, á sì tún máa ṣe àṣedànù tó bá ń lò ju ogún [20] wákàtí lọ lẹ́nu iṣẹ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, tó sì tún ń lọ síléèwé. Àwọn kan sì dábàá pé kò yẹ kéèyàn máa lò ju wákàtí mẹ́jọ sí mẹ́wàá lọ láti fi ṣiṣẹ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì sọ pé: “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.”—Oníwàásù 4:6.

Rántí pé, “agbára ìtannijẹ ọrọ̀” lè gba àwọn nǹkan tẹ̀mí mọ́ ẹ lọ́wọ́. (Máàkù 4:19) Torí náà, tó o bá fẹ́ máa ṣiṣẹ́ lẹ́yìn tó o bá ń ti iléèwé dé, àwọn nǹkan tẹ̀mí ni kó o fi sípò àkọ́kọ́ nínú ètò tó o bá ṣe. Gbàdúrà pé kí Jèhófà Ọlọ́run ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ó lè fún ẹ lágbára láti borí àwọn nǹkan tó bá fẹ́ dí ẹ lọ́wọ́, ó sì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ní àjọṣe rere pẹ̀lú rẹ̀.

KA PÚPỌ̀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 21, NÍNÚ APÁ KÌÍNÍ ÌWÉ YÌÍ

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Ṣé ìwọ lò ń ná owó ẹ, àbí owó ló ń ná ẹ? Mọ̀ nípa bó o ṣe lè máa fìrọ̀rùn náwó ẹ.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Ọ̀lẹ ń fọkàn fẹ́, ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ kò ní nǹkan kan. Bí ó ti wù kí ó rí, àní ọkàn àwọn ẹni aláápọn ni a óò mú sanra.”—Òwe 13:4.

ÌMỌ̀RÀN

Má ṣe dúró dìgbà táwọn ilé iṣẹ́ bá polówó pé àwọn ń wá òṣìṣẹ́ kó o tó fàwọn ìwé ẹ̀rí tó o ní ránṣẹ́.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Láwọn ibì kan, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ gba àwọn èèyàn sí ni wọn kì í polówó ẹ̀.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Ohun tí màá ṣe kí n lè tètè ríṣẹ́ ni pé ․․․․․

Àkókò tí màá máa fi ṣiṣẹ́ ò ní ju wákàtí lọ lọ́sẹ̀. ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣiṣẹ́ owó?

● Àwọn wàhálà wo lo lè rí tó o bá ń ṣiṣẹ́?

● Báwo lo ṣe lè máa fojú tó tọ́ wo owó?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 153]

“Bó o bá ń jẹ́ kó dìgbà tó o bá ra nǹkan tuntun kínú ẹ tó máa dùn, o ò lè láyọ̀. Torí gbogbo ìgbà ni nǹkan tuntun tó ò tíì ní á máa wù ẹ́. O gbọ́dọ̀ mọ béèyàn ṣe máa ń jẹ́ kí ohun tó bá ní tẹ́ ẹ lọ́rùn.”—Jonathan

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 155]

Mọyì Owó, Àmọ́ Má Ṣe Nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀

Irin iṣẹ́ tó wúlò ni ọ̀bẹ tó mú dáadáa lọ́wọ́ alásè. Àmọ́ ọ̀bẹ yìí kan náà lè ṣèpalára fẹ́ni tí ò dákan mọ̀, tàbí ẹni tí ò fọkàn sóhun tó ń ṣe. Bí ọ̀bẹ mímú lowó ṣe rí. Bó o bá lò ó dáadáa, irin iṣẹ́ tó wúlò ni. Àmọ́ bó ò bá ṣọ́ra, ó lè ṣe ẹ́ léṣe! Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé ká má ṣe nífẹ̀ẹ́ owó. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti sọ àwọn ọ̀rẹ́ wọn di ọ̀tá, tí wọ́n ti da ilé wọn rú, tí wọn ò sì ka àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run sí mọ́ torí pé wọ́n fẹ́ dolówó. Wọ́n wá fi “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.” (1 Tímótì 6:9, 10) Ẹ̀kọ́ wo lèyí kọ́ wa? Ó kọ́ wa pé ká máa fọgbọ́n náwó wa, ká mọyì owó, àmọ́ ká má ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 153]

Bó o bá ń wa nǹkan tó pọ̀ jù máyà, wàá di aláṣejù

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́